ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 4/22 ojú ìwé 3-5
  • Ìṣòro Náà Ń tàn Kálẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìṣòro Náà Ń tàn Kálẹ̀
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìṣòro Tí Ń Mọ́kàn Pami
  • Ohun Tí Ó Yẹ Kí A Mọ̀ Nípa Ẹgbẹ́ Ọmọ Ìta
    Jí!—1998
  • Dídáàbòbo Àwọn Ọmọ Wa Lọ́wọ́ Ẹgbẹ́ Ọmọ Ìta
    Jí!—1998
  • Àjọ Ìpàǹpá Àwọn Obìnrin—Ìtẹ̀sí Tí Ń Dáni Níjì
    Jí!—1996
  • “Mò Ń Fi Ẹ̀mí Ara Mi Tàfàlà”
    Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 4/22 ojú ìwé 3-5

Ìṣòro Náà Ń tàn Kálẹ̀

Ọ̀dọ́mọdé Robert jẹ́ ọmọ ọdún 11 péré, àmọ́ wọ́n bá òkú rẹ̀ ní ìdojúbolẹ̀ lábẹ́ afárá kan tí àwọn ènìyàn ti pa tì. Àpá ọta méjì wà ní ìpàkọ́ rẹ̀. A ronú pé àwọn ọmọ ìta ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ni wọ́n pa á.

Alex, ọmọ ọdún 15 ń lọ wọ ẹgbẹ́ ọmọ ìta tí ó lè yọrí sí ikú aláìtọ́jọ́ fún un. Ṣùgbọ́n ó rí bí ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan ṣe kú, ó sì rò lọ́kàn ara rẹ̀ pé: ‘N kò fẹ́ parí ìgbésí ayé mi bẹ́ẹ̀ yẹn.’

ÀWỌN ọmọ ìta oníwà ipá, tí wọ́n wà nínú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ìta tí ó gbajúmọ̀ tí ń jẹ́ Bloods àti èyí tí ń jẹ́ Crips ní Los Angeles nígbà kan rí, ti tàn káàkiri ayé. Ṣùgbọ́n ibi yòówù kí wọ́n wà, lọ́nà yíyanilẹ́nu, àwọn ọmọ ìta kò yàtọ̀ síra.

Àwọn “Teddy Boys” ti England dá ayé níjì ní àwọn ọdún 1950. Ìwé agbéròyìnjáde The Times ti London sọ pé wọ́n lo àáké, ọ̀bẹ, ṣéènì kẹ̀kẹ́, àti àwọn ohun ìjà mìíràn láti “ṣe ọṣẹ́ burúkú” fún àwọn ènìyàn tí kò mọwọ́mẹsẹ̀. ‘Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí gúnbẹ, wọ́n ba àwọn ibi ìgbafẹ́ jẹ́, wọ́n sì ba àwọn ilé ìtakọfí jẹ́.’ Wọ́n bá àwọn ènìyàn ṣèṣekúṣe, wọ́n jà wọ́n lólè, wọ́n lù wọ́n, wọ́n sì pa wọ́n láwọn ìgbà mìíràn.

Ìwé agbéròyìnjáde Die Welt ti Hamburg, Germany, ròyìn pé, lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn ọmọ ìta ti fi “báàtì ìgbábọ́ọ̀lù orí kankéré, ọ̀bẹ, àti ìbọn” ṣe àwọn ọ̀dọ́ “tí wọ́n ń lọ sí ilé ijó dísíkò tàbí tí wọ́n ń padà sílé léṣe.” Ìwé agbéròyìnjáde Süddeutsche Zeitung ti Munich sọ pé, ní Berlin, àwọn afáríkodoro ń gbéjà ko ẹnikẹ́ni “tí wọ́n bá ṣàkíyèsí pé kò lágbára tó—àwọn tí wọn kò nílé, àwọn abirùn, àwọn obìnrin tí wọ́n ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́.”

Aṣojúkọ̀ròyìn Jí! kan ní ilẹ̀ Sípéènì ròyìn pé ìṣòro ẹgbẹ́ ọmọ ìta tí àwọn ọ̀dọ́langba ń ṣe ṣẹ̀ṣẹ̀ débẹ̀ ni, àmọ́ ó ń peléke sí i. Ìwé agbéròyìnjáde ABC, ní Madrid, ní àkọlé náà, “Àwọn Afáríkodoro—Ohun Adẹ́rùbani Tuntun Lójú Pópó.” Afáríkodoro kan tẹ́lẹ̀ rí láti ilẹ̀ Sípéènì sọ pé, wọ́n yóò wá “àwọn àjèjì, àwọn aṣẹ́wó, àti àwọn abẹ́yà-kannáà-lòpọ̀” kàn. Ó fi kún un pé: “[Nígbà yẹn], bí kò bá sí ìwà ipá lálẹ́ ọjọ́ kan, ọjọ́ náà kì í ṣe ọjọ́ rere.”

Ní Gúúsù Áfíríkà, ìwé agbéròyìnjáde Cape Times sọ pé, púpọ̀ lára àwọn ìwà bíburú jáì tí ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ ló jẹ́ “àbájáde iṣẹ́ ọwọ́ àwọn ọmọ ìta bíburújáì.” Ìwé kan tí a ṣe jáde ní Cape Town sọ pé, àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ìta ní Gúúsù Áfíríkà di “afarahẹ” ní àwọn ìlú tí kò fi bẹ́ẹ̀ lọ́rọ̀ àti pé wọ́n “ja àwọn ará àdúgbò wọn lólè, wọ́n sì fipá bá wọn lò, wọ́n sì kópa nínú bíbá ẹgbẹ́ ọmọ ìta mìíràn jà nítorí àgbègbè ìpínlẹ̀, ọjà, àti obìnrin.”

Ìwé agbéròyìnjáde kan ní Brazil, O Estado de S. Paulo, sọ pé, àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ìta “ń pọ̀ sí i lọ́nà tí ń bani lẹ́rù” níbẹ̀. Ó sọ pé, wọ́n ń kọ lu àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ìta alábàádíje wọn, àwọn èwe tó sàn jù wọ́n lọ, àwọn ènìyàn ẹ̀yà mìíràn, àti àwọn òṣìṣẹ́ aṣíwọ̀lú tí wọ́n jẹ́ aláìní. Ó tún sọ pé, lọ́jọ́ kan, àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ìta mélòó kan pawọ́ pọ̀ “ja àwọn ènìyàn lólè létíkun . . . , wọ́n bá ara wọn jà,” wọ́n sì sọ òpópónà pàtàkì kan ní Rio de Janeiro di “pápá ogun.” Ìròyìn mìíràn láti Brazil sọ pé, iye àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ìta ń pọ̀ sí i ní àwọn ìlú ńláńlá bí São Paulo àti Rio de Janeiro àti ní àwọn ìlú tí ó túbọ̀ kéré.

Ìwé ìròyìn Kánádà náà, Maclean’s, sọ ní 1995 pé, àwọn ọlọ́pàá fojú díwọ̀n pé, ó kéré tán, ẹgbẹ́ ọmọ ìta mẹ́jọ tí ń gbéṣẹ́ ṣe lójú méjèèjì ló wà ní Winnipeg, Kánádà. Àwọn ìwé agbéròyìnjáde United States sì ti tẹ àwòrán àwọn tí wọ́n wà nínú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ìta, tí wọ́n kó àwọn aṣọ ẹgbẹ́ ọmọ ìta àti àwọn ìkọkíkọ lọ sí àwọn àgbègbè àdágbé tí a kọ́ síbi àdádó fún àwọn Àmẹ́ríńdíà ti Ìwọ̀ Oòrùn Gúúsù Amẹ́ríkà, jáde.

Ní New York City, láàárín àkókò díẹ̀, ọ̀pọ̀ ìwà ipá tí ẹgbẹ́ ọmọ ìta lọ́wọ́ nínú rẹ̀ ló bẹ́ sílẹ̀ lọ́dún tí ó kọjá. A gbọ́ pé àwọn mẹ́ńbà ẹgbẹ́ ọmọ ìta Bloods àti ti Crips, tí wọ́n ti lókìkí tẹ́lẹ̀ ní Los Angeles, lọ́wọ́ nínú rẹ̀. Olórí ìlú New York sọ pé, láàárín July sí September, àwọn ọlọ́pàá kó 702 ènìyàn nínú àwọn rògbòdìyàn tí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ìta lọ́wọ́ nínú rẹ̀ ní tààrà.

Ìṣòro náà kò mọ sí àwọn ìlú ńlá nìkan mọ́. Ìwé agbéròyìnjáde Quad-City Times, tí a ń ṣe ní àáríngbùngbùn United States, sọ nípa “ìwà ipá tí ń pọ̀ sí i láàárín àwọn ọ̀dọ́langba, lílo oògùn líle nílòkulò gan-an àti ìmọ̀lára àìnírètí tí ń pelemọ.”

Ìṣòro Tí Ń Mọ́kàn Pami

A gbọ́ pé ẹgbẹ́ ọmọ ìta kan bẹ̀rẹ̀ bí ọ̀wọ́ àwọn ọ̀rẹ́ kan. Ṣùgbọ́n bí aṣáájú ẹgbẹ́ náà ṣe ń gbajúmọ̀ sí i ni ìwà ipá wọn ń peléke sí i. Aṣáájú àwọn ọmọ ìta náà ń gbé ilé ìyá-ìyá rẹ̀, tí wọ́n ń fi ọta ba ara rẹ̀ jẹ́ léraléra, kódà nígbà tí ìyá náà bá wà nílé pàápàá. Ìwé agbéròyìnjáde kan ròyìn pé, ó lé ní 50 àpá ọta tó wà lára ilé náà. Ó dájú pé wọ́n yin àwọn ìbọn náà láti gbẹ̀san àwọn ohun tí ẹgbẹ́ ọmọ ìta ti ọmọ-ọmọ náà wà nínú rẹ̀ ṣe. Ní àfikún, ẹ̀gbọ́n aṣáájú àwọn ọmọ ìta náà ń ṣẹ̀wọ̀n lọ́wọ́ nítorí rògbòdìyàn tí àwọn ọmọ ìta lọ́wọ́ nínú rẹ̀, ẹnì kan tí ó wà nínú ọkọ̀ kan tí ń lọ sì yìnbọn pa ọmọ ẹ̀gbọ́n ìyá rẹ̀, tí ó ti kó kúrò níbẹ̀ tẹ́lẹ̀ láti yẹra fún ìwà ipá, tí ó sì wá sílé láti bẹ̀ wọ́n wò.

Ní Los Angeles, àwọn ọmọ ìta yìnbọn pa ọmọ ọlọ́dún mẹ́ta kan tí kò mọwọ́mẹsẹ̀ nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tí ìyá rẹ̀ àti ọ̀rẹ́kùnrin ìyá rẹ̀ ṣèèṣì wà gba òpópó tí kò yẹ. Ọta kan wọ ilé ẹ̀kọ́ kan, ó sì ba olùkọ́ kan tí ń gbìyànjú láti ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ láti mú ìgbésí ayé wọn sunwọ̀n. Ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn, tí wọn kò ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú àwọn ọmọ ìta, àmọ́ tí wọ́n kó sí wọn lọ́wọ́, ni wọ́n ti pa pẹ̀lú. Ìyá kan ní Brooklyn, New York, ti di ìyá tí a mọ̀ sí ẹni tí ìbànújẹ́ bá jù lọ ládùúgbò rẹ̀—tí àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta kú nínú ìwà ipá tí àwọn ọmọ ìta hù.

Kí ló fa ìṣòro ìwà ipá tí àwọn èwe ń hù jákèjádò ayé yìí, báwo ni a sì ṣe lè dáàbò bo àwọn ọmọ wa ọ̀wọ́n lọ́wọ́ rẹ̀? Báwo ni ẹgbẹ́ àwọn ọmọ ìta ṣe ń bẹ̀rẹ̀ ná, èé sì ti ṣe tí àwọn èwe púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀ fi ń wọ ẹgbẹ́ wọn? A jíròrò àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú àwọn àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé èyí.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]

Scott Olson/Sipa Press

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́