ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 7/1 ojú ìwé 23-27
  • Láti Inú Ipò Òṣì Paraku, Mo Bọ́ Sínú Ọrọ̀ Tó Gadabú Jù Lọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Láti Inú Ipò Òṣì Paraku, Mo Bọ́ Sínú Ọrọ̀ Tó Gadabú Jù Lọ
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Wíwá Ohun Tó Sàn Jù Kiri
  • Ìrètí Inú Bíbélì Mú Inú Mi Dùn
  • A Jàǹfààní Nípa Ṣíṣe Aájò Àlejò
  • Fífarada Inúnibíni
  • Gbígbádùn Ọrọ̀ Tó Gadabú Jù Lọ
  • Jèhófà Fi Inú Rere Àìlẹ́tọ̀ọ́sí Hàn sí Wa Lónírúurú Ọ̀nà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
  • ‘Alayọ ni Gbogbo Awọn Wọnni Ti Nduro De Jehofa’
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Títẹ́wọ́gba Ìkésíni Látọ̀dọ̀ Jèhófà Ń Mú Èrè Wá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Ohun Ìyanu Lọ́tùn-Ún Lósì Nínú Iṣẹ́ Ìsìn Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 7/1 ojú ìwé 23-27

Láti Inú Ipò Òṣì Paraku, Mo Bọ́ Sínú Ọrọ̀ Tó Gadabú Jù Lọ

GẸ́GẸ́ BÍ MANUEL DE JESUS ALMEIDA ṢE SỌ Ọ́

Oṣù October, ọdún 1916 ni wọ́n bí mi, èmi ló kéré jù nínú ọmọ mẹ́tàdínlógún. Mẹ́sàn-án nínú àwọn ẹ̀gbọ́n mi ni àìsàn àti àìjẹunkánú ti pa, nítorí bẹ́ẹ̀ ń kò mọ̀ wọ́n. Àwa mẹ́jọ tó ṣẹ́ kù ń gbé lọ́dọ̀ àwọn òbí wa ní abúlé kan nítòsí Porto, nílẹ̀ Potogí.

YÀRÁ kan àti pálọ̀ kan ló wà nínú ilé akúṣẹ̀ẹ́ táà ń gbé. Kànga kan tó tó nǹkan bí ìdajì kìlómítà sí ilé wa la ti máa ń pọn omi mímu, àwọn ohun èlò ìdáná wa kò sì bóde mu.

Gbàrà táwọn ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin bá ti tó iṣẹ́ ṣe ni wọ́n máa ń bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ nínú oko àgbàdo. Owó tí wọ́n ń rí níbẹ̀ ni ìdílé wa fi ń jẹun. Ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n ṣe ló mú kó jẹ́ pé èmi nìkan ṣoṣo lọmọ tó kàwé díẹ̀ nínú gbogbo wa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nǹkan ò rọrùn fún wa, a kò fi Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ṣeré rárá pẹ̀lú ìrètí pé èyí yóò mú kí ìgbésí ayé wa sunwọ̀n sí i láwọn ọ̀nà kan.

Láàárín oṣù May, ṣọ́ọ̀ṣì náà máa ń ṣe ohun tí wọ́n ń pè ní nòfẹ́nà [novena]. Ọjọ́ mẹ́sàn-án gbáko la fi ń jí lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì láàárọ̀ kùtù hàì kílẹ̀ tó mọ́. Ibẹ̀ la tí máa ń gbàdúrà lérò pé èyí máa mú ìbùkún kan wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. A tún rò pé ẹni mímọ́ ni àlùfáà, pé aṣojú Ọlọ́run ni. Àmọ́, kò pẹ́ tí ojú ìwòye wa fi yí padà.

Wíwá Ohun Tó Sàn Jù Kiri

Nígbà tí a kò rí owó tí ṣọ́ọ̀ṣì bù fún wa san, àlùfáà náà kò tilẹ̀ wo ti ipò òṣì táa wà mọ́ wa lára. Èyí kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa. Èrò tí mo ní nípa ṣọ́ọ̀ṣì náà yí padà pátápátá débi pé nígbà tí mo di ọmọ ọdún méjìdínlógún, mo pinnu láti fi ìdílé mi sílẹ̀ kí ń lè wádìí bí kò bá sí ohun kan tó sàn nínú ìgbésí ayé ju ká máa ṣiṣẹ́ nínú oko ká sì máa bá ṣọ́ọ̀ṣì ṣàríyànjiyàn lọ. Ní 1936, mo dé sí Lisbon, olú ìlú ilẹ̀ Potogí.

Ibẹ̀ ni mo ti pàdé Edminia. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo mọ̀ pé ìsìn ti tàn mí jẹ, a tẹ̀ lé àṣà ìbílẹ̀, a ṣègbéyàwó nínú Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì. Lẹ́yìn náà ní 1939, Ogun Àgbáyé Kejì bẹ̀rẹ̀. Lákòókò ogun, mo ń bójú to ilé ìkẹ́rùsí méjìdínlógún, a sì ń fi ọkọ̀ ẹrù márùnlélọ́gọ́fà tó kún fún ohun ìjà ogun ránṣẹ́ lọ́jọ́ kan ṣoṣo.

Ẹ̀rù tí ogun dá sí mi lára àti bí ọwọ́ mi ṣe kódí nínú Ìjọ Kátólíìkì nípa lórí mi gan-an ni. Mo wá ṣe kàyéfì pé, ‘Ǹjẹ́ lóòótọ́ ni Ọlọ́run bìkítà nípa ìran ènìyàn? Báwo ló ṣe yẹ ká sìn ín?’ Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà ní 1954, baba àgbàlagbà kan tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá mi sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìbéèrè tí mo ní. Ìjíròrò yìí yí ìgbésí ayé mi padà pátápátá.

Ìrètí Inú Bíbélì Mú Inú Mi Dùn

Ọkùnrin onínúure yìí, tí ń jẹ́ Joshua, ṣàlàyé fún mi pé Ìjọba Ọlọ́run ni ojútùú kan ṣoṣo sí àwọn ìṣòro ayé, àti pé Ìjọba náà ni yóò mú àlàáfíà àti ààbò wá. (Mátíù 6:9, 10; 24:14) Ohun tó sọ mú inú mi dùn gan-an, àmọ́, mo lọ́ tìkọ̀ láti tẹ́wọ́ gba àwọn àlàyé rẹ̀ nítorí ìrírí tí mo ti ní nípa ìsìn tẹ́lẹ̀. Nígbà tó sọ pé òun fẹ́ máa bá mi kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo gbà, lórí ìpinnu pé kò ní béèrè owó àti pé kò ní sọ̀rọ̀ nípa ìṣèlú. Ó gbà, ó sì mú un dá mi lójú pé ọ̀fẹ́ ni ohun tí òun ń fi lọ̀ mí.—Ìṣípayá 22:17.

Kíá ní ìgbẹ́kẹ̀lé tí mo ní sí Joshua pọ̀ sí i. Nítorí náà, mo wá béèrè ohun kan tó ti ń wù mí láti ìgbà tí mo ti wà lọ́mọdé lọ́wọ́ rẹ̀. “Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kí n ní ẹ̀dà Bíbélì tèmi?” Lẹ́yìn tí mo rí i gbà, ẹ wá wo bínú mi ṣe dùn tó láti ka Ọ̀rọ̀ Ẹlẹ́dàá wa fúnra rẹ̀ ní ìgbà àkọ́kọ́ nípa irú àwọn ìlérí bíi: “Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò sì wà pẹ̀lú [aráyé]. Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ”!—Ìṣípayá 21:3, 4.

Ní pàtàkì, àwọn ìlérí Bíbélì nípa mímú ipò òṣì àti àìsàn kúrò ló tù mí nínú jù. Ọkùnrin olóòótọ́ nì, Élíhù sọ nípa Ọlọ́run pé: “Ó ń pèsè oúnjẹ lọ́pọ̀ yanturu.” (Jóòbù 36:31) Bíbélì tún sọ pé lábẹ́ ìṣàkóso òdodo ti Ìjọba Ọlọ́run, “kò sì sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’” (Aísáyà 33:24) Jèhófà Ọlọ́run mà nífẹ̀ẹ́ sí ire aráyé o! Mo wá túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ọkàn sí àwọn ìlérí rẹ̀ gan-an ni!

Mo lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún ìgbà àkọ́kọ́ ní April 17, 1954. Àkànṣe ìpàdé kan ni—Ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí ikú Kristi. Láti ìgbà yẹn ni mo ti ń lọ sí ìpàdé déédéé. Kò pẹ́ tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàjọpín àwọn ohun dáradára tí mo ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Láyé ìgbà yẹn ní ilẹ̀ Potogí, a máa ń ṣe ìjáde fàájì létíkùn lóṣooṣù, ìgbà yẹn la máa ń ṣe batisí. Oṣù keje lẹ́yìn tí Joshua kọ́kọ́ bá mi sọ̀rọ̀ ni mo ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run tí mo sì fi ẹ̀rí rẹ̀ han nípa ṣíṣe ìrìbọmi nínú òkun náà.

Àwọn Ẹlẹ́rìí bí ọgọ́rùn-ún péré ló wà ní gbogbo ilẹ̀ Potogí ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1954. Nípa bẹ́ẹ̀, a nílò àwọn ọkùnrin tí yóò mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù. Mo tètè tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí gan-an, kò sì pẹ́ tí wọn fi fún mi ní àwọn ẹrù iṣẹ́ nínú ìjọ. Ní 1956, wọ́n fi mi ṣe ìránṣẹ́ ìjọ nínú ìjọ kejì tó jẹ́ ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Lisbon nígbà yẹn lọ́hùn-ún, ìránṣẹ́ ìjọ ni wọ́n ń pe alábòójútó olùṣalága. Lónìí, ó lé ní ọgọ́rùn-ún ìjọ tó wà ní ìlú ńlá yìí àti àwọn àgbègbè rẹ̀.

A Jàǹfààní Nípa Ṣíṣe Aájò Àlejò

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi àti Edminia kò fi bẹ́ẹ̀ rí jájẹ, gbogbo ìgbà la máa ń gba àwọn Kristẹni arákùnrin wa lálejò. Ní 1955, aṣáájú ọ̀nà kan, bí a ti ń pe àwọn ajíhìnrere alákòókò kíkún ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, yà nílẹ̀ Potogí nígbà tó ń ti ilé rẹ̀ ní Brazil lọ sí Àpéjọpọ̀ àgbáyé “Ayọ̀ Ìṣẹ́gun Ìjọba” ní Germany. Oṣù kan gbáko ló fi gbé ilé wa nítorí ìṣòro ọkọ̀ wíwọ̀, kẹ́ẹ wáá wo bí ìbẹ̀wò rẹ̀ ṣe ṣàǹfààní nípa tẹ̀mí fún wa tó!

Àwọn mìíràn tó tún máa ń wá sílé wa nígbà yẹn ni àwọn mẹ́ńbà ìdílé orílé iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Brooklyn, New York, àwọn bíi Hugo Riemer àti Charles Eicher tí wọ́n jọ ń gbé yàrá kan náà. A jọ jẹ oúnjẹ alẹ́ pọ̀ wọ́n sì sọ àsọyé fún àwọn arákùnrin tó ń sọ èdè Potogí. Bí àṣẹ̀ṣẹ̀pa òròmọdìyẹ tẹ́nu rẹ̀ là sílẹ̀ láti gba oúnjẹ, bẹ́ẹ̀ la ṣe máa ń dúró de àwọn oúnjẹ tẹ̀mí aládùn tí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ máa ń pèsè.

Àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún máa ń dé sílé wa nígbà ìbẹ̀wò wọ́n. Àlejò mánìígbàgbé kan táa gbà ní 1957 ni Álvaro Berecochea, alábòójútó ẹ̀ka ti Morocco, tí wọ́n yàn láti bẹ ilẹ̀ Potogí wò láti fún àwọn arákùnrin níṣìírí. Ó wá ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ ní ilé wa, a si rin kinkin pé kó dúró sílé wa ní gbogbo àkókò rẹ̀ tó kù láti lò ní ilẹ̀ Potogí. A bù kún wa gan-an a sì sanra sí i nípa tẹ̀mí láàárín ìbẹ̀wò rẹ̀ olóṣù gbọọrọ náà, àwọn oúnjẹ aládùn tí olólùfẹ́ mi Edminia ń sè sì mú kí Álvaro sanra sí i.

Ipò òṣì paraku, irú èyí tí mo nírìírí rẹ̀ nígbà ọmọdé lè máà jẹ́ kí àwọn èrò kan kúrò lọ́kàn èèyàn títí ayé. Síbẹ̀, mo wá rí i pé bí a ṣe ń fún Jèhófà àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ni nǹkan tó bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe ń bù kún wa tó. Léraléra ni kókó ọ̀rọ̀ yìí máa ń wá sí mi lọ́kàn báa ṣe ń fi ìfẹ́ àlejò hàn sí gbogbo àwọn táa lè fi hàn sí.

Wọ́n ṣe ìfilọ̀ kan ní àpéjọpọ̀ táa ṣe ní Porto ní 1955 nípa àpéjọpọ̀ àgbáyé ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó máa wáyé ní Ibi Ìṣeré Ìdárayá Yankee ní New York City ní 1958. Wọ́n gbé àpótí ọrẹ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba kọ̀ọ̀kan ní orílẹ̀-èdè wa—àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà nígbà yẹn kò pọ̀—owó inú rẹ̀ la fẹ́ lò láti fi rán àwọn aṣojú láti ilẹ̀ Potogí lọ sí àpéjọpọ̀ náà. Báwo lẹ ṣe rò pé inú wa yóò ṣe dùn tó nígbà tí wọ́n yan èmi àti ìyàwó mi mọ́ àwọn aṣojú wọ̀nyí? Ẹ wo ayọ̀ ńlá tó jẹ́ láti ṣèbẹ̀wò sí orílé iṣẹ́ àgbáyé ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Brooklyn lákòókò táa fi wà ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà fún àpéjọpọ̀ náà!

Fífarada Inúnibíni

Ní 1962, wọ́n fòfin de iṣẹ́ ìwàásù àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ilẹ̀ Potogí, wọ́n sì lé àwọn míṣọ́nnárì—títí kan Eric Britten, Domenick Piccone, Eric Beveridge, àti àwọn ìyàwó wọn—jáde lórílẹ̀-èdè náà. Lẹ́yìn náà, wọ́n kò gbà wá láyè láti ṣe àwọn ìpàdé wa ní àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba mọ́, a wá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe wọ́n ni bòókẹ́lẹ́ ní àwọn ilé àdáni; bákan náà ni kò ṣeé ṣe mọ́ láti ṣe àwọn àpéjọpọ̀ ńlá ni ilẹ̀ Potogí. Ó wá di ẹrù iṣẹ́ mi láti ṣètò ọkọ̀ fún àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin wa láti lọ ṣe irú àwọn àpéjọpọ̀ bẹ́ẹ̀ ní àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn.

Kò rọrùn láti ṣètò ìrìn àjò lọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn fún àwọn Ẹlẹ́rìí tó pọ̀ níye gan-an. Àmọ́, ìsapá náà tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ, táa bá ronú nípa àwọn àǹfààní gígadabú nípa tẹ̀mí tí àwọn arákùnrin ilẹ̀ Potogí rí gbà. Ẹ wo bó ti jẹ́ ìrírí tí ń gbéni ró tó fún wọn, láti wà ní àwọn àpéjọpọ̀ ní Switzerland, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Ítálì, àti ilẹ̀ Faransé! Irú àwọn àpéjọpọ̀ bẹ́ẹ̀ tún pèsè àǹfààní fún wọn láti kó àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wá sí ilẹ̀ Potogí. Láàárín àwọn ọdún wọ̀nyẹn, a béèrè pé kí wọ́n forúkọ wa sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ètò ìsìn kan ní ilẹ̀ Potogí, ṣùgbọ́n gbogbo ẹ̀bẹ̀ wa ni wọn kò gbà.

Lẹ́yìn tí wọ́n lé àwọn míṣọ́nnárì jáde ní 1962, àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ wa tẹra mọ́ ìgbétáásì wọn láti dá iṣẹ́ ìwàásù wa dúró. Àìmọye àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin ni wọ́n ń mú tí wọ́n sì kó lọ sílé ẹjọ́. Àwọn ìròyìn tí a ṣàkọsílẹ̀ wọn nípa mélòó kan lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí wà nínú ìwé ìròyìn yìí àti èkejì rẹ̀, Jí!a

Aṣáájú ọ̀nà kan tó jẹ́ pé èmi ni mo nawọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run sí i wà lára àwọn tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n nítorí wíwàásù. Nítorí tí àwọn ọlọ́pàá rí àdírẹ́sì mi nínú àwọn ohun ìní rẹ̀, ni wọ́n bá ránṣẹ́ pè mí, wọ́n sì fọ̀rọ̀ wá mi lẹ́nu wò.

Ẹ̀yìn ìyẹn ni àwọn ọlọ́pàá méjì ṣèbẹ̀wò sílé mi. Wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mi àti ẹ̀dà Bíbélì mẹ́tàlá pẹ̀lú. Wọ́n kàn ń fòòró wa ṣáá ni, ìgbà méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n padà wá láti yẹ ilé wa wò. Gbogbo ìgbà tí wọ́n bá wá ni wọn máa ń da ìbéèrè bò wá.

Ọ̀pọ̀ ìgbà ní wọ́n pè mi láti wá bá àwọn Ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ́ mi jẹ́rìí nílé ẹjọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ń kò fi bẹ́ẹ̀ kàwé, Jèhófà fún mí ni ‘ọgbọ́n tí gbogbo àwọn aṣòdì lápapọ̀ kò lè ta kò tàbí jà níyàn.’ (Lúùkù 21:15) Lọ́jọ́ kan, bí mo ṣe jẹ́rìí ya adájọ́ lẹ́nu tó bẹ́ẹ̀ tó fi béèrè pé ìwé mélòó ni mo kà. Gbogbo àwọn tó wà nílé ẹjọ́ náà ló bú sẹ́rìn-ín nígbà tí mo sọ pé ìwé mẹ́rin àkọ́kọ́ ni mo ti dúró.

Bí inúnibíni náà ṣe ń le sí i ni iye àwọn tó ń tẹ́wọ́ gba ìhìn rere Ìjọba náà ń pọ̀ sí i. Nítorí èyí, ìwọ̀nba kéréje àwa Ẹlẹ́rìí tí a kò tó ẹ̀ẹ́dégbèje [1,300] ní ilẹ̀ Potogí ní 1962 wá di ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlá ní 1974! Láàárín àkókò kan náà, ní May 1967, a ké sí mi láti sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó arìnrìn-àjò. Nínú iṣẹ́ yìí, mo máa ń bẹ àwọn ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà wò láti fún wọn lókun nípa tẹ̀mí.

Gbígbádùn Ọrọ̀ Tó Gadabú Jù Lọ

Ní December 1974, mo láǹfààní láti nípìn-ín nínú ìforúkọsílẹ̀ tó mú kí iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà di èyí tí a kà sí lábẹ́ òfin ní ilẹ̀ Potogí. Ọdún tó tẹ̀ lé e ni èmi àti ìyàwó mi di ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Estoril. A sì tún yàn mí láti sìn gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú mẹ́ńbà Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ti ilẹ̀ Potogí.

Ẹ wo bó ti jẹ́ ayọ̀ ńlá tó láti rí i bí iṣẹ́ ìwàásù náà ti ń tẹ̀síwájú ní ilẹ̀ Potogí àti àwọn ìpínlẹ̀ tí ẹ̀ka wa ń bójú tó! Lára ìwọ̀nyí ni Àǹgólà, Azore, Cape Verde, Madeira, àti São Tomé òun Príncipe. Láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá, rírí àwọn míṣọ́nnárì tí a rán jáde láti ilẹ̀ Potogí pé kí wọ́n lọ sìn ní àwọn ilẹ̀ mìíràn, níbi tí àwọn èèyàn ti fi ìfẹ́ ńlá hàn fún ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà, ti mú inú mi dún jọjọ. Fojú inú wo bí ayọ̀ wa ṣe pọ̀ tó nísinsìnyí láti ní àwọn tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà méjìdínláàádọ́rùn-ún [88,000] akéde Ìjọba ní àwọn ilẹ̀ wọ̀nyí, títí kan àwọn tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà mẹ́tàdínláàádọ́ta [47,000] tó wà ní ilẹ̀ Potogí! Iye àwọn tí wọ́n wá síbi Ìṣe Ìrántí ní àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí ní ọdún 1998 lọ sókè dé ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba ó lé márùnlélógójì [245,000] ní ìfiwéra pẹ̀lú èyí tí kò tó igba nígbà tí mo di Ẹlẹ́rìí ní 1954.

Èmi àti Edminia fi tọkàntọkàn gbà pẹ̀lú onísáàmù náà tó sọ nínú Bíbélì pé “ọjọ́ kan nínú àwọn àgbàlá [Jèhófà] sàn ju ẹgbẹ̀rún ọjọ́ níbòmíràn.” (Sáàmù 84:10) Nígbà tí mo bá ronú padà sẹ́yìn wo ipò tálákà tí mo wà nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ tí mo wá fi wé ọrọ̀ tẹ̀mí tí mo ti gbádùn lẹ́yìn náà, ọ̀rọ̀ wòlíì Aísáyà ló máa ń wá sí mi lọ́kàn, nígbà tó sọ pé: “Jèhófà, ìwọ ni Ọlọ́run mi. Mo gbé ọ ga, mo gbé orúkọ rẹ lárugẹ, nítorí pé o ti ṣe àwọn ohun àgbàyanu . . . Nítorí pé ìwọ ti di ibi odi agbára fún ẹni rírẹlẹ̀, ibi odi agbára fún òtòṣì.”—Aísáyà 25:1, 4.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a  Wo Jí! ti May 22, 1964, ojú ìwé 8 sí 16, (Gẹ̀ẹ́sì) àti Ile-Iṣọ Na ti October 1, 1966, ojú ìwé 581 sí 592 (Gẹ̀ẹ́sì)

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Lókè: Arákùnrin Almeida ní Lisbon tó ń kéde ètò tí wọ́n ṣe láti rán àwọn aṣojú lọ sí àpéjọpọ̀ àgbáyé ti New York ní 1958

Láàárín: Mò ń darí ìpàdé àwòṣe kan, tó jẹ́ ti àwọn ìránṣẹ́ ní Àpéjọ àgbáyé “Àlàáfíà ní Ayé” ní Paris

Ìsàlẹ̀: Àwọn bọ́ọ̀sì táa gbà ti ṣe tán àtilọ sí àpéjọpọ̀ àgbègbè ní ilẹ̀ Faransé

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Mo ń darí ìjọsìn òwúrọ̀ ní ẹ̀ka ilẹ̀ Potogí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Ẹ̀ka ilẹ̀ Potogí, tí a yà sí mímọ́ ní 1988

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Ọ̀rọ̀ tí Arákùnrin Hugo Riemer sọ nígbà tó wá láti Bẹ́tẹ́lì ní Brooklyn fún wa níṣìírí.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Èmi àti aya mi

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́