Ogun, Kẹ́rù ẹ
TIPẸ́TIPẸ́ ni àwọn èèyàn níbi gbogbo ti ń fọkàn fẹ́ ayé kan tí kò ní sí ogun. Àlá náà ò sì tíì ṣẹ. Bí a ṣe rí i nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà gbọ́ pé kìkì nípasẹ̀ ìjọba àgbáyé kan tí yóò ṣojú gbogbo ènìyàn ayé láìṣègbè ni àlàáfíà jákèjádò ayé yóò ti wá. Àmọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn ló mọ̀ pé àwọn alákòóso ènìyàn ò jẹ́ fínnúfíndọ̀ jọ̀wọ́ ipò àṣẹ wọn fún ìjọba kan tí ń ṣojú gbogbo èèyàn lágbàáyé. Ṣé ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé ìjọba àgbáyé kò lè ṣeé ṣe?
Ó lè jọ bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n, àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì fi hàn pé ìjọba kan tó ń bọ̀ wá ṣàkóso gbogbo àgbáyé ló máa mú àlàáfíà wá sórí ilẹ̀ ayé láìpẹ́. Èyí ò ní tìdí ìjíròrò láàárín ènìyàn tàbí nípasẹ̀ àdéhùn àjùmọ̀ṣe láàárín àwọn orílẹ̀-èdè wá. A mí sí wòlíì Dáníẹ́lì láti kọ̀wé pé: “Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ èyí tí a kì yóò run láé.”—Dáníẹ́lì 2:44.
Ìjọba yẹn náà ni Jésù ní kí àwọn ọmọlẹ́yìn òun máa gbàdúrà fún pé kó dé, nínú àdúrà tí ẹgbàágbèje èèyàn mọ̀ sí Àdúrà Olúwa, tàbí Baba Wa Tí Ń Bẹ ní Ọ̀run. Bóyá ìwọ náà tiẹ̀ mọ àdúrà yẹn, tó wà nínú Bíbélì, nínú ìwé Mátíù 6:9, 10. Apá kan nínú rẹ̀ jẹ́ ìjírẹ̀ẹ́bẹ̀ sí Ọlọ́run pé: “Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” Ọlọ́run yóò dáhùn àdúrà yẹn. Láìpẹ́, Ìjọba yẹn yóò “dé” láti mú ìfẹ́ Ọlọ́run fún orí ilẹ̀ ayé ṣẹ. Ó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run láti sọ àgbáyé di párádísè alálàáfíà.
Ìran Àlàáfíà Àgbáyé Tí Yóò Nímùúṣẹ
Ǹjẹ́ ìdí kankan wà tí a fi lè gbà gbọ́ pé Ìjọba Ọlọ́run yóò ṣàṣeyọrí ju èyí tí àwọn ìjọba ènìyàn ṣe lọ? Gbé apá mẹ́jọ nínú ohun tí Ìjọba Ọlọ́run yóò ṣe yẹ̀ wò, tí yóò fún àwọn tí yóò wà lábẹ́ rẹ̀ lálàáfíà pípẹ́ títí.
1. Jésù Kristi, “Ọmọ Aládé Àlàáfíà,” tí a ṣe lógo ni yóò jẹ́ aṣáájú tí Ọlọ́run yàn nínú Ìjọba náà. (Aísáyà 9:6) Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó fi hàn pé àwọn ìránṣẹ́ òun kì í dìhámọ́ra ogun. Ó wí fún Pétérù pé: “Dá idà rẹ padà sí àyè rẹ̀, nítorí gbogbo àwọn tí wọ́n bá ń mú idà yóò ṣègbé nípasẹ̀ idà.”—Mátíù 26:52.
2. Ní gidi, Ìjọba náà yóò jẹ́ àkóso àgbáyé. Dáníẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ nípa àṣẹ tí a fi lé Jésù lọ́wọ́ pé: “A sì fún un ní agbára ìṣàkóso àti iyì àti ìjọba, pé kí gbogbo àwọn ènìyàn, àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè àti àwọn èdè máa sin àní òun.”—Dáníẹ́lì 7:14.
3. Ìjọba náà yóò ṣojú fún gbogbo ènìyàn. Àwọn tí yóò ṣàkóso pẹ̀lú Jésù yóò wá “láti inú gbogbo ẹ̀yà àti ahọ́n àti àwọn ènìyàn àti orílẹ̀-èdè,” wọn yóò sì máa “ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lé ilẹ̀ ayé lórí.”—Ìṣípayá 5:9, 10.
4. Ìjọba Ọlọ́run yóò fòpin sí gbogbo ìjọba ènìyàn, tó kẹ̀yìn sí àṣẹ rẹ̀. “Ìjọba náà . . . yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn [ìjọba ènìyàn], òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Dáníẹ́lì 2:44.
5. Òfin kan náà ni yóò máa darí gbogbo èèyàn ayé. Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa àkókò yẹn pé: “Láti Síónì ni òfin ti jáde lọ, ọ̀rọ̀ Jèhófà yóò sì jáde lọ láti Jerúsálẹ́mù. Dájúdájú, òun yóò ṣe ìdájọ́ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, yóò sì mú àwọn ọ̀ràn tọ́ ní ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.”—Aísáyà 2:3, 4.
6. Àwọn ọmọ abẹ́ Ìjọba náà yóò kẹ́kọ̀ọ́ ọ̀nà àlàáfíà. Aísáyà ń bá a lọ pé: “Wọn yóò ní láti fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀, wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn. Wọn kì yóò gbé idà sókè, orílẹ̀-èdè lòdì sí orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.”—Aísáyà 2:4.
7. A óò ké àwọn tó nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá kúrò. “Jèhófà tìkára rẹ̀ ń ṣàyẹ̀wò olódodo àti ẹni burúkú, dájúdájú, ọkàn Rẹ̀ kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá. Òun yóò rọ̀jò pańpẹ́, iná àti imí ọjọ́ sórí àwọn ẹni burúkú àti ẹ̀fúùfù tí ń jóni gbẹ, gẹ́gẹ́ bí ìpín ife wọn.”—Sáàmù 11:5, 6.
8. Ohun ìjà yóò kásẹ̀ nílẹ̀. “Ẹ wá wo àwọn ìgbòkègbodò Jèhófà, bí ó ti gbé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ayanilẹ́nu kalẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Ó mú kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀ títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé. Ó ṣẹ́ ọrun sí wẹ́wẹ́, ó sì ké ọ̀kọ̀ sí wẹ́wẹ́; ó sun àwọn kẹ̀kẹ́ nínú iná.”—Sáàmù 46:8, 9.
Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Ká Gba Ìlérí Ọlọ́run Gbọ́? —Báwo Sì Ni A Ṣe Lè Ṣe É?
Bíbélì sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nǹkan púpọ̀ sí i nípa Ìjọba Ọlọ́run. Fún àpẹẹrẹ, ó sọ nípa àwọn tí yóò wà pẹ̀lú Jésù Kristi láti darí ọ̀ràn ayé. Ó tún sọ nípa bí a ṣe yàn wọ́n àti àwọn ohun tó mú wọn tóótun. Bíbélì tún sọ nípa bí Ìjọba náà yóò ṣe bójú tó àwọn ohun àmúṣọrọ̀ ilẹ̀ ayé lọ́nà tí gbogbo èèyàn ayé yóò fi ní aásìkí àti ayọ̀, tí yóò sì mú ìlara àti ìwọra tó sábà máa ń fa ìforígbárí kúrò.
Ǹjẹ́ ó yẹ ká gba irú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ gbọ́? Jèhófà fúnra rẹ̀ sọ pé: “Ọ̀rọ̀ mi tí ó ti ẹnu mi jáde . . . kì yóò padà sọ́dọ̀ mi láìní ìyọrísí, ṣùgbọ́n ó dájú pé yóò ṣe èyí tí mo ní inú dídùn sí, yóò sì ní àṣeyọrí sí rere tí ó dájú nínú èyí tí mo tìtorí rẹ̀ rán an.” (Aísáyà 55:11) Gbólóhùn yìí tún wúwo ju ọ̀rọ̀ ìdánilójú lásán pé Ọlọ́run máa ń mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ lọ. Jèhófà ni Alágbára Ńlá Gbogbo, nítorí náà, ó ní agbára láti mú kí àlàáfíà wà jákèjádò ayé. Kò sí ohun tó ré kọjá òye rẹ̀; nítorí náà, ó ní ọgbọ́n tí ó lè fi mú kí àlàáfíà máa wà lọ. (Aísáyà 40:13, 14) Síwájú sí i, Jèhófà ni àpẹẹrẹ ìfẹ́ gan-an, nítorí náà, kò sẹ́ni náà lágbàáyé tó ní ìfẹ́-ọkàn tó ju ìyẹn lọ láti mú àlàáfíà wá.—1 Jòhánù 4:8.
Àmọ́ ṣá o, a nílò ìgbàgbọ́ láti lè gba àwọn ìlérí Ọlọ́run gbọ́. Orí ìmọ̀ ni a gbé ìgbàgbọ́ kà, a sì lè ní in tí a bá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Fílípì 1:9, 10) Bí a ti ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ànímọ́ Ọlọ́run àti ète rẹ̀, ìjótìítọ́ Ìjọba Ọlọ́run yóò hàn gbangba sí wa. Bẹ́ẹ̀ ni, a óò rẹ́yìn ogun, kì í ṣe nípasẹ̀ agbára èèyàn, bí kò ṣe nípasẹ̀ ìjọba àgbáyé ológo kan tí Ọlọ́run jẹ́ alátìlẹ́yìn rẹ̀, ìyẹn ni Ìjọba Ọlọ́run.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18, 19]
Nínú Ìjọba Ọlọ́run, àwọn ọmọ abẹ́ ìjọba náà yóò kẹ́kọ̀ọ́ àlàáfíà, ohun ìjà ò sì ní sí mọ́