Ibo Ni Wọ́n Ti Wá?
“KÍ NI a ti ń pe ara wa kí Columbus tóó dé? . . . Ní gbogbo ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, àní lónìí pàápàá, bí o bá túmọ̀ orúkọ tí a fi ń pe ara wa lọ́kọ̀ọ̀kan, láìmọ ohun tí àwọn yòó kù yàn, ìtumọ̀ kan náà ni gbogbo rẹ̀ ní nípìlẹ̀. Ní ède wa [Narragansett], Ninuog ni, tàbí àwọn ènìyàn, [ní ède Navajo, Diné ni], àwọn ẹ̀dá ènìyàn. Bí a ti ń pe ara wa nìyẹn. Òun ló ṣe jẹ́ pé, nígbà tí àwọn alárìnkiri [ará Europe] déhìn-ín, a mọ ẹni tí a jẹ́, ṣùgbọ́n a kò mọ ẹni tí wọ́n jẹ́. Ni a bá kúkú sọ wọ́n ní Awaunageesuck, tàbí àwọn àjèjì, nítorí àwọn ni wọ́n jẹ́ àtìpó, àwọn la ò mọ̀, ṣùgbọ́n a mọ ara wa lẹ́nì kíní kejì. Àwa sì ni ẹ̀dá ènìyàn.”—Tall Oak, ẹ̀yà Narragansett.
Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àbá èrò orí ló wà nípa orírun àwọn Ọmọ Ìbílẹ̀ America.a Joseph Smith, olùdásílẹ̀ ìsìn Mormon, jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀, títí kan Quaker William Penn, tí wọ́n gbà gbọ́ pé àwọn ará India jẹ́ Hébérù, àwọn àtìrandíran àwọn tí a ń pè ní ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì tí ó sọ nù. Àlàyé tí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ẹ̀dá ènìyàn fara mọ́ lóde òní ni pé, yálà nípa afárá orílẹ̀ tàbí nípa ọkọ̀ ọ̀pẹẹrẹ, àwọn ẹ̀yà Éṣíà sọ dá sí ibi tí ó ń jẹ́ Alaska, Kánádà, àti United States nísinsìnyí. Kódà, ó jọ pé àwọn àyẹ̀wò DNA ti èrò yìí lẹ́yìn.
Àwọn Ọmọ Ìbílẹ̀ America —Orírun àti Ìgbàgbọ́ Wọn
Àwọn olùyẹ̀wòṣàtúnṣe Tom Hill (Seneca) àti Richard Hill Àgbà, (Tuscarora) tí wọ́n jẹ́ Ọmọ Ìbílẹ̀ America kọ ọ́ sínú ìwe wọn, Creation’s Journey—Native American Identity and Belief, pé: “Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọmọ ìbílẹ̀ gbà gbọ́ látọwọ́dọ́wọ́ pé a dá wọn láti inú ilẹ̀ fúnra rẹ̀, láti inú omi, tàbí láti inú àwọn ìràwọ̀. Ní ìdà kejì, àwọn awalẹ̀pìtán ní àbá èrò orí nípa afárá orí ilẹ̀ kíkàmàmà kan tí ó la Bering Strait kọjá, tí àwọn ará Éṣíà gbà kọjá sí America; àbá èrò orí náà tẹnu mọ́ ọn pé, àwọn ará Éṣíà wọ̀nyí ni àwọn baba ńlá àwọn ènìyàn ìbílẹ̀ Ìwọ̀ Oòrùn Ìlàjì Ayé.” Àwọn Ọmọ Ìbílẹ̀ America kan ń ṣiyè méjì nípa àbá èrò orí àwọn aláwọ̀ funfun nípa Bering Strait. Wọ́n yàn láti gba àwọn àròsọ àti ìtàn àtọwọ́dọ́wọ́ wọn gbọ́. Wọ́n ń rí ara wọn bí olùgbé láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí aláṣìíkiri tí ó jẹ́ olùṣàwárí láti Éṣíà.
Russell Freedman ṣàlàyé nínú ìwe rẹ̀, An Indian Winter, pé: “Gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ ẹ̀yà Mandan [ẹ̀yà tí ó sún mọ́ apá òkè Odò Missouri], Ènìyàn Àkọ́kọ́ jẹ́ ẹ̀mí alágbára kan, ẹ̀dá ọ̀run kan. A ti dá a lọ́jọ́ pípẹ́ sẹ́yìn láti ọwọ́ Olúwa Ìyè, ẹlẹ́dàá ohun gbogbo, kí ó lè máa ṣe alárinà láàárín àwọn ẹ̀dá ènìyàn lásánlàsàn àti àwọn àìlóǹkà ọlọ́run, tàbí ẹ̀mí, tí ń gbé nínú àgbáyé.” Ìgbàgbọ́ àwọn Mandan tilẹ̀ ní ìtàn ìkún omi kan nínú pẹ̀lú. “Nígbà kan, tí ìkún omi kán ya bo gbogbo ayé, Ènìyàn Àkọ́kọ́ gba àwọn ènìyàn là nípa kíkọ́ wọn láti kọ́ ilé ìṣọ́, tàbí ‘ọkọ̀’ ààbò kan, tí ó ga ré kọjá ibi tí omi náà kún dé. Láti bọlá fún un, ohun tí ń ṣàpẹẹrẹ ilé ìṣọ́ inú ìtàn náà lọ́nà kékeré kan máa ń wà ní ọ̀kọ̀ọ̀kan abúlé àwọn Mandan—òpó igi kédárì kan tí ó ga ní ẹsẹ̀ bàtà márùn-ún, tí a fi pákó sọgbà yí ká.”
Àwọn Mandan tún ní àmì ìsìn kan, “òpó gíga kan tí a fi ìyẹ́ àti irun ara ẹranko wé lára, tí ó sì ní orí bíbani lẹ́rù kan tí a fi igi gbẹ́, tí a kùn lọ́dà dúdú.” Ta ni eléyìí lè máa dúró fún? “Ère arínilára yìí dúró fún Ochkih-Haddä, ẹ̀mí búburú kan tí ó ní ipá ìdarí ńláǹlà lórí ẹ̀dá ènìyàn, ṣùgbọ́n tí kò lágbára tó Olúwa Ìyè tàbí Ènìyàn Àkọ́kọ́.” Ní ti àwọn ará India tí ń gbé ní Pẹ̀tẹ́lẹ̀, “ìgbàgbọ́ nínú àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí jẹ́ apá kan tí kò ṣeé jà níyàn nínú ìgbésí ayé ojoojúmọ́. . . . Kò sí ìpinnu pàtàkì kan tí a lè ṣe, kò sí ohun kan tí a lè dáwọ́ lé, láìkọ́kọ́ wá ìrànwọ́ àti ìfọwọ́sí àwọn ẹ̀dá mímọ́ ọlọ́wọ̀ tí ń ṣàkóso àwọn àlámọ̀rí ẹ̀dá ènìyàn.”
John Bierhorst ṣàlàyé nínú ìwé rẹ̀, The Mythology of North America, pé: “A sọ fún wa pé, kí àwọn ènìyàn tí ó ní baba ńlá kan náà tóó bẹ̀rẹ̀ sí í kóra wọn jọ, àwọn Osage máa ń rìn kiri láti ibì kan sí ibì kan lábẹ́ ipò kan tí a mọ̀ sí ganítha (láìsí òfin tàbí ìṣètò). Èròǹgbà àtọwọ́dọ́wọ́ kan gbà pé, ní ìgbà ìjímìjí yẹn, àwọn onírònú kan tí a ń pè ní Àwọn Arúgbó Ọkùnrin Kéékèèké . . . ṣàgbékalẹ̀ àbá èrò orí náà pé agbára ìṣẹ̀dá píparọ́rọ́ kan gba ojú òfuurufú àti ilẹ̀ ayé, ó sì mú kí àwọn ìràwọ̀, òṣùpá, àti oòrùn máa rìn lọ ní ìṣètò pípé. Wọ́n pè é ní Wakónda (agbára àwámáridìí) tàbí Eáwawonaka (ẹni tí ó mú kí a wà).” Èrò kan náà ni àwọn Zuni, àwọn Sioux, àti àwọn Lakota tí ń bẹ níhà Ìwọ̀ Oòrùn ní. Àwọn Winnebago pẹ̀lú ní ìtàn ìṣẹ̀dá tí ó sọ nípa “Aṣẹ̀dá Ayé.” Ìtàn náà sọ pé: “Ó fẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wà, ìmọ́lẹ̀ sì dé. . . . Ó tún ronú, ó sì fẹ́ kí ilẹ̀ ayé wà, ilẹ̀ ayé yìí sì dé.”
Ó jẹ́ ohun tí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́kàn ìfẹ́ sí jù lọ láti rí àwọn ìjọra díẹ̀ láàárín ìgbàgbọ́ àwọn Ọmọ Ìbílẹ̀ America àti àwọn ẹ̀kọ́ tí Bíbélì fi kọ́ni, ní pàtàkì nípa Ẹ̀mí Títóbi náà, “ẹni tí ó mú kí a wà,” tí ó múni rántí ìtumọ̀ orúkọ àtọ̀runwá náà, Jèhófà, “Ó Ń Mú Kí Ó Wà.” Àwọn ìjọra mìíràn tún kan ti Ìkún Omi àti ẹ̀mí búburú tí a mọ̀ sí Sátánì nínú Bíbélì.—Jẹ́nẹ́sísì 1:1-5; 6:17; Ìṣípayá 12:9.
Lílóye Ọgbọ́n Èrò Orí Àwọn Ọmọ Ìbílẹ̀ America
Tom Hill àti Richard Hill tí wọ́n jẹ́ òǹkọ̀wé Ọmọ Ìbílẹ̀ America ṣàlàyé ẹ̀bùn márùn-ún tí wọ́n sọ pé àwọn Ọmọ Ìbílẹ̀ America ti gbà lọ́dọ̀ àwọn baba ńlá wọn. “Ẹ̀bùn kíní . . . ni ìsopọ̀ tímọ́tímọ́ tí a ní pẹ̀lú ilẹ̀ náà.” Lójú ìwòye ìtan wọn ṣáájú àti láti ìgbà tí àwọn ará Europe ti dé, ta ní lè sẹ́ ìyẹn? Ilẹ̀ wọn, tí àwọn Ọmọ Ìbílẹ̀ America sábà máa ń kà sí ohun mímọ́ ọlọ́wọ̀, ni a ti fi ipá, ẹ̀tàn, tàbí àwọn àdéhùn tí a kò mú ṣẹ gbà díẹ̀díẹ̀.
“Ẹ̀bùn kejì ni agbára àti ẹ̀mí tí àwọn ẹrankó ṣàjọpín pẹ̀lú àwọn ènìyàn wa.” A ti ṣàfihàn ọ̀wọ̀ tí àwọn Ọmọ Ìbílẹ̀ America ní fún àwọn ẹranko lọ́pọ̀ ọ̀nà. Wọ́n máa ń ṣọdẹ nítorí oúnjẹ, aṣọ, àti ibùgbé nìkan. Ní kedere, kì í ṣe àwọn ọmọ ìbílẹ̀ ni ó pa àwọn ẹfọ̀n (bison) run, bí kò ṣe àwọn aláwọ̀ funfun, tí wọ́n ní ìtẹ̀sí àìníjàánu fún ìtàjẹ̀sílẹ̀ àti ìwọra aláìbìkítà nípa ọjọ́ ọ̀la.
“Ẹ̀kẹta ni àwọn agbára ẹ̀mí, tí wọ́n jẹ́ ìbátan wa tí ń bẹ láàyè, tí wọ́n sì ń bá wa ṣe pọ̀ nípasẹ̀ àwọn ère wọn tí a ń ṣe.” Èyí ni kókó lááríjà nínú ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìsìn jákèjádò ayé—ẹ̀mí tàbí ọkàn tí ń la ikú já.b
“Ẹ̀kẹ́rin ni ìmọ̀lára irú ẹni tí a jẹ́, tí a sọ jáde tí a sì fẹsẹ̀ rẹ̀ múlẹ̀ nínú àwọn àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ ẹ̀yà wa.” A lè ṣàwárí èyí lónìí, nínú àwọn ayẹyẹ ẹ̀yà wa, níbi tí àwọn ènìyàn ti ń pé jọ láti jíròrò àwọn àlámọ̀rí ẹ̀yà, tàbí níbi ìpéjọpọ̀ ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, tí ijó àti orin ẹ̀yà ti ń wáyé. Àwọn aṣọ Íńdíà, ìró ìlù tí ń dún bára jọ, ijó, ìtúnsopọ̀ ìdílé àti àwùjọ tí ó ní baba ńlá kan náà—gbogbo wọ́n ṣàfihàn àṣà àbáláyé ti ẹ̀yà.
“Ẹ̀bùn tí ó kẹ́yìn ni agbára láti ṣẹ̀dá nǹkan—a sọ àwọn ìgbàgbọ wa di ohun gidi nípa sísọ àwọn ohun àdánidá di nǹkan ìgbàgbọ́ àti ìṣògo.” Ì báà jẹ́ apẹ̀rẹ̀ híhun, aṣọ híhun, mímọ ìkòkò àti kíkùn ún lọ́dà, ṣíṣe ohun ọ̀ṣọ́ àti ìṣaralóge, tàbí ìgbòkègbodò ìṣẹ̀dá èyíkéyìí mìíràn, ó rọ̀ mọ́ àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àti àṣà ìbílẹ̀ wọn àtayébáyé.
Ọ̀pọ̀ ẹ̀yà ló wà débi pé yóò gba ọ̀pọ̀ ìwé láti ṣàlàyé gbogbo ìgbàgbọ́ àti ìṣe ìbílẹ̀. Ohun tí a lọ́kàn ìfẹ́ sí nísinsìnyí ni, Kí ni ipa tí ìyawọlé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ará Europe, tí a rò pé ọ̀pọ̀ lára wọ́n jẹ́ Kristẹni, ní lórí àwọn Ọmọ Ìbílẹ̀ America?
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ó ṣe kedere pé èdè ọ̀rọ̀ náà, “Àwọn Ọmọ Ìbílẹ̀ America,” ní àwọn ẹ̀yà tí ń gbé ní Kánádà nínú. Ọ̀pọ̀ ló gbà gbọ́ pé àwọn aláṣìíkiri àkọ́kọ́ láti Éṣíà rìn la ìhà ìwọ̀ oòrùn àríwa Kánádà kọjá ní ọ̀na wọn sí àwọn agbègbè tí ó túbọ̀ móoru níha gúúsù.
b Bíbélì kò ṣètìlẹ́yìn fún ìgbàgbọ́ nínú àìlèkú ọkàn tàbí ẹ̀mí tí ń la ikú já. (Wo Jẹ́nẹ́sísì 2:7; Ìsíkẹ́ẹ̀lì 18:4, 20.) Fún àlàyé kíkún rẹ́rẹ́ sí i lórí kókó ọ̀rọ̀ yìí, wo ìwe Mankind’s Search for God, ojú ìwe 52 sí 57, àti 75, àti atọ́ka rẹ̀ lábẹ́ “Àìlèkú ọkàn, ìgbàgbọ́ nínú.” Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ló ṣe ìwé yìí jáde.