Wíwo Ayé
Fífi Ìlú Sílẹ̀ Lọ Sóko
Àwùjọ kékeré àwọn ará Japan tí ń pọ̀ sí i ń fi ìlú sílẹ̀ lọ sóko nítorí pé másùnmáwo àti ìsásókè-sásódò inú ìgbésí ayé ìlú ńlá ti sú wọn. Bí ó ti lè jẹ́ òtítọ́ pé ìgbòkègbodò ìgbésí ayé ìgbèríko túbọ̀ rọrùn láàárín àyíká àdánidá, fífi ìlú ńlá sílẹ̀ lọ sí ìgbèríko kò ṣàìní àwọn ìṣòro tirẹ̀. Ìwé ìròyìn Asiaweek sọ pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn àgbẹ̀ tuntun kọ owó oṣù tí ń lọ déédéé, àwọn ohun amáyédẹrùn nínú ìgbésí ayé ìlú ńlá àti bóyá ipò ẹni láàárín àwùjọ nítorí jíjẹ́ apá kan ilé iṣẹ́ tí orúkọ rẹ̀ yọrí ọlá láwùjọ sílẹ̀.” Síwájú sí i, “àwọn tí wọ́n di ará àgbègbè àrọko sọ pé, àwọn ní láti dín ìnáwó àwọn kù, àti pé, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó ń di ọ̀ràn-anyàn fún àwọn láti ṣe àwọn iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ kí owó tí yóò wọlé fún àwọn lè gbé pẹ́ẹ́lí.” Ṣùgbọ́n ní ti àwọn tí wọ́n ti pinnu láti ṣe ìyípadà náà, Ẹ̀ka Iṣẹ́ Àgbẹ̀ ti dá Ilé Ẹ̀kọ́ Ìmúrasílẹ̀ fún Iṣẹ́ Àgbẹ̀ kan sílẹ̀ láti ran àwọn olùgbé ìlú ńlá lọ́wọ́ láti ṣàṣeyọrí ní mímú ara bá ìgbésí ayé ìgbèríko mu.
Ṣọ́ọ̀ṣì Tẹ́wọ́ Gba Àwọn Òjíṣẹ́ Tí Wọ́n Fẹ́ Láti Di Ẹ̀yà Òdì Kejì
Ní United States, òjíṣẹ́ kan ní ìjọ Presbyterian ti gba àṣẹ láti máa bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lọ lẹ́yìn tí ó ṣe iṣẹ́ abẹ yíyí ẹ̀yà ìbímọ pa dà. Wọ́n gbé ìpinnu náà jáde nígbà tí ẹni ọdún 49 náà, Eric Swenson, ní kí Ìgbìmọ̀ Alákòóso Ìjọ Presbyterian ní Ìlú Ńlá Atlanta (Georgia) yí orúkọ òun pa dà sí Erin, lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ tí ó ṣe láti mú ẹ̀yà ìbímọ rẹ̀ kúrò. Ìwé ìròyìn The Christian Century sọ pé: “Anne Sayre, mẹ́ńbà ìgbìmọ̀ alákòóso ìjọ Presbyterian tí ń bójú tó ọ̀ràn ìdájọ́ àti ti àwọn obìnrin, sọ pé, ìgbìmọ̀ alákòóso ìjọ Presbyterian ní ‘ìjàkadì tí ó ṣòro’ kan, àmọ́ ó pinnu pé òun ‘kò ní ìpìlẹ̀ tí ó ṣeé gbà gbọ́ ní ti ẹ̀kọ́ ìsìn tàbí ní ti ìwà rere’ láti gba oyè náà pa dà.” Ṣùgbọ́n Don Wade, òjíṣẹ́ kan tí ó sọ̀rọ̀ lòdì sí ohun tí Swenson béèrè fún, sọ pé, “kò sí ìjíròrò ṣíṣe kókó kankan nípa àwọn ọ̀ràn ẹ̀kọ́ ìsìn.”
Àpá Ọwọ́ Àwọn Ẹranko Koala Tí Ó Jọ Ti Ènìyàn
Onímọ̀ ìjìnlẹ̀ kan ní Australia sọ pé, àpá ọwọ́ àti ti ìka ẹsẹ̀ ẹranko koala jọ ti ẹ̀dá ènìyàn lọ́nà arabaríbí. Ọ̀jọ̀gbọ́n Maciej Henneberg, onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ohun alààyè tí ó tún jẹ́ ògbóǹtagí nínú dídá àpá ọwọ́ mọ̀ láti Yunifásítì Adelaide, sọ pé: “Kódà, àwọn awò asọhun kékeré di ńlá tí ń lo ìgbì ìmọ́lẹ̀ láti ṣàwárí nǹkan kò mọ ìyàtọ̀ wọn.” Kì í ṣe bí ìkúùkù ẹranko koala ṣe rí lápapọ̀ ni wọ́n fi jọra ṣùgbọ́n bí bátànì ara rẹ̀ ti rí—bátànì àwọn kókó, ilà ọwọ́, àti bí àwọn ilà roboto awọ ìkúùkù ọwọ́ àti ti ẹsẹ̀ rẹ̀ ṣe rí. Ní àfikún sí i, àwọn àpá ìka ọwọ́ àti ti ẹsẹ̀ ẹranko koala kọ̀ọ̀kan kò jọ ti òmíràn, bí ó ṣe rí ní ti ẹ̀dá ènìyàn pẹ̀lú.
Ṣé Wọ́n Ń Kọ́ Àṣà Ìkọ̀sílẹ̀ Ní?
Ìwé agbéròyìnjáde The Sydney Morning Herald, ti Australia, sọ pé: “Àwọn tọkọtaya tí wọ́n ní àwọn òbí tí wọ́n ti kọra sílẹ̀ wà nínú ewu gíga ti rírí i kí ìgbéyàwó wọn forí ṣánpọ́n ju ti àwọn tọkọtaya tí àwọn òbí wọn ṣì wà pa pọ̀ lọ.” Ọ̀jọ̀gbọ́n Paul Amato, ti Yunifásítì Nebraska, ní United States, “fi ọdún 12 wádìí nǹkan bí 2,000 ará America tí wọ́n ti ṣègbéyàwó,” gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde náà sì ti sọ, ó ṣàwárí pé, “àtọmọdọ́mọ àwọn òbí tí wọ́n ti kọra sílẹ̀ lè ‘jogún’ òye ipò ìbátan tí kò sunwọ̀n àti àwọn ìhùwà tí ń mú kí ó túbọ̀ ṣeé ṣe pé kí àwọn ìgbéyàwó tiwọn jálẹ̀ sí ìkọ̀sílẹ̀ túbọ̀ pọ̀ gan-an.” Ìwé agbéròyìnjáde Herald náà sọ pé: “Níbi tí àwọn òbí àwọn tọkọtaya náà bá ti kọra sílẹ̀, ewu kí ìgbéyàwó wọn wó palẹ̀ fi ìpín 300 lórí ọgọ́rùn-ún ga ju ti àwọn tọkọtaya tí àwọn òbí àwọn méjèèjì ṣì wà pa pọ̀ lọ.”
Ìtọrọ Àforíjì Lẹ́yìn 500 Ọdún
Ní 1496, Ọba Manuel Kíní ti ilẹ̀ Potogí ṣe òfin kan fún àwọn Júù tí ń gbé àgbègbè ìpínlẹ̀ rẹ̀ pé: Ẹ yí pa dà sí ìsìn Roman Kátólíìkì, bí bẹ́ẹ̀ kọ, ẹ káńgárá yín. Ní nǹkan bí 500 ọdún lẹ́yìn náà, ní 1988, ilẹ̀ Potogí ṣe ìtọrọ àforíjì kan tí a fi àṣẹ tì lẹ́yìn. Láìpẹ́ yìí, nínú ìrántí aláyẹyẹ ìjọsìn kan, ilẹ̀ Potogí pẹ̀tù sí i. Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn àjọ akóròyìnjọ Associated Press ti sọ, ààrẹ ilẹ̀ Potogí, Jorge Sampaio, sọ nínú ọ̀rọ̀ kan tí ó sọ níwájú Ìgbìmọ̀ Aṣòfin pé, ìlékúrò náà jẹ́ “ìwà òǹrorò tí ó ní àbáyọrí eléwu tí ó le koko.” Mínísítà Ètò Ìdájọ́, José Eduardo Vera Jardim, pe ìlékúrò náà ní “àkókò ibi nínú ìtàn ilẹ̀ wa.” Ó fi kún un pé, ìjọba jẹ àwọn Júù ní gbèsè “ìtọrọ àforíjì ìpalára èrò orí” fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún tí wọ́n fi ṣe “inúnibíni oníwà ẹhànnà” sí wọn. Bí iye àwọn olùgbé ilẹ̀ Potogí ti jẹ́ nǹkan bíi mílíọ̀nù 10 nísinsìnyí, nǹkan bí 1,000 péré ló jẹ́ Júù níbẹ̀.
Ṣọ́ra fún Gbàrọgùdù Oògùn Tí A Kọ Fúnni
Pẹ̀lú bílíọ̀nù 16 dọ́là tí a ń pa lọ́dọọdún, òwò oògùn ayédèrú ń bú rẹ́kẹ. Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde ilẹ̀ Paris náà, Le Monde, ti sọ, “Àjọ Ìlera Àgbáyé (WHO) fojú díwọ̀n pé, ó kéré tán, ìpín 7 nínú ọgọ́rùn-un oògùn tí a ń tà jákèjádò ayé lọ́dọọdún ló jẹ́ gbàrọgùdù.” Ní Brazil, ìpín náà lè pọ̀ tó 30 nínú ọgọ́rùn-ún, àti ní Áfíríkà, 60 nínú ọgọ́rùn-ún. Àwọn oògùn ayédèrú lè wà láti ahẹrẹpẹ àgbílẹ̀rọ àwọn ojúlówó ohun tí a ń ṣe jáde dé orí àwọn èròjà tí kò wúlò rárá tàbí àwọn onímájèlé pàápàá. Ìwé agbéròyìnjáde Le Monde tọ́ka sí àpẹẹrẹ àjàkálẹ̀ àrùn lọ́rùnlọ́rùn ní Niger, níbi tí a ti fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn ní omi lásán tí a fi pe abẹ́rẹ́ àjẹsára. Ní Nàìjíríà pẹ̀lú, àwọn 109 ọmọdé ló kú nígbà tí a fún wọn ní oògùn olómi tí ó ní èròjà tí kì í jẹ́ kí ohun olómi tètè dì pọ̀. Ìwé agbéròyìnjáde náà sọ pé: “Àwọn ilé ìwòsàn fúnra wọn sábà máa ń lọ ra àwọn oògùn lọ́jà fàyàwọ́ nítorí pé wọ́n máa ń rí ọjà rà lówó pọ́ọ́kú.” Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, àwọn alábòójútó ọ̀ràn ìlera ń ní ìṣòro láti rí ojútùú sí ìṣòro náà nítorí ọ̀nà ìgbófinró tí kò gbéṣẹ́ tàbí tí ó bà jẹ́.
Ìṣòro Àwùjọ Àwọn Àlùfáà Ń Pọ̀ Sí I
Ìwé ìròyìn Christianity Today sọ pé, nǹkan bí 40 àwọn bíṣọ́ọ̀bù ìjọ Episcopal fọwọ́ sí ìwé kan ní November 1996 ní kíké sí ṣọ́ọ̀ṣì náà láti “pèsè àwọn ìlànà ṣíṣe kedere tí ó sì jẹ́ ọ̀ràn-anyàn nípa ọ̀ràn ìbálòpọ̀ láàárín àwùjọ àwọn àlùfáà.” Àwọn ohun ẹ̀gàn bíi mélòó kan tí ó kan àwọn àlùfáà ti gbo ìjọ náà jìgìjìgì, èyí tí àwọn arọ̀mọ́pìlẹ̀ sọ pé ó jẹ́ àbájáde “kíkùnà láti sọ ní kedere ohun tí ó jẹ́ ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ ìjọ náà nípa àṣà ìbálòpọ̀.” Fún àpẹẹrẹ, àlùfáà tí ń bójú tó ìjọ Episcopal kan ní Brooklyn, New York, kọ̀wé fiṣẹ́ sílẹ̀ lẹ́yìn tí ó jẹ́wọ́ pé òun ń bá ẹ̀yà kan náà lò pọ̀. Todd Wetzel, olùdarí àgbà Àpapọ̀ Ìjọ Episcopal, sọ pé: “Kì í ṣe ohun ẹ̀gàn kan ṣoṣo ni ìjọ náà ń dojú kọ. Ó ń dojú kọ ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ, èyí ní ń dáni níjì jù lọ lára wọn.” Ṣáájú, a mọ̀ nípa ìjọ yìí gan-an nígbà tí ó fẹ̀sùn àdámọ̀ kan bíṣọ́ọ̀bù tí ó ti fẹ̀yìn tì náà, Walter Righter, fún fífi déákónì abẹ́yà-kannáà-lòpọ̀ kan tí kò sí lábẹ́ ẹ̀jẹ́ ànìkàngbé joyè àlùfáà. Wọ́n fagi lé àwọn ẹ̀sùn náà lẹ́yìn tí “ilé ẹjọ́ Episcopal kan pàṣẹ pé ìjọ náà kò ní ‘ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ ṣíṣekókó’ tí ó pàṣẹ fífi ìbálòpọ̀ mọ sáàárín ìdè ìgbéyàwó.”
Èémí Aáyù
Ìjọba Taiwan gbé àwọn ìgbésẹ̀ tuntun kan láìpẹ́ yìí láti ṣèrànwọ́ láti dín àpọ̀jù ìmújáde aáyù kù. Ìwé agbéròyìnjáde South China Morning Post sọ pé, àwọn olùṣàbójútó ti fún àwọn aráàlú níṣìírí láti “máa jẹ aáyù gan-an.” Ọmọ ilẹ̀ Taiwan kan tí ń ṣiṣẹ́ nínú Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Àgbẹ̀, Ọ̀gbẹ́ni Ku Te-yeh, ṣàlàyé pé: “Aáyù tí a gbìn lọ́dún yìí ti pọ̀ jù lóòótọ́.” Nínú ìsapá láti jẹ́ kí àwọn ènìyàn jẹ ẹ́ gan-an, ìjọba ń tẹ ìwé pẹlẹbẹ kan nípa lílo aáyù. Ìwé agbéròyìnjáde náà sọ pé, bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Ọ̀gbẹ́ni Ku gbà pé, “a kò lè retí pé kí àwọn aráàlú tán gbogbo ìṣòro náà.”
Sísọ Obìnrin Di Aláìlèbímọ Ń Pọ̀ Sí I
Láàárín àwọn ọdún 1960, ìdílé kan tí a lè mú bí àpẹẹrẹ ní Brazil ní ọmọ 6.1; lónìí, ìpíndọ́gba náà jẹ́ ọmọ 2.5. Kí ló fà á tó dín kù púpọ̀ bẹ́ẹ̀? Ìwé agbéròyìnjáde Jornal do Brasil sọ pé, gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan tí Àjọ Aṣèwádìí Ìṣàmúlò Ètò Ọrọ̀ Ajé ṣe, ìdí kan ni pé “ìpín 40 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn obìnrin tí wọ́n ti lọ́kọ [ní Brazil] ni a ti sọ di aláìlèbímọ.” Síwájú sí i, ìtẹ̀sí tí ó wà ní gbogbogbòò ni pé kí a sọ àwọn obìnrin di aláìlèbímọ nígbà tí wọn kò tí ì dàgbà púpọ̀. Fún àpẹẹrẹ, ní ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn, ìpíndọ́gba ọjọ́ orí tí a ti lè sọ obìnrin Brazil kan di aláìlèbímọ jẹ́ ní ẹni ọdún 34; lónìí, ó jẹ́ ní ẹni ọdún 29. Ìwádìí náà tún sọ pé, “ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ìsọnidi-aláìlèbímọ ń wáyé nígbà ìbímọ,” pàápàá nínú ọ̀ràn ìbímọ nípasẹ̀ iṣẹ́ abẹ. Ní ìyàtọ̀ ìfiwéra, ìpín 2.6 péré nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn ọkùnrin Brazil ló gbà kí a tẹ àwọn lọ́dàá.
Ogun Ẹja Pípa
Ìwé ìròyìn U.S.News & World Report sọ pé, àpọ̀jù àwọn ọkọ̀ tí ń lépa ìpèsè ẹja tí ń dín kù “ti ṣamọ̀nà sí ìforígbárí gbígbónájanjan láàárín ọ̀wọ́ àwọn apẹja àti àwọn ọmọ ogun ojú omi.” Ní 1990, iye ọ̀wọ́ ọkọ̀ àwọn apẹja lágbàáyé pọ̀ sí i dé nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́ta, èyí tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlọ́po méjì iye ti 1970. Síwájú sí i, àwọn ohun èlò ìpẹja ìgbàlódé, bíi ìhùmọ̀ tí ń fi ìgbì mọ ibi tí ẹja wà àti àwọn àwọ̀n jàn-ànràn tí a fi ń kẹ́ja, ti mú kí àwọn apẹja túbọ̀ jáfáfá gan-an. “Àbájáde tí ó kù wọ́n kù ni pé, àwọn ìjọba àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà ní etíkun ń ja ogun kan tí ń lọ lọ́wọ́ pẹ̀lú ọ̀wọ́ àwọn apẹja láti ilẹ̀ òkèèrè” bí wọ́n ti ń gbìyànjú láti dáàbò bo iye ẹja wọn tí ń dín kù. Láàárín ọdún méjì tó kọjá nìkan, ìforígbárí tí ó wáyé láàárín ọ̀wọ́ àwọn apẹja abáradíje lójú agbami ti yọrí sí ikú àwọn apẹja mẹ́jọ.