Ìjọba Ọlọ́run Ń Gbé Nǹkan Ṣe Lónìí
“Báwo ni ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè tí àṣà ìbílẹ̀ wọn yàtọ̀ síra, tí ibi tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn gòkè àgbà dé sì yàtọ̀ síra ṣe lè ṣọ̀kan? Àwọn kan sọ pé àyàfi tí wọ́n bá kọ lu ayé yìí láti pílánẹ́ẹ̀tì mìíràn ni ìran ènìyàn tó lè wá níṣọ̀kan.”—The Age, ìwé ìròyìn ilẹ̀ Ọsirélíà.
KÍ WỌ́N kọ lu ayé yìí láti pílánẹ́ẹ̀tì mìíràn kẹ̀? Bóyá ìyẹn á jẹ́ kí gbogbo orílẹ̀-èdè tó wà láyé pa pọ̀ ṣọ̀kan o, a ò lè sọ. Àmọ́, àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì sọ nípa yánpọnyánrin kan tó ń bọ̀, tí yóò mú kí àwọn orílẹ̀-èdè ayé wà níṣọ̀kan. Àwọn agbára kan tó ju ti ẹ̀dá lọ ló sì máa fa yánpọnyánrin ọ̀hún.
Dáfídì Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ipò tí ayé yìí máa wà. Ó kọ̀wé lábẹ́ ìmísí Ọlọ́run pé: “Àwọn ọba ilẹ̀ ayé mú ìdúró wọn, àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga sì ti wọ́ jọpọ̀ ṣe ọ̀kan lòdì sí Jèhófà àti lòdì sí ẹni àmì òróró rẹ̀, wọ́n wí pé: ‘Ẹ jẹ́ kí a fa ọ̀já wọn já kí a sì ju okùn wọn nù kúrò lọ́dọ̀ wa!’” (Sáàmù 2:2, 3; Ìṣe 4:25, 26) Kíyè sí i pé àwọn alákòóso ilẹ̀ ayé yóò wọ́ jọpọ̀ ṣe ọ̀kan lòdì sí Jèhófà, Ẹlẹ́dàá ọ̀run òun ayé, àti ẹni àmì òróró rẹ̀, tàbí Ọba rẹ̀ tí ó yàn, ìyẹn Jésù Kristi. Báwo nìyẹn á ṣe ṣẹlẹ̀?
Ìṣírò ọjọ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bíbélì àtàwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ti nímùúṣẹ fi hàn pé ọdún 1914 la gbé Ìjọba Ọlọ́run kalẹ̀ ní ọ̀run tí Jésù Kristi sì jẹ́ Ọba rẹ̀.a Èrò kan náà ni àwọn orílẹ̀-èdè ayé ní lọ́kàn lákòókò yẹn. Dípò tí wọ́n ì bá fi fi ara wọn sábẹ́ ipò àṣẹ Ìjọba tuntun tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀ yìí, ńṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bá ara wọn jà, ìyẹn Ogun Ńlá tàbí Ogun Àgbáyé Kìíní.
Ojú wo ni Jèhófà Ọlọ́run fi wo ohun tí àwọn èèyàn tó jẹ́ alákòóso wọ̀nyẹn ṣe? “Ẹni náà tí ó jókòó ní ọ̀run yóò rẹ́rìn-ín; Jèhófà yóò fi wọ́n ṣẹ̀sín. Ní àkókò yẹn, òun yóò sọ̀rọ̀ sí wọn nínú ìbínú rẹ̀, yóò sì kó ìyọnu bá wọn nínú ìkannú gbígbóná rẹ̀.” Lẹ́yìn náà ni Jèhófà yóò sọ fún Ọmọ rẹ̀, ìyẹn ẹni tí ó fòróró yàn gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba náà pé: “Béèrè lọ́wọ́ mi, kí èmi lè fi àwọn orílẹ̀-èdè fún ọ gẹ́gẹ́ bí ogún rẹ àti àwọn òpin ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí ohun ìní rẹ. Ìwọ yóò fi ọ̀pá aládé irin ṣẹ́ wọn, bí ohun èlò amọ̀kòkò ni ìwọ yóò fọ́ wọn túútúú.”—Sáàmù 2:4, 5, 8, 9.
Fífi ọ̀pá aládé irin fọ́ àwọn orílẹ̀-èdè tó ń ṣàtakò túútúú níkẹyìn yóò ṣẹlẹ̀ ní Amágẹ́dọ́nì, tàbí Har–Magedoni. Ìwé Ìṣípayá, ìyẹn ìwé tó kẹ́yìn nínú Bíbélì, pe ìṣẹ̀lẹ̀ tó máa ṣẹlẹ̀ kẹ́yìn yìí ni “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè,” tí a óò kó “àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá” jọ pọ̀ sí. (Ìṣípayá 16:14, 16) Lábẹ́ agbára ẹ̀mí èṣù, àwọn orílẹ̀-èdè ayé yóò wá wà níṣọ̀kan níkẹyìn pẹ̀lú ète àtiṣe ohun kan náà, ìyẹn ni láti dojú ìjà kọ Ọlọ́run Olódùmarè.
Àkókò tí àwọn èèyàn yóò kóra wọn jọ pọ̀ láti dojú ìjà kọ ipò Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ti sún mọ́lé gan-an báyìí. Á yà wọ́n lẹ́nu pé “ìṣọ̀kan” wọn yìí kò ní ṣe wọ́n láǹfààní kankan. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni ohun tí wọ́n yóò ṣe yẹn máa ṣẹlẹ̀ tán tí àlàáfíà tí gbogbo èèyàn ń retí tipẹ́ yóò wá tẹ̀ le. Lọ́nà wo? Nínú ogun ìkẹyìn yìí, Ìjọba Ọlọ́run “yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí [ìyẹn ìjọba ayé] túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.” (Dáníẹ́lì 2:44) Ìjọba Ọlọ́run ni ìjọba tó máa mú àlàáfíà táwọn èèyàn ń fẹ́ wá sí ayé, kì í ṣe ètò àjọ èèyàn kankan ló máa mú un wá.
Olórí Alákòóso Ìjọba Náà
Ìjọba yẹn ni ọ̀pọ̀ èèyàn tó jẹ́ olóòótọ́ ọkàn ń gbàdúrà fún pé: “Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” (Mátíù 6:10) Ìjọba Ọlọ́run kì í ṣe ohun kan tó wà lọ́kàn èèyàn, kàkà bẹ́ẹ̀ ó jẹ́ ìjọba gidi kan tó ti ṣe àwọn nǹkan àgbàyanu látìgbà tí Ọlọ́run ti gbé e kalẹ̀ ní ọ̀run lọ́dún 1914. Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn kókó pàtàkì kan yẹ̀ wò tó fi hàn pé Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ìjọba gidi kan tó ń gbé nǹkan ṣe lónìí.
Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ó ní ẹ̀ka kan tó lágbára, tó gbéṣẹ́ tó sì ń bójú tó bí nǹkan ṣe ń lọ, olùdarí rẹ̀ sì ni Jésù Kristi, Ọba tá a gbé gorí ìtẹ́. Ní ọdún 33 Sànmánì Tiwa, Jèhófà Ọlọ́run fi Jésù Kristi ṣe Orí ìjọ Kristẹni. (Éfésù 1:22) Àtìgbà yẹn ní Jésù ti ń lo ipò orí rẹ̀, tó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé òun tóótun láti jẹ́ alábòójútó tó dáńgájíá. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ìyàn mú ní Jùdíà ní ọ̀rúndún kìíní, kíá ni ìjọ Kristẹni wá nǹkan ṣe láti ṣèrànwọ́ fáwọn ará. Wọ́n ṣètò ìrànwọ́, wọ́n sì ní kí Bánábà àti Sọ́ọ̀lù kó àwọn ohun tí wọ́n fẹ́ fi ṣèrànwọ́ náà lọ síbẹ̀ láti Áńtíókù.—Ìṣe 11:27-30.
A lè retí pé Jésù Kristi máa ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ nísinsìnyí tí Ìjọba náà ti fìdí múlẹ̀ tó sì ti ń gbé nǹkan ṣe. Nígbàkigbà tí jàǹbá kan bá ṣẹlẹ̀, bí ìsẹ̀lẹ̀, ìyàn, ìkún omi, ìjì líle, ẹ̀fúùfù, tàbí kí òkè ńlá máa tú iná àti èéfín jáde, kíá ni ìjọ Kristẹni ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń wá nǹkan ṣe láti ṣèrànwọ́ fáwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ àtàwọn míì tó ń gbé níbi tí jàǹbá náà ti wáyé. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ìsẹ̀lẹ̀ búburú jáì kan wáyé ní orílẹ̀-èdè El Salvador ní oṣù January àti February 2001, jákèjádò orílẹ̀-èdè náà ni wọ́n ti ṣètò àwọn ohun tí wọ́n fi ṣèrànwọ́ fáwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà bá, àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti Kánádà, Guatemala, àti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sì tún ṣèrànwọ́ pẹ̀lú. Mẹ́ta lára àwọn ibi ìjọsìn wọn àti àwọn ilé tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] ni wọ́n tún kọ́ láàárín àkókò kúkúrú.
Àwọn Ọmọ Abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run
Látìgbà tí Ìjọba ọ̀run ti Ọlọ́run ti bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1914 ló ti ń kó àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ jọ látinú àwọn èèyàn káàkiri ayé, ó sì ń ṣètò wọn. Èyí jẹ́ ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ pàtàkì kan tí Aísáyà kọ sílẹ̀, tó kà pé: “Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́ pé òkè ńlá ilé Jèhófà [ìyẹn ìjọsìn tòótọ́ tá a gbé ga] yóò di èyí tí a fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in sí orí àwọn òkè ńláńlá, . . . gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì máa wọ́ tìrítìrí lọ sórí rẹ̀.” Àsọtẹ́lẹ̀ náà fi hàn pé “ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn” yóò lọ sí orí òkè yẹn wọ́n óò sì pa àwọn ìtọ́ni àti òfin Jèhófà mọ́.—Aísáyà 2:2, 3.
Ìgbòkègbodò yìí ti mú kí àwùjọ kan tó jọjú ju lọ wà ní àkókò tá a wà yìí, ìyẹn ẹgbẹ́ àwọn ará kárí ayé tó jẹ́ Kristẹni tí iye wọn lé ní mílíọ̀nù mẹ́fà [6,000,000] láti àwọn orílẹ̀-èdè tó pọ̀ ju igba ó lé ọgbọ̀n [230] káàkiri ayé. Ní àwọn àpéjọ àgbáyé ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó máa ń ya àwọn èèyàn lẹ́nu nígbà tí wọ́n bá rí ìfẹ́, àlàáfíà, àti ìṣọ̀kan tó wà láàárín ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn tó pé jọ, ìyẹn àwọn tí kò jẹ́ kí ọ̀ràn ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni, àṣà ìbílẹ̀ tó yàtọ̀ síra, àti onírúurú èdè tí wọ́n ń sọ nípa lórí wọn. (Ìṣe 10:34, 35) Ǹjẹ́ o ò gbà pé ìjọba kan tó lè kó ọgọ́rọ̀ọ̀rún ẹ̀yà pa pọ̀ ní àlàáfíà àti ní ìṣọ̀kan ní láti jẹ́ ìjọba kan tó gbéṣẹ́, tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, tó sì jẹ́ ìjọba gidi kan?
Ètò Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Gbogbo ìjọba ló ní ìlànà táwọn ọmọ abẹ́ wọn gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé, gbogbo ẹni tó bá sì fẹ́ gbé lábẹ́ ìjọba náà ló gbọ́dọ̀ kúnjú ìwọ̀n àwọn ohun tó yẹ ní ṣíṣe wọ̀nyí. Bẹ́ẹ̀ náà ni Ìjọba Ọlọ́run ṣe ní àwọn ìlànà tí gbogbo ẹni tó bá fẹ́ jẹ́ ọmọ abẹ́ rẹ̀ gbọ́dọ̀ pa mọ́. Àmọ́, láti kó ọ̀pọ̀ èèyàn tó ti onírúurú ibi wá jọ, kí wọ́n fara mọ́ ìlànà kan náà, kí wọ́n sì máa pa ìlànà kan náà mọ́ jẹ́ iṣẹ́ bàǹtàbanta ní tòótọ́. Nǹkan mìíràn rèé tó tún jẹ́ ẹ̀rí pé Ìjọba Ọlọ́run ń gbé nǹkan ṣe lóòótọ́, ìyẹn ìtòlẹ́sẹẹsẹ ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀ tó gbéṣẹ́ tí kì í ṣe pé ó ń wọni lára tó sì ń yíni lérò padà nìkan, àmọ́ tó tún ń wọni lọ́kàn tó sì ń yíni lọ́kàn padà pẹ̀lú.
Báwo ni Ìjọba náà ṣe ń bójú tó iṣẹ́ ńlá tó wà lọ́rùn rẹ̀ yìí? Nípa títẹ̀lé àpẹẹrẹ àwọn àpọ́sítélì tó wàásù “láti ilé dé ilé” ni àti nípa fífi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ àwọn èèyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. (Ìṣe 5:42; 20:20) Báwo ni irú ètò ẹ̀kọ́ yìí ṣe gbéṣẹ́ tó? Jacques Johnson, tó jẹ́ àlùfáà ìjọ Kátólíìkì kan, kọ nǹkan sínú ìwé ìròyìn ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ti ilẹ̀ Kánádà nípa bóun ṣe sapá láti yí obìnrin kan lérò padà kí ó má bàa kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́. Ó sọ pé: “Ó ya mí lẹ́nu gan-an ni, mo sì wá rí i pé ìjà àjàpòfo ni mò ń jà. Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í ri pé kò ju oṣù bíi mélòó kan lọ tí àwọn obìnrin Ẹlẹ́rìí Jèhófà yìí àti ọ̀dọ́ abiyamọ tí kì í jáde nílé yìí fi di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́. Bí wọ́n ṣe dojúlùmọ̀ rẹ̀ ni pé wọ́n máa ń ṣèrànlọ́wọ́ fún un, wọ́n bá a dọ́rẹ̀ẹ́, wọ́n tún jẹ́ kí èrò rẹ̀ bá tiwọn mu. Kò pẹ́ tó fi di ògbóǹtagí ọmọ ìjọ wọn, kò sì sóhun tí mo lè ṣe sí i.” Bí ẹ̀kọ́ Bíbélì táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń kọ́ni àti ìwà Kristẹni wọn ṣe wọ onísìn Kátólíìkì tẹ́lẹ̀ yìí lọ́kàn ṣinṣin náà ló ṣe ń wọ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn lọ́kàn kárí ayé.
Irú ètò ẹ̀kọ́ yìí, ìyẹn ẹ̀kọ́ Ìjọba náà, dá lórí Bíbélì, ìyẹn ni pé ó tẹ̀ lé ìlànà rẹ̀ lórí ọ̀ràn ìwà rere. Ó ń kọ́ àwọn èèyàn láti nífẹ̀ẹ́ ara wọn kí wọ́n sì máa bọlá fún ara wọn láìfi irú èèyàn tí wọ́n jẹ́ pè. (Jòhánù 13:34, 35) Ó tún ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó sọ pé: “Ẹ . . . jáwọ́ nínú dídáṣà ní àfarawé ètò àwọn nǹkan yìí, ṣùgbọ́n ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín padà, kí ẹ lè ṣàwárí fúnra yín ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.” (Róòmù 12:2) Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ló ti rí àlàáfíà àti ayọ̀ nísinsìnyí tí wọ́n sì ń retí ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀ nítorí pé wọ́n ti fi ọ̀nà tí wọ́n gbà ń gbé ìgbésí ayé wọn tẹ́lẹ̀ sílẹ̀, tí wọ́n sì ń fayọ̀ ṣe ohun tó bá àwọn òfin àti ìlànà Ìjọba náà mu.—Kólósè 3:9-11.
Ìwé títayọ tó ń mú kí ìṣọ̀kan kárí ayé tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí ṣeé ṣe ni ìwé ìròyìn yìí, ìyẹn Ilé Ìṣọ́. Nípasẹ̀ iṣẹ́ ìtumọ̀ tá a ṣètò dáadáa àtàwọn ẹ̀rọtó ń tẹ̀wé jáde ní onírúurú èdè, à ń tẹ àwọn lájorí àpilẹ̀kọ inú Ilé Ìṣọ́ jáde ní èdè márùnléláàádóje [135] nígbà kan náà, àti pé ìpín márùndínlọ́gọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tó ń ka ìwé ìròyìn yìí jákèjádò ayé lè kẹ́kọ̀ọ́ inú rẹ̀ ní èdè tiwọn ní àkókò kan náà.
Òǹkọ̀wé kan tó jẹ́ onísìn Mormon kọ orúkọ àwọn ìsìn tó kẹ́sẹ járí jù lọ nínú iṣẹ́ míṣọ́nnárì, àmọ́ kò sọ̀rọ̀ nípa ṣọ́ọ̀ṣì tirẹ̀ o. Ó kọ Ilé Ìṣọ́ àti Jí!, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ̀ jáde síbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ìwé ìròyìn tó dára jù lọ fún iṣẹ́ ìjíhìnrere, ó wá sọ pé: “Kò sẹ́ni tó lè sọ pé Ilé Ìṣọ́ tàbí Jí! ń jẹ́ kéèyàn ní ẹ̀mí ìdágunlá, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló ń fúnni ní ìmọ̀ tí mi ò kì í sábà rí nínú àwọn ìwé táwọn onísìn mìíràn ń tẹ̀ jáde. Ilé Ìṣọ́ àti Jí! máa ń tuni lára nítorí pé ọ̀rọ̀ inú wọn dá lórí òtítọ́, wọ́n ṣe ìwádìí dáadáa lórí wọn, ohun tó ń lọ láyé gan-an ni wọ́n sì kọ síbẹ̀.”
Ẹ̀rí púpọ̀ gan-an ti fi hàn pé Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ìjọba gidi kan tó ti ń báṣẹ́ lọ ní pẹrẹu báyìí. Pẹ̀lú ayọ̀ àti gbogbo agbára ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń wàásù “ìhìn rere ìjọba yìí” fún àwọn aládùúgbò wa, tá a sì ń pè wọ́n láti wá di ọmọ abẹ́ ìjọba náà. (Mátíù 24:14) Ǹjẹ́ irú àǹfààní bẹ́ẹ̀ wù ọ́? Ìwọ náà lè rí ìbùkún téèyàn máa ń rí látinú dídara pọ̀ mọ́ àwọn tó ti kọ́ nípa ìlànà Ìjọba náà tí wọ́n sì ń sapá láti gbé níbàámu pẹ̀lú rẹ̀. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó tún lè láǹfààní láti gbé lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba náà nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ti ṣèlérí, inú èyí tí “òdodo yóò sì máa gbé.”—2 Pétérù 3:13.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé, wo orí kẹwàá, tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ “Ìjọba Ọlọrun Ń Ṣàkóso,” ní ojú ìwé 90 sí 97 nínú ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4, 5]
Àwọn orílẹ̀-èdè ja ogun àgbáyé kan ní ọdún 1914
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Ṣíṣe ìrànwọ́ tinútinú jẹ́ ẹ̀rí tó fi ìfẹ́ àwọn Kristẹni hàn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jákèjádò ayé máa ń jàǹfààní látinú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ètò ẹ̀kọ́ kan náà