Dídáàbòbo Àwọn Ọmọ Wa Lọ́wọ́ Ẹgbẹ́ Ọmọ Ìta
“Àwọn ọmọdé nílò àwọn ènìyàn tó bìkítà nípa wọn.”—Not My Kid—Gang Prevention for Parents.
LẸ́YÌN ipò ìbátan wa pẹ̀lú Ọlọ́run, àwọn ọmọ wa jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun ìní ṣíṣeyebíye jù lọ tí a ní. A gbọ́dọ̀ máa bá wọn sọ̀rọ̀, kí a máa gbọ́ wọn, kí a gbá wọn mọ́ra, kí a sì rí i dájú pé wọ́n mọ̀ pé àwọn ṣe pàtàkì sí wa gan-an. A gbọ́dọ̀ máa fi àwọn ohun dáradára kọ́ wọn—láti jẹ́ olùṣòtítọ́ àti ẹni tí ó wúlò, bí wọ́n ṣe lè ní láárí láyé wọn, àti bí wọ́n ṣe lè ṣe inúure sí àwọn ẹlòmíràn.
Alábòójútó ilé àhámọ́ àwọn èwe kan tí wọ́n ya pòkíì tọ́ka sí ìṣòro ńlá kan lónìí, ní wíwípé: “A kì í fi ìwà ọmọlúwàbí kọ́ àwọn ọmọ nínú ìdílé.” Ó dájú pé a ní láti fún ṣíṣe èyí láfiyèsí. A gbọ́dọ̀ máa hùwà lọ́nà tí a fẹ́ kí àwọn ọmọ wa máa gbà hùwà, kí a sì jẹ́ kí wọ́n rí ayọ̀ tí èyí ń fi kún ìgbésí ayé wa. Bí a kò bá fi ojúlówó ìwà ọmọlúwàbí kọ́ wọn, báwo ni a ṣe lè retí pé kí wọ́n hu irú ìwà ọmọlúwàbí bẹ́ẹ̀?
Ìwé ìròyìn Today, tí a ń ṣe nítorí àwọn olùkọ́ ní Amẹ́ríkà, sọ pé, àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ìta sábà máa ń fa àwọn èwe tí wọ́n “wo ara wọn bí aláìlè-ṣàṣeyọrí,” tí wọ́n sì “ń wá ààbò, ìmọ̀lára àjọṣe kòríkòsùn, àti ìtẹ́wọ́gbà láàárín ẹgbẹ́,” mọ́ra. Ní gidi, bí a bá fún àwọn ọmọ wa ní àwọn ohun wọ̀nyẹn ní ilé—ààbò àti ìmọ̀lára àṣeyọrí tó jíire nínú ìdílé àti nínú ìgbésí ayé tiwọn—ó ṣeé ṣe gan-an kí àwọn ìlérí asán tí ẹgbẹ́ ọmọ ìta kan ń ṣe má fà wọ́n mọ́ra páàpáà.
Aṣáájú ẹ̀ka ọlọ́pàá kan tí ń gbógun ti ẹgbẹ́ ọmọ ìta ní California sọ nípa ìrísí bíbanilẹ́rù tí ó máa ń wà ní ojú àwọn òbí nígbà tí àwọn ọlọ́pàá bá kan ilẹ̀kùn wọn láti wá fi tó wọn létí pé ọmọ wọn ti wọ ìjàngbọ̀n. Ó máa ń yà wọ́n lẹ́nu pé ẹni tí wọ́n lérò pé àwọn mọ̀ dáradára lè ti ṣe ohun tí kò dára. Àmọ́ ọmọ wọn ti ní àwọn ọ̀rẹ́ tuntun, ó sì ti yí padà. Àwọn òbí náà kò wulẹ̀ tí ì ṣàkíyèsí ni.
Lílo Ìṣọ́ratẹ́lẹ̀ Ṣe Pàtàkì
Àwọn ènìyàn tí ń gbé àwọn àgbègbè tí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ìta ti ń fàjàngbọ̀n sọ pé, àwọn ọ̀dọ́ àti àwọn àgbàlagbà gbọ́dọ̀ lo òye, kí wọ́n má ṣe gbéjà ko ẹgbẹ́ àwọn ọmọ ìta kan tàbí kí wọ́n halẹ̀ mọ́ wọn. Máa yẹra fún àwọn ọmọ ìta tí wọ́n pọ̀ gan-an, má sì ṣàfarawé ọ̀nà tí wọ́n ń gbà wo nǹkan tàbí tí wọ́n ń gbà hùwà, títí kan bí wọ́n ṣe ń rán aṣọ tí wọ́n ń wọ̀ àti àwọ̀ rẹ̀. Fífarawé wọn lè mú kí ẹgbẹ́ ọmọ ìta kan tí ó jẹ́ alábàádíje wọn dájú sọ ọ́.
Bákan náà, bí ẹnì kan bá ń wọṣọ tàbí tí ó ń hùwà bí pé ó fẹ́ láti wà nínú ẹgbẹ́ ọmọ ìta kan, àwọn tí wọ́n wà nínú ẹgbẹ́ náà lè yọ ọ́ lẹ́nu láti di ọ̀kan lára wọn. Bàbá ọlọ́mọ mẹ́ta kan ní Chicago fi ìjẹ́pàtàkì mímọ ìṣarasíhùwà àwọn tí wọ́n wà nínú ẹgbẹ́ ọmọ ìta ládùúgbò hàn. Ó sọ pé: ‘Bí mo bá dé fìlà mi, tí mo yí bẹntigọ́ọ̀ rẹ̀ sápá ọ̀tún, wọ́n á rò pé n kò bọ̀wọ̀ fún àwọn ni.’ Ìyẹn sì lè yọrí sí ìwà ipá!
Fi Ara Rẹ fún Àwọn Ọmọ Rẹ
Ìyá kan sọ pé: “A gbọ́dọ̀ kíyè sí àwọn ọmọ wa—ìmọ̀lára wọn àti ohun tí wọ́n ń ṣe. A kò ní lè ràn wọ́n lọ́wọ́ bí àwa fúnra wa kò bá ní ọkàn ìfẹ́ nínú ìgbésí ayé wọn.” Òmíràn sọ pé, ìṣòro ẹgbẹ́ ọmọ ìta náà kò ní tán bí àwọn òbí kò bá dá a dúró. Ó fi kún un pé: “Ẹ jẹ́ kí a fi ìfẹ́ hàn sí wọn. Bí ayé wọn bá bà jẹ́, nǹkan kò lè rọgbọ fún àwa náà.”
Ǹjẹ́ a mọ àwọn ọ̀rẹ́ àwọn ọmọ wa, ibi tí àwọn ọmọ wa ń lọ tí wọ́n bá kúrò ní ilé ẹ̀kọ́, àti ibi tí wọ́n ń wà lálẹ́ nígbà tí ilẹ̀ bá ṣú? Dájúdájú, kì í ṣe gbogbo ìyá ni ó lè wà nílé nígbà tí àwọn ọmọ rẹ̀ bá dé láti ilé ẹ̀kọ́. Ṣùgbọ́n àwọn ìyá anìkàntọ́mọ tí wọ́n ń tiraka tagbáratagbára láti san owó ilé àti láti bọ́ àwọn ọmọ wọn lè ṣètò pẹ̀lú àwọn ìyá mìíràn tàbí ẹnì kan tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé láti máa bá wọn mójú tó àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ ọ̀sán.
A béèrè lọ́wọ́ ọkùnrin kan, tí ń gbé àgbègbè kan tí ẹgbẹ́ ọmọ ìta pàtàkì kan wà, bí yóò ṣe dáàbò bo àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ìta. Ó sọ pé, òun yóò mú ọmọkùnrin òun yí po àdúgbò láti fi ohun tí rògbòdìyàn tí àwọn ọmọ ìta ń dá sílẹ̀ máa ń yọrí sí hàn án. Òun yóò nawọ́ sí àwọn ìkọkíkọ àti àwọn ilé tí wọ́n ti sọ dahoro, òun yóò sì jẹ́ kí ó mọ̀ pé, “kò jọ pé ààbò wà ní àdúgbò náà àti pé àwọn tí wọ́n wà nínú ẹgbẹ́ ọmọ ìta wulẹ̀ ń fẹsẹ̀ palẹ̀ kiri ni, wọn kì í ṣe ohun gúnmọ́ kan ní ìgbésí ayé wọn.” Ó fi kún un pé: “Lẹ́yìn náà, n óò ṣàlàyé pé, fífi àwọn ìlànà Bíbélì sílò nínú ìgbésí ayé yóò dáàbò bò ó lọ́wọ́ dídà bí wọ́n ti dà yẹn.”
Àwọn ohun pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ bí ìfẹ́ ọkàn aláìlẹ́tàn nínú iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ wa lè jẹ́ ààbò fún wọn. Bí ilé ẹ̀kọ́ wọn bá ní ìṣètò kíké sí àwọn òbí nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan tàbí àkókò mìíràn tí a ń ké sí àwọn òbí láti wá ṣèbẹ̀wò sí àwọn iyàrá ìkẹ́kọ̀ọ́, kí wọ́n sì bá àwọn olùkọ́ sọ̀rọ̀, ẹ rí i dájú pé ẹ lọ. Ẹ mọ àwọn olùkọ́ àwọn ọmọ yín, ẹ sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ nípa àníyàn yín lórí ọmọ yín àti ìfẹ́ ọkàn tí ẹ ní nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Bí ilé ẹ̀kọ́ náà kò bá ní ìṣètò fún ìbẹ̀wò, ẹ gbìyànjú láti wá àkókò láti lọ bá àwọn olùkọ́ sọ̀rọ̀ nípa bí ọmọ yín ṣe ń ṣe sí ní ilé ẹ̀kọ́ àti nípa bí ẹ ṣe lè ṣèrànwọ́.
Ìwádìí kan tí a ṣe ní ìlú ńlá kan ní Amẹ́ríkà ṣàwárí pé lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí àwọn ìdílé wọn ràn lọ́wọ́ tàbí tí wọ́n fún níṣìírí nídìí iṣẹ́ àṣetiléwá, ìpín 9 nínú ọgọ́rùn-ún ló ti wọ ẹgbẹ́ ọmọ ìta. Àmọ́ ní àwọn ìdílé tí a kò ti fún wọn ní irú àfiyèsí bẹ́ẹ̀, iye àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà wọ ìlọ́po méjì—ìpín 18 nínú ọgọ́rùn-ún—ló ti wọ ẹgbẹ́ ọmọ ìta. Bí ìdílé wa bá nífẹ̀ẹ́, tí a sì sún mọ́ra pẹ́kípẹ́kí àti bí a bá sì ń ṣe àwọn ohun tó gbámúṣé pọ̀, àwọn ìlérí asán tí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ìta ń ṣe kò ní lè fi bẹ́ẹ̀ fa àwọn ọmọ wa mọ́ra.
Ohun Tí Àwọn Ọmọ Wa Nílò Ní Gidi
Àwọn ọmọ wa nílò ohun kan náà tí àwa nílò—ìfẹ́, inú rere, àti ìfẹ́ni. Ọ̀pọ̀ ọmọ ni a kò tíì fọwọ́ kàn lọ́nà onífẹ̀ẹ́ni àti ìfẹ́ rí, tàbí ni a kò tíì sọ fún rí pé wọ́n já mọ́ nǹkan ní ti gidi. Kí ìyẹn má ṣe ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ wa láé! Kí a máa gbá wọn mọ́ra, kí a máa wí fún wọn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn, kí a sì máa gbìyànjú láti rí i pé wọ́n gbé ìgbésí ayé wọn lọ́nà oníwàrere tí a fi kọ́ wọn láti gbé. Wọ́n ṣeyebíye sí wa ju pé kí a hùwà sí wọn lọ́nà èyíkéyìí mìíràn lọ.
Gerald, tí ó wà nínú ẹgbẹ́ ọmọ ìta kan tẹ́lẹ̀ rí, ṣàlàyé pé: “N kò ní bàbá tí mo lè máa wo àpẹẹrẹ rẹ̀, nítorí náà ni mo ṣe wọ ẹgbẹ́ ọmọ ìta kí wọ́n lè máa ṣe ojúṣe yẹn fún mi nínú ìgbésí ayé mi.” Ó bẹ̀rẹ̀ sí lo oògùn líle nígbà tí ó pé ọmọ ọdún 12. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó pé ọmọ ọdún 17, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí bá ìyá rẹ̀ ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé déédéé. Obìnrin náà fi àwọn ìlànà rere inú Bíbélì sílò nínú ìgbésí ayé rẹ̀. Ọmọkùnrin náà wí pé: “Mo rí i pé ó ti yí padà, mo wá rò lọ́kàn ara mi pé, ‘Ohun kan ní láti wà nídìí rẹ̀.’” Àpẹẹrẹ rere tí obìnrin náà fi lélẹ̀ sún ọmọkùnrin yìí láti yí ìgbésí ayé rẹ̀ padà.
Àwọn ọmọ wa gbọ́dọ̀ rí àpẹẹrẹ rere lára wa—pé bí a ṣe ní kí wọ́n máa hùwà ni àwa náà ń hùwà. Ó yẹ kí wọ́n lè ní èrò rere nípa ìdílé wọn, kì í ṣe nítorí ohun tí ó ní, ṣùgbọ́n nítorí ohun tí ó ń ṣe. Ó sì yẹ kí a ti ran àwọn ọmọ náà lọ́wọ́ lọ́nà tí wọn óò lè máa fi ìwà rere ti àwọn alára yangàn. Agbẹjọ́rò Àgbègbè Àrọko Los Angeles tẹ́lẹ̀ rí, Ira Reiner, sọ ọ́ lọ́nà yìí pé: “A gbọ́dọ̀ fi ìfẹ́ hàn sí àwọn ọmọ kí wọ́n tó wọ ẹgbẹ́ ọmọ ìta.”
Pípèsè Ohun Tí Wọ́n Nílò
Kì í ṣe àwọn ohun ìní ti ara tí a pèsè fún àwọn ọmọ wa ni ó ṣe pàtàkì jù. Ohun tó jà ni pé kí a ràn wọ́n lọ́wọ́ láti dàgbà di ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́, tí ó bìkítà, tí ó sì ní àwọn ìlànà ìwà rere tí ó gbámúṣé. Bíbélì sọ pé, Jékọ́bù olódodo náà pe àwọn ọmọ rẹ̀ ní “àwọn ọmọ tí Ọlọ́run fi ṣe ojú rere sí [mi].” (Jẹ́nẹ́sísì 33:5) Bí a bá wo àwọn ọmọ wà bẹ́ẹ̀—bí ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fi fún wa—a óò túbọ̀ múra tán láti hùwà sí wọn pẹ̀lú ìfẹ́ àti láti kọ́ wọn láti gbé ìgbésí ayé aláìlábòsí, adúróṣinṣin, àti oníwàrere.
Nípa bẹ́ẹ̀, a óò sa gbogbo ipá wa láti gbé ìgbésí ayé wa ní ọ̀nà tí a óò fi lè fi àpẹẹrẹ títọ́ lélẹ̀ fún àwọn ọmọ wa. A óò jẹ́ kí wọ́n rí ìdílé wọn mú yangàn—kì í ṣe àwọn ohun ìní ìdílé, bí kò ṣe irú ènìyàn tí a jẹ́—lọ́nà tí ó tọ́, tí ó sì gbámúṣé. Nípa bẹ́ẹ̀, kò ní fi bẹ́ẹ̀ ṣeé ṣe pé kí wọ́n lọ wá ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ àwọn asùnta.
Nígbà tí bàbá àgbà kan ronú kan ìgbà tí ó wà léwe, ó wí pé: “Kò sí ohun tí ì bá sún mi ṣe ohunkóhun láti kó ìtìjú bá ìdílé mi.” Ó sọ pé òun ronú lọ́nà yìí nítorí òun mọ̀ pé àwọn òbí òun nífẹ̀ẹ́ òun. Lótìítọ́, ó lè má rọrùn fún àwọn bàbá àti ìyá kan, tí àwọn òbí àwọn alára kò fi ìfẹ́ hàn sí wọn rí, láti fi ìfẹ́ hàn sí àwọn ọmọ wọn. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn òbí ní láti sapá láti fi ìfẹ́ hàn sí àwọn ọmọ wọn.
Èé ṣe tí èyí fi ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀? Nítorí pé bí ìwé ìròyìn “What’s Up,” tí Àjọ Àwọn Aṣèwádìí Nípa Ẹgbẹ́ Ọmọ Ìta ní Utah ń ṣe, ti sọ, “nígbà tí àwọn èwé bá nímọ̀lára pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn, pé àwọn sì láàbò—kì í ṣe ààbò ní ti owó, bí kò ṣe ní ti ìmọ̀lára—àwọn àìní tí ó máa ń sún wọn wọ ẹgbẹ́ ọmọ ìta sábà máa ń pòórá.”
Àwọn kan tí ń kàwé yìí lè ronú pé irú àwọn ìdílé onífẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀ kò tún sí mọ́. Àmọ́ wọ́n wà. O lè rí púpọ̀ lára wọn ní àwọn ìjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà káàkiri àgbáyé. Lóòótọ́, àwọn ìdílé wọ̀nyí kò pé, àmọ́ wọ́n ní àǹfààní ńlá kan: Wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí Bíbélì sọ nípa ọmọ títọ́, wọ́n sì ń sapá láti mú àwọn ìlànà Ọlọ́run tí ó wà nínú Bíbélì lò nínú ìgbésí ayé wọn. Ní àfikún sí i, wọ́n ń fi àwọn ìlànà wọ̀nyí kọ́ àwọn ọmọ wọn.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fara mọ́ ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú ìwé ìròyìn The Journal of the American Medical Association pé: “A kò lè retí kí a ní kí . . . àwọn ọ̀dọ́langba ‘Wulẹ̀ kọ̀’ láìjẹ́ pé a fún wọn ní ohun kan tí wọ́n óò ‘Tẹ́wọ́ gbà.’” Ní ọ̀rọ̀ mìíràn, bí a bá fẹ́ kí àwọn ọmọ wa tẹ́wọ́ gba àwọn ohun tí ó dára, tí ó sì gbámúṣé, a gbọ́dọ̀ tọ́ wọn sípa ọ̀nà yẹn.
Kò sí ẹnikẹ́ni nínú wa tí yóò jẹ́ fẹ́ láti sọ, bí bàbá kan ṣe sọ pé: ‘Ọmọkùnrin mi rí ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ àti ọ̀wọ̀ tí kò rí gbà rí nínú ẹgbẹ́ ọmọ ìta tó wà.’ Bẹ́ẹ̀ sì ni a kò ní fẹ́ láti gbọ́ kí àwọn ọmọ wa sọ, bí ọ̀dọ́ kan ṣe sọ pé: “Mo wọ ẹgbẹ́ ọmọ ìta nítorí pé mo nílò ìdílé kan.”
Àwa òbí ni a gbọ́dọ̀ jẹ́ ìdílé yẹn. A sì gbọ́dọ̀ sa gbogbo ipá wa láti rí i pé àwọn ọmọ wa kéékèèké ṣíṣeyebíye ń bá a lọ láti jẹ́ apá kan rẹ̀, tó jẹ́ onífẹ̀ẹ́ àti ọlọ́yàyà.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Àkọsílẹ̀ Iṣẹ́ fún Àwọn Òbí Tí Wọ́n Bìkítà
✔ Ẹ máa lo àkókò pẹ̀lú àwọn ọmọ yín ní ilé, ẹ sì máa ṣe nǹkan pọ̀ bí ìdílé
✔ Ẹ mọ àwọn ọ̀rẹ́ àwọn ọmọ yín àti ìdílé wọn, kí ẹ sì máa kíyè sí ibi tí àwọn ọmọ yín ń lọ àti ẹni tí wọ́n ń bá lọ
✔ Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ yín mọ̀ pé àwọn lè mú ìṣòro èyíkéyìí tọ̀ yín wá nígbàkigbà
✔ Ẹ kọ́ àwọn ọmọ láti bọ̀wọ̀ fún àwọn ẹlòmíràn, ẹ̀tọ́ wọn, àti èrò wọn
✔ Ẹ ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ nípa dídi ojúlùmọ̀ àwọn olùkọ́ wọn, kí ẹ sì jẹ́ kí àwọn olùkọ́ náà mọ̀ pé ẹ mọyì wọn, ẹ sì ń ṣètìlẹ́yìn fún ìsapá wọn
✔ Ẹ má ṣe máa lọgun tàbí lo ìwà ipá láti yanjú àwọn ìṣòro
Àwọn ọmọ rẹ nílò ìfẹ́ni ọlọ́yàyà rẹ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Níní ọkàn ìfẹ́ nínú iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ ọmọ rẹ lè jẹ́ ààbò kan