ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 4/22 ojú ìwé 4-7
  • Ta Ló Lè Mú Àlàáfíà Pípẹ́ Títí Wá?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ta Ló Lè Mú Àlàáfíà Pípẹ́ Títí Wá?
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Dídín Àwọn Nǹkan Ogun Kù
  • Òwò Ohun Ìjà Ogun Jákèjádò Àwọn Orílẹ̀-Èdè
  • Ohun Ìhalẹ̀ Ọ̀gbálẹ̀gbáràwé Ṣì Wà Níbẹ̀
  • Gbígbé Ohun Ìjà Ogun Tì àti Àlàáfíà
  • Ìbáradíje Ẹ̀yà Ìran Ń Pọ̀ Sí I
  • Àwọn Ìṣòro Tí Ń Rọ̀ Dẹ̀dẹ̀
  • Àwọn Wo Ló Ń Gbára Dì fún Ogun Ọ̀gbálẹ̀gbáràwé?
    Jí!—2004
  • Ǹjẹ́ Ogun Ọ̀gbálẹ̀gbáràwé Ṣì Ń Bọ̀ Wá Jà?
    Jí!—2004
  • Ó Dájú Pé Ewu Ohun Ìjà Ọ̀gbálẹ̀gbáràwé Kò Tíì Kásẹ̀ Nílẹ̀
    Jí!—1999
  • Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ogun Tí Wọ́n Á Fi Bọ́ǹbù Átọ́míìkì Jà?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 4/22 ojú ìwé 4-7

Ta Ló Lè Mú Àlàáfíà Pípẹ́ Títí Wá?

“Wọn óò fi idà wọn rọ ọ̀bẹ-plau, wọn óò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ dòjé; orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè; bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ ogun jíjà mọ́.”

Ọ̀RỌ̀ ẹsẹ ìwé mímọ́ òkè yìí wá láti inú Isaiah orí 2, ẹsẹ̀ 4, nínú ẹ̀dà Bibeli ti King James. Ìròyìn Human Development Report 1994, tí Ètò Ìdàgbàsókè Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè (UNDP) gbé jáde, ló fa ọ̀rọ̀ wọ̀nyí yọ. Ó sì fi kún un pé: “Ó jọ pé àkókò àsọtẹ́lẹ̀ yìí ti dé pẹ̀lú òpin ogun tútù [ní 1990]. Àmọ́, títí di báyìí, ó ti fara hàn gẹ́gẹ́ bí ìrètí tí kò ní ìmúṣẹ.”

Dídín Àwọn Nǹkan Ogun Kù

Kókó abájọ kan tí ń fawọ́ ìrètí àlàáfíà sẹ́yìn ni pé a kò tí ì mú dídín iye tí a ń ná sórí ohun ìjà ogun kù bá ìyípadà nínú ipò ìṣèlú káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè dọ́gba. Lótìítọ́, wọ́n ti dín in kù díẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìṣirò tí àjọ UN gbé jáde, iye tí wọ́n ná sórí ohun ìjà ogun lágbàáyé tí lọ sílẹ̀ láti iye kàbìtì ti 995 bílíọ̀nù dọ́là, tí ó ju ti ìgbàkígbà rí lọ, tí ó wà ní 1987 sí 815 bílíọ̀nù dọ́là ní 1992. Síbẹ̀, iye tí ó pọ̀ jọjọ ṣì ni 815 bílíọ̀nù dọ́là jẹ́. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ bá àpapọ̀ iye tí ń wọlé fún ìdajì gbogbo àwọn olùgbé ayé dọ́gba!

Kókó abájọ mìíràn tí ń da gbígbé ohun ìjà ogun tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan rú ni ojú ìwòye pé ó ṣeé ṣe kí àwọn nǹkan ogun mú ààbò wá. Nípa bẹ́ẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ogun Tútù ti dópin, ọ̀pọ̀ ènìyàn ní àwọn orílẹ̀-èdè onílé iṣẹ́ ẹ̀rọ ń jiyàn pé ó yẹ kí owó tí wọ́n ń ná lórí ààbò orílẹ̀-èdè pọ̀ gan-an. Nígbà tí James Woolsey jẹ́ olùdarí Ibùdó Ìsọfúnni Àpapọ̀ ní United States, ó sọ fún Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ní February 1993 pé: “A ti dúḿbú dírágónì ńlá kan [U.S.S.R.], ṣùgbọ́n a ń gbé inú igbó ńlá tí ó kún fún onírúurú ejò olóró tí ń dani láàmú báyìí.”

Ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, wọ́n tún dá nínáwó púpọ̀ lórí ohun ìjà ogun láre gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà láti paná ìgbéjàkò tí ó bá ń ti ọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n kà sí èyí tí ó lè jẹ́ dírágónì àti ejò olóró wá. Ṣùgbọ́n ní ti gidi, ètò UNDP sọ pé, “àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà ti bá àwọn orílẹ̀-èdè òkèèrè díẹ̀ jagun, púpọ̀ lára wọn sì ti lo àwọn agbo ọmọ ogun wọn láti ká àwọn ènìyàn wọn lọ́wọ́ kò.” Ní tòótọ́, ìròyìn ètò UNDP náà ṣàlàyé pé: “Ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, ṣíṣeéṣe pé kí ènìyàn kú nítorí àìṣe ohun tí ó yẹ nípa ètò ìfẹ́dàáfẹ́re (lọ́wọ́ àìjẹunrekánú àti àwọn àrùn tí ó ṣeé dènà) fi ìgbà 33 pọ̀ ju ṣíṣeéṣe pé kí ènìyàn kú nínú ogun tí ìwà jàgídíjàgan láti ẹ̀yìn odi ìlú fà. Síbẹ̀, ní ìpíndọ́gba, àwọn sójà pọ̀ ju àwọn oníṣègùn lọ lọ́nà 20. Lọ́nà kan tàbí òmíràn, ó ṣeé ṣe kí àwọn sójà máa dín ààbò tí àwọn ènìyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ní kù ju kí wọ́n mú un pọ̀ sí i lọ.”

Òwò Ohun Ìjà Ogun Jákèjádò Àwọn Orílẹ̀-Èdè

Nígbà tí Ogun Tútù ń lọ lọ́wọ́, àwọn orílẹ̀-èdè alágbára ńlá méjèèjì ń ta ohun ìjà ogun fún àwọn alájọṣepọ̀ kí àjọṣepọ̀ wọn lè fìdí múlẹ̀ gbọnyin, kí wọ́n lè jèrè ìtìlẹ́yìn ìgbẹ́kẹ̀lé ológun, kí wọ́n sì lè máa wà ní ipò agbára nìṣó. Agbára àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ń légbá kan sí i. Fún àpẹẹrẹ, ní lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí, ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn orílẹ̀-èdè 33 ní ọkọ̀ ológun tí ó lé ní 1,000.

Ní báyìí tí Ogun Tútù ti dópin, ìdáláre ọgbọ́n ìwéwèé àti ìṣèlú fún títa àwọn ohun ìjà ogun ti jó rẹ̀yìn. Síbẹ̀, ìsúnniṣe ti ètò ọrọ̀ ajé ṣì lágbára. Àǹfààní ni ó jẹ́ láti pawó wọlé! Nítorí náà, bí ìbéèrè fún ohun aṣọṣẹ́ lábẹ́lé ti ń dín kù, àwọn tí ń ṣe ohun ìjà ogun ń rọ àwọn alákòóso wọn pé ọ̀nà àtidáàbò bo iṣẹ́, kí a sì mú kí ọrọ̀ ajé wà dáadáa, ni títa àwọn ohun ìjà ogun sí ilẹ̀ òkèèrè.

Ìwé ìròyìn World Watch sọ pé: “Lọ́nà tí ó ta kora, bí àwọn orílẹ̀-èdè alágbára ńlá ṣe ń fawọ́ àwọn ohun aṣọṣẹ́ ọ̀gbálẹ̀gbáràwé wọn sẹ́yìn, wọ́n ń yára wá ọ̀nà láti ta púpọ̀ sí i lára àwọn bọ́m̀bù àti ìbọn alábọ́ọ́dé wọn fún ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ láti rà.” Èló ni ó tó? Gẹ́gẹ́ bí Ibùdó Ìwádìí Àlàáfíà Káàkiri Àwọn Orílẹ̀-Èdè ní Stockholm ti sọ, iye àwọn ohun ìjà alábọ́ọ́dé tí wọ́n tà sí àwọn orílẹ̀-èdè káàkiri láàárín ọdún 1988 sí 1992 jẹ́ 151 bílíọ̀nù dọ́là. United States ni orílẹ̀-èdè tí ó ta ohun ìjà sí ilẹ̀ òkèèrè jù lọ, tí àwọn orílẹ̀-èdè Soviet Union tẹ́lẹ̀rí sì tẹ̀ lé e.

Ohun Ìhalẹ̀ Ọ̀gbálẹ̀gbáràwé Ṣì Wà Níbẹ̀

Ọ̀ràn ti ohun ìhàlẹ̀ ọ̀gbálẹ̀gbáràwé ń kọ́? United States àti Soviet Union (tàbí àwọn orílẹ̀-èdè tí ó jáde láti inú rẹ̀) fọwọ́ sí Àdéhùn Àgbá Alọmájìnnà Ọ̀gbálẹ̀gbáràwé ní 1987 àti Àwọn Àdéhùn Ìmúdínkù Àwọn Ohun Ìjà Ogun Alọjìnnà (START) méjì ní ọdún 1991 àti 1993.

Àdéhùn START fòfin de àwọn ohun ìjà ogun orí ilẹ̀ tí ó ní ju àfọ̀njá aṣọṣẹ́ kan ṣoṣo lọ, ó sì ṣòfin mímú nǹkan bí ìdámẹ́ta nínú mẹ́rin kúrò lára gbogbo àwọn ìhùmọ̀ tí ó lè gbé àfọ̀njá aṣọṣẹ́ ọ̀gbálẹ̀gbáràwé, tí yóò bá fi di ọdún 2003. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìhalẹ̀ Ogun Àgbáyé Kẹta tí ó jẹ́ ọ̀gbálẹ̀gbáràwé mọ́ni ti ń pòórá, ọ̀pọ̀ ibi ìtọ́júpamọ́ ohun ìjà ogun ọ̀gbálẹ̀gbáràwé—tí ó pọ̀ tó láti pa gbogbo ìwàláàyè lórí ilẹ̀ ayé run lọ́pọ̀ ìgbà, ló ṣì wà.

Títú àwọn ohun ìjà ogun wọ̀nyí ká yóò túbọ̀ ṣí àyè sílẹ̀ fún ṣíṣàfọwọ́rá ohun ìjà ogun ọ̀gbálẹ̀gbáràwé. Fún àpẹẹrẹ, Rọ́ṣíà ń ṣe ìtúpalẹ̀, ó sì ń kó nǹkan bí 2,000 àfọ̀njá aṣọṣẹ́ jọ lọ́dún, ó sì tún ń jèrè àwọn ègé roboto èròjà plutonium, tí ń jẹ́ pit, tí kò ju ìkúùkù lọ. Àfọ̀njá pit kan, tí ń gba ìnáwó àti ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ púpọ̀ láti ṣe é, ni lájorí èròjà inú bọ́m̀bù ọ̀gbálẹ̀gbáràwé kan. Níwọ̀n bí àwọn pit ti máa ń wà nínú akóló onírin tí ó máa ń dènà ìtújáde ìgbì olóró gíga, olè kan lè jí ọ̀kan gbé sá lọ nínú àpò rẹ̀. Apániláyà kan tí ó ní pit tí a ti ṣe sílẹ̀ lè wá gbé ohun asúnnásí ìbúgbàù kan tì í láti tún ṣẹ̀dá bọ́m̀bù ńlá ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ kan.

Àníyàn míràn ni ti ewu títan àwọn ohun ìjà ogun ọ̀gbálẹ̀gbáràwé kálẹ̀ lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè púpọ̀ púpọ̀ sí i. A mọ àwọn orílẹ̀-èdè márùn-ún sí òléwájú nínú ohun ìjà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé—China, Faransé, Rọ́ṣíà, United Kingdom, àti United States—a sì tún ronú pé àwọn orílẹ̀-èdè bíi mélòó kan ní agbára láti yára lo àwọn ohun ìjà ogun ọ̀gbálẹ̀gbáràwé.

Bí àwọn orílẹ̀-èdè púpọ̀ púpọ̀ sí i ṣe ń sapá láti ra àwọn ohun ìjà ogun ọ̀gbálẹ̀gbáràwé, ṣíṣeéṣe pé ẹnì kan yóò lò wọ́n ń pọ̀ sí i. Àwọn ènìyàn ní ìdí tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ láti bẹ̀rù lílo àwọn ohun ìjà ogun ṣíṣàrà-ọ̀tọ̀ yìí. Gẹ́gẹ́ bí ìwé The Transformation of War ti sọ ọ́, “agbára wọn kàmàmà débi tí wọ́n mú kí àwọn ohun ìjà alábọ́ọ́dé dà bí àwàdà lásán.”

Gbígbé Ohun Ìjà Ogun Tì àti Àlàáfíà

Àmọ́ bí àwọn orílẹ̀-èdè yóò bá kó àwọn ohun ìjà aṣèparun dídíjú wọn dànù ń kọ́? Ǹjẹ́ ìyẹn yóò mú ayé alálàáfíà dáni lójú bí? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Òpìtàn ogun John Keegan sọ pé: “Àwọn ohun ìjà ogun ọ̀gbálẹ̀gbáràwé kò tí ì pa ẹnikẹ́ni láti August 9, 1945. Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn 50,000,000 tí ogun ti pa láti ìgbà yẹn, ni ó jẹ́ pé àwọn ohun ìjà ogun pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́, tí ó wọ́ pọ̀ àti àwọn ohun ìdìhámọ́ra ẹlẹ́nu róbótó kékeré, tí iye wọn fi díẹ̀ ju ti àwọn rédíò àti àwọn bátìrì tí ó ya wọ àgbáyé nígbà yẹn kan náà lọ́hùn-ún, ni ó pa wọ́n.”

Àpẹẹrẹ lọ́ọ́lọ́ọ́ kan ti lílo àwọn ohun ìjà ogun tí kò la iṣẹ́ ẹ̀rọ aládàá ńlá lọ ni ti ìpànìyàn tí ó ṣẹlẹ̀ ní Rwanda, orílẹ̀-èdè tí gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia (1994) sọ nípa rẹ̀ pé: “Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ènìyàn ibẹ̀ jẹ́ Roman Kátólíìkì. . . . Roman Kátólíìkì àti àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kristian mìíràn ní ń darí ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti ilé ẹ̀kọ́ gíga níbẹ̀.” Síbẹ̀, àwọn tí ó tó ìdajì mílíọ̀nù ni àwọn ènìyàn fi àdá pa ní Rwanda. Ó hàn kedere pé, láti mú àlàáfíà àgbáyé wá, a nílò ohun kan tí ó ju dídín àwọn ohun ìjà alábọ́ọ́dé àti ti ọ̀gbálẹ̀gbáràwé kù lọ. Bákan náà, a nílò ohun tí ó yàtọ̀ sí àwọn ẹ̀kọ́ tí àwọn ìsìn ayé ń fi kọ́ni.

Ìbáradíje Ẹ̀yà Ìran Ń Pọ̀ Sí I

Sadako Ogata, ọ̀gá alábòójútó ọ̀ràn àwọn olùwá-ibi-ìsádi ti àjọ UN, sọ láìpẹ́ yìí pé: “Gbàrà lẹ́yìn Ogun Tútù, a lérò pé a óò yanjú gbogbo ìṣòro náà ni. A kò mọ̀ pé Ogun Tútù náà ní apá mìíràn nínú—pé àwọn orílẹ̀-èdè alágbára ńlá pàṣẹ tàbí fipá ṣòfin fún ẹ̀ka tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ń darí. . . . Nítorí náà, nísinsìnyí lẹ́yìn Ogun Tútù, a ń rí ìbẹ́sílẹ̀ ìforígbárí ẹ̀yà ìran, ẹ̀yà ìbílẹ̀, tí kò kúrò lójú kan, tí ó lè jẹ́ irú ti ìṣáájú Ogun Àgbáyé Kìíní, tí ń pọ̀ sí i.”

Arthur Schlesinger, òpìtàn àti òǹkọ̀wé tí ó gba ẹ̀bùn Pulitzer, sọ kókó ọ̀rọ̀ kan náà: “Ọ̀wọ́ ìkórìíra kan ń rọ́pò òmíràn. Jíjọ̀wọ́ ìwàmú dan-indan-in ti ìgbáwọlẹ̀ ìjẹ́wọ́ èrò ní Ìlà Oòrùn Europe àti Soviet Union tẹ́lẹ̀rí mú ìdojúùjàkọ ẹ̀yà ìran, orílẹ̀-èdè, ìsìn, àti èdè tí a ti gbá wọlẹ̀ tẹ́lẹ̀rí, èyí tí gbòǹgbò rẹ̀ wà nínú ìtàn àti nínú ọpọlọ rọjú. . . . Bí ọ̀rúndún ogún bá ti jẹ́ ọ̀rúndún tí ó kún fún àwọn ogun ìjẹ́wọ́ èrò, ọ̀rúndún kọkànlélógún yóò bẹ̀rẹ̀ bí ọ̀rúndún àwọn ogun ẹ̀yà ìran.”

Gẹ́gẹ́ bí ìṣirò kan tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ṣe, ogun 82 ló jà láàárín 1989 sí 1992, wọ́n sì ja ọ̀pọ̀ lára wọn láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà. Ní 1993, orílẹ̀-èdè 42 forí gbárí lọ́nà lílé kenkà, àwọn orílẹ̀-èdè 37 mìíràn sì nírìírí rògbòdìyàn ìṣèlú. Láàárín àkókò náà, Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè—tí owó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tán lápò rẹ̀—tiraka láti mú àlàáfíà wá ní kìkì ibi 17 péré tí ó ṣe ètò ológun sí, kò sì kẹ́sẹjárí púpọ̀. Ó ṣe kedere pé, aráyé gbọ́dọ̀ yíjú sí ibòmíràn fún àlàáfíà àgbáyé.

Àwọn Ìṣòro Tí Ń Rọ̀ Dẹ̀dẹ̀

Dípò kí àwọn ènìyàn máa fi ẹ̀mí nǹkan-yóò-dára wo ọjọ́ iwájú, ọ̀pọ̀ lára wọn ń fi èrò pé ibi ń bọ̀ hàn. Èèpo iwájú ìtẹ̀jáde The Atlantic Monthly, February 1994, ṣàkópọ̀ ìsọtẹ́lẹ̀ kan nípa ẹ̀wádún tí ń bọ̀ pé: “Àwọn orílẹ̀-èdè ń wó palẹ̀ nítorí ìrọ́wọlé àwọn olùwá-ibi-ìsádi tí ìjábá àyíká àti ti ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà ń lé kúrò látìgbàdégbà. . . . Àwọn ènìyàn ń jagun nítorí àwọn ohun àmúṣọrọ̀ tí ó ṣọ̀wọ́n, ní pàtàkì omi, ogun fúnra rẹ̀ ń bá a lọ pẹ̀lú ìwà ọ̀daràn, bí agbo ẹgbẹ́ àwọn onísùnmọ̀mí adìhámọ́ra tí a kò mọ orílẹ̀-èdè wọn ti ń kọlura pẹ̀lú agbo ọmọ ogun àdáni àwọn ọ̀tọ̀kùlú ọlọ́lá tí ń pèsè ààbò.”

Èyí ha túmọ̀ sí pé àlàáfíà pípẹ́ títí kò lè bọ́ sí i bí? Kí a máà rí i! Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀ lé e fi ìdí tí a fi lè wo ọjọ́ iwájú pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé hàn.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 5]

Ìsìn—Aṣètìlẹ́yìn fún Àlàáfíà Ni Bí?

Nígbà tí àwọn orílẹ̀-èdè bá lọ sí ogun, àwọn ìsìn ayé máa ń fọwọ́ rọ́ àwọn ẹ̀kọ́ nípa àlàáfíà àti ẹgbẹ́ ará sẹ́yìn. Ọmọ ilẹ̀ Britain náà, ọ̀gágun Frank P. Crozier, sọ nípa bí nǹkan ti rí nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní pé: “Àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì Kristian ni onígbọ̀wọ́ dídára jù lọ tí a ní fún ìtàjẹ̀sílẹ̀, a sì ń lò wọ́n fàlàlà.”

Ipa tí ìsìn ń kó nínú ogun jẹ́ ọ̀kan náà jálẹ̀jálẹ̀ gbogbo sànmánì. Òpìtàn Kátólíìkì náà, E. I. Watkin, jẹ́wọ́ pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò báradé láti gbà, a kò lè torí ìtọ́ni èké tí ìsìn ń fún wa tàbí nítorí ìdúróṣinṣin ti ìsìn lọ́nà àìṣòótọ́, kí a wá sẹ́ tàbí kí a kọtí ikún sí òkodoro tí ó wà nínú ìtàn pé àwọn Bíṣọ́ọ̀bù tí ṣètìlẹ́yìn délẹ̀délẹ̀ fún gbogbo ogun tí ìjọba ilẹ̀ wọn gbé dìde.” Ọ̀rọ̀ olóòtú kan nínú ìwé ìròyìn Sun ti Vancouver, Kánádà, sọ pé: “Bóyá, àbùkù tí gbogbo ìsìn tí a gbé kalẹ̀ ní ni pé kí ṣọ́ọ̀ṣì máa gbá tẹ̀ lé àsíá . . . Ogun wo ni ó jà rí tí a kò tí ì sọ pé Ọlọrun wà ní ìhà méjèèjì?”

Ó hàn kedere pé, dípò kí àwọn ìsìn ayé jẹ́ ìpa àlàáfíà, wọ́n ti ṣonígbọ̀wọ́ fún ogun àti ìpànìyàn—bí ìpànìyàn tí ó ṣẹlẹ̀ ní Rwanda ti ṣàpẹẹrẹ rẹ̀ lọ́nà tí ó lágbára.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]

Ìmúlẹ̀mófo Ogun

Nínú ìwe I Found No Peace, tí a ṣe jáde ní 1936, aṣojúkọ̀ròyìn ilẹ̀ òkèèrè náà, Webb Miller, kọ̀wé pé: “Ó yani lẹ́nu pé ìjábá ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ ìgbà [Ogun Àgbáyé Kìíní], pẹ̀lú gbogbo àlùfààṣá àti ìmúlẹ̀mófo púpọ̀ jọjọ tí ó mú lọ́wọ́, kò fi bẹ́ẹ̀ wọ̀ mí lára títí wá di ọdún mẹ́jọ géérégé lẹ́yìn tí ó ti parí.” Ní àkókò yẹn ni ó ṣèbẹ̀wò sí pápá ogun ti Verdun, níbi tí ó sọ pé 1,050,000 ènìyàn kú sí.

Miller kọ̀wé pé: “Nígbà ogun náà, wọ́n tan èmi àti àràádọ́ta ọ̀kẹ́ mìíràn jẹ. Ogun Àgbáyé náà ti kẹ́sẹjárí kìkì láti máa mú àwọn ogun tuntun jáde. Àwọn ènìyàn mílíọ̀nù mẹ́jọ ààbọ̀ ti kú dànù, mílíọ̀nù mẹ́wàá-mẹ́wàá ti jìyà ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ tí kò ṣeé fẹnu sọ, ọgọ́rọ̀ọ̀rún mílíọ̀nù ti rí ìbànújẹ́, ìfiǹkan-duni, àti àìláyọ̀. Gbogbo èyí sì ṣẹlẹ̀ pẹ̀lú ìtannijẹ tí ó kọ sísọ.”

Ọdún mẹ́ta lẹ́yìn tí wọ́n ṣe ìwé yìí jáde ni Ogun Àgbáyé Kejì bẹ̀rẹ̀. Ìwé agbéròyìnjáde The Washington Post sọ pé, “àwọn ogun tí ó bẹ́ sílẹ̀ ní ọ̀rúndún ogún tiwa ti jẹ́ ‘ogun gbogbogbòò’ tí a bá àwọn ológun àti àwọn aráàlú pẹ̀lú jà. . . . Àwọn ogun abẹ́lé tí ó ti jà ní àwọn ọ̀rúndún sẹ́yìn kò tó nǹkan tí a bá fi wéra.” Gẹ́gẹ́ bí ìfojúdíwọ̀n tí ògbógi kan ṣe, mílíọ̀nù 197 ènìyàn ló ti kú nínú àwọn ogun àti ìṣọ̀tẹ̀ sí àwọn alákòóso ìlú láti 1914 wá.

Síbẹ̀, gbogbo àwọn ogun àti ìṣọ̀tẹ̀ tí àwọn ènìyàn ń ṣe sí àwọn alákòóso ìlú kò tí ì mú àlàáfíà tàbí ayọ̀ wá. Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde The Washington Post ti sọ: “Kò tí ì sí ètò ìgbékalẹ̀ ìṣèlú tàbí ti ọrọ̀ ajé tí ó tí ì pẹ̀tù sí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn afàjàngbọ̀n lọ́kàn tàbí kí ó tẹ́ wọn lọ́rùn ní ọ̀rúndún yìí.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ìyá yìí jẹ́ ọ̀kan lára ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún ènìyàn tí wọ́n pa ní Rwanda—ọ̀pọ̀ láti ọwọ́ mẹ́ḿbà ìsìn tiwọn fúnra wọn

[Credit Line]

Albert Facelly/Sipa Press

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́