Ìjáfara ti Léwu!
AWỌN idile mẹta, agbalagba meje ati awọn ọmọde mẹfa, fi ìgbékútà sáre tete fun iwalaaye wọn. O hàn gbangba pe wọn ti korajọpọ sabẹ aabo ile ẹnikan, pẹlu ireti pe wọn yoo lè yèbọ́ lọwọ okuta yìnyín ti ń dayafoni naa. Ṣugbọn bi ariwo awọn okuta ti ń bọ́ naa ti rọlẹ, ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ miiran dé—eérú aséniléèémí ṣíṣú dẹ̀dẹ̀. Nisinsinyi kò si yíyàn miiran ju pe ki wọn sare lọ.
Ọkunrin kan ni o gba iwaju, o ṣeeṣe ki o jẹ́ ẹrú, ẹni ti ń sare pẹlu apo awọn ohun-eelo kan ti o gbé kọ́ ejika rẹ̀. Awọn ọmọdekunrin meji tẹle e, ọ̀kan tó nǹkan bi ọmọ ọdun mẹrin, ti ikeji sì jẹ́ marun-un, wọn ń sare ni ifẹgbẹkẹgbẹ. Awọn yooku—ti jinnijinni ti dàbò, ti wọn ń jijakadi, ti wọn ń subúlébú, ti wọn ń fi ìgbékútà wá aabo ń sá tẹle wọn. Wọn gbiyanju lati mí, ṣugbọn dipo ki o jẹ́ afẹfẹ, eérú tútù ni wọn ń mí símú. Lọkọọkan, gbogbo awọn 13 naa ṣubu lulẹ ti wọn kò sì lè mira mọ́ tí eérú ti ń rọ̀ silẹ naa ní opin gbogbo rẹ̀ sì di ibojì wọn. Àkẹ̀kù wọn ti ń banilọkanjẹ yoo wa nipamọ titi di ìgbà ti awọn awalẹpitan bá tó hú wọn jade ni eyi ti o fẹrẹẹ tó 2,000 ọdun lẹhin naa ti wọn sì ṣawari lẹkun-un-rẹrẹ nipa iṣẹju ikẹhin wọn ti o banilọkanjẹ.
Awọn ojiya ipalara 13 wọnyii wulẹ jẹ iwọnba diẹ lara iye ti a fojudiwọn si 16,000 ti wọn ṣegbe ni ilu-nla Pompeii igbaani, ni Italy, ni August 24, 79 C.E. Ọpọlọpọ laaja nipa sisa kuro ninu ilu-nla naa nigba ti Oke Vesuvius fi tagbaratagbara mú ìbúgbàù rẹ̀ akọkọ jade. Sibẹ, awọn ti wọn jáfara—ni pataki awọn olówó ti wọn kò fẹ lati fi ile ati awọn ohun-ìní wọn silẹ—ni a sin sabẹ apata ati eérú ti o jin ni mita mẹfa.
Ohun ti o ṣẹlẹ ni Pompeii ní eyi ti o fẹrẹẹ tó 2,000 ọdun sẹhin lè jẹ́ ìtàn atijọ. Ṣugbọn ni ọpọlọpọ ọ̀nà o baradọgba pẹlu ipo ti o dojukọ iran eniyan lapapọ lonii. Àmì kari-aye, ti o jẹ́ alajaalu ibi ju ariwo kíkù Oke Vesuvius lọ, ń funni ni ikilọ pe eto ayé isinsinyi ń dojukọ iparun ti o rọ̀dẹ̀dẹ̀. Lati laaja, a nilati gbe igbesẹ kánkán. Ijafara lewu. Ohun ti àmì yẹn jẹ gan-an ati bi a ṣe le dahunpada si i lọna lilọgbọn ninu jẹ́ koko ọrọ-ẹkọ wa ti o tẹle e.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]
Cover photo by National Park Service
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
Soprintendenza Archeologica di Pompei