Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé wa
Ìyọlẹ́gbẹ́ Mo mọrírì àpilẹ̀kọ náà, “Ojú Ìwòye Bíbélì: Ìdí Tí Ìyọlẹ́gbẹ́ Fi Jẹ́ Ìṣètò Onífẹ̀ẹ́.” (September 8, 1996) Wọ́n yọ èmi alára lẹ́gbẹ́ ní 1987, wọ́n sì gbà mí pa dà ní 1988, lẹ́yìn tí mo ti kọ́gbọ́n. Ìṣètò onífẹ̀ẹ́ yìí ràn mí lọ́wọ́ láti ṣàtúnṣe ọ̀nà tí mo ń gbà gbé ìgbésí ayé mi, àti àwọn tí mo ń bá kẹ́gbẹ́. Ẹ wo bí a ti jẹ́ alábùkúnfún tó láti ní ètò àjọ kan tí ó mọyì àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n Bíbélì!
R. R., United States
Wọ́n yọ èmi náà níjọ. Mo ronú nígbà náà pé ó jẹ́ ìwà ìlekokomọ́ni, àti pé ó jẹ́ ìwà àránkàn líle jù lọ tí a lè ṣe sí ẹnì kan. N kò tọ̀nà! Kí wọ́n tó yọ mí lẹ́gbẹ́, àwọn alàgbà ìjọ ṣiṣẹ́ takuntakun láti ràn mí lọ́wọ́ láti ronú pìwà dà. N kò ṣáà mọrírì ìrànlọ́wọ́ náà nígbà yẹn. Dídi ẹni tí a yọ lẹ́gbẹ́ rẹ̀ mí sílẹ̀ gidigidi. Ó mú kí n rí bí ipò ìbátan wa pẹ̀lú Jèhófà ti ṣe pàtàkì tó.
B. T., United States
Àwọn Àmẹ́ríńdíà Ẹ ṣeun fún ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ náà “Àwọn Amerind—Kí Ni Ìrètí Wọn fún Ọjọ́ Ọ̀la?” (September 8, 1996) Mo ti máa ń nífẹ̀ẹ́ nínú ìtàn àwọn Àmẹ́ríńdíà. Lẹ́ẹ̀kan sí i, àìfọ̀rọ̀-sábẹ́-ahọ́n, àìṣègbè, àti bí ìwé ìròyìn yín ṣe ń gbé ọ̀rọ̀ ìtàn lọ́nà pípé pérépéré wú mi lórí.
A. M., Ítálì
A kò rí Àmẹ́ríńdíà kan tí ó jẹ́ olùkọ́ tàbí agbẹjọ́rò níwájú ìwé ìròyìn kan rí. Àwọn àwòrán ìgbà láéláé, bíi ti èyí tí ó wà níwájú ẹ̀dà ìtẹ̀jáde yín náà, ni wọ́n máa ń gbé jáde léraléra. Lílo àwọn àwòrán yìí láìdábọ̀ ń ṣèdíwọ́ fún àwọn ìsapá wa láti gbógun ti ṣíṣe ẹ̀dàyà.
K. M. T., United States
Dájúdájú kì í ṣe èrò ọkàn wa láti mú kí ìṣẹ̀dàyà aṣèpalára èyíkéyìí máa bá a lọ láìdábọ̀. A pète àwòrán iwájú ìwé náà láti gbé àwọn Àmẹ́ríńdíà yọ lọ́nà tí ó wà déédéé, tí ó sì buyì kún wọn. A lo aṣọ ìbílẹ̀ nítorí pé ó bá kókó ọ̀rọ̀ náà mu, ó sì rọrùn fún àwọn òǹkàwé wa kárí ayé láti lè dá a mọ̀. Ó dùn mọ́ni pé ọ̀pọ̀ lára àwọn Àmẹ́ríńdíà tí ń kàwé wa fi ìmọrírì hàn fún àwọn àpilẹ̀kọ náà àti àwọn àwòrán rẹ̀. Àwọn kan ní ìfẹ́ ọkàn láti tọ́jú díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà àtijọ́ náà, wọ́n sì fẹ́ láti máa wọ àwọn aṣọ ìbílẹ̀ ní àwọn àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ kan.—Olùyẹ̀wòṣàtúnṣe.
Nítorí pé mo ń ṣiṣẹ́ ní ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí bí onímọ̀ nípa pípín ẹ̀dá sí ìsọ̀rí orírun ní pàtàkì nípa Àríwá America, mo nífẹ̀ẹ́ sí kókó ọ̀rọ̀ yí gan-an. Ṣé ó lè ṣeé ṣe kí ẹ fi ẹ̀dá mẹ́wàá lára ìtẹ̀jáde yìí ránṣẹ́ sí mi, kí n pín in fún àwọn mìíràn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ọkàn nínú àwọn Àmẹ́ríńdíà?
P. B., Germany
Inú wa dùn láti ṣe ohun tí o béèrè fún.—Olùyẹ̀wòṣàtúnṣe.
Ìwọ̀nba ohun tí mo mọ̀ nípa àwọn Àmẹ́ríńdíà wá láti inú sinimá. Mo rí i láti inú àpilẹ̀kọ yìí pé ilé iṣẹ́ sinimá America kò fi òkodoro òtítọ́ hàn. Ojú ti mo fi ń wo àwọn Àmẹ́ríńdíà ti yí pa dà.
T. M., United States
Apá kan ìran tí mo ti wá jẹ́ Àmẹ́ríńdíà, nítorí náà, inú mi dùn jọjọ láti ka ìtẹ̀jáde yìí. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ní ìyàtọ̀ sí èrò wíwọ́pọ̀, Sitting Bull kì í ṣe olórí ogun kan nígbà ogun Little Bighorn.
P. H., United States
Ó jọ pé yálà Sitting Bull fúnra rẹ̀ jà nínú ogun náà tàbí kò jà jẹ́ ọ̀ràn àríyànjiyàn láàárín àwọn òpìtàn. Ojú ìwòye tí ó jọ pé ó borí láàárín ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọ̀mọ̀wé ni a rí nínú ìwé ìròyìn tí a gbé níyì náà, “Natural History,” tí ó wí pé: “Ní ìbámu pẹ̀lú àkọsílẹ̀ àwọn Àmẹ́ríńdíà, Sitting Bull, tí a ronú pé ó jẹ́ elénìní Custer nínú ogun, kò kópa nínú ìjà náà, àmọ́, ó mú ọwọ́ ara rẹ̀ dí nínú ṣíṣe egbòogi láti fún àwọn jagunjagun Àmẹ́ríńdíà náà lókun.” A kò tí ì mọ̀ bóyá a óò tún rí àwọn ìsọfúnni tí ó túbọ̀ ṣe kedere.—Olùyẹ̀wòṣàtúnṣe.