ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwbq àpilẹ̀kọ 25
  • Báwo Ni Àlàáfíà Ṣe Máa Wà ní Ayé?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ni Àlàáfíà Ṣe Máa Wà ní Ayé?
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ogun, Kẹ́rù ẹ
    Jí!—1999
  • Ẹ Jẹ Ki “Alaafia Ọlọrun” Maa Daabobo Ọkan-aya Yin
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Àlàáfíà Tòótọ́—Láti Orísun Wo?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Máa Wá Àlàáfíà Tòótọ́, Kí O Sì Máa Lépa Rẹ̀!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
Àwọn Míì
Ohun Tí Bíbélì Sọ
ijwbq àpilẹ̀kọ 25
Àwọn èèyàn oríṣiríṣi ẹ̀yà

Báwo Ni Àlàáfíà Ṣe Máa Wà ní Ayé?

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Kì í ṣe ìsapá àwọn èèyàn ló máa mú kí àlàáfíà wà ní ayé, Ìjọba Ọlọ́run ni. Èyí jẹ́ ìjọba ọ̀run tí Jésù Kristi máa jẹ́ olórí rẹ̀. Wo bí Bíbélì ṣe kọ́ wa nípa ìrétí àgbàyanu yìí.

  1. Ọlọ́run máa mú “kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀ títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé,” á sì tipa báyìí mú ìlérí tó ṣe ṣẹ pé òun máa mú kí àlàáfíà wà ní ayé láàárín “àwọn ẹni tí inú Ọlọ́run dùn sí.”—Sáàmù 46:9; Lúùkù 2:14, Ìròyìn Ayọ̀.

  2. Ìjọba Ọlọ́run máa ṣàkóso láti ọ̀run lórí gbogbo ayé. (Dáníẹ́lì 7:14) Ìjọba kan ṣoṣo tó kárí ayé yìí máa mú kí ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni dópin, ìfẹ́ yìí ló sábà máa ń dá ìjà sílẹ̀.

  3. Bíbélì pe Jésù, tó jẹ́ Alákòóso Ìjọba Ọlọ́run, ní “Ọmọ Aládé Àlàáfíà” tó máa rí sí i pé “àlàáfíà kì yóò lópin.”—Isaiah 9:6, 7.

  4. Ọlọ́run kò ní jẹ́ kí àwọn tó fẹ́ máa jà gbé lábẹ́ Ìjọba náà, torí pé “ọkàn [Ọlọ́run] kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá.”—Sáàmù 11:5; Òwe 2:22.

  5. Ọlọ́run ń kọ́ àwọn ọmọ abẹ́ ìjọba rẹ̀ ní béèyàn ṣe ń gbé ìgbé ayé àlàáfíà. Nígbà tí Bíbélì ń ṣàpèjúwé ohun tí ẹ̀kọ́ yìí máa yọrí sí, ó sọ pé: “Wọn yóò ní láti fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀, wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn. Orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.”—Aísáyà 2:3, 4.

Ní báyìí, ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé ló ń kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Ọlọ́run nípa bí wọ́n ṣe lè jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà. (Mátíù 5:9) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a wá láti inú onírúurú ẹ̀yà, tá a sì ń gbé ní àwọn ilẹ̀ tí iye wọn lé ní igba àti ọgbọ̀n [230], a ti pinnu pé a ò ní gbé ohun ìjà sókè sí èèyàn bí i tiwa.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ọ̀nà àlàáfíà lónìí

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́