Ọdún Ìsapá Òtúbáńtẹ́
“ÀWA ÈNÌYÀN ÌPARAPỌ̀ ÀWỌN ORÍLẸ̀-ÈDÈ TI PINNU láti gba àwọn ìran tí ń bọ̀ lẹ́yìn là kúrò lọ́wọ́ ìyà ogun, tí ó ti mú ìbànújẹ́ tí kò ṣe é fẹnu sọ wá fún aráyé nígbà méjì ní àkókò ìgbésí ayé wa, àti láti tún mú ìgbàgbọ́ nínú àwọn ìpìlẹ̀ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, nínú iyì àti ìtóye ẹ̀dá ènìyàn, nínú ẹ̀tọ́ ọgbọọgba tọkùnrin-tobìnrin àti ti àwọn orílẹ̀-èdè ńlá àti kéékèèké dáni lójú, . . . ”—Ọ̀rọ̀ àkọ́sọ ti Ìwé Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè.
OCTOBER 24, 1995, sàmì sí àjọ̀dún àádọ́ta ọdún Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè. Ó di dandan fún gbogbo àwọn Orílẹ̀-Èdè 185 tí wọ́n jẹ́ mẹ́ḿbà ní lọ́ọ́lọ́ọ́ láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà àti góńgó ìpilẹ̀ṣẹ̀ ti ètò-àjọ náà, gẹ́gẹ́ bí a ti là á lẹ́sẹẹsẹ nínú ìwé àjọ náà pé: láti rí i pé àlàáfíà àti ààbò jọba láàárín àwọn orílẹ̀-èdè; láti ki àwọn ìṣe oníjàgídíjàgan tí ń wu àlàáfíà ayé léwu wọlẹ̀; láti fún àjọṣepọ̀ ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè níṣìírí; láti dáàbò bo òmìnira ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí gbogbogbòò ní láìsí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà tí a gbé karí ẹ̀yà ìran, ẹ̀yà akọ tàbí abo, èdè, tàbí ìsìn; àti kí ọwọ́ lè tó ìfọwọ́sowọ́pọ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè nínú yíyanjú àwọn ìṣòro ọrọ̀ ajé, ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà, àti àṣà ìbílẹ̀.
Fún 50 ọdún, ètò-àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ti ṣe àwọn ìsapá pípẹtẹrí láti mú àlàáfíà àti ààbò àgbáyé wá. A lè jiyàn rẹ̀ pé, ó ti lè dènà ogun àgbáyé kẹta, àti pé a kò tí ì ṣe àṣetúnṣe ìparun tìrìgàngàn ti ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn nípasẹ̀ lílo bọ́m̀bù alágbára átọ́míìkì. Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ti pèsè oúnjẹ àti egbòogi fún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ọmọdé. Ó ti ṣèrànwọ́ láti mú ipò ìlera sunwọ̀n sí i ní orílẹ̀-èdè púpọ̀, lára àwọn nǹkan mìíràn, ó ń pèsè omi mímú tí ó dára sí i àti abẹ́rẹ́ àjẹsára lòdì sí àwọn àrùn tí ó léwu. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn olùwá-ibi-ìsádi ti rí ìtìlẹ́yìn afẹ́dàáfẹ́re gbà.
Ní kíka àwọn àṣeparí rẹ̀ sí, a ti fún ètò-àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ní Ẹ̀bùn Àlàáfíà ti Nobel nígbà márùn-ún. Àmọ́, òtítọ́ gidi tí ó múni kédàárò náà ni pé, a kò tí ì máa gbé nínú ayé kan láìsí ogun síbẹ̀síbẹ̀.
Àlàáfíà àti Ààbò—Góńgó Tí Ọwọ́ Kò Tí ì Tó
Lẹ́yìn ìsapá àádọ́ta ọdún, àlàáfíà àti ààbò ṣì jẹ́ góńgó tí ọwọ́ kò tí ì tó. Nínú ọ̀rọ̀ kan sí Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè láìpẹ́ yìí, ààrẹ United States sọ ìjákulẹ̀ rẹ̀ jáde, nígbà tí ó sọ pé, “ọ̀rúndún yìí tí ó kún fún ìrètí àti àǹfààní àti àṣeyọrí tún ti jẹ́ sànmánì ìparun gígadabú àti amúnisọ̀rètínù.”
Bí 1994 ṣe ń parí, ìwé ìròyìn The New York Times ṣàkíyèsí pé: “Nǹkan bí 150 ogun àti ìjà fẹ́ẹ́rẹ́ ń lọ lọ́wọ́, nínú èyí tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn ti ń kú—ìṣirò tí ó pọ̀ jù lọ fi hàn pé àwọn ará ìlú ń kú ju àwọn sójà lọ—ọgọ́rọ̀ọ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún sì ń di olùwá-ibi-ìsádi.” Ẹ̀ka Ìsọfúnni Gbogbogbòò Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ròyìn pé, láti 1945, iye tí ó lé ní 20 mílíọ̀nù ènìyàn ti pàdánù ìwàláàyè wọn nítorí ìforígbárí ohun ìjà ogun. Aṣojú U.S. nínú Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, Madeleine Albright, ṣàkíyèsí pé, “ìforígbárí ẹlẹ́kùnjẹkùn ti túbọ̀ rorò sí i ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà.” Títẹ àwọn ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lójú àti kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà ni ìròyìn ojoojúmọ́. Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè dà bí ẹni ń fara dà á fún ara wọn, kàkà kí wọ́n máa bá ara wọn lẹ́nì kíní-kejì ṣọ̀rẹ́.
Ọlọ́lá David Hannay, aṣojú Britain nínú Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, gbà pé “títí di àwọn ọdún 1980, Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ti fẹ́rẹ̀ẹ́ mọ̀ọ́mọ̀ di ìjákulẹ̀.” Akọ̀wé àgbà Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, Boutros Boutros-Ghali, kédàárò pé ìdágunlá àti àárẹ̀ ń pọ̀ sí i láàárín àwọn Orílẹ̀-Èdè tí wọ́n jẹ́ mẹ́ḿbà, nígbà tí ó bá di ti àwọn ìgbòkègbodò mímú kí àlàáfíà jọba. Ó parí rẹ̀ pé, lójú ọ̀pọ̀ àwọn mẹ́ḿbà náà, “Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè kì í ṣe ohun tí ó ṣe pàtàkì jù lọ.”
Ipa Ìdarí Àwọn Ilé Iṣẹ́ Ìròyìn
Bí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ti fi hàn pé òun lágbára tó, ìṣèlú àti àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn ti ké ìsapá rẹ̀ nígbèrí lọ́pọ̀ ìgbà. Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè di aláìlágbára bí kò bá ní ìtìlẹ́yìn àwọn mẹ́ḿbà rẹ̀. Ṣùgbọ́n bí gbogbo ènìyàn kò bá fọwọ́ sí i, ọ̀pọ̀ mẹ́ḿbà ètò-àjọ UN kì yóò kọ́wọ́ ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè lẹ́yìn. Fún àpẹẹrẹ, gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn àtìgbàdégbà The Wall Street Journal ṣe sọ, “àwọn ìkùnà tí ó gba àfiyèsí jù lọ ní Somalia àti Bosnia ti mú kí ọ̀pọ̀ àwọn ará America gbà pé ètò-àjọ náà kì í wulẹ̀ ṣe òfò nìkan, ṣùgbọ́n pé ó léwu ní ti gidi.” Ìṣarasíhùwà gbogbogbòò yìí yí àwọn òṣèlú America kan lérò padà láti pète dídín ìtìlẹ́yìn ìnáwó tí U.S. ń fún Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè kù.
Àwọn ètò-àjọ ìròyìn kì í lọ́ra láti ṣe lámèyítọ́ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè lọ́nà líle koko. Àwọn ọ̀rọ̀ bí “àìtóótun pátápátá,” “adẹ́rùpọkọ̀,” “aláìjáfáfá,” àti “aláìlágbára” ni a ti lò láìṣẹ́nupo nígbà tí a bá ń ṣàpèjúwe onírúurú apá ẹ̀ka àwọn ìgbòkègbodò ètò-àjọ UN. Ìwé ìròyìn àtìgbàdégbà The Washington Post National Weekly Edition sọ láìpẹ́ yìí pé, “Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ti di ilé iṣẹ́ ayọ́gínní tí ń jìjàkadì láti mú ara rẹ̀ bá ipò àgbáyé mu ni ti gidi.”
Ìwé agbéròyìnjáde mìíràn fa ọ̀rọ̀ Akọ̀wé Àgbà Boutros Boutros-Ghali yọ bí ó ṣe ń sọ ìjákulẹ̀ rẹ̀ jáde ní ti ìpakúpa ní Rwanda. Ó wí pé: “Kì í ṣe Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè nìkan ni ó kùnà; ó jẹ́ ìkùnà fún àpapọ̀ àwùjọ káàkiri orílẹ̀-èdè. Gbogbo wa ni a sì jẹ̀bi ìkùnà yìí.” Ní 1993, gbajúmọ̀ àkànṣe ìròyìn orí tẹlifíṣọ̀n kan sọ pé Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè “ti kùnà láti dáwọ́ ìwuléwu títóbi jù lọ fún àlàáfíà dúró—ìtànkálẹ̀ ohun ìjà átọ́míìkì.” Ètò orí tẹlifíṣọ̀n náà sọ nípa Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè kan pé “lọ́nà púpọ̀ jùlọ ẹnu lásán nìkan ni ó ní fún àwọn ẹ̀wádún.”
Ìmọ̀lára ìjákulẹ̀ tí ó tàn kálẹ̀ yìí ń da èrò inú àwọn lọ́gàá-lọ́gàá Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè rú, ó sì ń fi kún ìkùnà wọn. Síbẹ̀, láìka àwọn ìkùnà náà sí, nígbà ayẹyẹ àádọ́ta ọdún Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, ó dà bí ẹni pé ọ̀pọ̀ ní ẹ̀mí-nǹkan-yóò-dára tí a sọ dọ̀tun, wọ́n sì ń retí ìbẹ̀rẹ̀ titun. Bí ó tilẹ̀ tẹ́wọ́ gba àwọn àlèébù Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, Aṣojú Albright sọ àwọn èrò ìmọ̀lára ọ̀pọ̀ ènìyàn ní àsọtúnsọ nígbà tí o wí pé: “Ó yẹ kí a dẹ́kun sísọ̀rọ̀ nípa ohun tí a ti ṣe sẹ́yìn, kí a sì sọ̀rọ̀ nípa ibi tí a ń lọ.”
Bẹ́ẹ̀ ni, níbo ni ayé ń lọ? Ayé kan láìsí ogun yóò ha wà bí? Bí yóò bá rí bẹ́ẹ̀, ipa wo ni Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè yóò kó nínú rẹ̀? Jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí o bá jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọrun, ó yẹ kí o béèrè pé, ‘Ipa wo ni Ọlọrun yóò kó nínú rẹ̀?’
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 4]
ÀWỌN ÌSAPÁ ÒTÚBÁŃTẸ́
Kò lè sí àlàáfíà àti ààbò bí ogun, òṣì, ìwà ipá, àti ìwà ìbàjẹ́ bá ṣì wà. Láìpẹ́ yìí ni Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè gbé àwọn ìsọfúnni oníṣirò wọ̀nyí jáde.
Ogun: “Nínú ìforígbárí 82 nípa ohun ìjà ogun láàárín 1989 sí 1992, 79 jẹ́ ti abẹ́lé, ọ̀pọ̀ jẹ́ ti ẹ̀yà ìran kan sí èkejì; ìpín 90 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tí wọ́n jìyà rẹ̀ jẹ́ ará ilú.”—Ẹ̀ka Ìsọfúnni Gbogbogbòò Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè (UNDPI)
Ohun Ìjà Ogun: “Ìgbìmọ̀ ICRC [Ìgbìmọ̀ Ẹgbẹ́ Alágbèélébùú Pupa Káàkiri Orílẹ̀ Èdè] fojú ṣírò pé, àwọn olùṣèmújáde tí ó lé ní 95, ní àwọn orílẹ̀-èdè 48, ń ṣe nǹkan bíi mílíọ̀nù 5 sí 10 ohun abúgbàù láti dojú ìjà kọ àwọn ológun lọ́dọọdún.”—Kọmíṣọ́nnà Àgbà fún Àwọn Olùwá-Ibi-Ìsádi ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè (UNHCR)
“Ní Africa, nǹkan bí 30 mílíọ̀nù ohun abúgbàù wà tí a fọ́n ká àwọn orílẹ̀-èdè tí ó lé ní 18.—UNHCR
Òṣì: “Kárí ayé, ẹnì kan nínú ènìyàn márùn-ún—iye tí ó lé ní billion kan lápapọ̀—ń gbé ní ipò tí ó rẹlẹ̀ sí ipò òṣì, àwọn tí a sì fojú díwọ̀n sí mílíọ̀nù 13 sí mílíọ̀nù 18 ni àwọn àrùn tí òṣì ń fà ń ṣekú pa lọ́dọọdún.”—UNDPI
Ìwà Ọ̀daràn: “Ìwà ọ̀daràn tí a fi sùn ti pọ̀ sí i ní ìpíndọ́gba ìpìn 5 nínú ọgọ́rùn-ún kárí ayé lọ́dọọdún, láti àwọn ọdún 1980; ní USA nìkan, mílíọ̀nù 35 ìwà ọ̀daràn ni a ń hù lọ́dọọdún.”—UNDPI
Ìwà Ìbàjẹ́: “Ìwà ìbàjẹ́ àwọn aláàkòso ti ń wọ́pọ̀ níbi gbogbo. Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, jìbìtì ìṣúnná owó ni a fojú díwọ̀n pé ó lè máa ná wọn ní iye tí ó dọ́gba pẹ̀lú ìpín 10 nínú ọgọ́rùn-ún àpapọ̀ ohun tí a ń mú jáde lábẹ́lé ní àwọn orílẹ̀-èdè náà lọ́dọọdún.”—UNDPI