ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 9/8 ojú ìwé 22-25
  • Pompeii—Ibi Tí Ohunkóhun Kò Yí Padà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Pompeii—Ibi Tí Ohunkóhun Kò Yí Padà
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìbúgbàù ní Ọdún 79 Sànmánì Tiwa
  • Kò Sí Ààbò ní Herculaneum
  • Ohunkóhun Kò Yí Padà
  • Ìgbésí Ayé Ara Ẹni
  • Ó Tó Àkókò Láti Gbégbèésẹ̀
  • Ẹ Wà Lójúfò Nísinsìnyí Ju Ti Ìgbàkígbà Rí Lọ!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Ìjáfara ti Léwu!
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé wa
    Jí!—1997
  • Láìpẹ́—Òpin Máa Dé Bá Gbogbo Àjálù
    Jí!—2005
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 9/8 ojú ìwé 22-25

Pompeii—Ibi Tí Ohunkóhun Kò Yí Padà

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ ÍTÁLÌ

ÀWỌN ilé ìdáná tí a gbé páànù sórí ààro wọn, àwọn ṣọ́ọ̀bù tí ẹrù kún fọ́fọ́, àwọn ìsun omi tí kò ní omi nínú, àwọn òpópónà tí ó wà ní sẹpẹ́—gbogbo rẹ̀ wà gẹ́lẹ́ bí wọ́n ṣe wà tẹ́lẹ̀, ní ìlú ńlá kan tí kò ní olùgbé, tí ó ṣófo, tí a sì pa tì. Pompeii ni, ibi tí ó ti jọ pé ohunkóhun kò yí padà.

Ohun gbogbo wà gẹ́lẹ́ bí ó ṣe wà ní ọjọ́ àgbákò yẹn ní ohun tí ó lé ní 1,900 ọdún sẹ́yìn nígbà tí Òkè Ńlá Vesuvius, òkè ayọnáyèéfín tí a ti lè yọjú wo ìyawọlẹ̀ omi òkun Naples, bú gbàù. Eérú àti gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ rẹ̀ bo Pompeii, Herculaneum, Stabiae, àti àwọn agbègbè àrọko tí ó wà láyìíká ibẹ̀ mọ́lẹ̀.

Ìwé náà, Pompei, sọ pé: “Èrò tí kò ṣe kedere ni àwọn ọ̀làjú ènìyàn ìgbà ìjímìjí ní nípa irú òkè ayọnáyèéfín ti Vesuvius jẹ́, wọ́n sì ní àṣa kíkà á sí òkè ńlá onírúgbìn títutù yọ̀yọ̀ níbi tí a ti ń gbin àwọn ọgbà àjàrà sáàárín àwọn igi nínípọn.” Ṣùgbọ́n ní August 24, ọdún 79 Sànmánì Tiwa, lẹ́yìn ìdákẹ́jẹ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún, òkè ńlá náà sọjí pẹ̀lú ìbúgbàù kíkàmàmà.

Ìbúgbàù ní Ọdún 79 Sànmánì Tiwa

Òkè ayọnáyèéfín náà pọ ìṣù rìgìdi gáàsì, òkúta yíyọ́, àti pàǹtírí tí ó sọ òfuurufú di dúdú tí ó sì ṣokùnfa òjò eérú àti afẹ́fẹ́ kíki (àwọn gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ kéékèèké jáde lójijì). Láàárín ọjọ́ méjì, ohun nínípọn kan ti bo Pompeii àti agbègbè àrọko gbígbòòrò mọ́lẹ̀, tí gíga rẹ̀ tó mítà méjì àti ààbọ̀. Bí àwọn ìmìtìtì aṣèparun ti ń bá a lọ ní mími ilẹ̀, ìkuukùu kíki tí ó kún fún gáàsì onímájèlé, aláìṣeéfojúrí ṣùgbọ́n tí ó lè ṣekú pani, bo ìlú ńlá náà mọ́lẹ̀, tí ó sì wà á mú lọ́nà aṣèparun. Nígbà tí Pompeii ń rì lọ díẹ̀díẹ̀, Herculaneum pòórá lójú ẹsẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìwe Riscoprire Pompei (Ṣíṣàtúnrí Pompeii) ṣe sọ, Herculaneum rá sábẹ́ ìṣàn “ẹrẹ̀ àti pàǹtírí òkè ayọnáyèéfín tí ó ga ní mítà méjìlélógún [ẹsẹ̀ bàtà 72] nítòsí etíkun náà.”

Ìhùwàpadà nǹkan bí 15,000 olùgbe Pompeii kò dọ́gba. Kìkì àwọn tí wọ́n fẹsẹ̀ fẹ́ẹ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ló rọ́nà dáàbò bo ara wọn. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn kan tí wọn kò fẹ́ fi ilé wọn àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀ sílẹ̀, dúró, pẹ̀lú ìrètí pé àwọn yóò yẹra fún ewu náà. Àwọn mìíràn tí wọ́n ń ṣàníyàn láti dáàbò bo àwọn ohun iyebíye tí wọ́n ní, lọ́ra kí wọ́n tó pinnu láti fẹsẹ̀ fẹ́ẹ, àmọ́ òrùlé ilé wọn, tí ọ̀ọ̀rìn eérú náà wó palẹ̀, ṣekú pa wọ́n.

Àpẹẹrẹ kan ni ti ẹnì kan tí ó ni “ilé ère Faun,” tí ó dájú pé kò ṣe tán láti fi ọrọ̀ rẹ̀ sílẹ̀. Robert Étienne sọ nínú ìwe rẹ̀ La vie quotidienne à Pompéi (Ìgbésí Ayé Ojoojúmọ́ ní Pompeii) pé: “Láìjáfara, obìnrin onílé náà bẹ̀rẹ̀ sí í kó àwọn ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀ ṣíṣeyebíye jù lọ jọ—àwọn ẹ̀gbà ọwọ́ onígóòlù tí a ṣe bí ejò, àwọn òrùka, irin ìmúrun, yẹtí, dígí onífàdákà kan, àpò kan tí ó kún fún owó ẹyọ onígóòlù—ó sì múra láti fẹsẹ̀ fẹ́ẹ.” Bóyá eérú tí ń dà ló dẹ́rù bá á, kò jáde síta. Étienne ń bá ọ̀rọ̀ lọ pé: “Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, òrùlé náà wó lulẹ̀, ó sì bo obìnrin tí ó kàgbákò náà mọ́lẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìṣúra rẹ̀.” Àwọn gáàsì olóró tó bo gbogbo àyíká náà ni ó pa àwọn yòó kù.

Ńṣe ni àwọn tí wọ́n lọ́ra ní láti sá àsálà fún ẹ̀mi wọn, wọ́n gba orí àwọn gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ eérú tó ti dà jọ́ sílẹ̀. Ibi tí wọ́n ṣubú sí ni wọ́n kú sí, àwọn gáàsì olóró tí wọ́n fà sínú ló pa wọ́n, eérú tí ń tú jáde láìdáwọ́ dúró sì bò wọ́n mọ́lẹ̀. Ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ti kọjá kí a tóó rí òkú wọn, pẹ̀lú àwọn ohun ṣíṣeyebíye wọn tí ó ṣì wà ní ẹ̀gbẹ́ wọn. Òkìtì eérú tó ga tó mítà mẹ́fà ló bo ìlú ńlá náà àti àwọn olùgbé rẹ̀ mọ́lẹ̀.

Síbẹ̀, ọpẹ́lọpẹ́ òjò eérú gbẹ̀mígbẹ̀mí náà, kódà, àwọn olùgbé ìlú ńlá náà ti yọjú padà. Ǹjẹ́ o mọ bí ó ṣe ṣẹlẹ̀? Ṣàkíyèsí ara wọn tí a fi àmọ̀ yọ, tí ó wà nínu fọ́tò tó wà lójú ìwé yìí. Báwo ni a ṣe ṣe wọ́n? Nípa dída amọ̀ plaster of Paris sójú ihò tí ara tó ti jẹrà náà dá sínú eérú, àwọn awalẹ̀pìtàn jẹ́ kí a rí bí àwọn òjìyà ìpalára aláìlólùrànlọ́wọ́ náà ṣe jẹ̀rora kí wọ́n tóó kú—“ọ̀dọ́bìnrin tí ó gbórí lé ọwọ́ níbi tó dùbúlẹ̀ sí; ọkùnrin kan, tí áńkáṣíìfù tí kò lè sẹ́ eérú àti àwọn gáàsì olóró bo ẹnu rẹ̀; àwọn olùtọ́jú èrò níbi ìsun omi Forum Baths, tí wọ́n ṣubú gátagàta pẹ̀lú iṣan ara wọ́n lọ́nà ṣíṣàjèjì tí àìsí afẹ́fẹ́ ṣokùnfà; . . . ìyá kan tí ó gbá ọmọbìnrin rẹ̀ kékeré mọ́ra, lọ́nà tí ń ṣeni láàánú ṣùgbọ́n tí kò ṣàǹfààní, kí wọ́n tóó kú.”—Archeo.

Kò Sí Ààbò ní Herculaneum

Ní Herculaneum, tí ó wà ní ibùsọ̀ bíi mélòó kan sí Pompeii, àwọn tí wọn kò sá àsálà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni a ká mọ́. Ọ̀pọ̀ ló yára gba ìhà etíkun lọ, bóyá tí wọ́n retí láti sá àsálà gba ojú òkun, ṣùgbọ́n ìmìtìtì òkun kan tí ó le koko kò jẹ́ kí àwọn ọkọ̀ ojú omi rìn. Àwọn ohun tí a hú jáde láìpẹ́ yìí ní etíkun Herculaneum ìgbàanì ti mú kí a rí egungun ara tí ó lé ní 300. Ẹrẹ̀ àti pàǹtírí òkè ayọnáyèéfín tí ń ṣàn kíkankíkan ló bo àwọn ènìyàn wọ̀nyí mọ́lẹ̀ lóòyẹ̀ nígbà tí wọ́n ń wá ìsádi lábẹ pèpéle kan tí a ti ń dúró wo òkun náà. Níhìn-ín, pẹ̀lú, àwọn púpọ̀ ti gbìyànjú láti dáàbò bo àwọn ohun ìní wọn ṣíṣeyebíye: ohun ọ̀ṣọ́ onígóòlù, àwọn ohun èèlo fàdákà, odindi àpapọ̀ ohun èèlò iṣẹ́ abẹ—gbogbo wọ́n ṣì wà níbẹ̀, láìwúlò, nítòsí ara òkú àwọn tó ni wọ́n.

Ohunkóhun Kò Yí Padà

Pompeii jẹ́ ẹ̀rí dídájú sí bí ìwàláàyè ṣe jẹ́ ẹlẹgẹ́ tó lójú ipá àdánidá. Láìdà bí àwọn ibi ìwalẹ̀pìtàn míràn lágbàáyé, àwókù Pompeii àti àwọn agbègbè tí ó yí i ká pèsè èrò àtẹ̀mọ́nilọ́kàn ránpẹ́ tí ń mú kí àwọn ọ̀mọ̀wé òde òní àti àwọn onífẹ̀ẹ́ ìtọpinpin lè máa ṣàyẹ̀wò kínníkínní nípa ìgbésí ayé ojoojúmọ́ ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa.

Ní pàtàkì jù lọ aásìkí agbègbè náà ni a gbé karí iṣẹ́ àgbẹ̀, ilé iṣẹ́ ẹ̀rọ, àti ìṣòwò. Pẹ̀lú bí àwọn ènìyàn ṣe ń ṣiṣẹ́ takuntakun—tí a ń gba tẹrútọmọ síṣẹ́ lójoojúmọ́—agbègbè àrọko alẹ́tùlójú náà ń méso jáde lọ́pọ̀ yanturu. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ìgbòkègbodò ìlú ńlá náà ní ìsopọ̀ pẹ̀lú títa èèlò oúnjẹ. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣèbẹ̀wò sí Pompeii ṣì lè ṣàkíyèsí àwọn ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń lọ àgbàdo, ọja ewébẹ̀, àti àwọn ṣọ́ọ̀bù àwọn eléso àti ti àwọn oníṣòwò wáìnì. O lè rí àwọn ilé tí a ń lò fún ọjà títà tẹ́lẹ̀—fún ṣíṣe òwú àti aṣọ àti fún rírànwú àti híhunṣọ lọ́nà títóbi. Pẹ̀lú ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ilé iṣẹ́ alábọ́ọ́dé mìíràn, láti orí ṣọ́ọ̀bù àwọn tí ń ta ohun ọ̀ṣọ́ dé ṣọ́ọ̀bù àwọn tí ń ta ẹ̀yà ara ẹ̀rọ, àwọn ilé wọ̀nyí, papọ̀ pẹ̀lú àwọn ilé gbígbé, para pọ̀ jẹ́ ìlú ńlá kan.

Wọ́n fi òkúta ṣe àwọn òpópónà tóóró, tí wọ́n máa ń kún fọ́fọ́ fún èrò nígbà kan rí náà. Àwọn ọ̀nà ẹlẹ́sẹ̀ tí ó ga sókè, àti àwọn ìsun omi gbogbogbòò, tí ọ̀nà omi tí a ṣètò lọ́nà gbígbọ́nféfé kan ń gbé omi lọ sínu rẹ̀ wà lẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ wọn. A lè rí kúlẹ̀kúlẹ̀ àrà ọ̀tọ̀ kan ní àwọn igun òpópónà pàtàkì pàtàkì. Bíi ti àwọn ọ̀nà ẹlẹ́sẹ̀ ìgbàanì tí ó wà ṣáájú ti ìsinsìnyí, àwọn òkúta ńláńlá tí ó yọrí sókè tí a tò sáàárín àwọn òpópónà mú kí ó lè rọrùn fún àwọn ènìyàn láti máa kọjá, kì í sì í jẹ́ kí ẹsẹ̀ wọ́n kan omi bí òjò bá ń rọ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ti ọmọlanke nínú ìlú ńlá náà gbọ́dọ̀ ní òye gbígbọ́nféfé láti yẹra fún àwọn òkúta tí ó yọrí síta wọ̀nyí. Wọ́n ṣì wà níbẹ̀! Kò sí ohun tí ó yí padà.

Ìgbésí Ayé Ara Ẹni

Ìṣọ́ra tí ó yí ìgbésí ayé ara ẹni àwọn ará Pompeii ká kò tilẹ̀ lè dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn ènìyàn òde òní tí ń tẹjú mọ́ wọn. Obìnrin kan tí ó wọ àwọn ohun ọ̀ṣọ́ ṣíṣeyebíye kú sọ́wọ́ eléré ìjà ikú kan nínú àkámọ́ rẹ̀. Ilẹ̀kùn àwọn ilé àti ṣọ́ọ̀bù ṣí sílẹ̀ gbayawu. A pàtẹ àwọn ilé ìgbọ́únjẹ, bí ẹni pé ìṣẹ́jú bíi mélòó kan sẹ́yìn ni a fi í sílẹ̀, pẹ̀lú àwọn abọ́ lórí ààrò, búrẹ́dì tí a kò tí ì yan ṣì wà nínú ààrò, àti àwọn àmù ńláńlá tó fara ti ògiri. Àwọn iyàrá tí a rẹ́ ògiri wọn lọ́nà aláràbarà, àwòrán ara ògiri, àwọn ohun ìṣelé lọ́ṣọ̀ọ́, ibi tí àwọn ọlọ́rọ̀ ti ń jàsè ńlá pẹ̀lú ìdẹ̀ra, ní lílo ife onífàdákà àti àwọn ohun èèlò tí a ṣe dáradára lọ́nà yíyani lẹ́nu. Àwọn ọgbà atura láyìíká ni a kọ́ àwọn ilé gogoro yí ká, tí a sì fi àwọn ìsun omi dídáni lọ́rùn, tí kò ṣiṣẹ́ mọ́ nísinsìnyí, ṣe lọ́ṣọ̀ọ́. A tún rí àwọn ère mábìlì àti idẹ tí a fi òye iṣẹ́ takuntakun ṣe, àti àwọn pẹpẹ àwọn òrìṣà ìdílé.

Bí ó ti wù kí ó rí, ọ̀nà ìgbésí ayé àwọn púpọ̀ jù lọ wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì. Ọ̀pọ̀ àwọn tí kò ní ohun ìdáná nílé sábà máa ń lọ sí àwọn búkà ọtí tí ó pọ̀ níbẹ̀. Wọ́n lè ṣòfófó, ta tẹ́tẹ́, tàbí ra oúnjẹ àti ọtí níbẹ̀, lówó pọ́ọ́kú. Ó ṣeé ṣe kí díẹ̀ lára àwọn ibi wọ̀nyí jẹ́ ilé aṣẹ́wó níbi tí àwọn agbóúnjẹ, tí wọ́n sábà máa ń jẹ́ ẹrúbìnrin, ti ń ṣiṣẹ́ aṣẹ́wó, lẹ́yìn tí wọ́n bá ti gbé ọtí fún àwọn oníbàárà. Yàtọ̀ sí irú àwọn ilé ọtí púpọ̀ rẹpẹtẹ bẹ́ẹ̀, àwọn ohun tí a hú jáde ti fi àwọn ibòmíràn tí ó lé ní ogún hàn, tí wọ́n jẹ́ ilé aṣẹ́wó, tí wọ́n sábà máa ń ní àwọn àwòrán àti ọ̀rọ̀ àlùfààṣá púpọ̀ nínú.

Ó Tó Àkókò Láti Gbégbèésẹ̀

Ìparun òjijì tó dé bá Pompeii ń mú ènìyàn ronú. Dájúdájú, àwọn ẹgbẹẹgbẹ̀rún tí wọ́n parun nibẹ̀ kò hùwà padà ní kánmọ́kánmọ́ tó nípa àwọn àmì ìkìlọ̀ ewu tí ó rọ̀dẹ̀dẹ̀—àwọn ìsẹ̀lẹ̀ tí ó ṣe lemọ́lemọ́, ìbúgbàù òkè ayọnáyèéfín náà, àti òjò aláfẹ́fẹ́ kíki rẹpẹtẹ náà. Wọ́n lọ́ra, bóyá nítorí pé wọn kò fẹ́ẹ́ fi ìgbésí ayé ìdẹ̀ra tí wọ́n ń gbé àti àwọn ohun ìní amáyédẹrùn wọn sílẹ̀ ni. Bóyá wọ́n retí pé ewu náà yóò ré kọjá ni tàbí pé àwọn yóò ṣì ní àkókò láti sá là bí nǹkan bá burú sí i. Ó bani nínú jẹ́ pé àṣìṣe ni wọ́n ń ṣe.

Ìwé Mímọ́ fi tó wa létí pé lónìí, gbogbo àgbáyé wà nínú irú ipò kan náà. Ẹgbẹ́ àwùjọ tí ó díbàjẹ́ tí a ń gbé inú rẹ̀ ti ta kété sí Ọlọ́run. Àkókò láti gbá a dànù lójijì ń tó bọ̀. (Pétérù Kejì 3:10-12; Éfésù 4:17-19) Gbogbo ẹ̀rí fi hàn pé àkókò yẹn ti sún mọ́lé. (Mátíù 24:3-42; Máàkù 13:3-37; Lúùkù 21:7-36) Àfọ́kù ọ̀ràn ìbànújẹ Pompeii dúró bí ẹ̀rí dídákẹ́ jẹ́ẹ́ nípa ibi tí àìnípinnu ń ṣe.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 24]

Àgbélébùú Àwọn Kristẹni Ha Ni Bí?

Onírúurú àgbélébùú tí a ṣàwárí ní Pompeii, títí kan ọ̀kan tí a fi sìmẹ́ǹtì yà sára ògiri ilé búrẹ́dì kan, ni àwọn kan ti sọ pé ó jẹ́ ẹ̀rí pé àwọn Kristẹni wà ní ìlú ńlá náà kí ó tóó parun ní ọdún 79 Sànmánì Tiwa. Èrò tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ha ni èyí bí?

Dájúdájú kò rí bẹ́ẹ̀. Antonio Varone sọ nínú ìwe rẹ̀, Presenze giudaiche e cristiane a Pompei (Wíwà Àwọn Júù àti Àwọn Kristẹni ní Pompeii), pé láti rí “gbogbo apá ìjọsìn tí ó ní í ṣe pẹ̀lú àgbélébùú gẹ́gẹ́ bí ohun àfojúrí, a ní láti dúró di ọ̀rúndún kẹrin, nígbà tí ìyílọ́kànpadà olú ọba àti gbáàtúù àwọn kèfèrí yóò yọrí sí mímú irú ìbuyìfún bẹ́ẹ̀ wà déédéé pẹ̀lú ipò tẹ̀mi wọn.” Varone fi kún un pé: “Kódà, ní ọ̀rúndún kejì àti ìkẹta àti títí di ìgba Constantine, ó ṣọ̀wọ́n gan-an láti rí kí irú àmì bẹ́ẹ̀ fara hàn ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìsìn Kristẹni.”

Bí wọn kò bá ní í ṣe pẹ̀lú ìsìn Kristẹni, kí ni ìpilẹ̀ irú àmì bẹ́ẹ̀? Yàtọ̀ sí àwọn iyè méjì nípa dídá àmì yìí tí a ronú pé ó jẹ́ àgbélébùú mọ̀ àti ti àwòrán ọlọ́run kan tí ó ní ìrísí ejò tí a rí nínú ilé búrẹ́dì kan náà, Varone sọ pé àwọn “àwárí tí ń fi ohun ìbàjẹ́ akóninírìíra ré kọjá ààlà hàn, tí ó ṣòro láti so àwọn pẹ̀lú mọ́ ipò tẹ̀mí Kristẹni tí a ronú rẹ̀ sí àwọn olùgbé ilé búrẹ́dì náà” tún wà níbẹ̀. Ó fi kún un pé: “A mọ̀ pé láti ìbẹ̀rẹ̀ ayé ọ̀làjú, ṣáájú kí ó tóó di àmì ìràpadà, a máa ń lo ohun ìṣàpẹẹrẹ onírìísí àgbélébùú tí ó ṣe kedere pé ó ní í ṣe pẹ̀lú idán àti ààtò ìsìn.” Ọmọ̀wé yìí ṣàlàyé pé ní ìgbà ìjímìjí, wọ́n ka àgbélébùú sí ohun tí ó lágbára láti lé àwọn agbára ẹ̀mí èṣù dànù tàbí kí ó pa wọ́n, wọ́n sì ń lò ó, gẹ́gẹ́ bí ońdè, ju ohunkóhun mìíràn lọ.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Òkúta Bìrìkìtì Caligula pẹ̀lú Òkè Ńlá Vesuvius ní ẹ̀yìn

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Lókè: Àwòrán àwọn olùgbé Pompeii tí a fi amọ̀ yọ

Lápá òsì: Ìrísí Òkúta Bìrìkìtì Nero àti apá kan tẹ́ḿpìlì Jupiter

[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 22]

Àwòrán etí ìwé: Glazier

Àwọn fọ́tò ojú ìwé 2 (ìsàlẹ̀), 22, àti 23: Soprintendenza Archeologica di Pompei

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́