ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g99 5/8 ojú ìwé 28-29
  • Wíwo Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwo Ayé
  • Jí!—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Mímúrasílẹ̀ De Ọdún 2000
  • Àrùn Sunrunsunrun Tún Dé
  • Jíjẹ́ Ẹni Tí Ara Rẹ̀ Le
  • Ewu Kọ̀ǹpútà Nínú Ọkọ̀ Òfuurufú
  • Ọ̀nà Tuntun Tí A Ń Gbà Fiṣẹ́ Abẹ Bímọ
  • Kì í Ṣe Àbájáde Tí A Fẹ́
  • Tardigrade Alágbára Ńlá
  • Fífi Orin Abágbàmu Tu Àwọn Èrò Ọkọ̀ Lára
  • Ojúṣe Olúkúlùkù
  • Bí Ọkàn Rẹ Ṣe Lè Balẹ̀ Nínú Ọkọ̀ Òfuurufú
    Jí!—2002
  • Wíwo Ayé
    Jí!—1997
  • Ǹjẹ́ Ó Tiẹ̀ Yẹ Kó O Máa Ṣeré Ìmárale?
    Jí!—2005
  • Ọdún 2000—Ṣọ́dún Abàmì Ni?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
Jí!—1999
g99 5/8 ojú ìwé 28-29

Wíwo Ayé

Mímúrasílẹ̀ De Ọdún 2000

Ìwé ìròyìn The Wall Street Journal sọ pé: “Ọdún 2000 lè mú ìdàrúdàpọ̀ nínú iṣẹ́ ẹ̀rọ wá, àmọ́, Ìgbìmọ̀ Tí Ń Bójú Tó Ìṣúra Ìjọba Àpapọ̀ ní [Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà] fẹ́ rí i dájú pé bó ti wù kí ọ̀ràn náà rí, yóò ṣeé ṣe fún àwọn ará Amẹ́ríkà láti ra oúnjẹ nínú ẹgbẹ̀rúndún tuntun náà. Báńkì ìjọba àpapọ̀ ti ṣètò láti tẹ àádọ́ta bílíọ̀nù dọ́là tuntun síta ní àfikún sí owó tí àwọn ènìyàn ń ná kí ó má bàa di pé owó kò tó fún àwọn tó ń fowó sí báńkì kí ó wá di pé a ń fi ẹ̀rọ yí ìwé ìsanwó sí báńkì.” Ó yẹ kí àfikún owó náà ti délẹ̀ ní ìparí September 1999. Àwọn ògbólógbòó kọ̀ǹpútà tó ń lo kìkì fígọ̀ méjì tó gbẹ̀yìn láti tọ́ka sí ọdún lè máa pe ọdún 2000 ní 1900. Àwọn ògbógi kan ń bẹ̀rù pé àwọn kọ̀ǹpútà kan lè dẹnu kọlẹ̀ nítorí ìṣòro yìí tí a mọ̀ sí Y2K [Ọdún 2000]. A lè yanjú ìṣòro yìí nípa ṣíṣe àtúnṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ lọ́nà tó gbòòrò, tó sì ń gba àkókò, àmọ́ àìpẹ́ yìí ní ọ̀pọ̀ báńkì àti àwọn ilé iṣẹ́ ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ irú ìtòlẹ́sẹẹsẹ bẹ́ẹ̀. Ìròyìn náà sọ pé: “Àwọn ẹgbẹ́ onísìn kan tí wọ́n ka òpin ẹgbẹ̀rúndún náà sí àmì ìkìlọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì” àti “ìwópalẹ̀ ẹgbẹ́ àwùjọ tó lè wáyé,” ti ru àníyàn àwọn aráàlú sókè lórí ìlọ́lùpọ̀ tó lè ṣẹlẹ̀ sí ìnáwó.

Àrùn Sunrunsunrun Tún Dé

Ní 1974, Àǹgólà ròyìn ẹni mẹ́ta tí àrùn sunrunsunrun mú. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, Àjọ Ìlera Àgbáyé fojú díwọ̀n iye àwọn tó ń yọ lẹ́nu níbẹ̀ sí nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọ̀ọ́dúnrún [300,000], ó kéré tán. Ó ṣeé ṣe kí ẹgbẹẹgbẹ̀rún, tàbí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ sí i pàápàá tún wà nínú ewu. Àrùn sunrunsunrun máa ń ṣeni lẹ́yìn tí irù bá jẹ ènìyàn. Lẹ́yìn tí irù bá fa ẹ̀jẹ̀ ẹnì kan tó ní kòkòrò àrùn náà lára, yóò lọ dà a sára ẹlòmíràn. Àwọn tí ń ṣiṣẹ́ lórí pápá tàbí tí wọ́n ń fọṣọ lódò—àti àwọn ọmọ ọwọ́ tí àwọn òbí wọn pọ̀n sẹ́yìn pàápàá—ló ń fara gbá a jù. Àwọn tí àrùn náà ń ṣe kọ́kọ́ máa ń ní ẹ̀fọ́rí, ibà, wọn a sì máa bì. Wọn kì í lè sùn lóru, wọ́n sábà máa ń tòògbé lójú mọmọ. Kòkòrò àfòmọ́ náà máa ń gbógun ti ìgbékalẹ̀ iṣan ara, yóò sì lọ sí ọpọlọ níkẹyìn, yóò wá yọrí sí ọpọlọ dídàrú, dídákú, àti ikú. Ìwé ìròyìn The Daily Telegraph ti London ròyìn pé, ṣíṣẹ́pá ìpele ìbàjẹ́ tó ń ṣe fún ara àti títọ́jú ẹni tó bù jẹ gbówó lórí gan-an, ó sì ṣòro—ó jẹ́ nǹkan bíi àádọ́rùn-ún dọ́là fún ẹnì kan, “owó ńlá sì nìyẹn jẹ́ ní Àǹgólà.”

Jíjẹ́ Ẹni Tí Ara Rẹ̀ Le

Ìwé The Physical Activity Guide, tí Health Canada ṣe jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí, sọ pé: “Eré ìmárale kò ní láti jẹ́ èyí táa fi gbogbo agbára ṣe ká tó lè mú kí ìlera wa sunwọ̀n sí i.” Bí ìwé ìròyìn The Toronto Star ṣe sọ, “o lè mú kí ìlera rẹ àti ọkàn-àyà rẹ sunwọ̀n sí i nípa ṣíṣe eré ìmárale tó mọ níwọ̀n fún nǹkan bí ìṣẹ́jú mẹ́wàá kí o sì wá ro gbogbo rẹ̀ pọ̀ sí wákàtí kan lójúmọ́.” Àwọn eré ìmárale wo ni a dábàá? Ìrìn rírìn, gígun àtẹ̀gùn, ṣíṣe iṣẹ́ nínú oko etílé, àti nínà tàntàn wà lára wọn. Àwọn iṣẹ́ ilé bíi fífi ẹ̀rọ gbálẹ̀ ilé tàbí nínú ilẹ̀ tún ṣe pàtàkì, wọ́n sì ń mú ara yá gágá. Ìwé atọ́nisọ́nà náà dábàá pé góńgó lílo wákàtí kan lóòjọ́ “lè ṣeé ṣe nípa fífi eré ìmárale kún ìgbòkègbodò rẹ ojoojúmọ́.” Dókítà Francine Lemire, ọ̀gá àgbà ní Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Oníṣègùn Ìdílé ní Kánádà, sọ pé: “Bí ara rẹ kò bá gbé kánkán, ìwádìí fi hàn pé ó lè jẹ́ sìgá mímu ló ń wu ìlera rẹ léwu.”

Ewu Kọ̀ǹpútà Nínú Ọkọ̀ Òfuurufú

Ìwé ìròyìn The Daily Telegraph ti Sydney, Ọsirélíà, sọ pé: “Àwọn ògbóǹkangì gbà gbọ́ pé ọjọ́ kan ń bọ̀ tí ẹ̀rọ abánáṣiṣẹ́ àdáni (PED) kékeré bíi kọ̀ǹpútà kélébé, fóònù alágbèéká, ẹ̀rọ amìjìnjìn tó ń lo ike ìkósọfúnnisí CD tàbí kọ̀ǹpútà tí a fi ń ṣe eré ìdárayá yóò fa jàǹbá ńlá nínú ọkọ̀ òfuurufú bíi bọ́ǹbù àwọn apániláyà. Ìròyìn tuntun kan fìdí ẹ̀rí àádọ́ta ìṣẹ̀lẹ̀ tí ọkọ̀ òfuurufú tó ń kérò ti fojú winá jàǹbá onígbàdíẹ̀ nígbà tí ọkọ̀ wà lórí ìrìn nítorí pé àwọn èrò ọkọ̀ ń lo àwọn ohun abánáṣiṣẹ́ àdáni.” Àpẹẹrẹ kan ni ti ọkọ̀ òfuurufú kan tó fẹ́ balẹ̀ sí pápákọ̀ òfuurufú Melbourne, Ọsirélíà. Ọkọ̀ òfuurufú tí a mú kí ó máa dá tu ara rẹ̀ náà ṣàdédé já lọ sí apá òsì lójijì, ìdíwọ̀n ìdagun rẹ̀ sì tó nǹkan bí ọgbọ̀n ní ìwọ̀n. Àmọ́ ẹnikẹ́ni kò fọwọ́ kan àwọn ohun tí a fi ń darí rẹ̀. Ìwádìí fi hàn pé ọ̀kan lára èrò ọkọ̀ tó jókòó sí ìlà kẹta ló ń lo kọ̀ǹpútà àgbélétanlò rẹ̀, láìka ìtọ́ni tó ṣe kedere tí ẹni tí ń darí ọkọ̀ fún wọn sí pé kí wọ́n pa gbogbo ohun èlò abánáṣiṣẹ́ wọn. Irú àwọn ìhùmọ̀ bẹ́ẹ̀ ti mú kí ọkọ̀ òfuurufú lọ sókè, kí ó dojú dé, kí ó kọjú sí ọ̀nà ibòmíràn, kí ó tilẹ̀ pàdánù agbára ìgbéra sókè rẹ̀ lójú òfuurufú. Àwọn ẹ̀rọ tí ń darí ọkọ̀ lè gbé àwọn ìsọfúnni tí ń wá láti inú àwọn ẹ̀rọ abánáṣiṣẹ́ àdáni lójú ẹsẹ̀ kí ó sì nípa lórí wọn. Àwọn èrò tó ń jókòó síwájú ọkọ̀ òfuurufú ló máa ń fa ìṣòro jù, nítorí pé òkè àwọn ẹ̀rọ abánáṣiṣẹ́ ọkọ̀ òfuurufú náà gan-an ni wọ́n jókòó sí.

Ọ̀nà Tuntun Tí A Ń Gbà Fiṣẹ́ Abẹ Bímọ

Ìwé ìròyìn Augsburger Allgemeine ti ilẹ̀ German sọ pé: “Ọ̀nà tuntun kan tí a ń gbà fiṣẹ́ abẹ bímọ lè mú kí ọmọ bíbí yára, kí ó sì túbọ̀ máa rọrùn sí i. Ní lílo ìlànà Misgav-Ladach, oníṣẹ́ abẹ náà yóò fa ọ̀rá inú ẹni náà, ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ àpòlúkù, àti iṣu ẹran ara obìnrin tó ń bímọ náà kí ó lè nà, dípò fífi abẹ tí a fi ń ṣiṣẹ́ abẹ gé e bíi ti tẹ́lẹ̀.” Níwọ̀n ìgbà tí ibi tí wọ́n ń gé ti dín kù, ẹ̀jẹ̀ dídà ti mọ níwọ̀nba, àti pé ipele awọ àti ẹran ara mẹ́ta péré la óò rán lẹ́yìn-ọ-rẹyìn, yàtọ̀ sí méje tó bá jẹ́ pé ọ̀nà táa mọ̀ tẹ́lẹ̀ la lò. Síwájú sí i ìlànà yìí kì í gba àkókò púpọ̀, ó sì ń dín ewu àkóràn àrùn kù, ìwọ̀nba oògùn apàrora la nílò, obìnrin náà sì lè kúrò nílé ìwòsàn lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta sí márùn-ún. A fún ìlànà yìí ní orúkọ ilé ìwòsàn kan tó kọ́kọ́ dán an wò ní Ísírẹ́lì.

Kì í Ṣe Àbájáde Tí A Fẹ́

Ètò ìrìnnà ọkọ̀ láàárín ìlú sábà máa ń tán àwọn awakọ̀ ní sùúrù. Ìwádìí kan tí àwọn afìṣemọ̀rọ̀nú ní Yunifásítì La Sapienza ní Róòmù ṣe ti fi hàn pé bí ọkọ̀ ṣe ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀kọ́rọ̀ tí ń bọ́ lẹ́nu àwọn tí ń sọ̀rọ̀ nípa ìsìn ń pọ̀ sí i. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Corriere della Sera ti sọ, “mẹ́rìnléláàádọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọ̀rọ̀ ìbúra àti àwọn ìwà tí kò fọ̀wọ̀ fún ìsìn” ni ìṣòro tó ní í ṣe pẹ̀lú ètò ìrìnnà ń fà lójú pópó. Bó ti wù kó rí, “ìtẹ̀sí láti dẹ́bi fún àwọn ẹni mímọ́ àti àwọn ẹni ọ̀wọ̀” túbọ̀ hàn gbangba nínú ìṣètò ìrìnnà ọkọ̀ ní àwọn ìlú ńlá. Ìwé ìròyìn náà sọ pé: “Lóde òní, ní àwọn ìlú ńlá àkànṣe, méjìdínlọ́gọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọ̀rọ̀ àìlọ́wọ̀ tí a mọ̀ sí ọ̀rọ̀ ìbúra, ni ètò ìrìnnà ọkọ̀ ń fà.” Ètò ìrìnnà ọkọ̀ ti wá di ìṣòro ńlá lẹ́nu àìpẹ́ yìí ní Róòmù nítorí ètò tí wọ́n ń ṣe ní ìmúrasílẹ̀ de ọdún 2000, tí wọ́n ti polongo pé yóò jẹ́ Ọdún Ìdásílẹ̀ fún Ìjọ Kátólíìkì nígbà tí sísan owó ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ yóò wáyé. Olùdarí àwọn gbáàtúù Olùwòye Ọdún Ìdásílẹ̀ náà sọ pé: “Ó dà bí ẹ̀dà ọ̀rọ̀ àmọ́ òtítọ́ ni, pé ipa àkọ́kọ́ tí Ọdún Ìdásílẹ̀ náà lè ní ní Róòmù lè jẹ́ sísọ ọ̀rọ̀ ìbúra di púpọ̀, kí ó máà jẹ́ ti ìsanpadà owó ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀.”

Tardigrade Alágbára Ńlá

Ìwé ìròyìn New Scientist sọ pé, ẹranko tí kò tó ààbọ̀ mìlímítà ní gígùn ní tardigrade jẹ́, a sì lérò pé òun ni ohun alààyè tó lágbára jù láyé. A máa ń pè é ní béárì inú omi nítorí bó ṣe máa ń rí nígbà tí a bá fi awò amúǹkantóbi wò ó, ó ní ẹsẹ̀ mẹ́jọ, ó sì dà bíi pé a di ìhámọ́ra fún wọn. Kódà, bí ojú ọjọ́ bá tutù nini tó ìwọ̀n 270 nísàlẹ̀ òdo sí ìwọ̀n 151 nísàlẹ̀ òdo lórí òṣùwọ̀n Celsius kò lè rí i gbé ṣe, ó ṣeé ṣí payá sí ìtànná X ray, tàbí atẹ́gùn, àti ipá alágbára tó fi ìlọ́po mẹ́fà ju èyí tó wà ní ìsàlẹ̀ inú ibú òkun pátápátá. A lè rí i ní àwọn ibi tí omi dárogún sí lórí òrùlé àti láàárín pàlàpálá òkúta. Àwọn kan lára àwọn kòkòrò wọ̀nyí ti sọjí padà lẹ́yìn tí wọ́n ti wà lójú kan fún ohun tó ju ọgọ́rùn-ún ọdún nínú àkójọ ewédò gbígbẹ ni ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí. Kí ló mú kí èyí ṣeé ṣe? Ọ̀jọ̀gbọ́n Kunihiro Seki ti Yunifásítì Kanagawa ní Japan, sọ pé, wíwà ní ipò mímú kí àwọn ẹ̀yà ara kan dúró láìṣiṣẹ́ fún ìgbà díẹ̀ ni, nígbà tí “ìwọ̀n ara bá dínkù sí ìdajì tàbí kó kéré jù bẹ́ẹ̀ lọ, nípa mímú kí gbogbo omi ara fẹ́rẹ̀ẹ́ gbẹ tán.”

Fífi Orin Abágbàmu Tu Àwọn Èrò Ọkọ̀ Lára

Àwọn èrò ọkọ̀ ti wa ń gbọ́ àwọn orin abágbàmu tí àwọn akọrin bíi Strauss, Vivaldi, Chopin, Tchaikovsky, Mozart, Bach, Bizet, Schubert, àti Brahms kọ nígbà tí wọ́n bá ń dúró de ọkọ̀ ojú irin ní ibùdókọ̀ abẹ́lẹ̀ méjìdínlógún lára àwọn ibùdókọ̀ abẹ́lẹ̀ tó wà ní Rio de Janeiro. Ìwé ìròyìn O Globo sọ pé, lọ́nà yìí, àwọn aláṣẹ ibùdókọ̀ abẹ́lẹ̀ fẹ́ “láti fọkàn àwọn èrò ọkọ̀ balẹ̀ ní àárín àkókò tí wọ́n fi ń rin ìrìn-àjò.” Nígbà tí wọ́n ń yan àwọn orin náà, “àwọn orin tí yóò tu àwọn èrò ọkọ̀ lára, síbẹ̀ tí kò ní fún wọn ní èrò pé àwọn wà lórí pèpéle ní gbọ̀ngàn ijó.” Luiz Mário Miranda, olùdarí ètò kárakátà ní ibùdókọ̀ abẹ́lẹ̀ ti Rio de Janeiro sọ pe: “Àwọn ènìyàn tẹ́wọ́ gbà á ju bí a ti retí lọ.”

Ojúṣe Olúkúlùkù

Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn The Guardian Weekly sọ pé: “Àwọn ènìyàn ti ń fi dídín igbó, omi tí kò níyọ̀ àti àwọn ohun tó wà nínú òkun tí ìwàláàyè sinmi lé kù lọ́nà líléwu pa èyí tó ju ìpín ọgbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn ohun àmúṣọrọ̀ tó wà láyé run láti ọdún 1970.” Àpilẹ̀kọ tí a gbé karí ìròyìn ètò àjọ mẹ́ta tó ń ṣàníyàn títí kan Àjọ Akówójọ fún Ìdáàbòbò Ohun Alààyè Inú Ìgbẹ́ Lágbàáyé (WWF), ṣàkíyèsí pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn orílẹ̀-èdè Ìwọ̀ Oòrùn ni wọ́n ní àwọn ènìyàn ti ń lo ohun àmúṣọrọ̀ jù láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀, àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà ti wá “ń pa àwọn ohun àmúṣọrọ̀ wọn rẹ́ dé ìwọ̀n tí ń bani lẹ́rù” báyìí. Ẹnì kan tí ń bá Àjọ WWF ṣiṣẹ́ sọ pé: “A mọ̀ pé ó burú, ṣùgbọ́n títí di ìgbà tí a ṣe ìròyìn yìí, a kò mọ̀ pé ó burú tó bẹ́ẹ̀.” Ìwé ìròyìn náà sọ pé, nígbà tí ìròyìn náà dẹ́bi fún àwọn ìjọba nítorí àìdá ìṣòro náà dúró, ó tún mẹ́nu bà á pé “olúkúlùkù wa ló jẹ̀bi àìbìkítà nípa àwọn ohun àmúṣọrọ̀ orí ilẹ̀ ayé.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́