ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 11/8 ojú ìwé 29-30
  • Wíwo Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwo Ayé
  • Jí!—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Èrò Dókítà Kejì Ha Pọndandan Bí?
  • Àwọn Ọ̀rẹ́ Tó Léwu
  • “Arúgbó Ń Gbọ́n Sí I”
  • Ọ̀nà Òkun Àríwá
  • Àwọn Ìṣòro Tó Wà Nínú Ṣíṣàyẹ̀wò Ẹ̀jẹ̀
  • Bíbá Ọmọdé Ṣèṣekúṣe ní Íńdíà
  • Jíjẹun Pọ̀ Gẹ́gẹ́ Bí Ìdílé Ló Dára Jù Lọ
  • Àwọn Ọ̀jáfáfá Takùntakùn
  • Òórùn Inú Ilé
  • Wíwo Ayé
    Jí!—1997
  • Wíwo Ayé
    Jí!—1997
Jí!—2000
g00 11/8 ojú ìwé 29-30

Wíwo Ayé

Èrò Dókítà Kejì Ha Pọndandan Bí?

Ìwé ìròyìn The News ti Ìlú Mẹ́síkò sọ pé: “Lórí ọ̀ràn ti wíwá èrò dókítà kejì nípa ìtọ́jú àìsàn, ọ̀pọ̀ jù lọ lára wa ni kì í fi ọwọ́ gidi mú un. Ṣùgbọ́n irú àṣà fífi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè ṣekú pa àwọn aláìsàn.” Àwọn aláìsàn sábà máa ń bẹ̀rù pé dókítà àwọn á rò pé àwọn fojú di í ni bí àwọn bá fẹ́ mọ èrò dókítà mìíràn nípa àìlera àwọn. Ṣùgbọ́n ìwé ìròyìn náà sọ pé, “ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn dókítà ni kò ní bínú tí àwọn aláìsàn bá lọ béèrè èrò dókítà mìíràn nípa àìsàn tó ń ṣe wọ́n. Bí dókítà tìrẹ bá bínú, a jẹ́ pé ìṣòro ń bọ̀ nìyẹn o.” Lónìí, àwọn dókítà àti àwọn elétò ìbánigbófò wo bíbéèrè èrò dókítà mìíràn gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà tó dára láti mú ìtọ́jú tó dára jù lọ dá àwọn aláìsàn lójú. Dókítà Michael Andrews, ààrẹ Ẹgbẹ́ Olùtọ́jú Àrùn Ara Wíwú ní Ìpínlẹ̀ Georgia, sọ pé, òun máa ń gba àwọn tí òun ń tọ́jú nímọ̀ràn láti lọ béèrè èrò dókítà mìíràn nípa àìsàn wọn nítorí lọ́pọ̀ ìgbà wọ́n sábà máa ń padà wá, wọn á sì túbọ̀ nígbàgbọ́ nínú àwọn oògùn tí òun kọ fún wọn. Ọ̀gá ẹgbẹ́ kan tó ń tọ́jú àwọn ará ìlú sọ pé: “Àwọn aláìsàn ní láti rántí pé ara àwọn ló wà nínú ewu.”

Àwọn Ọ̀rẹ́ Tó Léwu

Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan tí ìwé ìròyìn The Journal of the American Medical Association sọ nípa rẹ̀ ti fi hàn, ó ṣeé ṣe gan-an kí àwọn ọ̀dọ́langba tí ń wakọ̀ ní jàǹbá tó lè la ikú lọ bí wọ́n bá gbé àwọn èèyàn sínú ọkọ̀ tí wọ́n ń wà. Àwọn olùwádìí ní Yunifásítì Johns Hopkins, ní Ìpínlẹ̀ Maryland, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, ṣàwárí pé ewu kí ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún tó ń wakọ̀ kú fi ìpín mọ́kàndínlógójì pọ̀ sí i tó bá gbé èèyàn kan ṣoṣo sínú ọkọ̀ tó ń wà, ó fi ìpín mẹ́rìndínláàádọ́rùn-ún pọ̀ sí i tó bá gbé èèyàn méjì, ó sì fi ìpín ọgọ́rùn-ún méjì ó lé méjìlélọ́gọ́rin pọ̀ sí i tó bá gbé èèyàn mẹ́ta tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Nínú ìwádìí náà, ohun pàtàkì tí wọ́n sọ pé ó ń fà á ni “àṣà wíwakọ̀ níwàkuwà . . . , ohun tó sì máa ń fà á jù ni pé àwọn ojúgbà wọn wà níbẹ̀.” Lára irú àwọn ìwà tó léwu bẹ́ẹ̀ ni sísáré àsápajúdé, sísúnmọ́ ọkọ̀ tó wà níwájú jù, tàbí ṣíṣàìdúró nígbà tí iná ojú títì bá tan pupa tàbí wíwakọ̀ nígbà téèyàn bá ti lo oògùn líle tàbí tó ti mutí, àti kí àwọn èrò ọkọ̀ tí ń ṣerépá máa díni lọ́wọ́.

“Arúgbó Ń Gbọ́n Sí I”

Ìwé ìròyìn The Times ti London sọ pé àwọn olùwádìí ti ṣàwárí pé àwọn ẹ̀yà kan nínú ọpọlọ lè mú àwọn sẹ́ẹ̀lì tuntun jáde bí àwọn èèyàn ṣe ń darúgbó sí i. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, ohun táwọn èèyàn gbà gbọ́ ni pé àwọn sẹ́ẹ̀lì ọpọlọ kì í mú ẹ̀yà tuntun jáde mọ́ tí èèyàn bá ti dàgbà. Ìwé ìròyìn The Times náà sọ pé: “Tí èrò orí bá jí pépé, àwọn ẹ̀yà tuntun náà á lè máa yọ.” Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe láìpẹ́ yìí, tí wọ́n lo àwọn èèyàn tí wọ́n ti lé ní ẹni ọdún márùndínláàádọ́rin fi hàn pé ó jọ pé kíkẹ́kọ̀ọ́ àti àjọṣe pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn ń mú kí àwọn ẹ̀yà tuntun náà máa dàgbà nínú sẹ́ẹ̀lì ọpọlọ àti àwọn okùn ọpọlọ. Àwọn olùwádìí náà ṣàwárí pé níní àjọṣe pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn ń mú kí “ìlera sunwọ̀n sí i, ó ń mú kí ẹ̀mí gùn sí i, ó sì ń mú kí ìgbésí ayé sunwọ̀n sí i.” Susan Greenfield, tó jẹ́ onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ètò iṣan ara, sọ pé: “Bí ìrírí rẹ bá ṣe pọ̀ tó ni àwọn okùn ọpọlọ rẹ yóò ṣe pọ̀ tó. Nítorí náà, àwọn èèyàn ń darúgbó, wọ́n sì ń gbọ́n sí i.”

Ọ̀nà Òkun Àríwá

Robert Thorne tí í ṣe oníṣòwò tó ń ta nǹkan amóúnjẹ-tasánsán ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún wòye nígbà kan pé òun rí ọ̀nà kan lójú òkun táa lè gbà láti Yúróòpù lọ́ sí Ìpẹ̀kun Ìlà Oòrùn tí a bá gba Ilẹ̀ Olótùútù Nini kọjá. Ìwé ìròyìn The Times ti London sọ pé, lónìí, ohun tí Thorne wòye rẹ̀ nígbà yẹn ti ṣẹ, mímóoru ilẹ̀ ayé ló sì mú kó rí bẹ́ẹ̀. Nísinsìnyí, omi tó wà ní àwọn etíkun Rọ́ṣíà àti Ìlà Oòrùn Siberia ti fẹ́rẹ̀ẹ́ máà ní yìnyín nínú mọ́ jálẹ̀ àwọn oṣù ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn, èyí sì ń jẹ́ kí àwọn ọkọ̀ òkun tí ń kẹ́rù lè máa gba Àgbègbè Ilẹ̀ Olótùútù Nini wá láti Òkun Àríwá, kí wọ́n sì gba Ipadò Bering wá sí àgbègbè Pàsífíìkì. Nígbàkigbà tí ọ̀nà ojú omi tí àwọn ọkọ̀ òkun tó ń bọ̀ láti Yúróòpù ń gbà bá ti di yìnyín, ńṣe ni wọ́n máa ń gba Ọ̀nà Abẹ́lẹ̀ ti Suez, tàbí kí wọ́n gba igun apá ìsàlẹ̀ Áfíríkà, tàbí kí wọ́n gba Ọ̀nà Abẹ́lẹ̀ ti Panama láti dé Ìpẹ̀kun Ìlà Oòrùn. Àǹfààní tó wà nínú gbígba ọ̀nà òkun ìhà àríwá kò kéré rárá. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ dín bí Hamburg, Jámánì, àti Yokohama, Japan ṣe jìnnà síra kù sí ìdajì—tí kò tó ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlá kìlómítà.

Àwọn Ìṣòro Tó Wà Nínú Ṣíṣàyẹ̀wò Ẹ̀jẹ̀

Ìròyìn kan tí àjọ akóròyìnjọ Associated Press gbé jáde sọ pé: “Ó lé ní ìdajì lára àwọn orílẹ̀-èdè ayé tí kì í ṣàyẹ̀wò àwọn ẹ̀jẹ̀ tí àwọn èèyàn fi tọrẹ ní kíkún, èyí sì ń mú kí ewu títan àrùn éèdì àti àwọn àrùn mìíràn kálẹ̀ pọ̀ sí i.” Ìròyìn yìí tí a gbé karí ìsọfúnni tó wá látọ̀dọ̀ Àjọ Ìlera Àgbáyé, tún sọ pé “ìpín márùn-ún sí mẹ́wàá nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn èèyàn tó ní kòkòrò tó ń di àrùn éèdì la fojú díwọ̀n pé láti inú ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n gbà sára ni wọ́n ti kó o.” Bó ti wù kó rí, àrùn éèdì wulẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àrùn tí àwọn èèyàn ń kó lọ́nà yìí ni. Lọ́dọọdún, mílíọ̀nù mẹ́jọ sí mẹ́rìndínlógún àkóràn àrùn mẹ́dọ̀wú ìpele B àti mílíọ̀nù méjì sí mẹ́rin àkóràn àrùn mẹ́dọ̀wú ìpele C làwọn èèyàn ń kó láti inú ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n gbà sára àti lílo abẹ́rẹ́ tí kò mọ́. Ìdí kan tí wọ́n sọ pé ó ń fà á tí wọ́n kì í fi í ṣàyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ dáadáa ni pé ó ti wọ́n jù láti ṣe é. Ó ń ná wọn tó ogójì sí àádọ́ta dọ́là lórí ìdì kan péré láti ṣàyẹ̀wò bóyá àwọn kòkòrò wọ̀nyẹn wà níbẹ̀. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìròyìn náà sọ pé, irú àyẹ̀wò wọ̀nyẹn “kì í fi bẹ́ẹ̀ láyọ̀lé, ní pàtàkì tó bá jẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ tí wọn kò kọ́ nípa rẹ̀ dáadáa ló ṣe é tàbí tó bá jẹ́ àwọn ohun èèlò tí kò dára tó ni wọ́n fi ṣe é.”

Bíbá Ọmọdé Ṣèṣekúṣe ní Íńdíà

Ìwé ìròyìn The New Indian Express sọ pé, ní ìṣẹ́jú mẹ́wàá-mẹ́wàá ni wọ́n ń mú ọmọdé kan wọnú iṣẹ́ aṣẹ́wó ní Íńdíà. Èyí túmọ̀ sí pé nǹkan bí ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [50,000] ọmọdé ní ilẹ̀ Íńdíà ni wọ́n ń fipá mú wọnú òwò ìṣekúṣe lọ́dọọdún. Ní ìpínlẹ̀ Kerala, ìpàdé àpérò kan tó dá lórí gbígbógun ti bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe gbé ohun tó yani lẹ́nu mìíràn tó tún ń ṣẹlẹ̀ jáde. Ìwé ìròyìn náà sọ pé, àwọn dókítà ibẹ̀ máa ń “lọ́ra láti ṣiṣẹ́ lórí àwọn ọ̀ràn ìfipábáni-lòpọ̀ nítorí pé wọn kò mọ̀ nípa rẹ̀ dunjú, wọn kì í sì í fẹ́ dáwọ́ lé e.” Nínú àwọn ọ̀ràn kan, àwọn òbí pàápàá ń dá kún ìṣòro náà. Sreelekha, tí í ṣe Ọ̀gá Àwọn Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ti Ìjọba Àpapọ̀, sọ pé: “Àwọn òbí máa ń lọ́ra láti fi ẹjọ́ [ọ̀ràn ìfipábáni-lòpọ̀] sun àwọn aláṣẹ nítorí pé ó lè di àmì tí ń dójú tini, ó sì lè mú kí wọ́n ta wọ́n nù láwùjọ.”

Jíjẹun Pọ̀ Gẹ́gẹ́ Bí Ìdílé Ló Dára Jù Lọ

Ìwé ìròyìn Globe and Mail sọ pé ọ̀kan lára ọ̀nà tó dára jù lọ tí àwọn òbí fi lè mú kí àwọn ọmọ wọ́n ní ìlera tó pé jẹ́ nípa jíjẹun pọ̀ pẹ̀lú wọn. Gẹ́gẹ́ bí Dókítà Matthew Gillman tó ń ṣiṣẹ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìṣègùn ti Harvard ti sọ, “oúnjẹ tí ìdílé jẹ papọ̀ máa ń fára lókun gan-an ju èyí tí àwọn ọmọdé àti àwọn aṣẹ̀ṣẹ̀bàlágà lè máa rà jẹ lọ.” Ó ṣeé ṣe kí àwọn ọmọ tó ń jẹ oúnjẹ tí ìdílé sè máa jẹ ìwọ̀n èso àti ewébẹ̀ tó yẹ, láti gba fítámì àti èròjà aṣaralóore tí ara wọ́n nílò sára, kí wọ́n má sì máa jẹ ṣúgà àti ọ̀rá jù. Àwọn olùwádìí náà tún ṣàwárí pé jíjẹun pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé á jẹ́ kí wọ́n lè jùmọ̀ sọ̀rọ̀ nípa jíjẹun lọ́nà tó dára, yóò sì gbin àṣà jíjẹun lọ́nà tó dára sọ́kàn àwọn ọmọ—àṣà yìí yóò sì mọ́ wọn lára nígbà tí wọ́n bá ń jẹun níta. Ìwé ìròyìn Globe sọ pé ìwádìí tuntun náà, tí a mú láti inú iṣẹ́ ìwádìí tí kò dáwọ́ dúró tí a sì lo ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógún ọmọ tí ọjọ́ orí wọ́n wà láàárín ọdún mẹ́sàn-án sí mẹ́rìnlá, fi hàn pé “méjì péré lára ọmọ márùn-ún tí wọ́n ṣì ń lọ sílé ẹ̀kọ́ ló ń jẹun papọ̀ pẹ̀lú àwọn òbí wọn ní ọjọ́ tó pọ̀ jù lọ, ọ̀kan lára àwọn márùn-ún ni kò sì jẹun papọ̀ pẹ̀lú wọn rí.”

Àwọn Ọ̀jáfáfá Takùntakùn

Ìwé ìròyìn New Scientist sọ pé: “Okùn aláǹtakùn jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun tó lágbára jù lọ ní Ayé.” Fọ́nrán rẹ̀ kọ̀ọ̀kan lè nà ní ìlọ́po méjì sí mẹ́rin gígùn rẹ̀ kó tó gé, ó sì lágbára gan-an tí wọ́n fi lè sọ nípa rẹ̀ pé fọ́nrán okùn náà tó ki tó pẹ́ńsù lè dá ọkọ̀ òfuurufú ayára bí àṣá tó ń fò lọ dúró. Àwọn olùwádìí ti ń gbìyànjú láti mọ àṣírí bí aláǹtakùn ṣe ń hun okùn rẹ̀ kí wọ́n lè máa lò ó ní onírúurú ilé iṣẹ́. Fún àpẹẹrẹ, ìwé ìròyìn náà sọ pé Kevlar, tó jẹ́ oríṣi òwú kan tí wọ́n fi “ògidì ásíìdì sulphuric tí wọ́n mú kí ó gbóná dé ìwọ̀n tó fẹ́rẹ̀ẹ́ máa hó ṣe, ni òwú tí wọ́n yàn láti máa fi hun ẹ̀wù ayẹta.” Ṣùgbọ́n bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdọ̀tí tó ń jáde láti inú Kevlar jẹ́ èròjà onímájèlé, tó sì ṣòro láti ríbi dà á nù sí, aláǹtakùn máa ń ran òwú tirẹ̀ láti inú “potéènì àti omi lásán, tí ìwọ̀n ásíìdì inú rẹ̀ àti ìdíwọ̀n ìgbóná-òun-ìtutù rẹ̀ dọ́gba pẹ̀lú ti ẹnu èèyàn.” Síwájú sí i, wọ́n á wá ran àdàlú omi àti potéènì yìí di fọ́nrán tí òjò kò lè gbá dà nù. Ìdí nìyẹn tí ìwé ìròyìn New Scientist fi sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti fi ọ̀pọ̀ ọdún ṣèwádìí nípa okùn aláǹtakùn, ó ṣì ṣòro láti ṣàlàyé rẹ̀.”

Òórùn Inú Ilé

Ìwé ìròyìn The Times ti London sọ pé: “Ó ṣeé ṣe kí inú ilé rẹ máa rùn ní ìlọ́po mẹ́wàá ju bí oko iwájú ilé rẹ ṣe ń rùn lọ.” Ìwádìí kan tí Àjọ Woléwolé ṣe ní àwọn ilé mẹ́rìnléláàádọ́sàn-án ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì fi hàn pé òórùn burúkú, tó ń jáde láti inú àga tí wọ́n fi páálí àti àwọn èròjà àgbélẹ̀rọ mìíràn ṣe, fi ìlọ́po mẹ́wàá pọ̀ nínú ilé ju bó ṣe ń rùn ní ìta lọ. Méjìlá lára àwọn ilé tí wọ́n wò kò kúnjú ìwọ̀n ohun tí Àjọ Ìlera Àgbáyé ń béèrè nípa irú òórùn tó yẹ kí àyíká ní. Àwọn àga tí wọ́n fi èròjà àgbélẹ̀rọ ṣe, ilẹ̀ tí wọ́n fi kẹ́míkà dán, àwọn ohun èlò ìkọ́lé àti ohun èlò ìṣelélọ́ṣọ̀ọ́, èròjà oníkẹ́míkà tí wọ́n fi ń fọ ilé, tàbí àwọn ohun èlò tí wọ́n fi ń mú ilé móoru àti èyí tí wọ́n fi ń se oúnjẹ lè mú kí èéfín tí ń tani lójú àti àwọn òórùn burúkú mìíràn gbalẹ̀ kan. Ọ̀kan lára wọn, ìyẹn òórùn benzene, tó máa ń fa àrùn jẹjẹrẹ, jẹ́ àdàlù àwọn ohun fínfín tí a fi ń fọ ilé àti ti èéfín tábà, tí òun pẹ̀lú jẹ́ lájorí ohun tó ń dá òórùn sílẹ̀ nínú ilé. Charlotte Gann, tí í ṣe olóòtú ìwé ìròyìn Health Which? sọ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń lo ìpín ọgọ́rin sí àádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún àkókò wọn nínú ilé. Ó dámọ̀ràn “dídín bí a ṣe ń lo àwọn èròjà oníkẹ́míkà kù, ṣíṣí àwọn fèrèsé mélòó kan àti yíyẹ àwọn ohun èlò tó ń lo gáàsì wò” kí òórùn inú ilé lè sunwọ̀n sí i.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́