Ohun Tí Ó Yẹ Kí A Mọ̀ Nípa Ẹgbẹ́ Ọmọ Ìta
Wade, tí ó wà lára ẹgbẹ́ ọmọ ìta kan tẹ́lẹ̀ rí ní California sọ pé: “A kàn jẹ́ ara àdúgbò kan náà ni. Ìgbà kan náà ni a bẹ̀rẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀. Ó kàn jẹ́ pé a kò ṣe ìpinnu tí ó tọ́ ni.”
ẸGBẸ́ ọmọ ìta sábà máa ń bẹ̀rẹ̀ bí àwùjọ àwọn kan tí wọ́n kóra jọ ládùúgbò. Àwọn ènìyàn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ di ọ̀dọ́langba tàbí tí wọn kò dàgbà tó bẹ́ẹ̀, tí wọ́n kóra jọ sí igun ojú pópó kan. Wọ́n máa ń ṣe nǹkan pọ̀, wọ́n sì máa ń pawọ́ pọ̀ láti dáàbò bo ara wọn lọ́wọ́ ẹgbẹ́ kan tí ó túbọ̀ fẹsẹ̀ múlẹ̀ nítòsí wọn. Àmọ́ láìpẹ́, ẹgbẹ́ wọn túbọ̀ ń jingíri sí i tó bí àwọn mẹ́ńbà rẹ̀ tí wọ́n ya jàǹdùkú jù lọ ti rí, ó sì ń lọ́wọ́ nínú àwọn rògbòdìyàn oníwà ọ̀daràn tí ó léwu.
Ẹgbẹ́ ọmọ ìta alábàádíje kan láti òpópónà mìíràn lè ti wo ẹgbẹ́ tuntun náà bí ọ̀tá rẹ̀. Ìbínú sì fa ìwà ipá. Àwọn tí ń ṣe fàyàwọ́ oògùn líle lo ẹgbẹ́ ọmọ ìta náà láti bá wọn ta àwọn oògùn líle aláìbófinmu. Àwọn ìgbòkègbodò oníwà ọ̀daràn mìíràn sì ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà.
Ọmọ ọdún 11 ni Luis nígbà tí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ dá ẹgbẹ́ ọmọ ìta kan sílẹ̀. Nígbà tí ó di ọmọ ọdún 12, ó bẹ̀rẹ̀ sí lo oògùn líle. Nígbà tí ó di ọmọ ọdún 13, wọ́n mú un fún ìgbà àkọ́kọ́. Ó lọ́wọ́ nínú jíjímọ́tògbé, fífọ́lé, àti dídigunjalè. Ó sì ti ṣẹ̀wọ̀n lọ́pọ̀ ìgbà nítorí ìjà àti ìjà ìgboro tí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ìta dá sílẹ̀.
Irú àwọn ẹni tó wà nínú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ìta lè jẹ́ ìyàlẹ́nu fún wa lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Martha, ọmọ ilé ẹ̀kọ́ gíga kan, tí ìrísí rẹ̀ jọjú, tí ń ṣe dáradára gan-an, máa ń gba máàkì dáradára, ó sì ń hùwà dáadáa ní ilé ẹ̀kọ́. Àmọ́, òun ni aṣáájú ẹgbẹ́ ọmọ ìta kan tí ń ta igbó, oògùn líle heroin, àti kokéènì. Ìgbà tí wọ́n yìnbọn fún ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ nígbà bí mélòó kan, tí ó sì kú, ni ẹ̀rù tó bà á débi tí ó fi yí ìgbésí ayé rẹ̀ padà.
Ìdí Tí Wọ́n Fi Ń Wọ Ẹgbẹ́ Ọmọ Ìta
Ó yani lẹ́nu pé àwọn kan tí wọ́n wà nínú ẹgbẹ́ ọmọ ìta sọ pé àwọn wọ ẹgbẹ́ náà nítorí àtirí-ìfẹ́. Wọ́n ń wá ẹ̀mí àjọṣe ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ rere, àjọṣe kòríkòsùn tí wọn kò rí ní ilé. Ìwé agbéròyìnjáde Die Zeit ti Hamburg, Germany, sọ pé, inú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ìta ni àwọn ọ̀dọ́ ti ń gbìyànjú láti wá ààbò tí wọn kò lè rí níbòmíràn. Eric, tí ó wà lára ẹgbẹ́ ọmọ ìta kan tẹ́lẹ̀ rí, sọ pé, bí wọn kò bá nífẹ̀ẹ́ rẹ ní ilé, “ìwọ gba ìta lọ, kí o lọ wá ohun tí ó sàn jù.”
Bàbá kan, tí ó wà nínú ẹgbẹ́ ọmọ ìta nígbà kan rí, kọ nípa ìrírí ìgbésí ayé rẹ̀ nígbà tí ó wà lọ́dọ̀ọ́ pé: “Mo ti ṣẹ̀wọ̀n lọ́pọ̀ ìgbà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́, ìjà àwọn ọmọ ìta, ìjà ìgboro àti nígbẹ̀yìngbẹ́yín nítorí ìgbìyànjú láti yìnbọn pànìyàn láti inú ọkọ̀ tí ń lọ.” Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, nígbà tí ó bí ọmọkùnrin rẹ̀ Ramiro, kò fi bẹ́ẹ̀ ráyè ti ọmọ náà. Nígbà tí Ramiro túbọ̀ dàgbà, òun náà wọ ẹgbẹ́ ọmọ ìta kan, àwọn ọlọ́pàá sì mú un lẹ́yìn ìjà kan tí àwọn ọmọ ìta jà. Nígbà tí bàbá rẹ̀ rin kinkin pé kí ó kúrò nínú ẹgbẹ́ ọmọ ìta náà, ó lọgun pé: “Àwọn ni ìdílé mi nísinsìnyí.”
Ní ilé ìwòsàn kan ní Texas, nọ́ọ̀sì kan tí ó ti bá àwọn ọ̀dọ́ 114 tí wọ́n ti fara gbọta láàárín àkókò tí ó fi díẹ̀ lé ní ọdún kan sọ̀rọ̀, sọ pé: “Kò wọ́pọ̀. N kò rò pé mo tí ì gbọ́ kí ọ̀kan lára wọn béèrè ìyá wọn tàbí ẹbí wọn kankan rí.”
Lọ́nà tí ó gbàfiyèsí, kì í ṣe àwọn ọmọ tí wọ́n wá láti àwọn apá ibi tí ó túbọ̀ tòṣì láàárín ìlú nìkan ní ń wọ ẹgbẹ́ ọmọ ìta. Ní ọdún bí mélòó kan sẹ́yìn, ìwé ìròyìn Kánádà náà, Maclean’s, fa ọ̀rọ̀ àwọn ọlọ́pàá yọ pé, bí àwọn ṣe rí àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n wá láti àwọn àdúgbò tí ó lọ́rọ̀ jù lọ nílùú ni àwọn rí àwọn tí ó kúṣẹ̀ẹ́ jù lọ nílùú náà tí wọ́n wà lára ẹgbẹ́ ọmọ ìta kan náà. Àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n wá láti onírúurú ìdílé wọ̀nyí ń kóra jọ pọ̀ fún ète jíjọra kan—wọ́n ń wá ìmọ̀lára ìṣọ̀kan ìdílé tí wọn kò rí ní ilé.
Ní àwọn àgbègbè kan, bí àwọn ọ̀dọ́ ṣe ń dàgbà sí i ni wọ́n ń wo wíwọ ẹgbẹ́ ọmọ ìta bí ọ̀nà ìgbésí ayé tí ó bójú mu. Fernando, ọmọ ọdún 16, ṣàlàyé pé: “Wọ́n rò pé wíwọ ẹgbẹ́ ọmọ ìta yóò bá àwọn yanjú ìṣòro àwọn. Wọ́n ronú pé: ‘Màá ní àwọn ọ̀rẹ́ púpọ̀. Wọ́n tagun, wọ́n sì ní ìbọn. Wọn óò dáàbò bò mí, kò sì sí ẹni tó lè ṣe nǹkan kan fún mi.’” Àmọ́ kì í pẹ́ kí àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ di ara ẹgbẹ́ ọmọ ìta náà tó rí i pé wíwà nínú ẹgbẹ́ ọmọ ìta kan ń mú kí àwọn ọ̀tá ẹgbẹ́ ọmọ ìta náà fojú sí àwọn lára.
Lọ́pọ̀ ìgbà, a máa ń rí àwọn ọmọ ìta ní àwọn àdúgbò tí owó kò ti pọ̀ àmọ́ tí ìbọn ti pọ̀. Àwọn ìròyìn ń sọ nípa àwọn iyàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ láàárín àwọn ìlú ńláńlá níbi tí 2 lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ 3 ti ń gbé nínú àwọn ìdílé olóbìíkan. Nígbà mìíràn, ó ń ṣẹlẹ̀ pé òbí akẹ́kọ̀ọ́ kan jẹ́ ajòògùnyó tí ó ṣeé ṣe kí ó má wọlé lálẹ́, akẹ́kọ̀ọ́ náà sì gbọ́dọ̀ mú ọmọ tirẹ̀ tí ó ń dá tọ́ lọ sí ọ̀dọ̀ abánitọ́mọ kí ó tó gba ilé ẹ̀kọ́ lọ lówùúrọ̀.
Gómìnà California, Pete Wilson, sọ pé: “A ní ìṣòro ńlá kan nítorí pé ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ń dàgbà láìsí bàbá, láìsí ọkùnrin àwòfiṣàpẹẹrẹ kan tí yóò fi ìfẹ́, ìdarísọ́nà, ìbáwí àti ìwà ọmọlúwàbí kọ́ wọn—láìsí òye ìdí tí wọ́n fi gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fún ara wọn tàbí kí wọ́n bọ̀wọ̀ fún àwọn ẹlòmíràn.” Ó sọ pé, àìlèbá àwọn ẹlòmíràn kẹ́dùn yìí ni ìdí tí àwọn ọ̀dọ́ kan ṣe “dà bí ẹni tí ó lè gbẹ̀mí ẹnì kan [kí wọ́n yìnbọn pa wọ́n] láìkábàámọ̀ páàpáà.”
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àìsí ìṣọ̀kan ìdílé, àìsí kíkọ́ ara ẹni, àti àìsí àpẹẹrẹ ìwà rere tí ó fìdí múlẹ̀ ni àwọn ohun pàtàkì tí ń fa kí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ìta máa pọ̀ sí i, àwọn ohun mìíràn tún wà tí ń fà á. Èyí ní nínú, àwọn ètò orí tẹlifíṣọ̀n àti sinimá tí ń gbé ìwà ipá jáde bí ọ̀nà rírọrùn láti yanjú àwọn ìṣòro; àwùjọ ènìyàn tí ó sábà máa ń pe àwọn aláìní ní aláìlè-ṣàṣeyọrí, tí ó sì ń rán wọn létí léraléra pé wọn kò lè ṣe ohun tí àwọn ẹlòmíràn ń ṣe; àti iye àwọn ìdílé anìkàntọ́mọ tí ń pọ̀ sí i níbi tí ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ ìyá kan tí ìṣẹ́ ti pá lórí ti gbọ́dọ̀ tiraka láti tọ́ ọmọ kan tàbí àwọn púpọ̀ tí a kò bójú tó. Àpapọ̀ ọ̀pọ̀ jù lọ tàbí gbogbo àwọn okùnfà wọ̀nyí, àti bóyá ti àwọn mìíràn, ló ń fa pípọ̀ tí ìṣòro ẹgbẹ́ ọmọ ìta ń pọ̀ sí i jákèjádò ayé.
Ó Ṣòro Láti Kúrò Nínú Ẹgbẹ́
Òtítọ́ ni pé lẹ́yìn àkókò kan, àwọn tí wọ́n wà nínú ẹgbẹ́ ọmọ ìta kan ń fà sẹ́yìn kúrò nínú ẹgbẹ́ ọmọ ìta tí wọ́n wà, tí wọ́n sì ń wá nǹkan mìíràn ṣe. Àwọn mìíràn lè lọ máa gbé ọ̀dọ̀ àwọn ẹbí wọn ní àgbègbè mìíràn, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ bọ́ lọ́wọ́ ìgbésí ayé ọmọ ìta. Ṣùgbọ́n lọ́pọ̀ ìgbà, kíkúrò nínú ẹgbẹ́ ọmọ ìta kì í fi bẹ́ẹ̀ rọrùn.
Ó wọ́pọ̀ pé kí wọ́n tó gbà pé kí àwọn kan kúrò nínú ẹgbẹ́ ọmọ ìta kan láàyè, àwọn ọmọ ẹgbẹ́ bí mélòó kan ní láti lù wọ́n ní àlùbolẹ̀. Ní gidi, àwọn tí wọ́n fẹ́ láti kúrò nínú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ìta kan pàtó ní láti joró ìbọn tí a óò yìn fún wọn. Bí wọ́n bá rù ú là, a gbà wọ́n láyè láti máa lọ! Ṣé ó yẹ kí wọ́n fìyà jẹni lọ́nà lílekoko bẹ́ẹ̀ nítorí àtikúrò nínú ẹgbẹ́ ọmọ ìta kan?
Ẹnì kan tí ó ti wà nínú ẹgbẹ́ ọmọ ìta kan tẹ́lẹ̀ rí ṣàlàyé ìdí tí ó fi fẹ́ láti kúrò nínú ẹgbẹ́ náà pé: “Márùn-ún lára àwọn ọ̀rẹ́ mi ló ti kú.” Láìṣe àní-àní, ìgbésí ayé nínú ẹgbẹ́ ọmọ ìta kan lè fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ohun tí ó léwu lọ́nà tí ó yani lẹ́nu. Ìwé ìròyìn Time sọ nípa ẹnì kan tí ó ti wà nínú ẹgbẹ́ ọmọ ìta kan tẹ́lẹ̀ rí ní Chicago pé: “Láàárín ọdún méje tí ó lò nínú ẹgbẹ́, wọ́n yìnbọn fún un ní ikùn, wọ́n fi irin tí wọ́n fi ń ṣe ojú irin lù ú lórí, ó dá lápá nínú ìjà kan, wọ́n sì fi í sẹ́wọ̀n lẹ́ẹ̀mejì nítorí jíjí-mọ́tò-gbé . . . Àmọ́ nísinsìnyí tí kò hùwà ọ̀daràn mọ́, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ nígbà kan rí tilẹ̀ ń wá a láti ṣe é lọ́ṣẹ́.”
Ìgbésí Ayé Tí Ó Sàn Jù Ṣeé Ṣe
Eleno, tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Brazil, ti fìgbà kan wà nínú ẹgbẹ́ Headbangers, ẹgbẹ́ ọmọ ìta kan tí ó má ń fi ọ̀bẹ àti ìbọn jà nígbà mìíràn. Bí ó ti ń nímọ̀lára jíjẹ́ òtòṣì, ó rí ìtẹ́lọ́rùn nínú fífọ́ nǹkan àti gbígbéjàko àwọn ènìyàn. Alájọṣiṣẹ́ rẹ̀ kan bá a sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì. Nígbà tí ó yá, Eleno lọ sí ọ̀kan lára àpéjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, níbi tí ó ti pàdé àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ àtijọ́ tí wọ́n ti kúrò nínú ẹgbẹ́ ọmọ ìta tí ó wà, ó tún rí ẹnì kan tí ó wà lára ẹgbẹ́ ọmọ ìta kan tí ó jẹ́ alábàádíje pẹ̀lú tiwọn. Wọ́n kí ara wọn bí arákùnrin—èyí yàtọ̀ gan-an sí ohun tí ì bá ti ṣẹlẹ̀ ní àwọn ìgbà tí ó ti kọjá.
Èyí ha ń ṣẹlẹ̀ ní tòótọ́ bí? Dájúdájú, ó ń ṣẹlẹ̀! Láìpẹ́ yìí, aṣojú Jí! kan jókòó pẹ̀lú àwọn tí wọ́n ti wà nínú ẹgbẹ́ ọmọ ìta pàtàkì kan tẹ́lẹ̀ rí, tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ sìn nísinsìnyí pẹ̀lú àwọn ìjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ní Los Angeles. Lẹ́yìn tí wọ́n ti sọ̀rọ̀ fún wákàtí mélòó kan, ọ̀kan lára wọn dákẹ́, ó fẹ̀yìn tì, ó sì wí pé: “Ẹ wò ó ná! Àwa tí a wà nínú ẹgbẹ́ Bloods àti ẹgbẹ́ Crips tẹ́lẹ̀ rí jókòó tira wa níhìn-ín, a sì nífẹ̀ẹ́ ara wa bí arákùnrin!” Wọ́n gbà pé yíyí tí àwọn yí padà, kúrò ní jíjẹ́ ọmọ ìta aláìláàánú, tí àwọn sì di ọkùnrin onínúure àti onífẹ̀ẹ́ ti jẹ́ ìyọrísí òtítọ́ náà pé àwọn ti kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ìlànà oníwà-bí-Ọlọ́run nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àfẹ̀sọ̀ṣe.
Èyí ha lè ṣẹlẹ̀ ní àwọn ọdún 1990 ní tòótọ́ bí? Àwọn tí wọ́n wà nínú ẹgbẹ́ ọmọ ìta ha lè ṣe irú àwọn ìyípadà bẹ́ẹ̀ nísinsìnyí bí? Wọ́n lè ṣe bẹ́ẹ̀ bí wọ́n bá fẹ́ láti ṣàyẹ̀wò ìṣírí lílágbára tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pèsè, kí wọ́n sì mú ìgbésí ayé wọn bá àwọn ìlànà Bíbélì mu. Bí o bá wà nínú ẹgbẹ́ ọmọ ìta kan, o kò ṣe ronú nípa ṣíṣe irú ìyípadà bẹ́ẹ̀?
Bíbélì rọ̀ wá láti “bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀, èyí tí ó bá ipa ọ̀nà ìwà yín àtijọ́ ṣe déédéé,” àti láti “gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, èyí tí a dá ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run nínú òdodo tòótọ́ àti ìdúróṣinṣin.” (Éfésù 4:22-24) Báwo ni a ṣe ń mú àkópọ̀ ìwà tuntun yẹn dàgbà? Bíbélì sọ pé, a lè “sọ” àkópọ̀ ìwà ẹnì kan “di tuntun nípasẹ̀ ìmọ̀ pípéye ní ìbámu pẹ̀lú àwòrán [Ọlọ́run] tí ó dá a.”—Kólósè 3:9-11.
Ṣe ó yẹ kí a gbìyànjú yí padà? Bẹ́ẹ̀ ni, ó yẹ! Bí o bá wà nínú ẹgbẹ́ ọmọ ìta kan, ìwọ lè nílò ìrànlọ́wọ́ láti ṣe irú ìyípadà bẹ́ẹ̀. Àwọn ènìyàn tí inú wọn yóò dùn láti ràn ọ́ lọ́wọ́ wà ládùúgbò rẹ. Síbẹ̀, àwọn òbí sábà máa ń wà ní ipò àtiní ipa títọ̀nà tí ó pọ̀ jù lọ lórí àwọn ọmọ wọn. Nítorí náà, a óò gbé ohun tí àwọn òbí lè ṣe láti dáàbò bo àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ìta yẹ̀ wò nísinsìnyí.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Òtítọ́ Bíbélì ti so àwọn tí wọ́n wà nínú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ìta tí ń bára wọn díje tẹ́lẹ̀ rí ṣọ̀kan