ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 5/22 ojú ìwé 30
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé wa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé wa
  • Jí!—1997
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé wa
    Jí!—1997
  • Ó Ha Yẹ Kí N Máa Ṣe Àwọn Eré Àṣedárayá Orí Kọ̀m̀pútà Tàbí Fídíò Bí?
    Jí!—1996
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Pompeii—Ibi Tí Ohunkóhun Kò Yí Padà
    Jí!—1996
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 5/22 ojú ìwé 30

Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé wa

Àwọn Eré Àṣedárayá Orí Kọ̀ǹpútà Ọmọ ọdún 15 ni mí, mo sì dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Ó Ha Yẹ Kí N Máa Ṣe Àwọn Eré Àṣedárayá Orí Kọ̀m̀pútà Tàbí Fídíò Bí?” (August 22, 1996) Ó fi àwọn apá tí kò dára nínú àwọn eré àṣedárayá wọ̀nyẹn hàn mí ní gidi, yóò sì ran àwọn Kristẹni lọ́wọ́ láti gbé àwọn apá dídára àti àwọn búburú tí ó wà nínú ṣíṣe wọ́n yẹ̀ wò.

F. R., Indonesia

Ọmọ ọdún 17 ni mí, mo sì fẹ́ràn àwọn eré àṣedárayá oníwà ipá orí kọ̀ǹpútà tẹ́lẹ̀. Mo rò pé wọn kò nípa lórí mi, àmọ́ mo wá sọ àwọn eré àṣedárayá wọ̀nyí di bárakú—ní pàtàkì, irú àwọn oníwà ipá tí ẹ júwe. Ní báyìí, mo ti fọ́ gbogbo àwọn ike ìkósọfúnnisí kọ̀ǹpútà mi tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìwà ipá àti ẹ̀jẹ̀. Kí ni ìyọrísí rẹ̀? Ara mi túbọ̀ yá gágá, mo sì ní ọ̀pọ̀ àkókò sí i láti fi kàwé, kí n fi kẹ́kọ̀ọ́, kí n sì sọ nípa Jèhófà Ọlọ́run.

S. A., Gíríìsì

Ipò Wúńdíá Ẹ ṣeun fún àpilẹ̀kọ kúkúrú, ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ àgbàyanu, tí ẹ pe àkọlé rẹ̀ ní “Ipò Wúńdíá—Èé Ṣe?” (August 22, 1996) Ní àwọn àkókò òde òní, tí àwọn ènìyàn rò pé ẹni tí ó burẹ́wà ni ó lè yàn láti wà ní ipò wúńdíá, ó jẹ́ ìṣírí gidigidi láti rí àwọn arẹwà ọ̀dọ́, tí ń rọ̀ mọ́ àwọn ìlànà Jèhófà tímọ́tímọ́. Lẹ́ẹ̀kan sí i, ẹ ṣeun!

R. D., United States

Àwọn Àmẹ́ríńdíà Mo fẹ́ láti fi ìmọrírì mi hàn fún ọ̀wọ́ náà, “Àwọn Amerind—Kí Ni Ìrètí Wọn fún Ọjọ́ Ọ̀la?” (September 8, 1996) Mo fara balẹ̀ ka àwọn àpilẹ̀kọ náà, n óò sì tún wọn kà. Apá tí ó sọ nípa àjíǹde yẹn wọ̀ mí lọ́kàn ní pàtàkì.

S. B., Ítálì

Àpilẹ̀kọ wọ̀nyí wọ̀ mí lọ́kàn ju bí àwọn èyíkéyìí mìíràn ti ṣe rí lọ. Wọ́n jẹ́ kí n mọ̀ pé ojú ìwòye mi nípa àwọn Àmẹ́ríńdíà jẹ́ ti ìyanisọ́tọ̀, kò sì bá àwọn ìlànà àtọ̀runwá mu. Láti ìgbà tí mo ti wà nílé ẹ̀kọ́ ni mo ti ní ojú ìwòye náà pé àwọn Àmẹ́ríńdíà wulẹ̀ jẹ́ àwọn òkú òǹrorò, aláìlọ́làjú. Àwọn ìwé ìtàn wulẹ̀ ṣàìfúnwa ní ojú ìwòye títọ́ nípa ayé tí ó yí wa ká. Àwọn àpilẹ̀kọ yín jẹ́ kí n rí ipò ìbànújẹ́ àwọn Àmẹ́ríńdíà—àpẹẹrẹ bí ‘ènìyàn ṣe ń jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.’—Oníwàásù 8:9, NW.

M. M., United States

Gẹ́gẹ́ bí àtìrandíran àwọn Àmẹ́ríńdíà kan, mo fi ìrusókè ọkàn gidigidi ka àwọn àpilẹ̀kọ yín. Kíkà nípa ìyà tí ó jẹ àwọn ènìyàn kan tí wọ́n ní irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ fún ìṣẹ̀dá mú kí n sunkún. Ẹ wo bí mo ṣe ń fojú sọ́nà tó fún ọjọ́ náà, nígbà tí Ọlọ́run yóò yí àìṣèdájọ́-òdodo tí a ti ṣe fún gbogbo aráyé pa dà, tí a óò sì lè ṣàjọpín párádísè ilẹ̀ ayé kan pa pọ̀.

N. S., United States

Pompeii Láìpẹ́ yìí, mo ka àpilẹ̀kọ yín, “Pompeii—Ibi Tí Ohunkóhun Kò Yí Padà” (September 8, 1996), mo sì gbádùn rẹ̀ gan-an. Ńṣe ló dà bíi pé mo wà níbẹ̀ gan-an! Àmọ́, n óò mọrírì àlàyé kíkún lórí kókó kan. Àpilẹ̀kọ náà sọ pé ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣèbẹ̀wò sí Pompeii “ṣì lè ṣàkíyèsí àwọn ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń lọ àgbàdo.” Ẹ tún ojú ìwòye mi ṣe, bí mo bá ṣì í, àmọ́ àgbàdo kì í ha ṣe ọkà ìbílẹ̀ àgbáálá ilẹ̀ America, tí àwọn ará Europe kò mọ̀, títí di ìgbà ayé Christopher Columbus bí?

R. D., United States

Ó ṣe wá láàánú bí ọ̀ràn yí bá ti fa ìdàrúdàpọ̀ kankan. Ì bá ti sàn jù ká ní a sọ pé a lè rí àwọn ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń lọ “ọkà” níbẹ̀. Lọ́nà gbígbàfiyèsí, ọ̀rọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì fún “àgbàdo” lè wulẹ̀ túmọ̀ sí “hóró irúgbìn oníhóró kan,” bíi àlìkámà tàbí “oats.”—Olùyẹ̀wòṣàtúnṣe.

Láti ìgbà ọmọdé ni mo ti ní òòfà ọkàn sí ìtàn ìgbàanì. Ìtàn Pompeii ti sábà máa ń gbàfiyèsí mi ní pàtàkì. Nígbà tí mo ka àpilẹ̀kọ náà, ńṣe ló dà bíi pé mo ń rìnrìn àjò la ìlú ńlá náà kọjá. Ó ga jù! Mo kọ́ nípa àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ díẹ̀ tó jẹ́ tuntun sí mi. Mo sì fẹ́ràn àfiwéra tí ẹ ṣe pẹ̀lú àkókò òpin ní ọjọ́ wa. Ẹ ṣeun fún jíjẹ́ kí n mọ̀ nípa àwọn ibi tí n kò lè ṣèbẹ̀wò sí.

J. S. A., Brazil

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́