Àwọn Àmẹ́ríńdíà Àti Bíbélì
LÁTI ìgbà tí àwọn ará Yúróòpù ti gbógun ti àwọn ọmọ Amẹ́ríkà ni ọ̀pọ̀ ti gbìyànjú láti fi Bíbélì kọ́ àwọn Àmẹ́ríńdíà.
Láti ọ̀rúndún kẹtàdínlógún ni a ti túmọ̀ Bíbélì lódindi sí èdè Àríwá Àmẹ́ríńdíà mẹ́fà. Àkọ́kọ́ rẹ̀ ni Bíbélì ti John Eliot, tí wọ́n tẹ̀ jáde ní 1663 fún àwọn Àmẹ́ríńdíà ti Massachusett nítòsí Boston àti Roxbury, Massachusetts. Harvey Markowitz kọ ọ́ sínú ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopedia of North American Indians, pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ òpìtàn ló ń ṣiyèméjì nípa òótọ́ inú tí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn atẹ̀lúdó fi fọwọ́ sí àdéhùn [kan, ìyẹn ni, “láti ‘la’ àwọn ‘aláìlajú’ Ìwọ̀ Oòrùn Ìlàjì Ayé ‘lójú’”], ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún tí Eliot fi ṣiṣẹ́ àṣekára láti kọ́ èdè Massachusett àti láti hùmọ̀ àwọn lẹ́tà àkọtọ́ tó fi da Bíbélì kọ fi ẹ̀rí bó ṣe gbé gbogbo ẹ̀mí rẹ̀ lé e tó hàn. Eliot ka iṣẹ́ tó ṣòro yìí sí ‘iṣẹ́ mímọ́ àti ọlọ́wọ̀, tó yẹ ká fìbẹ̀rù, àníyàn, àti ọ̀wọ̀ ṣe.’”
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a túmọ̀ àwọn apá kọ̀ọ̀kan Bíbélì sí àwọn èdè Àmẹ́ríńdíà mìíràn, ó gba igba ọdún kí wọ́n tó ṣe Bíbélì tó jáde lódindi tẹ̀ lé e, abala kan ní èdè Àmẹ́ríńdíà ti Ìwọ̀ Oòrùn Cree (1862) láti ọwọ́ àwọn alábàákẹ́gbẹ́ British and Foreign Bible Society. Kò pẹ́ tí àwọn ìtumọ̀ mìíràn fi tẹ̀ lé e: ti Inuit Ilẹ̀ Olótùútù Nini ní Ìlà Oòrùn (1871); ti àwọn Dakota, tàbí Sioux ní Ìlà Oòrùn (1880); àti Gwich’in, èdè àríwá àgbègbè kan ní Amẹ́ríkà (1898).
Bíbélì tó jáde lódindi kẹ́yìn ni ti ìtumọ̀ Navajo, tí a tẹ̀ jáde ní 1985, lẹ́yìn ìṣètò àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ọlọ́dún mọ́kànlélógójì láàárín àwọn ẹgbẹ́ méjì tí ń ṣe Bíbélì jáde. Àwọn apá Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù àti Gíríìkì ti wà nísinsìnyí ní èdè Àmẹ́ríńdíà mẹ́rìndínláàádọ́ta, ó kéré tán.
Àwọn Wo Ló Mú Ipò Iwájú?
Markowitz sọ pé: “Ó ṣe pàtàkì . . . pé iṣẹ́ títúmọ̀ Bíbélì ti jẹ́ ìsapá kan tí ó mu àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì lómi.” Òǹkọ̀wé kan náà tún sọ pé ṣáájú Àpérò Kejì ní Ibùjókòó Ìjọba Póòpù (1962), Ìjọ Kátólíìkì “kò fọwọ́ sí pípín Bíbélì kiri láàárín àwọn gbáàtúù, wọ́n gbà gbọ́ pé àwọn tí kì í ṣe àlùfáà kò ní ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó péye . . . láti túmọ̀ àwọn ẹsẹ Bíbélì lọ́nà tó tọ́.”
Ní báyìí, ó kéré tán, iṣẹ́ ìtumọ̀ tí ó tó ogún ló wà lọ́wọ́ onírúuru ẹgbẹ́ tí ń ṣe Bíbélì láti túmọ̀ Bíbélì sí èdè àwọn Àmẹ́ríńdíà ti Àríwá Amẹ́ríkà, títí kan Cheyenne, Havasupai Micmac, àti Zuni. A ti ń ṣètò ẹ̀dà tuntun kan ti Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì fún orílẹ̀-èdè Navajo. Àwọn ìtumọ̀ mìíràn ni a ń ṣètò fún àwọn Àmẹ́ríńdíà ti Àáríngbùngbùn àti Gúúsù Amẹ́ríkà.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò ní àjọṣe kankan pẹ̀lú ètò àjọ Pùròtẹ́sítáǹtì èyíkéyìí. Síbẹ̀, wọ́n ń ṣiṣẹ́ àṣekára láàárín àwọn Àmẹ́ríńdíà, àbájáde rẹ̀ sì ni pé ọ̀pọ̀ lára àwọn Àmẹ́ríńdíà ń tẹ́wọ́ gba òtítọ́ Bíbélì nípa “ọ̀run tuntun àti ayé tuntun” náà, nínú èyí tí òdodo yóò máa gbé. (2 Pétérù 3:13) Àwọn Ẹlẹ́rìí ń lo àwọn Bíbélì tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó báyìí ní èdè ìbílẹ̀ àwọn Àmẹ́ríńdíà. Wọ́n tún ń lo àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí Watch Tower Society ti túmọ̀ sí àwọn èdè Àmẹ́ríńdíà kan, títí kan Aymara, Cree, Dakota, Guarani, Inuktitut, Iroquois, Navajo, Quechua, àti àwọn èdè mẹ́sàn-án mìíràn.—Wo Jí!, September 8, 1996.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
“Jèhófà” fara hàn nínú Bíbélì Navajo ní Sáàmù 68:4