ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 8/1 ojú ìwé 3-4
  • Àwọn Èèyàn Ń wá Ìjọba Rere

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Èèyàn Ń wá Ìjọba Rere
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ni?
  • “Àlàáfíà Kì Yóò Lópin”
    Jí!—2019
  • Ọdún Ìsapá Òtúbáńtẹ́
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Kí Ló Máa Kẹ́yìn Ogun?
    Jí!—1999
  • A Rí Ojútùú Ohun Ìjìnlẹ̀ Kan Tó Ṣeni Ní Kàyéfì
    Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 8/1 ojú ìwé 3-4

Àwọn Èèyàn Ń wá Ìjọba Rere

“Bí gbogbo ayé ṣe túbọ̀ ń di ọ̀kan ṣoṣo báyìí ti fa onírúurú ìṣòro kárí ayé, àwọn ìṣòro náà pọ̀ débi pé orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan ò lè dá yanjú wọn mọ́. Àyàfi tí gbogbo èèyàn tó wà láyé bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀ nìkan la fi lè kojú àwọn ewu tó túbọ̀ ń pọ̀ sí i àtàwọn ìṣòro tó dojú kọ aráyé.”—Ghulam Umar, ọmọ ilẹ̀ Pakistan tó jẹ́ olùṣe atótónu lórí ọ̀ràn òṣèlú, ló sọ ọ̀rọ̀ yìí.

Ọ̀RÀN kàyéfì kún inú ayé gan-an lóde òní. Owó àti nǹkan ìní pọ̀ jaburata, síbẹ̀ náà agbára káká làwọn kan fi ń gbọ́ bùkátà ara wọn. Àwa èèyàn tó ń gbé lákòókò tí ìmọ̀ nípa ohun abánáṣiṣẹ́ gbòde kan yìí ni a lè sọ pé ó kàwé jù lọ, tó sì nímọ̀ jù lọ nínú gbogbo èèyàn tó tíì gbé ayé títí di bá a ti ń wí yìí, síbẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ni kò rọrùn fún rárá láti ríṣẹ́ kan pàtó. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òmìnira táwọn èèyàn ní báyìí dà bí èyí tó pọ̀ ju ti ìgbàkígbà rí lọ, síbẹ̀ ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló ń gbé nínú ìbẹ̀rù àti àìsí ìfọ̀kànbalẹ̀. A lè láǹfààní láti ríṣẹ́ tó ń mówó wọlé dáadáa, àmọ́ ìwà ìbàjẹ́ àti ìwà ta-ló-máa-mú-mi tó gbòde kan ti sọ ọ̀pọ̀ èèyàn dẹni tí kò retí pé ọ̀la ń bọ̀ wá dára.

Àwọn ìṣòro tó dojú kọ aráyé pọ̀ gan-an débi pé ó ti kọjá ohun tí orílẹ̀-èdè kan, tàbí àwùjọ àwọn orílẹ̀-èdè pàápàá lè yanjú. Abájọ tí ọ̀pọ̀ àwọn tó ń kíyè sí ohun tó ń lọ fi sọ pé kí àlàáfíà àti ààbò tó lè wà, gbogbo orílẹ̀-èdè gbọ́dọ̀ pawọ́ pọ̀ kí wọ́n fìmọ̀ ṣọ̀kan lábẹ́ ìjọba kan ṣoṣo. Bí àpẹẹrẹ, ó ti pẹ́ gan-an tí Albert Einstein tí ń sọ̀rọ̀ nípa irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Ohun tó sọ ní ọdún 1946 ni pé: “Ó dá mi lójú hán-únhán-ún pé ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn èèyàn tó wà láyé ló máa fẹ́ láti gbé níbi tó ní àlàáfíà àti ààbò . . . Gbígbé ìjọba kan tó kárí ayé kalẹ̀ nìkan ló lè mú káwọn èèyàn rí àlàáfíà tọ́kàn wọn ń fẹ́.”

Ó ti lé ní àádọ́ta ọdún báyìí tó ti sọ̀rọ̀ yìí, síbẹ̀ ọwọ́ àwọn èèyàn ò tíì tẹ nǹkan pàtàkì tó jẹ wọ́n lógún yìí. Nígbà tí ìwé ìròyìn Le Monde ti Paris, nílẹ̀ Faransé mẹ́nu kan àwọn ìṣòro ọ̀rúndún kọkànlélógún lọ́kan-ò-jọ̀kan, àpilẹ̀kọ náà sọ pé: “Ńṣe ló yẹ ká gbé ètò ìdájọ́, ètò ìṣàkóso, àti ètò ìṣòfin tó jẹ́ ti ìjọba kan tó kárí ayé kalẹ̀, tó jẹ́ pé ojú ẹsẹ̀ ni yóò máa dá sí ọ̀ràn pípa ẹ̀yà kan nípakúpa, níbikíbi tí irú ẹ̀ bá ti wáyé. Ó tún ṣe pàtàkì láti gbà pé láti ìsinsìnyí lọ, orílẹ̀-èdè kan ṣoṣo ni Ayé yìí jẹ́.” Ta ló lágbára láti ṣe èyí, tó sì tóótun láti rí sí i pé ìran ènìyàn ní àlàáfíà lọ́jọ́ iwájú?

Ṣé Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ni?

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló retí pé àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ló máa mú àlàáfíà ayé wá. Ṣé àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ni ìjọba tó máa mú àlàáfíà àti ààbò tòótọ́ wá sórí ilẹ̀ ayé? Ní ti tòótọ́, ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ dídùndídùn tó jẹ́ mọ́ ọ̀ràn ìṣèlú ni àjọ yìí ti sọ, èyí tó jọ ohun tó ń gbéni ró tó sì fini lọ́kàn balẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Àpéjọ Gbogbo Gbòò ti àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ń ṣe “Ìpolongo Ẹgbẹ̀rúndún” ti ọdún 2000, wọ́n ṣe ìpinnu tó gbàrònú yìí pé: “A óò sa gbogbo ipá wa láti yọ àwọn èèyàn wa nínú wàhálà ogun, ì báà jẹ́ èyí tí wọ́n ń já láàárín orílẹ̀-èdè kan tàbí èyí tí orílẹ̀-èdè kan ń bá òmíràn jà, bí irú èyí tó gbẹ̀mí àwọn èèyàn tó lé ní mílíọ̀nù márùn-ún ní ẹ̀wádún tó kọjá.” Irú àwọn ìpolongo bí èyí ti mú kí àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè gbayì gan-an, ó ti mú kí onírúurú èèyàn máa kan sáárá sí i, débi pé àjọ náà gba Ẹ̀bùn Nobel Lórí Àlàáfíà lọ́dún 2001. Bí wọ́n ṣe bọlá fún àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè lọ́nà yìí ló mú kí Ìgbìmọ̀ tó Ń Fúnni ní Ẹ̀bùn Nobel ní Orílẹ̀-Èdè Norway sọ pé “Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè nìkan ṣoṣo ló dájú pé ó lè mú àlàáfíà àti àjọṣe kárí ayé wá.”

Pẹ̀lú gbogbo èyí, ǹjẹ́ a lè sọ pé Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, tí wọ́n dá sílẹ̀ lọ́dún 1945, ti fi ẹ̀rí hàn pé òun ni ìjọba tó tóótun láti mú ojúlówó àlàáfíà tó máa wà pẹ́ títí wá? Rárá o, nítorí pé ẹ̀mí ìmọtara ẹni nìkan táwọn orílẹ̀-èdè tó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ní àti ipò ọlá tí wọ́n ń lé ti mú kí ọ̀pọ̀ lára nǹkan tí àjọ náà ń ṣe forí sánpọ́n. Èrò táwọn èèyàn ní gbogbo gbòò wá ní báyìí, gẹ́gẹ́ bí olóòtú ìwé ìròyìn kan ṣe sọ ọ́ ni pé àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè wulẹ̀ jẹ́ “àjọ kan níbi táwọn èèyàn jákèjádò ayé ti máa ń sọ èrò wọn” àti pé “àwọn ìṣòro ọlọ́jọ́ pípẹ́ tí kò ní ojútùú kankan ló pọ̀ jù lọ lára ohun tí wọ́n ń jíròrò níbẹ̀.” A ṣì ń wá ìdáhùn sí ìbéèrè tó sọ pé: Ǹjẹ́ àwọn orílẹ̀-èdè ayé yóò wà níṣọ̀kan lọ́jọ́ kan?

Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé irú ìṣọ̀kan bẹ́ẹ̀ yòó ṣeé ṣe láìpẹ́. Báwo lèyí ṣe máa ṣẹlẹ̀? Ìjọba wo ni yóò sì mú kó ṣeé ṣe? Láti rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí, jọ̀wọ́ ka àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

Einstein sọ pé a nílò ìjọba kan tó kárí ayé

[Credit Line]

Einstein: fọ́tò U.S. National Archives

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́