Ayé kan Láìsí Ogun—Nígbà Wo?
ÌWÉ ÀJỌ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní October 24, 1945. Òun ṣì ni ọgbọ́n ìwéwèé gbígbòòrò jù lọ tí ẹ̀dá ènìyàn tí ì wéwèé rí fún àlàáfíà àgbáyé. Pẹ̀lú àwọn Orílẹ̀-Èdè 51 tí wọ́n jẹ́ mẹ́ḿbà rẹ̀ ní ìpilẹ̀ṣẹ̀, Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè di ètò àjọ títóbi jù lọ kárí ayé nínú ìtàn àgbáyé. Bákan náà, fún ìgbà àkọ́kọ́, ètò àjọ kan kárí ayé yóò ní agbára láti lo ẹgbẹ ọmọ ogun láti mú kí àlàáfíà àti ààbò jọba, kí ó sì mú ayé kan láìsí ogun wá.
Lónìí, pẹ̀lú Orílẹ̀-Èdè 185 tí ó jẹ́ mẹ́ḿbà rẹ̀, Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè lágbára ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Nígbà náà, èé ṣe tí ètò àjọ kárí ayé, tí ó lágbára jù lọ nínú ìtàn, fi kùnà láti ṣàṣeparí ète rere rẹ̀ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́?
Ìsìn—Ohun Ìdènà Ńláǹlà
Olórí ohun tí ó fa ìlọ́júpọ̀ ni ipa tí ìsìn ń kó nínú àlámọ̀rí ayé. Lóòótọ́, láti ìgbà ìdásílẹ̀ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, àwọn ìsìn kàǹkà-kàǹkà ní ayé ti jẹ́jẹ̀ẹ́ ìtìlẹ́yìn wọn fún ètò àjọ náà. Nígbà tí ó ń tọ́ka sí ayẹyẹ àádọ́ta ọdún rẹ̀, Póòpù John Paul II sọ nípa Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè gẹ́gẹ́ bí “irinṣẹ́ títayọ lọ́lá jù lọ fún gbígbé àlàáfíà lárugẹ àti pípa á mọ́.” Àpapọ̀ àwùjọ àwọn aṣáájú ìsìn lágbàáyé ṣàjọpín èrò ìmọ̀lára rẹ̀. Ṣùgbọ́n ìsopọ̀ tímọ́tímọ́ ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́ yìí láàárín ìsìn àti ìjọba kò lè fi òkodoro òtítọ́ náà pamọ́ pé, ìsìn ti jẹ́ ohun ìdènà àti ìyọnu fún Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè.
Fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, ìsìn ti kó ipa pàtàkì nínú gbígbé ìkórìíra ẹlẹ́mìí ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni, ogun, àti ìparun ẹ̀yà lárugẹ tàbí ṣíṣe ìtìlẹ́yìn fún wọn. Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, lábẹ́ ìbòjú ìgbónára ìsìn, àwọn aládùúgbò ti pa ara wọn lẹ́nì kíní-kejì. Ọ̀rọ̀ náà “pípa ẹ̀yà ìran run” ni a ti lò lọ́nà gbígbòòrò ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ogun ní àwọn ilẹ̀ Balkan. Bí ó ti wù kí ó rí, ìkórìíra oníwà ipá tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí ó wà níbẹ̀ ní fún ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì ní a gbé karí ìsopọ̀ pẹ̀lú ìsìn dípò ẹ̀yà ìran, níwọ̀n bí púpọ̀ jù lọ nínú wọn ti wá láti inú ẹ̀yà ìran kan náà. Bẹ́ẹ̀ ni, ìsìn gbọ́dọ̀ gba èyí tí ó pọ̀ jù lọ nínú ẹ̀bi fún ìfẹ̀jẹ̀wẹ̀ ní Yugoslavia tẹ́lẹ̀ rí, kò sì tí ì ṣeé ṣe fún Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè láti dá a dúró.
Lọ́nà tí ó bá a mu gẹ́ẹ́, ọ̀jọ̀gbọ́n nípa ìsìn ní kọ́lẹ́ẹ̀jì kan láìpẹ́ yìí sọ pé, “nínú ayé ẹ̀yìn ogun tútù, níbi tí ogun ìsìn tí ń pọ̀ sí i wà, ṣíṣàyẹ̀wò ìsìn àti ìparun ẹ̀yà lè jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun pàtàkì tí ó jẹ́ kánjúkánjú jù lọ fún wa, láìka ìnira tí ń mú wá sí.” Òye tuntun nípa bí ìsìn ṣe ń ké àwọn ìsapá àlàáfíà àgbáyé nígbèrí hàn gbangba lónìí.
Ní 1981, ìkéde ètò àjọ UN kà pé: “Nítorí àníyàn lórí àìráragba-nǹkan-sí àti nítorí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà tí ń bẹ nínú ọ̀ràn ìsìn tàbí ìgbàgbọ́ tí ó ṣì hàn kedere ní àwọn agbègbè kan nínú ayé, A pinnu láti lo gbogbo ọgbọ́n tí ó bá pọndandan fún títètè mú irú àìráragba-nǹkan-sí bẹ́ẹ̀ ní onírúurú rẹ̀ àti bí ó ti ń jẹyọ kúrò, kí a dènà kí a sì gbógun ti kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà lórí ọ̀ràn ìsìn àti èrò ìgbàgbọ́.”
Ní ìbámu pẹ̀lú ìkéde wọn, Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ti pe 1995 ní Ọdún Ìráragba-Nǹkan-Sí. Ṣùgbọ́n, kí a kúkú sọjú abẹ níkòó, yóò ha lè ṣeé ṣe láé pé kí ọwọ́ tó àlàáfíà àti ààbò nínú ayé kan tí ìsìn tí pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ bí?
Ọjọ́ Ọ̀la Ìsìn
Àsọtẹ́lẹ̀ kan nínú Bibeli nínú ìwé Ìṣípayá pèsè ìdáhùn náà. Ó sọ̀rọ̀ nípa “aṣẹ́wó ńlá” kan, tí ó jókòó bí “ọbabìnrin,” tí ó sì ní “ìjọba kan lórí awọn ọba ilẹ̀-ayé.” Aṣẹ́wó yìí ń gbé nínú “fàájì aláìnítìjú,” ó sì ní àṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn ìjọba ayé. Àwọn ìjọba ayé wọ̀nyí ni a ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí “ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò,” èyí tí aṣẹ́wó náà ń gùn pẹ̀lú ìdẹ̀ra. (Ìṣípayá 17:1-5, 18; 18:7) Alágbára obìnrin àti oníwà àìmọ́ yìí, tí a mọ̀ sí “Babiloni Ńlá,” ni a sọ ní orúkọ Babiloni ìgbàanì, ibi tí ìsìn ìbọ̀rìṣà ti bẹ̀rẹ̀. Lọ́nà tí ó bá a mu wẹ́kú, aṣẹ́wó náà, lónìí, ń ṣojú fún gbogbo ìsìn àgbáyé, tí ó ti dara pọ̀ nínú àlámọ̀rí àwọn ìjọba.
Àkọsílẹ̀ náà ń bá a nìṣó ní sísọ pé, nígbà tí àkókò bá tó, Ọlọrun yóò fi í sínú ọkàn àwọn ológun, tí wọ́n jẹ́ apá kan ẹranko ẹhànnà náà, láti gbé ìgbésẹ̀. Àwọn wọ̀nyí “yoo kórìíra aṣẹ́wó naa wọn yoo sì sọ ọ́ di ìparundahoro ati ìhòòhò, wọn yoo sì jẹ awọn ibi kìkìdá ẹran-ara rẹ̀ tán wọn yoo sì fi iná sun ún pátápátá.” (Ìṣípayá 17:16)a Jehofa Ọlọrun fúnra rẹ̀ yóò tipa báyìí lo ìdánúṣe nípa dídarí àwọn orílẹ̀-èdè alágbára sínú ìgbétáásì kan láti mú ìsìn èké kúrò. Ètò ìgbékalẹ̀ ìsìn káàkiri àgbáyé, pẹ̀lú àwọn tẹ́ḿpìlì àti ojúbọ rẹ̀ tí ó pinmirin, ni a óò sọ dahoro pátápátá. Ìdènà ìsìn láti fìdí àlàáfíà àti ààbò múlẹ̀ ni a óò mú kúrò lọ́nà. Ṣùgbọ́n nígbà yẹn pàápàá, àlàáfíà àti ààbò gidi yóò ha wà lórí ilẹ̀ ayé bí?
Àbùdá Ẹ̀dá Ènìyàn Aláìpé
Ẹ̀rí kan tí ó dájú ha wà pé kíkásẹ̀ ìsìn kúrò nílẹ̀ yóò ṣamọ̀nà sí ayé kan láìsí ogun bí? Rárá o. Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè yóò máa bá a nìṣó láti dojú kọ ipò tí a kò retí. Ní apá kan, àwọn ènìyàn ń fẹ́ àlàáfíà àti ààbò. Síbẹ̀, ní òdìkejì, àwọn ènìyàn náà ni wọ́n ń wu àlàáfíà àti ààbò léwu lọ́nà tí ó ga lọ́lá. Ìkórìíra, ìgbéraga, ìgbéra-ẹni-lárugẹ, imọtara-ẹni-nìkan, àti àìmọ̀kan ni àwọn ànímọ́ ẹ̀dá ènìyàn tí ó wà nídìí gbogbo ìforígbárí àti ogun.—Jakọbu 4:1-4.
Bibeli sọ tẹ́lẹ̀ pé ní ọjọ́ wa, àwọn ènìyàn yóò jẹ́ “olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, ajọra-ẹni-lójú, onírera, asọ̀rọ̀-òdì, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìdúróṣinṣin, aláìní ìfẹ́ni àdánidá, aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan, afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere, afinihàn, olùwarùnkì, awúfùkẹ̀ pẹlu ìgbéraga.”—2 Tim. 3:1-4.
Àkọ̀wé Àgbà Boutros Boutros-Ghali gbà pé, “ayé ń jìyà lọ́wọ́ rògbòdìyàn ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà àti ti ọ̀nà ìwà híhù, tí ó ti dé ìwọ̀n gíga ní ọ̀pọ̀ àwùjọ.” Kò sí bí ọgbọ́n mẹ̀bẹ́mẹ̀yẹ̀ ti lè pọ̀ tó, tí ó lè pẹ̀tù sí àwọn ìwà àbùdá ẹ̀dá ènìyàn aláìpé.—Fi wé Genesisi 8:21; Jeremiah 17:9.
Jesu Kristi—Ọmọ Aládé Àlàáfíà
Ó hàn gbangba pé, Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè kò ní agbára láti mú àlàáfíà àgbáyé wá. Gbogbo mẹ́ḿbà àti alátìlẹ́yìn rẹ̀ jẹ́ ẹ̀dá ènìyàn aláìpé, láìka àwọn góńgó wọn gíga fíofío sí. Bibeli sọ pé, “ọ̀nà ènìyàn kò sí ní ipa ara rẹ̀: kò sí ní ipa ènìyàn tí ń rìn láti tọ́ ìṣísẹ̀ rẹ̀.” (Jeremiah 10:23) Síwájú sí i, Ọlọrun kìlọ̀ pé: “Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ yín lé àwọn ọmọ aládé, àní lé ọmọ ènìyàn, lọ́wọ́ ẹni tí kò sí ìrànlọ́wọ́.”—Orin Dafidi 146:3.
Bibeli sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tí Jehofa yóò ṣàṣeparí rẹ̀ nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀, “Ọmọ Aládé Àlàáfíà.” Isaiah 9:6, 7 sọ pé: “A bí ọmọ kan fún wa, a fi ọmọkùnrin kan fún wa: ìjọba yóò sì wà ní èjìká rẹ̀: a óò sì máa pe orúkọ rẹ̀ ní Ìyanu, Olùdámọ̀ràn, Ọlọrun Alágbára, Baba Ayérayé, Ọmọ Aládé Àlàáfíà. Ìjọba yóò bí sí i, àlàáfíà kì yóò ní ìpẹ̀kun.”
Àádọ́ta ọdún àwọn ìsapá òtúbáńtẹ́ ti sú àwọn orílẹ̀-èdè ayé. Láìpẹ́, wọn yóò pa ètò àjọ ìsìn tí ó dà bí aṣẹ́wó run. Lẹ́yìn náà, Jesu Kristi, “Ọba awọn ọba ati Oluwa awọn oluwa,” àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀, àwọn jagunjagun òkè ọ̀run, yóò tú gbogbo ìjọba ẹ̀dá ènìyàn ká, wọn yóò sì pa gbogbo àwọn tí wọ́n bá kọ ipò ọba aláṣẹ Ọlọrun run. (Ìṣípayá 19:11-21; fi wé Danieli 2:44.) Ní ọ̀nà yìí, Jehofa Ọlọrun yóò mú ayé kan láìsí ogun wá.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ó jinlẹ̀ sí i nínú àsọtẹ́lẹ̀ Ìṣípayá nípa Babiloni Ńlá náà, wo àwọn orí 33 sí 37 ìwé náà, Revelation—Its Grand Climax At Hand!, tí a tẹ̀ jáde ní 1988, láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 7]
OJÚ ÌWÒYE KRISTIAN NÍPA ÌPARAPỌ̀ ÀWỌN ORÍLẸ̀-ÈDÈ
Nínú àsọtẹ́lẹ̀ Bibeli, a sábà máa ń fi àwọn ẹranko ẹhànnà ṣàpẹẹrẹ àwọn ìjọba ẹ̀dá ènìyàn. (Danieli 7:6, 12, 23; 8:20-22) Nípa bẹ́ẹ̀, fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún, ìwé ìròyìn Ilé-Ìṣọ́nà ti fi àwọn ẹranko ẹhànnà inú Ìṣípayá orí 13 àti 17 hàn gẹ́gẹ́ bí ìjọba ayé lónìí. Èyí ní Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè nínú, tí a ṣàpèjúwe rẹ̀ nínú Ìṣípayá orí 17 gẹ́gẹ́ bí ẹranko aláwọ̀ rírẹ̀dòdò, tí ó ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá.
Bí ó ti wù kí ó rí, ipò tí Ìwé Mímọ́ fi hàn yìí kò fàyè gba àìlọ́wọ̀ èyíkéyìí fún àwọn ìjọba tàbí òṣìṣẹ́ wọn. Bibeli sọ kedere pé: “Kí olúkúlùkù ọkàn wà lábẹ́ awọn aláṣẹ onípò gíga, nitori kò sí ọlá-àṣẹ kankan àyàfi lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun; awọn ọlá-àṣẹ tí ó wà ni a gbé dúró sí awọn ipò wọn aláàlà lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun. Nitori naa ẹni tí ó bá tako ọlá-àṣẹ ti mú ìdúró kan lòdì sí ìṣètò Ọlọrun; awọn wọnnì tí wọ́n ti mú ìdúró kan lòdì sí i yoo gba ìdájọ́ fún ara wọn.”—Romu 13:1‚ 2.
Ní ọ̀nà tí ó ṣe wẹ́kú, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, tí wọ́n ń pa àìdásí tọ̀túntòsì nínú ọ̀ràn ìṣèlú mọ́ láìgba gbẹ̀rẹ́, kì í tojú bọ ọ̀ràn àwọn ìjọba ẹ̀dá ènìyàn. Wọ́n kì í ru ìyípadà tegbò tigaga tàbí ṣíṣàìgbọràn sí ìjọba sókè. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọn gbà pé irú ọ̀nà ìṣèjọba kan pọndandan láti lè rí i pé òfin àti àṣẹ jọba láwùjọ ẹ̀dá ènìyàn.—Romu 13:1-7; Titu 3:1.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń fi ojú kan náà tí wọ́n fi ń wo àwọn ilé iṣẹ́ ìjọba mìíràn, tí ó jẹ́ ti ayé, wo ètò àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè. Wọ́n gbà pé Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ń bá a lọ láti máa wà nípasẹ̀ ìyọ̀ọ̀da Ọlọrun. Ní ìbámu pẹ̀lú Bibeli, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń fún gbogbo ìjọba ní ọ̀wọ̀ tí ó yẹ, wọ́n sì ń ṣègbọràn sí wọn níwọ̀n ìgbà tí irú ìgbọràn bẹ́ẹ̀ kò bá béèrè pé kí wọ́n dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọrun.—Ìṣe 5:29.