Wíwo Ayé
Ìwà Ọ̀daràn—Òwò Tí Ń Mówó Wọlé
Ìròyìn 1997 ti Àjọ Olówò, àjọ àwọn oníṣòwò ní Ítálì, sọ pé, ìwà ọ̀daràn tí ẹgbẹ́ ń ṣètò ń pa iye tí a fojú díwọ̀n sí 200 sí 240 bílíọ̀nù dọ́là lọ́dọọdún ní Ítálì. Ó kéré tán, bílíọ̀nù 18 dọ́là ni a ròyìn pé ó ń wọlé láti inú òwò gbígbé oògùn olóró, bílíọ̀nù 11 dọ́là ń wọlé láti inú iṣẹ́ aṣẹ́wó, àti bílíọ̀nù 15 sí 18 dọ́là láti inú ìyánilówó èlé àti òwò jìbìtì. Ìwé agbéròyìnjáde La Repubblica sọ pé: “Mẹ́ta lára òwò mẹ́wàá ni àwọn ènìyàn tàbí àwọn ilé iṣẹ́ tí ó ní ìsopọ̀ pẹ̀lú àwọn àjọ oníwà ọ̀daràn ń bójú tó; ìpín 20 sí ìpín 25 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn iṣẹ́ òwò tí a ń ṣe ní báńkì lójoojúmọ́ ló ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí ó rúni lójú.”
Kíka Ìwé Ṣì Wọ́pọ̀
Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan tí Àjọ Ìwádìí Nípa Ìlànà ṣe ti sọ, ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà kò tí ì yí àṣà ìwé kíka pa dà ní Britain. Gẹ́gẹ́ bí a ti ròyìn rẹ̀ nínú ìwé agbéròyìnjáde The Times, “ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ìdajì àwọn tí a lò fún ìwádìí ni wọ́n sọ pé àwọn ń ka ìwé kan lọ́wọ́lọ́wọ́ fún fàájì, ìpín kan tí ìyípadà rẹ̀ kéré jọjọ láti 1989.” Àwọn obìnrin máa ń kàwé ju àwọn ọkùnrin lọ, àwọn ènìyàn tí wọ́n sì ti lé ní ẹni ọdún 55 ni wọ́n máa ń kàwé jù lọ. Àwọn ìwé oúnjẹ gbígbọ́ ló wọ́pọ̀ jù lọ, lẹ́yìn náà ni àwọn ìwé nípa ìwà ọ̀daràn tàbí èyí tí ń runi sókè, àwọn ìwé eléré ìfẹ́, àti ti ìtàn àròsọ ọ̀rúndún ogún. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìpín 30 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn agbo ilé ló ní kọ̀ǹpútà, kìkì ìpín 7 nínú ọgọ́rùn-ún lára wọn ló ní ìṣètò lílo àwọn ike ìkósọfúnnisí, tí ó jẹ́ alábàádíje ìwé. Àti pé, ìwé agbéròyìnjáde The Times sọ pé, láìdà bí àwọn kọ̀ǹpútà àgbélétan, ìwé kan tí ó gbádùn mọ́ni kò lè bà jẹ́ bí iyanrìn bá dà sínú rẹ̀ létíkun kan tí a ti lọ lo ìsinmi, bẹ́ẹ̀ ni àwọn èrò tí ń rọ́ gìrìgìrì lójú ọ̀nà abẹ́lẹ̀ tí ìgbòkègbodò pọ̀ kan kò lè bà á jẹ́, ìwé kan tí a ṣe jáde lọ́nà jíjojúnígbèsè sì lè “jojú ní gbèsè tó bí ohun tí ó wà nínú rẹ̀ ṣe ń ṣeni láǹfààní tó.”
Pípadà sí Lílo Omi
Ìwé ìròyìn New Scientist sọ pé: “Wíwá tí a ti ń wá kẹ́míkà tí ó lè paná, tí kò ní ṣèpalára fún ìpele ozone láti ọjọ́ pípẹ́ ti ṣamọ̀nà níkẹyìn sí . . . omi. Lẹ́yìn dída omi sí ọgọ́rọ̀ọ̀rún iná àfiṣàyẹ̀wò, Ibi Ìwádìí Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀ fún Ìṣèwádìí Nípa Iná ní Norway, tí ó wà ní Trondheim, ti dé ìparí èrò náà pé, fífọ́n omi jẹ́ àfirọ́pò tí ó bá a mu fún àwọn kẹ́míkà halon tí ń ṣèpalára fún ìpele ozone, tí a ṣì ń lò lọ́nà púpọ̀ nínú àwọn èròjà ìpaná.” Àwọn kẹ́míkà halon—àwọn àpòpọ̀ èròjà carbon, bromine, àti fluorine—ń pa iná. Àwọn ẹ̀kán omi ń ṣe ohun kan náà, ní fífà wọ́n gbẹ àti fífẹ̀ wọ́n fún ìgbà 1,700 ju ìwọ̀n wọn gidi lọ láti mú afẹ́fẹ́ oxygen kúrò. Àkókò kan ṣoṣo tí a rí i tí wọn kì í gbéṣẹ́ tó àwọn kẹ́míkà halon jẹ́ nínú iná eléèéfín, tí kò pọ̀ dé àyè tí kò gbóná tó láti fa omi rẹ̀ gbẹ. Àmọ́ a ṣì ń wá àwọn àfirọ́pò àtọwọ́dá fún àwọn èròjà halon, nítorí pé omi ń gbé ìṣòro mìíràn dìde: A kò lè jèrè rẹpẹtẹ ní títà á.
Ní Báyìí —Àrùn Mẹ́dọ̀wú Ìpele G
Àwọn dókítà ní Japan ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé láàárín oṣù kan tí àwọn aláìsàn bá gba ẹ̀jẹ̀ sára, wọ́n máa ń kó fáírọ́ọ̀sì àrùn mẹ́dọ̀wú ìpele G, ipa tuntun kan tí a ṣàwárí ní 1995 ní United States. Nípa ṣíṣàtúnyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ àwọn agbàtọ́jú fún àrùn jẹjẹrẹ inú ẹ̀dọ̀ tí a ṣiṣẹ́ abẹ fún láàárín ọdún 1992 sí 1994 ní Ilé Ìwòsàn Toranomon ní Tokyo, àwọn dókítà ṣàwárí pé 2 lára àwọn aláìsàn 55 ti ní àkóràn kí a tó ṣiṣẹ́ abẹ fún wọn àti pé àwọn 7 mìíràn kó o lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ. Àwọn dókítà náà sọ pé, àwọn ẹ̀jẹ̀ alárùn tí ọ̀kọ̀ọ̀kan lára àwọn aláìsàn 7 náà gbà sára wá láti ọ̀dọ̀ ìpíndọ́gba afẹ̀jẹ̀tọrọ 71, èyí ń fi hàn pé ìpín 1.4 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn ìpèsè ẹ̀jẹ̀ tí a lò ni àwọn fáírọ́ọ̀sì tuntun náà wà nínú rẹ̀. Ìwé agbéròyìnjáde Asahi Evening News sọ pé, ìwọ̀nba ohun díẹ̀ ni a mọ̀ nípa fáírọ́ọ̀sì àrùn mẹ́dọ̀wú ìpele G tàbí ìpín mélòó nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn tí wọ́n ní in lára ni yóò wá ní àrùn mẹ́dọ̀wú tàbí àrùn jẹjẹrẹ inú ẹ̀dọ̀.
“Àṣìṣe Ẹgbẹ̀rúndún Náà”
Ìwé ìròyìn U.S.News & World Report sọ pé: “A mọ̀ ọ́n sí Àṣìṣe Ẹgbẹ̀rúndún, Ìṣòro Ọdún 2000, tàbí ní ṣákálá ‘Y2K,’” òun ni “ọ̀kan lára àwọn ipá tí ó lábùkù jù lọ tí a mọ̀ mọ ìṣiṣẹ́ kọ̀ǹpútà òde òní.” Ó bẹ̀rẹ̀ ní àwọn ọdún 1960 nígbà tí kọ̀ǹpútà wọ́n, tí ìwọ̀n agbára ìsọfúnni tí wọ́n lè gbà sì mọ níwọ̀n. Láti má fi àyè ṣòfò, àwọn aṣègbékalẹ̀ ètò ìṣiṣẹ́ kọ̀ǹpútà kọ àwọn déètì ní lílo kìkì àwọn nọ́ńbà méjì tí ó kẹ́yìn nínú ọdún. Lójú kọ̀ǹpútà, ọdún 1997 wulẹ̀ jẹ́ “97.” Kí wá ni ìṣòro ibẹ̀? “Ní Jan. 1, 2000, nǹkan bí ìpín 90 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn kọ̀ǹpútà àti ètò ìṣiṣẹ́ kọ̀ǹpútà tó wà lágbàáyé ni yóò ‘ronú’ pé ọjọ́ àkọ́kọ́ ní ọdún 1900 ni.” A ti ṣe àṣìṣe náà ná. Ìwé ìròyìn Newsweek sọ pé: “Ní ọgbà ẹ̀wọ̀n ìpínlẹ̀ kan, àṣìṣe náà mú kí àwọn kọ̀ǹpútà ṣi àkókò tó yẹ kí àwọn ẹlẹ́wọ̀n bíi mélòó kan tí a dá sílẹ̀ nígbà náà lò lẹ́wọ̀n. A ti kọ àwọn káàdì ìrajà àwìn kan ní àwọn ibi ìtajà àti àwọn ilé àrójẹ nígbà tí déètì ‘00’ tí wọ́n gbéṣẹ́ mọ́ dà rú mọ́ kọ̀ǹpútà lójú. Bákan náà ni ní àwọn ìpínlẹ̀ mélòó kan, a ti fagi lé àwọn ìwé àṣẹ àwọn awakọ̀ akẹ́rù kan fún wíwọ ìpínlẹ̀ míràn nígbà tí àwọn kọ̀ǹpútà kò lè ṣiṣẹ́ lórí àwọn ìbéèrè fún ẹ̀dà ìsọdituntun tí wọ́n ní àwọn déètì ẹgbẹ̀rúndún tó wọnú tí ń bọ̀.” Àwọn ilé iṣẹ́ jákèjádò ayé yóò ní láti ná iye tí a fojú díwọ̀n sí 600 bílíọ̀nù dọ́là láti yí àmì ìgbékalẹ̀ déètì náà pa dà—wọ́n sì lérò pé àwọn lè ṣe é ní ọdún méjì tó kù.
Àwọn Ẹranko Tí Wọ́n Ṣe Orúkọ Fúnra Wọn
Ìwé agbéròyìnjáde ilẹ̀ Ítálì náà, Corriere della Sera, sọ pé, láàárín ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn 1996, ẹyẹ àkẹ̀ wíwọ́pọ̀ kan ṣe orúkọ fúnra rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “ẹ̀dá alààyè tí ó tí ì fò jìnnà jù lọ nínú ìṣíkiri” èyí tí a ní ẹ̀rí rẹ̀. Lẹ́yìn gbígbéra láti Finland, níbi tí wọ́n ti fi òrùka sí ẹsẹ̀ rẹ̀, a rí ẹyẹ àkẹ̀ náà mú ní ọ̀sẹ̀ 18 lẹ́yìn náà ní ìpínlẹ̀ Victoria ní ìhà Gúúsù Ìlà Oòrùn Australia—lẹ́yìn ìrìn àjò 24,400 kìlómítà, tí ó rin ìpíndọ́gbà 200 kìlómítà lóòjọ́. Ẹyẹ àkẹ̀ ti ilẹ̀ olótùútù nini, tí ó fò 22,530 kìlómítà láti Rọ́ṣíà dé Australia ní 1955 ló fakọ yọ tẹ́lẹ̀. Àwọn ẹ̀dá alààyè míràn tí ìṣíkiri wọn kárí ẹgbẹẹgbẹ̀rún kìlómítà ni ẹja salmon pupa, àwọn ẹja àdàgbá, àwọn labalábá monarch, àwọn ìjàpá aláwọ̀ ewé, àti àwọn ẹranmi àbùùbùtán oníké.
Àwọn ẹranmi àbùùbùtán oníké sábà máa ń lo nǹkan bí ọjọ́ 102 láti ṣí láti Alaska lọ sí Hawaii, àmọ́ àwọn olùṣèwádìí ti ṣàwárí ọ̀kan tí ó gba ọjọ́ 39 péré láti wẹ kìlómítà 4,465! Ìrìn àjò náà jẹ́ ìpíndọ́gbà ìwọ̀n ìsáré kìlómítà 4.8 láàárín wákàtí kan. A tún ti rí ẹranmi àbùùbùtán kan náà ní Mexico. Àwọn ẹranmi àbùùbùtán oníké ṣí lọ sí Hawaii láti mú irú jáde nítorí pé àwọn ọmọ wọn kò ní ọ̀rá tí ó tó láti kojú omi oníyìnyín ti Alaska. Ìwé agbéròyìnjáde The Times ti London sọ pé, ìṣíkiri wọn jẹ́ ọ̀kan lára èyí tí ó jìnnà jù lọ tí àwọn ẹ̀dá afọ́mọlọ́mú inú òkun tí ì rìn rí.
Eṣinṣin Adọ́gbọ́nyẹra-Fúnni Yẹn!
Èé ṣe tó fi ṣòro gan-an láti pa eṣinṣin kan? Báwo ló ṣe ń ṣe é tó fi ń yára sá lọ bẹ́ẹ̀? Àṣírí ibẹ̀ wà nínú ìṣètò kan nínú ọpọlọ rẹ̀ tí ń jẹ́ fọ́nrán gígùn. Sẹ́ẹ̀lì kan tí ó jọ okùn tẹ́ẹ́rẹ́ ìdiǹkan tí ń gbé ìsọfúnni kiri láàárín àwọn apá ibòmíràn nínú ọpọlọ eṣinṣin náà ní lílo agbára mànàmáná, dípò agbára kẹ́míkà. Ní àbájáde rẹ̀, ìgbì mànàmáná náà ń yára lọ káàkiri sí apá ibi tí ń mú ìfòsókè àti ìfòkiri ṣiṣẹ́ nínú ọpọlọ, tí èyí sì ń jẹ́ kí eṣinṣin náà lè sá kúrò nínú ewu ní ìwọ̀nba ìpín mélòó kan nínú ìpín ẹgbẹ̀rún ìṣẹ́jú àáyá. Fún àpẹẹrẹ, nínú ẹ̀dá ènìyàn tí a lè mú bí àpẹẹrẹ, ó máa ń gba nǹkan bí ìdá mẹ́rin ìṣẹ́jú àáyá kan kí ọwọ́ tó gbéra ní ìhùwàpadà sí ohun kan tí ojú rí. Ìwé agbéròyìnjáde The Times ti London sọ pé, pẹ̀lú ìmọ̀ yí nípa àwọn eṣinṣin, àwọn olùṣèwádìí ní Yunifásítì Sussex ní Britain ń retí láti gbé oògùn apakòkòrò kan tí yóò ṣàṣeyọrí láti sọ ìhùwàpadà eṣinṣin náà di aláìgbéṣẹ́ jáde.
Ìṣòro Ìjàpá Òkun
Ìwé agbéròyìnjáde The Weekend Australian sọ pé, iye àwọn ìjàpá òkun ti ń kéré gan-an lọ́nà tó léwu nítorí dídọdẹ wọn jù nínú agbami òkun Asia-Pacific. Èyí mú kí Australia àti Indonesia jùmọ̀ gbàlejò àpérò kan ní Java pẹ̀lú èrò láti mú kí ọ̀nà ìdáàbòbò sunwọ̀n sí i. Nítorí pé àwọn ìjàpá òkun jẹ́ ẹ̀dá aṣíkiri, wọn kì í sì í ṣe ti orílẹ̀-èdè kan pàtó, àwọn ètò ìdáàbòbò dídára jù lọ ní orílẹ̀-èdè kan kò fi bẹ́ẹ̀ níye lórí púpọ̀ bí orílẹ̀-èdè míràn tí wọ́n ń dé bí wọ́n ti ń ṣí kiri bá ń dọdẹ àwọn ìjàpá òkun náà láìronú nípa ọjọ́ iwájú. Ìwé agbéròyìnjáde náà sọ pé: “Àwọn ìjàpá òkun tí a fojú díwọ̀n iye wọn sí 50,000 ni a ń pa lọ́dọọdún fún òwò àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ ní Bali nìkan, ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún ẹyin àwọn ìjàpá òkun ni a sì ń kó fi ṣe oúnjẹ.” Papua New Guinea pẹ̀lú ń ṣòwò ìjàpá òkun, títí kan àwọn olórí ràgàjì tí a wu léwu àti ẹlẹ́yìn awọ tí ó ṣeé tètè pa lára àti ìjàpá òkun aláwọ̀ ewé. Àwọn irú ọ̀wọ́ mìíràn tí ó wà nínú ewu ni àwọn alágòógó-àṣá, ẹlẹ́yìn pẹrẹsẹ, àti ìjàpá òkun Oliver Ridley.
Ẹnà Alámì Tóótòòtó Morse Fẹ́rẹ̀ẹ́ Run Tán ní 150 Ọdún
Ní ohun tí ó lé ní 150 ọdún sẹ́yìn, Samuel Morse, olùhùmọ̀ ará America kan, fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn wóróhùn ní ẹnà alámì tóótòòtó àti onílà gbọọrọ pàtó kan. Èyí ń mú kí a lè fa ìsọfúnni jáde láti inú àwọn ìgbì rédíò nípasẹ̀ ìhùmọ̀ kan tí a mọ̀ sí kọ́kọ́rọ́ Morse. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ohun alààyè ni a ti gbà là lórí òkun nígbà tí àwọn ọkọ̀ òkun tí wọ́n wà nínú wàhálà lo àmì pàjáwìrì ẹlẹ́nà náà, SOS. Àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun lágbàáyé pẹ̀lú ti lo ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ rírọrùn yí, bí àìmọye àwọn tí ń fi fífi ìsọfúnni ránṣẹ́ ṣe fàájì ti ṣe lò ó. Àǹfààní gíga tí ẹnà alámì tóótòòtó Morse ní ni pé ó ṣe kedere, kókó abájọ kan tí ó pọn dandan nígbà tí ẹnì kan tí ń lo rédíò bá ń sọ̀rọ̀ ní ọ̀nà ìgbàsọ̀rọ̀ àbínibí rẹ̀ tàbí tí kò lè sọ èdè ibi tí ó ṣeé ṣe kí a ti gbọ́ ìsọfúnni rẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn ìsọfúnni Morse ni a ti ń fi ìkànsíni orí rédíò ọlọ́rọ̀ ẹnu àti ètò ìgbékalẹ̀ ìbánisọ̀rọ̀ orí sátẹ́láìtì rọ́pò. Ní 1993, a kò lo ẹnà alámì náà mọ́ nínú àwọn ọkọ̀ òkun tí ń lọ lójú agbami. Ilẹ̀ Faransé kọ ètò ìgbékalẹ̀ Morse náà sílẹ̀ ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yìí, tí ó bá sì fi máa di ọdún 1999, yóò ti di ohun tí a kò lò mọ́ jákèjádò ayé.