Àjọ Ìpàǹpá Àwọn Obìnrin—Ìtẹ̀sí Tí Ń Dáni Níjì
“ALÁÌLÁÀÁNÚ, adárútúrútú àti òkú òǹrorò” ni àwọn ọ̀rọ̀ tí ìwé agbéròyìnjáde The Globe and Mail lò láti ṣàpèjúwe àwọn àjọ ìpàǹpá àwọn ọmọbinrin tí wọ́n fìdí kalẹ̀ sí àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga ilẹ̀ Kánádà. Bí jíjẹ́ ara àjọ ìpàǹpá àwọn ọkùnrin ṣe ń sú wọn, iye àwọn ọmọbìnrin tí ń pọ̀ sí i ń ṣàfihàn ipò òmìnira wọn ní tipátipá. Ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ kan ní Toronto, tí ó jẹ́ ògbógi nípa àjọ ìpàǹpá àwọn èwe, ṣàkíyèsí pé àwọn ọmọbìnrin “ń fi ara wọn hàn lọ́nà oníwà ipá.” Nínú ìwé agbéròyìnjáde Globe, Ọ̀mọ̀wé Fred Mathews sọ pé, wọ́n múra tán láti “lo àwọn ohun ìjà àti ipá ‘tí ó ré kọjá ààlà,’” wọ́n sí “túbọ̀ ya aláìláàánú àti oníjàgídíjàgan ju àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn tí ó jẹ́ ọkùnrin lọ.” Èé ṣe? Gẹ́gẹ́ bí ọlọ́pàá kan tí kò lókùn ṣe sọ, ojú ìwòye kan tí ó wọ́pọ̀ láàárín àwọn èwe oníwà àìlófin ni pé, àwọn ọmọbìnrin “ṣeé ṣe kí wọn lo ìwọ̀nba àkókò díẹ̀ péré lẹ́wọ̀n bí ọwọ́ bá tẹ̀ wọ́n.” Agbẹnusọ ọlọ́pàá kan sọ fún ìwé agbéròyìnjáde Globe pé “àwọn ọmọbìnrin tí ọjọ́ orí wọn kéré tó ọdún 11 ń lọ́wọ́ sí ìwà ọ̀daràn pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ àti kíkó oògùn olóró àti ohun ìjà kiri ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga.”
Ọ̀mọ̀wé Mathews, tí ó jẹ́ afìṣemọ̀rònú àti ògbógi kan nípa irú ìwà ipá bẹ́ẹ̀, fọ̀rọ̀ wá àwọn mẹ́ḿbà àjọ ìpàǹpá àwọn obìnrin lẹ́nu wò láàárín sáà ọdún mẹ́wàá, ó sì rí i pé wọ́n jẹ́ “oníbìínú àti ọlọ̀tẹ̀, tí ó jẹ́ àbájáde ìdílé tí ń lo ọmọ nílòkulò tàbí tí kò bójú tó ẹrù iṣẹ́ rẹ̀ bí ó ti yẹ.” Kí ní ń fa irú àwọn èwe bẹ́ẹ̀ mọ́ra nínú àjọ ìpàǹpá? Mẹ́ḿbà kan látijọ́ sọ pé, àwọn àjọ ìpàǹpá máa ń fúnni ní “ìmọ̀lára ààbò ti pé a jẹ́ ara àwùjọ kan.” Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí ìwé agbéròyìnjáde náà fọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò, ó jẹ́wọ́ pé òun ti gbìyànjú láti pa ara òun nígbà méjì kí òun lè bọ́ kúrò nínú àjọ ìpàǹpá náà, ó sì fi kún un pé: “Ọ̀pọ̀ lára àwọn ohun tí a pè ní ikú òjijì àti ìfọwọ́ ẹni para ẹni tí ń ṣẹlẹ̀ ní àwọn agbègbè àrọko wulẹ̀ jẹ́ ìpànìyàn láti ọwọ́ àjọ ìpàǹpá ní ti gidi. Àjọ ìpàǹpá kan lè dáàbò bò ọ́ lọ́wọ́ òmíràn nígbà tí o bá wà nínú rẹ̀. Ìṣòro tí ó wà níbẹ̀ ni pé, kò lè dáàbò bo ọmọ ẹgbẹ́ kan náà lọ́wọ́ èkejì.”
Olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga kan, tí ọ̀ràn náà ń dà lọ́kàn rú, sọ pé: “A kò lè sọ ṣáájú, ohun tí àwọn ọmọbìnrin oníwà ipá tí a ní lọ́dọ̀ lè ṣe. Bí inú bá ń bí wọn, o kò lè sọ irú ìwà ipá tí wọ́n lè hù. Bí o bá sì wáá lọ jẹ́ olùkọ́, yóò bà ọ́ lẹ́rù gan-an ni.” Nípa “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn àkókò yóò “nira láti bá lò” nítorí àwọn ènìyàn, títí kan àwọn èwe, yóò jẹ́ “aláìní ìkóra ẹni níjàánu, òǹrorò.”—Tímótì Kejì 3:1-5.