Bí Wọ́n Ṣe Pàdánù Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Wọn
FÚN ọ̀pọ̀ ọdún, a ń fi gbólóhùn ọ̀rọ̀ yìí ṣàkópọ̀ ìtan United States pé, “Bí a ṣe ṣẹ́gun Ìwọ̀ Oòrùn.” Àwọn fíìmù Hollywood ń fi àwọn abulẹ̀dó aláwọ̀ funfun hàn bí wọ́n ti ń la àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ àti òkè ńláńlá ilẹ̀ America já, pẹ̀lú àwọn jagunjagun bíi ti John Wayne, àwọn adamàlúù, àti àwọn abulẹ̀dó tí ń bá àwọn òǹrorò, ará oko, afèlèjà, ará India, jagun. Nígbà tí àwọn aláwọ̀ funfun ń wá ilẹ̀ àti wúrà, wọ́n lérò pé àwọn àlùfáà àti oníwàásu Kirisẹ́ńdọ̀mù mélòó kan ń gba ọkàn là.
Báwo ni ìtàn yẹ́n ṣe rí lójú àwọn olùgbé ìjímìjí, àwọn ọmọ ìbílẹ̀ America? Ìwé The Native Americans—An Illustrated History sọ pé, nígbà tí àwọn ará Europe dé, àwọn ará India ni “a fipá mú láti fara mọ́ ìfilọ́lẹ̀ ọ̀kánjúwà afiniṣèjẹ gíga jù lọ tí wọ́n tí ì kò lójú rí: àwọn akótini aláwọ̀ funfun ará Europe.”
Àjọṣepọ̀ Tí Ó Yọrí Sí Gbọ́nmisi-Omi-Òto
Níbẹ̀rẹ̀, àwọn ọmọ ìbílẹ̀ fi inú rere àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ hàn sí ọ̀pọ̀ lára àwọn ará Europe tí wọ́n kọ́kọ́ dé ìhà Ìlà Oòrùn Àríwá America. Ìròyìn kan sọ pé: “Láìsí ìrànwọ́ àwọn Powhatan, ibùdó àwọn ará Britain ni Jamestown, Virginia, àkọ́kọ́ ilẹ̀ ìṣàkóso àwọn Gẹ̀ẹ́sì ní Ìwọ̀ Oòrùn ayé, kì bá tí la ìgbà òtútù líle koko rẹ̀ àkọ́kọ́ já ní 1607 sí 1608. Bákan náà, ilẹ̀ ìṣàkóso àwọn Alárìnkiri tí ó wà ní Plymouth, Massachusetts, ì bá ti já kulẹ̀, bí kò bá sí ìrànwọ́ àwọn Wampanoag.” Àwọn kan lára àwọn ọmọ ìbílẹ̀ fi bí a ṣe ń lo ajílẹ̀ tí a sì ń gbin ohun ọ̀gbìn han àwọn aṣíwọ̀lú náà. Báwo ni ìṣàwárí Lewis àti Clark ní 1804 sí 1806—láti ṣàwárí ọ̀nà ìkólọkóbọ̀ tí ó so Agbègbe Louisiana àti ibi tí wọ́n ń pè ní Àrọko Oregon pọ̀—ì bá sì ti kẹ́sẹ járí tó láìsí ìrànwọ́ àti ìdásí obìnrin ẹ̀yà Shoshone náà, Sacagawea? Òun ni “àmì àlàáfíà” wọn nígbà tí wọ́n fojú kojú pẹ̀lú àwọn ará India.
Bí ó ti wù kí ó rí, nítorí ọ̀nà tí àwọn ará Europe gbà ń lo ilẹ̀ àti orísun ìpèsè oúnjẹ tí kò tó nǹkan tẹ́lẹ̀, ìṣíwọ̀lú rẹpẹtẹ wá sí Àríwá America fa pákáǹleke láàárín àwọn akótini náà àti àwọn ọmọ ìbílẹ̀. Òpìtàn Ian K. Steele, ará Kánádà, ròyìn pé ní ọ̀rúndún kẹtàdínlógún, 30,000 àwọn Narragansett ni ó wà ní Massachusetts. Olórí wọn, Miantonomo, “nígbà tí ó ń nímọ̀lára pé ewu ń bọ̀, . . . wá ọ̀nà láti bẹ̀rẹ̀ àjọṣe pẹ̀lú àwọn Mohawk, kí wọ́n lè ṣèdásílẹ̀ àpapọ̀ ẹgbẹ́ àwọn Amerind alátakò.” A gbọ́ pé, ní 1642, ó sọ fún àwọn Montauk pé: “A [gbọ́dọ̀] jẹ́ ọ̀kan bí wọ́n [àwọn Gẹ̀ẹ́sì] ṣe jẹ́, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, gbogbo wa kì yóò sí mọ́ láìpẹ́, nítorí ẹ mọ̀ pé àwọn baba wa ní ọ̀pọ̀ yanturu ìgalà àti awọ ẹranko, àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ wa, pẹ̀lú àwọn igbó wa kún fún ìgalà, àti [tòlótòló], àwọn ìyawọlẹ̀ omi wá sì kún fún ẹja àti àwọn ohun abìyẹ́. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Gẹ̀ẹ́sì wọ̀nyí bá gba ilẹ̀ wa, tí wọ́n fi dòjé gé koríko, tí wọ́n sì fi àáké ge igi lulẹ̀; tí àwọn màlúù àti ẹṣin wọ́n fi koríko jẹ, tí àwọn ẹlẹ́dẹ̀ wọ́n fọ́ àbàta clam wa, ebi yóò sì pa gbogbo wa.”—Warpaths—Invasions of North America.
Ìsapá Miantonomo láti dá ẹgbẹ́ ogun àpapọ̀ Ọmọ Ìbílẹ̀ America sílẹ̀ já sí òtúbáńtẹ́. Nínú ogun ẹlẹ́yàmẹyà kan ní 1643, Olóyè Uncas ti ẹ̀yà Mohegan mú un, ó sì fà á lé àwọn Gẹ̀ẹ́sì lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí ọlọ̀tẹ̀. Àwọn Gẹ̀ẹ́sì kò lè dá Miantonomo lẹ́bi lábẹ́ òfin, kí wọ́n sì pa á. Wọ́n ronú ojútùú rírọrùn kan. Steele ń bá ọ̀rọ̀ lọ pé: “Nígbà tí wọn kò lè pa [Miantonomo], ẹni tí kò sí lábẹ́ ọlá àṣẹ èyíkéyìí lára àwọn ilẹ̀ ìṣàkóso wọn, àwọn alábòójútó mú kí Uncas pa á, lójú àwọn Gẹ̀ẹ́sì gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí pé, ó ti ṣe bẹ́ẹ̀.”
Kì í ṣe ìforígbárí àtìgbàdégbà láàárín àwọn atòkèèrè ṣàkóso àti àwọn onílẹ̀ nìkan ni èyí fi hàn, bí kò ṣe ìbánidíje àti ìwà ọ̀dàlẹ̀ oníkúpani láàárín àwọn ẹ̀yà tí wọ́n ti wà ní Àríwá America, kódà, kí àwọn aláwọ̀ funfún tóó dé pàápàá. Ilẹ̀ Britain ní àwọn ẹ̀yà díẹ̀ níhà ọ̀dọ wọn nínú ogun lòdì sí ilẹ̀ Faransé nítorí ìjẹgàba ìgbókèèrè ṣàkóso Àríwá America, nígbà tí àwọn yòó kù ti ilẹ̀ Faransé lẹ́yìn. Láìka ìhà yòó wù kí ó pàdánù sí, gbogbo àwọn ẹ̀yà tí ọ̀rán kàn ni ó fara gbá àdánù rẹpẹtẹ.
“Ìyàtọ̀ Nítorí Àṣìlóye”
Ojú ìwòye kan nípa ìkótini tí àwọn ará Europe ṣe ni pé: “Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tí àwọn aṣáájú àwọn orílẹ̀-èdé India kò lóye, títí tí ó fi pẹ́ jù, ni ojú tí àwọn ará Europe fi ń wo àwọn ará India. Wọn kò kà wọ́n sí aláwọ̀ funfun tàbí Kristẹni. Wọ́n kàn jẹ́ ará oko—ẹhànnà àti òkú òǹrorò—ní ojú ìwòye ọ̀pọ̀lọpọ̀, wọ́n jẹ́ ohun eléwu tí kò ní ìmọ̀lára ẹ̀dá ènìyàn, ohun títà ní ọjà ẹrú.” Ìṣarasíhùwà ẹlẹ́mìí èmi lọ̀gá yìí ní ipa asọni dahoro lórí àwọn ẹ̀yà wọ̀nyẹn.
Ojú ìwòye àwọn ará Europe kò ṣeé lóye fún àwọn Ọmọ Ìbílẹ̀ America. Gẹ́gẹ́ bí olùgbani nímọ̀ràn Philmer Bluehouse láti ẹ̀yà Navajo ṣe pè é nínú ìfọ̀rọ̀ wáni lẹ́nu wò kan pẹ̀lu Jí! láìpẹ́ yìí, “ìyàtọ̀ nítorí àṣìlóye” ń bẹ. Àwọn ọmọ ìbílẹ̀ kò fojú àìníláárí wo ọ̀làju wọn, ṣùgbọ́n, kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n wò ó bí ohun kan tí ó yàtọ̀, pẹ̀lú àwọn ànímọ́ yíyàtọ̀ pátápátá. Gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ kan, títa ilẹ̀ ṣàjèjì pátápátá sí àwọn ará India. O ha lè ní afẹ́fẹ́, ẹ̀fúùfù, àti omi, kí ó sì máa tà wọ́n bí? Ilẹ̀ ńkọ́ nígbà náà? Ó wà níbẹ̀ fún gbogbo ènìyàn láti máa lò ni. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn ará India kì í sọgbà yí ilẹ̀ ká.
Nígbà tí àwọn ará Britain, Sípéènì, àti Faransé dé, ohun tí a pè ní “ìforígbárí oníjàábá láàárín àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ ṣíṣàjèjì méjì” dé pẹ̀lú. Fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, àwọn ènìyàn ìbílẹ̀ ti kọ́ láti mú ara wọn dọ́gba pẹ̀lú ilẹ̀ àti àwọn ẹ̀da rẹ̀, wọ́n sì mọ ọ̀nà láti wà láàyè láìdabarú ìbáradọ́gba àyíká. Síbẹ̀, àwọn aláwọ̀ funfún dé láìpẹ́, wọ́n sì ń wo àwọn olùgbé ọmọ ìbílẹ̀ bí àwọn ẹni rírẹlẹ̀, òǹrorò ẹ̀dá—wọ́n sì ń mọ̀ọ́mọ̀ fìrọ̀rùn gbójú fo ìwà ará oko tiwọn náà ní títẹ̀ wọ́n lórí ba! Ní 1831, òpìtàn Alexis de Tocqueville, tí ó jẹ́ ará Faransé, ṣàkópọ̀ ojú ìwòye àwọn aláwọ̀ funfun nípa àwọn ará India báyìí pé: “Ọlọ́run ò yà wọ́n lọ́làjú; ọ̀ranyàn ni kí wọ́n kú.”
Panipani Búburú Jù Lọ
Bí àwọn abulẹ̀dó tuntún ṣe ń ya lọ sí ìwọ̀ oòrùn la Àríwá America kọjá ni ìwà ipá ń bí ìwà ipá. Nítorí náà, yálà àwọn ará India ló kọ́kọ́ ń kọluni tàbí àwọn akótini ará Europe, ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ní ń hùwà ìkà búburú jáì. Ẹ̀rù àwọn ará India ń bani nítorí wọ́n gbajúmọ̀ ní ti pípa awọ agbárí, àṣà kan tí àwọn kán gbà gbọ́ pé àwọn ará Europe, tí ń fúnni ní ẹ̀bùn ìṣírí nítorí awọ agbárí ló kọ́ àwọn. Bí ó ti wù kí ó rí, ogun tí àwọn ará India kò lè ṣẹ́ ni wọ́n ń jà lòdì sí àwọn tó jù wọ́n lọ—ní iye àti ohun ìjà. Nígbà púpọ̀ jù lọ, àwọn ẹ̀yà náà ń parí rẹ̀ sí kíkó kúrò lórí ilẹ̀ àjogúnbá wọn tàbí kí wọ́n kú. Ó sábà máa ń jẹ́ méjèèjì—wọ́n ń fi ilẹ̀ wọn sílẹ̀, a sì ń pa wọ́n, tàbí kí àrùn àti ebi pa wọ́n.
Síbẹ̀, kì í ṣe ikú ojú ogun ló ń pa àwọn ẹ̀ya ìbílẹ̀ jù lọ. Ian K. Steele kọ̀wé pé: “Ohun ìjà gbígbéṣẹ́ jù lọ nínú ìkóguntì Àríwá America kì í ṣe ìbọn, ẹṣin, Bíbélì, tàbí ‘ọ̀làjú’ ilẹ̀ Europe. Àjàkálẹ̀ àrùn ni.” Lórí ipa tí àwọn àrùn Ìlà Oòrùn ayé ní lórí àwọn ará America, Patrica Nelson Limerick, ọ̀jọ̀gbọ́n ìmọ̀ ìtàn, kọ̀wé pé: “Bí wọ́n bá dé Ìwọ̀ Oòrùn ayé, àwọn àrùn kan náà wọ̀nyí [tí ara àwọn ará Europe ti lè gbógun tì láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún]—ilẹ̀ẹ́gbóná, èèyi, gágá, ibà malaria, ibà pọ́njúpọ́ntọ̀, kúrúnà, ikọ́ ẹ̀gbẹ, àti, ju gbogbo rẹ̀ lọ, àrùn ìgbóná—kò bá ìgbéjàkò tó bẹ́ẹ̀ pàdé. Ìwọ̀n àwọn tí ń kú láti abúlé kan dé òmíràn lọ sókè tó ìpín 80 tàbí 90 nínú ọgọ́rùn-ún.”
Russell Freedman ṣàpèjúwe àjàkálẹ̀ àrùn ìgbóná tí ó jà ní 1837. “Àwọn Mandan ló kọ́kọ́ kọ lù, ó sì yára kánkán kọ lu àwọn Hidatsa, àwọn Assiniboin, àwọn Arikara, àwọn Sioux, àti àwọn Blackfeet, tẹ̀léra-tẹ̀léra.” Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ run àwọn Mandan tán yán-ányán-án. Láti nǹkan bí 1,600 ní 1834, iye wọ́n lọ sílẹ̀ sí 130 ní 1837.
Kí Ní Ṣẹlẹ̀ sí Àwọn Àdéhùn?
Títí di òní olónìí, àwọn àgbààgbà ẹ̀yà kọ̀ọ̀kán lè sọ àwọn déètì àwọn àdéhùn tí ìjọba United States fọwọ́ sí pẹ̀lú àwọn baba ńlá wọn ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún, láìgbọ́fun sókè. Ṣùgbọ́n kí ni àwọn àdéhùn wọ̀nyẹ́n fúnni? Lọ́pọ̀ ìgbà, a fi ilẹ̀ dáradára ṣe pàṣípààrọ̀ tí kò báradé fún ọ̀tọ́ọ́rọ́ aṣálẹ̀ tí a yà sọ́tọ̀ àti owó ìgbọ́bùkátà táṣẹ́rẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ ìjọba.
Àpẹẹrẹ ọ̀nà ìtẹ́ḿbẹ́lú tí a gbà bá àwọn ẹ̀yà ìbílẹ̀ lò ni ti àwọn orílẹ̀-èdè Iroquois (láti ìlà oòrùn sí ìwọ̀ oòrùn, Mohawk, Oneida, Onondaga, Cayuga, àti Seneca) lẹ́yìn tí àwọn agbókèèrè ṣàkóso ará America ti ṣẹ́gun àwọn ará Britain nínú ogun òmìnira, tí ó parí ní 1783. Àwọn Iroquois ti gbè lẹ́yìn àwọn ará Britain, gẹ́gẹ́ bí Alvin Josephy Kékeré, sì ṣe sọ, gbogbo ìsanpadà tí wọ́n rí ni ìpatì àti èébú. “Ní pípa [àwọn Iroquois] tì,” àwọn ará Britain “ti gbé àṣẹ ilẹ̀ àwọn Iroquois lé United States lọ́wọ́.” Ó fi kún un pé, kódà, “ẹgbẹ́ àwọn ọ̀kánjúwà aláràtúntà ilẹ̀ àti àwọn olówò bòḿbàtà àti ìjọba America fúnra rẹ̀ fipá jẹ gàba lórí” àwọn Iroquois tí wọ́n ti gbè lẹ́yìn àwọn agbókèèrè ṣàkóso náà ní ìlòdì sí àwọn ará Britain.
Nígbà ìpàdé àdéhùn kan ní 1784, James Duane, aṣojú Ìgbìmọ̀ Àpérò Kọ́ńtínẹ́ǹtì Lórí Àlámọ̀rí Àwọn Ará India tẹ́lẹ̀ rí, rọ àwọn aṣojú ìjọba “láti jin ìdára ẹni lójú èyíkéyìí tí ó bá kù láàárín àwọn Iroquois lẹ́sẹ̀ nípa mímọ̀ọ́mọ̀ bá wọn lò bí àwọn tí kò já mọ́ nǹkankan.”
Wọ́n mú àwọn àbá agbéraga rẹ̀ lò. Wọ́n kó àwọn Iroquois mélòó kan nígbèkùn, wọ́n sì ṣe “ìdúnàádúrà” lábẹ́ ìhalẹ̀ ikú mọ́ni. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò ka ara wọn sí ẹni tí a ṣẹ́gun lójú ogun, àwọn Iroquois ní láti fi gbogbo ilẹ̀ wọn níhà ìwọ̀ oòrun New York àti Pennsylvania sílẹ̀, kí wọ́n sì fara mọ́ ìwọ̀n ọ̀tọ́ọ́rọ́ ilẹ̀ tí ó dín kù gan-an ní New York State.
Ọgbọ́n ìgbógun jíjọra ni wọ́n lò fún ẹ̀yà ìbílẹ̀ púpọ̀ jù lọ. Josephy tún sọ pẹ̀lú pé, àwọn aṣojú ilẹ̀ America lo “rìbá, ìhalẹ̀mọ́ni, ọtí líle, àti ìtànjẹ àwọn aṣojú tí a kò fún láṣẹ láti já ilẹ̀ gbà lọ́wọ́ àwọn ẹ̀yà Delaware, Wyandot, Ottawa, Chippewa [tàbí Ojibwa], Shawnee, àti àwọn orílẹ̀-èdè Ohio míràn.” Abájọ tí àwọn ará India kò fi nígbẹkẹ̀lé nínú àwọn aláwọ̀ funfun àti àwọn ìlérí òfo wọn!
“Ìrìn Gígùn” Náà àti Ipa Ọ̀nà Omijé
Nígbà tí Ogun Abẹ́lé Ilẹ̀ America (1861 sí 1865) bẹ̀rẹ̀, ó kó àwọn ọmọ ogun kúrò ní ibi tí àwọn Navajo ń gbé ní ìhà Ìwọ̀ Oòrun Gúúsù. Àwọn Navajo lo àǹfààní àkókò ìtura yìí láti gbógun ti àwọn ibùdó àwọn ará America àti àwọn ará Mexico ní Àfonífojì Rio Grande tí ó wà ní agbègbè ìpínlẹ̀ New Mexico. Ìjọbá rán Colonel Kit Carson àti àwọn Ológun New Mexico rẹ̀ láti tọwọ́ àwọn Navajo bọṣọ, kí wọ́n sì kó wọn lọ sí ọ̀tọ́ọ́rọ́ aṣálẹ̀ tí a yà sọ́tọ̀ kan, tí a ń pè ní Bosque Redondo. Carson tẹ̀ lé ìlànà ìfebipọ̀tá láti lé àwọn Navajo kúrò ní Canyon de Chelly tí ó kún fún ẹ̀rù, ní ìhà ìlà oòrùn àríwá Arizona. Ó tilẹ̀ pa igi peach tí ó lé ní 5,000 run.
Carson gbá nǹkan bí 8,000 àwọn Navajo jọ, ó sì fipá mú wọn rin “Ìrìn Gígùn” tí ó tó nǹkan bí 300 ibùsọ̀ [480 kìlómítà] lọ sí àgọ́ ìsénimọ́ Bosque Redondo ní Fort Sumner, New Mexico. Ìròyìn kán sọ pé: “Ojú ọjọ́ tutù nini, ọ̀pọ̀ àwọn ìgbèkùn tí kò láṣọ lára, tí a kò sì bọ́ yó náà sì kú lójú ọ̀nà.” Ipò nǹkan níbi ìyàsọ́tọ̀ náà burú jáì. Àwọn Navajo ní láti máa gbẹ́ ihò ilẹ̀ nínú ìsapá láti rí ibi ìsádi. Ní 1868, ìjọbá fún àwọn Navajo ní 3.5 mílíọ̀nù éékà nínú ilẹ̀ àjogúnbá wọn ní Arizona àti New Mexico, lẹ́yìn tí ó ti rí àṣìṣe tí ó fi ìwà òmùgọ̀ ṣe. Wọ́n padà lọ, ṣùgbọ́n, ẹ wo irú ìyà tí wọ́n fara gbá tipátipá!
Láàárín 1820 sí 1845, a lé ẹgbẹẹgbàarùn-ún àwọn Choctaw, Cherokee, Chickasaw, Creek, àti Seminole kúrò lórí ilẹ̀ wọn ní ìhà Ìlà Oòrun Gúúsù, a sì fipá mú wọn kó lọ síhà ìwọ̀ oòrùn, ré kọjá Odò Mississippi, lọ sí ibi tí a mọ̀ sí Oklahoma nísinsìnyí, tí ó jìn ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún kìlómítà. Nínú òtútù gidigidi, àwọn púpọ̀ kú. Ìrìn tipátipá lọ sí ìhà ìwọ̀ oòrùn náà wáá ní òkìkí burúkú gẹ́gẹ́ bí Ipa Ọ̀nà Omijé.
A tún fìdí àwọn ìwà àìṣèdájọ́ òdodo tí a hù sí àwọn Ọmọ Ìbílẹ̀ America múlẹ̀ síwájú sí i nínú ọ̀rọ̀ ọ̀gágun George Crook ti ilẹ̀ America, ẹni tí ó ti ṣẹ́gun àwọn Sioux àti àwọn Cheyenne ní ìhà àríwá. Ó sọ pé: “A kì í sábà gbọ́ ẹjọ́ ẹnu àwọn ará India nínú ọ̀ràn náà. . . . Kìkì nígbà tí jàgídíjàgan [àwọn ará India] bẹ̀rẹ̀ ni gbogbo ayé wáá fiyè sí àwọn ará India, kìkì ìwà ipá àti aṣemáṣe tiwọn la ń dẹ́bi fún, nígbà tí àwọn tí àìṣèdájọ́ òdodo wọ́n sún wọn dé irú ọ̀nà ìgbésí ayé bẹ́ẹ̀ ń lọ láìsí ìdálẹ́bi kankan . . . Kò sí ẹni tí ó mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ kókó yìí ju ará India lọ, nítorí náà, ẹjọ́ rẹ̀ tọ́, bí kò bá rí ohun kan tí ó jẹ́ ẹ̀tọ́ lára ìjọba kan tí ó wulẹ̀ ń jẹ ẹ́ níyà, nígbà tí ó ń fàyè gba àwọn aláwọ̀ funfun láti máa piyẹ́ rẹ̀ bí wọ́n ṣe fẹ́.”—Bury My Heart at Wounded Knee.
Kí ni ipò àwọn Ọmọ Ìbílẹ̀ America ṣe rí lónìí, lẹ́yìn èyí tí ó lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún tí àwọn ará Europe fi jẹ gàba lé wọn lórí? Wọ́n ha wà nínú ewu pípòórá nítorí gbígbà tí a gbà wọ́n mọ́ra bí? Ìrètí wo ni wọ́n ní fún ọjọ́ ọ̀la? Àpilẹ̀kọ tí ó kàn yóò ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ìbéèrè wọ̀nyí àti àwọn mìíràn.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 9]
Ìgbésí Ayé Líle Koko fún Àwọn Obìnrin
Nígbà tí àwọn ọkùnrin jẹ́ ọdẹ àti jagunjagun ní ẹ̀yà púpọ̀ jù lọ, iṣẹ́ àwọn obìnrin kò lóǹkà, títí kan títọ́ àwọn ọmọ, gbígbìn àti kíkórè ọkà, gígún ọkà di ìyẹ̀fun. Colin Taylor ṣàlàyé pé: “Olórí iṣẹ́ àwọn obìnrin ará India tí ń gbé ní Pẹ̀tẹ́lẹ̀ . . . ni mímójú tó agbo ilé tí a ti fìdi rẹ̀ múlẹ̀, bíbímọ àti gbígbọ́únjẹ. Nínú àwọn àwùjọ oníṣẹ́ ọ̀gbìn, wọ́n tún ń ṣàbójútó oko, . . . nígbà tí ó jẹ́ pé, láàárín àwọn ẹ̀yà aláṣìíkiri ìhà ìwọ oòrùn tí ń ṣọdẹ ẹfọ̀n, wọ́n máa ń ṣèrànwọ́ láti pa ẹran náà, kí wọ́n kó o wá sí ibùdó, kí wọ́n sì ṣètò ẹran àti awọ náà fún ìlò ọjọ́ iwájú.”—The Plains Indians.
Orísun ìtọ́kasí mìíràn sọ pé láàárín àwọn ẹ̀yà Apache: “Iṣẹ́ àwọn obìnrin ni iṣẹ́ oko, kò sì sí ohun tí ń rẹni nípò wálẹ̀ tàbí tí kò buyì fúnni nípa rẹ̀. Àwọn ọkùnrin ń ràn wọ́n lọ́wọ́, ṣùgbọ́n àwọn obìnrín fi ojú pàtàkì wo iṣẹ́ oko ju àwọn ọkùnrin lọ. . . . Àwọn obìnrín sábà máa ń mọ bí a ti í ṣe àwọn ètùtù iṣẹ́ ọ̀gbìn. . . . Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn obìnrín máa ń gbàdúrà nígbà tí wọ́n bá ń bomi rin ilẹ̀.”—The Native Americans—An Illustrated History.
Àwọn obìnrin ní ń kọ́ ilé ibùgbé wọn onígbà díẹ̀ tí wọ́n ń pè ní tepee, tí ó sábà máa ń wà fún nǹkan bí ọdún méjì. Wọ́n ń kọ́ wọn, wọ́n sì ń wó wọn palẹ̀ nígbà tí ẹ̀yà náà bá ń ṣí lọ. Láìsíyè méjì, ìgbésí ayé àwọn obìnrin kò rọrùn. Ṣùgbọ́n bẹ́ẹ̀ náà ni ti àwọn ọkùnrin wọn gẹ́gẹ́ bí aláàbò ẹ̀yà náà. A ń bọ̀wọ̀ fún àwọn obìnrin, wọ́n sì ní ẹ̀tọ́ púpọ̀. Nínú àwọn ẹ̀yà kan, irú bíi ti àwọn Hopi, kódà lóde òní, àwọn obìnrin ló ń ní ìní.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ẹranko Kan Tí Ó Yí Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Wọn Padà
Àwọn ará Europe mú ẹranko kan wọ Àríwá America, tí ó yí ọ̀nà ìgbésí ayé ọ̀pọ̀ ẹ̀yà padà—ẹṣin. Ní ọ̀rúndún kẹtàdínlógún, àwọn ará Sípéènì ni ó kọ́kọ́ mú ẹṣin wọ kọ́ńtínẹ́ǹtì náà. Àwọn Ọmọ Ìbílẹ̀ America di ọ̀jáfáfá òǹgẹṣin láìdi gàárì, gẹ́gẹ́ bí àwọn akótini ará Europe ti ṣàwárí rẹ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Ó túbọ̀ rọrùn fún àwọn ọmọ ìbílẹ̀ náà láti ṣọdẹ ẹfọ̀n, láti orí ẹṣin. Ó sì túbọ̀ rọrùn fún àwọn ẹ̀yà alárìnkiri láti gbógun ti àwọn ẹ̀yà tí ó múlé gbè wọ́n, tí ń gbé àwọn abúlé, kí wọ́n si tipa bẹ́ẹ̀ piyẹ́ wọn, kó wọn lóbìnrin, kí wọ́n sì kó wọn lẹ́rú.
[Àwòrán ilẹ̀/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Ọ̀gangan àyè àwọn ẹ̀yà díẹ̀ ní Àríwá America ní ọ̀rúndún kẹtàdínlógún
Kutenai
Spokan
Nez Perce
Shoshone
Klamath
Paiute ti Àríwá
Miwok
Yokuts
Serrano
Mohave
Papago
Blackfoot
Flathead
Crow
Ute
Hopi
Navajo
Jicarilla
Apache
Mescalero
Lipan
Plains Cree
Assiniboin
Hidatsa
Mandan
Arikara
Teton
Sioux
Yankton
Pawnee
Arapaho
Oto
Kansa
Kiowa
Comanche
Wichita
Tonkawa
Atakapa
Yanktonai
Santee
Iowa
Missouri
Osage
Quapaw
Caddo
Choctaw
Ojibwa
Sauk
Fox
Kickapoo
Miami
Illinois
Chickasaw
Alabama
Ottawa
Potawatomi
Erie
Shawnee
Cherokee
Catawba
Creek
Timucua
Algonquian
Huron
Iroquois
Susquehanna
Delaware
Powhatan
Tuscarora
Micmac
Malecite
Sokoki
Massachuset
Wampanoag
Narragansett
Mohegan
Montauk
Cheyenne
[Àwọn Credit Line]
Ará Íńdíà: Iṣẹ́ ọnà tí a gbé karí fọ́tò tí Edward S. Curtis yà; Àríwá America: Mountain High Maps® Copyright © 1995 Digital Wisdom, Inc.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Nǹkan híhun àti ohun ọ̀ṣọ́ oníṣẹ́ ọnà àwọn Navajo
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Canyon de Chelly, níbi tí “Ìrìn Gígùn” náà ti bẹ̀rẹ̀