ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 10/1 ojú ìwé 23-28
  • ‘Alayọ ni Gbogbo Awọn Wọnni Ti Nduro De Jehofa’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ‘Alayọ ni Gbogbo Awọn Wọnni Ti Nduro De Jehofa’
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A Gbin Irugbin Ijihin Iṣẹ Ọlọrun
  • Awọn Iṣoro ni Spain
  • Wiwaasu Labẹ Akoso Bóofẹ́ Bóokọ̀ ti Katoliki
  • Inunibini ati Awọn Ìléjáde
  • Iṣẹ Ayanfunni Miiran, Ede Miiran
  • Akoko Idaamu Bẹrẹ
  • Wiwaasu Ni Morocco Ti Isin Islam
  • Ibi Ayanfunni Onigba Kukuru Kan Ha Ni Bi?
  • Awọn Idanwo ati Ibukun
  • Imugbooro ni El Salvador
  • Ohun Ìyanu Lọ́tùn-Ún Lósì Nínú Iṣẹ́ Ìsìn Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Láti Inú Ipò Òṣì Paraku, Mo Bọ́ Sínú Ọrọ̀ Tó Gadabú Jù Lọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Jèhófà Fi Inú Rere Àìlẹ́tọ̀ọ́sí Hàn sí Wa Lónírúurú Ọ̀nà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
  • A Fún Wa Ní Péálì Tí Ìníyelórí Rẹ̀ Ga
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 10/1 ojú ìwé 23-28

‘Alayọ ni Gbogbo Awọn Wọnni Ti Nduro De Jehofa’

GẸGẸ BI DOMENICK PICCONE TI SỌ Ọ

Awọn obi mi ṣí kuro lati Italy lọ si United States ni ibẹrẹ awọn ọdun 1920 wọn si ṣe atipo ni South Philadelphia, ti a mọ si Italy Kekere nigba naa. Saaju 1927 wọn ndarapọ pẹlu awọn Akẹkọọ Bibeli, ti a mọ si awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lẹhin naa.

A BÍ mi ni 1929 a si tipa bayii ṣiju   mi si otitọ Bibeli lati igba ọmọ    de jojolo. Mo le ranti pe awọn Ẹlẹrii yoo pade ninu ile wa ṣaaju ki wọn to lọ sẹnu iwaasu ninu awọn ilu ti wọn jẹ Roman Katoliki paraku ni ẹkùn ìwakùsà eedu ti Pennsylvania nibi ti a ti faṣẹ ọba mu awọn arakunrin ni ọpọlọpọ igba. A baptisi mi ni 1941 ni apejọpọ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni St. Louis, Missouri. Lẹhin naa awọn nǹkan bẹrẹ sii dojuru.

Mo bẹrẹ sii ko ẹgbẹkẹgbẹ pẹlu awọn ọdọ ni adugbo mo si bẹrẹ sii mu siga ti mo si nta tẹtẹ ni awọn kọ̀rọ̀gún opopona. O ṣe kòńgẹ́ lọna rere pe, awọn obi mi ri i pe apa wọn ko fẹ́ ka mi mọ́ wọn si pinnu lati ṣi lọ si agbegbe miiran ninu ilu yẹn. Ko tẹ́ mi lọrun, niwọn igba ti mo ti padanu awọn ọrẹ mi ọmọ asunta. Bi o ti wu ki o ri, lonii, mo wẹhin wò mo si kun fun imoore gidigidi si baba mi. O ṣe irubọ iṣunna owo gidigidi lati fa mi jade kuro ninu awọn ayika wọnni. Nigba ti o jẹ pe ni iṣaaju oun le rin lọ si ibi iṣẹ, nisinsinyi oun nilati maa wọ ọkọ oju irin abẹlẹ onigba gigun. Ṣugbọn iṣikuro yii mu mi pada sinu ayika iṣakoso Ọlọrun.

A Gbin Irugbin Ijihin Iṣẹ Ọlọrun

Ni ohun ti o fẹrẹẹ jẹ gbogbo ọdun, a nrinrin ajo lọ si South Lansing, New York, lati wà nibi ayẹyẹ ikẹkọọyege ti Watchtower Bible School of Gilead. Ni riri awọn ojihin iṣẹ Ọlọrun wọnni ti a ran lọ yika gbogbo aye gbin ifẹ fun iṣẹ-isin ijihin iṣẹ Ọlọrun sinu ọkan mi. Nitori naa, lẹhin kikẹkọọ jade lati ile-ẹkọ giga, mo forukọ silẹ gẹgẹ bi ojiṣẹ aṣaaju-ọna deedee kan, bẹrẹ ni May 1947.

Ọdọbinrin aṣaaju-ọna miiran ninu ijọ wa ni Elsa Schwarz, o si jẹ onitara gan an ninu iṣẹ iwaasu. Awọn obi rẹ ti maa nfun un niṣiiri nigba gbogbo lati jẹ ojihin iṣẹ Ọlọrun, nitori naa o ṣeeṣe ki iwọ le mefo ohun ti o yọrisi. A ṣègbéyàwó ni 1951. Nigba ti a nṣiṣẹsin papọ gẹgẹ bi aṣaaju-ọna ni Pennsylvania, a kọwe beere lati lọ si ile-ẹkọ ijihin iṣẹ Ọlọrun. Ni 1953 a kesi wa si kilaasi ikẹtalelogun ti Gilead. Lẹhin oṣu marun-un ti ikẹkọọ ati imurasilẹ jinlẹjinlẹ ni Gilead, a kẹkọọyege ni apejọpọ kan ni Toronto, Canada, a si gba ibi ti a yàn fún wa—Spain!

Awọn Iṣoro ni Spain

Nigba ti a nmura lati lọ si ibi iṣẹ ayanfunni ijihin iṣẹ Ọlọrun wa ni 1955, Elsa ati emi ní ọpọlọpọ ibeere. Spain! Bawo ni yoo ti rí? Orilẹ-ede naa wa labẹ iṣakoso apaṣẹ wàá aarẹ mẹmba Katoliki naa Francisco Franco, iṣẹ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni o sì wa labẹ ifofinde. Bawo ni awa yoo ṣe ṣaṣeyọrisi rere labẹ iru awọn ipo bẹẹ?

Awọn ara ni orile-iṣẹ Society ni Brooklyn ti fi tó wa leti pe Frederick Franz ti o jẹ igbakeji aarẹ Watch Tower Society nigba naa, ati Alvaro Berecochea, ojihin iṣẹ Ọlọrun kan lati Argentina, ni a ti faṣẹ mú, papọ pẹlu ọpọlọpọ awọn arakunrin miiran. Apejọ ìdákọ́ńkọ́ kan ni a ti ṣeto ninu igbo lẹba Barcelona. Bi o ti wu ki o ri, awọn ọlọpaa ti mọ nipa ikorajọ ìdákọ́ńkọ́ yii wọn si ti faṣẹ mú ọpọ julọ awọn wọnni ti wọn wá sibẹ.a

A ti sọ fun wa pe boya ko ni si ẹnikankan ti yoo le pade wa nigba ti a ba de si Barcelona. Awọn itọni ti wọn fun wa ni pe: “Ẹ wa ile ero kan, lẹhin naa ẹ sọ adirẹsi rẹ fun Society ni New York.” A fi awọn ọrọ Aisaya sọkan pe: “Alayọ ni awọn wọnni ti nduro ni ifojusọna de [Jehofa]. Eti yin yoo si gbọ ọrọ kan lẹhin yin ti nwi pe: ‘Eyi ni ọna naa. Ẹ rin ninu rẹ, ẹyin eniyan.’” (Aisaya 30:18, 21, NW) Awa yoo wulẹ nilati maa duro de Jehofa ki a si tẹle awọn idari eto-ajọ rẹ̀.

A sọ pe o digbooṣe fun awọn obi ati ọrẹ wa ti wọn wá sí New York lati juwọ si wa pe ó dàbọ̀, ati laipẹ, ọkọ oju omi wa, Saturnia, nlọ loju Odo Hudson ni fiforile Atlantic. Iyẹn ni igba ikẹhin ti mo ri baba mi. Ọdun meji lẹhin naa, nigba ti mo wà ní ìdálẹ̀, o ku lẹhin aisan ọlọjọ gbọọrọ kan.

Asẹhinwa asẹhinbọ a dé ibi ti a yan wa sí, ilu ebute ti Barcelona. O jẹ ọjọ ṣiṣu dudu, ti ojo nrọ, ṣugbọn gẹgẹ bi a ti nkọja lara awọn oṣiṣẹ ibode, a ri “itanṣan imọlẹ.” Alvaro Berecochea, papọ pẹlu awọn arakunrin Spain diẹ, wà nibẹ lati pade wa. Inu wa dun gidigidi lati mọ pe a ti da awọn arakunrin wa silẹ.

Nisinsinyi a nilati kẹkọọ ede Spain. Ni awọn ọjọ wọnni awọn ojihin iṣẹ Ọlọrun nilati kọ́ awọn ede lọna lilekoko—laisi awọn iwe ẹkọ tabi awọn olukọ. Ko si itolẹsẹẹsẹ ikẹkọọ ede kankan nigba naa. A nilati doju iwọn wakati ti a beere fun ninu iṣẹ iwaasu ati nigba kan naa, ki a kọ́ ede—lẹnu iṣẹ, ki a sọ ọ́ bẹẹ.

Wiwaasu Labẹ Akoso Bóofẹ́ Bóokọ̀ ti Katoliki

Eto-ajọ Jehofa wà ní ibẹrẹ rẹ̀ ni Spain nigba naa. Ni 1955 gongo awọn akede ti o wa jẹ́ 366 ni ilẹ kan ti o ni ohun ti o pọ tó 28 million awọn eniyan. Ijọ mẹwaa pere ni o wà ni gbogbo orilẹ-ede naa. Yoo ha wà bẹẹ titilọ fun akoko gigun bi? Gbara ti emi ati aya mi ti bẹrẹ wiwaasu lati ile de ile, a rii pe Spain dabii paradise kan fun awọn wọnni ti ntan ihinrere kalẹ. Bẹẹni, awọn eniyan naa nkebi fun otitọ.

Ṣugbọn bawo ni a ti nṣe iṣẹ iwaasu, niwọn igba ti o jẹ pe ó wà labẹ ifofinde? Niye igba a kii ṣebẹwo si gbogbo ile ti o wa ni opopona kan, tabi gbogbo awọn iyara ti ó wà ninu ile kan. Barcelona ni ọpọlọpọ awọn ile alaja marun-un ati mẹfa, a si fun wa ní ìtọ́ni lati bẹrẹ lati oke ki a si maa ṣiṣẹ bọ nisalẹ. Boya a o bẹ kiki iyara kan wò ni àjà kọọkan tabi ki a tilẹ fo awọn àjà melookan dá. Ọna yii mu ki o tubọ ṣoro fun awọn ọlọpaa lati mu wa bi onile kan ti ara rẹ gbona nipa isin ba fẹjọ wa sun.

Awọn ipade ijọ ni a nṣe ninu awọn ile adagbe, ti awọn ijọ si ni tó awujọ ikẹkọọ iwe ijọ mẹta si mẹrin. Eyi mu ki o ṣeeṣe fun iranṣẹ ijọ lati bẹ awọn awujọ ikẹkọọ iwe wọnyi wò lẹẹkan loṣu. Oludari ikẹkọọ iwe ijọ naa ni o lẹru iṣẹ fun didari gbogbo awọn ipade, ti a nṣe ni alẹ meji ọtọọtọ lọsẹ fun awujọ kekere ti o tó lati 10 si 20 awọn eniyan.

A nilati kẹkọọ ọna igbesi-aye titun. Ni akoko yẹn ko si awọn iṣeto ile ojihin iṣẹ Ọlọrun ni Spain. Nibi ti o ba ti ṣeeṣe, a ngbe pẹlu awọn ara ninu ile wọn. Kikẹkọọ lati se ounjẹ lori ààrò eléèédú jẹ iriri ti npeninija fun Elsa! Asẹhinwa asẹhinbọ o ṣeeṣe fun wa lati ra sítóòfù idana kekere kan ti nlo kẹrosin-inni, eyi ti o jẹ itẹsiwaju gidi kan.

Inunibini ati Awọn Ìléjáde

Laipẹ a gbọ ọrọ pe ìgbì inunibini ti bẹrẹ ni Andalusia, nibi ti a ti faṣẹ mu aṣaaju-ọna akanṣe kan. O ṣenilaaanu pe, oun mu awọn iwe pẹlẹbẹ ti o ni orukọ ati adirẹsi awọn ará ni gbogbo apa orilẹ-ede naa nínú dani. A bẹrẹ sii gba irohin pe awọn ará wa ni a nfaṣẹ mu ni ilu kan tẹle omiran. Igbogunti naa nsunmọ Barcelona pẹkipẹki sii. Nikẹhin, inunibini kọlu Barcelona.

Ni oṣu diẹ ṣaaju, awọn ọlọpaa ti mu mi lọ si orile-iṣẹ wọn fun fifi ibeere wanilẹnuwo. Lẹhin awọn wakati melookan a tú mi silẹ, mo si lero pe iyẹn ni opin ọran naa. Lẹhin naa Ọfiisi Aṣoju Orilẹ-ede America kọwe si mi o si damọran pe lati yẹra fun ikojutibani ti didi ẹni ti a le kuro ni ilu, mo gbọdọ fi orilẹ-ede naa silẹ wọọrọwọ. Ni kete lẹhin naa, awọn ọlọpaa sọ fun wa pe a ni ọjọ mẹwaa lati lọ. Niwọn igba ti a ko ti ni akoko kankan lati kọwe si Watch Tower Society, ki ni a nilati ṣe? Awọn ipo dabi eyi ti o tọka pe a gbọdọ forile papa ijihin iṣẹ Ọlọrun ti o sunmọ tosi julọ lẹhin ode Spain—Portugal, si iha iwọ oorun.

Iṣẹ Ayanfunni Miiran, Ede Miiran

Gbàrà ti a dé si Lisbon, Portugal, ni July 1957, a yan wa gẹgẹ bi ojihin iṣẹ Ọlọrun si Porto, ilu kan ti o sunmọ ariwa Lisbon. A kà á si olu ilu keji ti orilẹ-ede naa o si wa ni ẹkùn kan ti o lokiki fun waini didun rẹ̀. Ijọ kan ti ńgbèrú nṣe awọn ipade rẹ̀ ninu yara isalẹ ile kan ni apa isalẹ ilu naa. Iṣẹ iwaasu ni a fofinde ni Portugal pẹlu, gẹgẹ bi ilu naa ti wa labẹ ijọba bóofẹ́ bóokọ̀ ti Salazar. Sibẹ, awọn ipo yatọ gidigidi si ti awọn wọnni ni Spain. Awọn ipade ni a nṣe ninu ile awọn ara, awujọ lati 40 si 60 si npesẹ. Ko si awọn itọka pe awọn ile naa jẹ ibi ipade awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ani bi o tilẹ jẹ pe emi kii sọ ede Portugal, a yan mi ni iranṣẹ ijọ. Lẹẹkan sii, a kẹkọọ ede titun ni ọna lilekoko.

Ni nǹkan bi ọdun kan lẹhin naa, a yan wa si Lisbon. Nihin in, fun igba akọkọ, a ni ibugbe tiwa funraawa, yara kan ti a ti le wo ilu Lisbon. A yàn wa lati bojuto ayika kan—gbogbo Republic of Portugal. Nigba ti a de si Portugal, kiki 305 awọn akede ati ijọ marun un ni o wà.

Akoko Idaamu Bẹrẹ

Lori diẹ lara awọn aworan ilẹ ti nfi Portugal ati awọn ilu ti ó tẹdo han, ọrọ kan wà ti o kà pe: “Oorun kii wọ̀ ni ipinlẹ awọn ara Portugal.” Eyi jẹ otitọ, niwọn igba ti Portugal ti ni awọn ilu ti a njọba le lori ni apa ibi pupọ ni aye, ti meji ti o tobi julọ lara wọn jẹ́ Mozambique ati Angola ní Africa. Ni 1961 o dabi ẹni pe awọn iṣoro ngbarajọ ninu awọn ilẹ atokeere ṣakoso wọnyi, Portugal si ri aini lati mu awọn agbo ọmọ ologun rẹ̀ pọ sii.

Nisinsinyi, ki ni awọn ọdọ arakunrin yoo ṣe nigba ti a ba gbà wọn fun iṣẹ-isin ologun? O ṣeeṣe fun awọn kan lati gba itusilẹ nitori ailera ara, ṣugbọn ọpọ julọ mu iduro gbọnyingbọnyin fun aidasi tọtun tosi Kristẹni. Laipẹ ìgbì inunibini nla bẹrẹ. Ẹka naa gba irohin pe awọn aṣaaju-ọna akanṣe ni a nfaṣẹ mu ti a si ńnà lọna biburu jai lati ọwọ awọn ọlọpa-inu, P.I.D.E. (Policia Internacional e Defesa do Estado). Diẹ ninu awọn ojihin iṣẹ Ọlọrun ni a pe si orile-iṣẹ ọlọpaa fun ifibeere wanilẹnuwo. Lẹhin naa, awọn tọkọtaya mẹta ni a fun ni 30 ọjọ lati fi ilu naa silẹ. Gbogbo wa pe ẹjọ kòtẹ́milọ́rùn.

Nikọọkan a pe awọn tọkọtaya ojihin iṣẹ Ọlọrun si orile iṣẹ ọlọpaa fun ifọrọwanilẹnuwo pẹlu oludari P.I.D.E. Lakọọkọ, iranṣẹ ẹka naa, Eric Britten, ati aya rẹ, Christina, ni a wadii ọrọ wo lẹnu wọn. Lẹhin naa Eric Beveridge Hazel, ati nikẹhin Elsa ati emi ni a fi ibeere walẹnuwo. Ọga ọlọpaa naa fẹsun kan wa lọna eke pe a jẹ awọn ti àjọ Kọmunisti nlo lati jin awọn orilẹ-ede Iwọ-oorun lẹsẹ nipa awọn ẹkọ wa lori aidasi tọtun tosi. Pípẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn wa jasi asan.

Bawo ni o ti baninínújẹ́ tó lati fi 1,200 awọn arakunrin ati arabinrin ti wọn nla akoko lilekoko já silẹ sẹhin nitori iṣakoso mimuna ti apàṣẹwàá alainironu! Nigba ti idile Beveridge lọ si Spain ti idile Britten si lọ si England, ibo ni yoo jẹ ibi ayanfunni wa titun? Morocco ti awọn Musulumi!

Wiwaasu Ni Morocco Ti Isin Islam

Lẹẹkan sii, a nfojusọna ni diduro de Jehofa. Ibi ayanfunni titun kan, awọn aṣa titun ati awọn ede titun! Larubawa, Faranse, ati Spanish ni ede ti Ijọba Morocco faṣẹ si, nibi ti 234 awọn Ẹlẹrii wa ninu ijọ mẹjọ. Isin ilu naa ti a faṣẹ si ni Islam, yiyi awọn eniyan lero pada laaarin awọn Musulumi si jẹ eyi ti ko bofinmu. Nitori naa awa le waasu fun kiki awọn ara ilu ti wọn jẹ ara Europe ti kii ṣe Musulumi.

Ni gbàrà ti awọn ojihin iṣẹ Ọlọrun bẹrẹ sii de ni opin awọn ọdun 1950, awọn ibisi ni a ri. Ṣugbọn ijọba Morocco bẹrẹ sii fínnámọ́ awọn eniyan ara Europe, ìṣílọ awọn àjèjì pupọ rẹpẹtẹ ni o si wà, titi kan ọpọlọpọ awọn ara.

Gẹgẹ bi awọn olugbe ti wọn kii ṣe Musulumi ti joro, o pọndandan fun wa lati wá ọna ọlọgbọn ẹwẹ lati ba awọn Musulumi sọrọ, eyi si ṣamọna si fifẹjọsun fun awọn ọlọpaa. Bi awọn ifẹjọsun naa ti ndi lemọlemọ sii ni Tangier ati awọn ilu miiran, a sọ fun wa nikẹhin pe a ni kiki 30 ọjọ lati fi ilu naa silẹ. Ni May 1969, emi ati Elsa ni a lé jade kuro ninu ibi ayanfunni miiran sibẹ.

Ibi Ayanfunni Onigba Kukuru Kan Ha Ni Bi?

A sọ fun wa lati pada si Brooklyn, a si kesi mi lati lọ si ipade fun awọn iranṣẹ ẹka ti a ṣe nigba ẹrun yẹn. Nigba ti mo wà nibẹ, a sọ fun mi pe ibi ayanfunni wa titun yoo jẹ El Salvador, Central America, ati pe emi yoo nilati ṣiṣẹsin nibẹ gẹgẹ bi iranṣẹ ẹka. Mo mọ pe eyi ṣeeṣe julọ ki o pẹ to nǹkan bi ọdun marun-un, igba ti a yọnda mọ fun awọn ojihin iṣẹ Ọlọrun lati fi wa ninu orilẹ-ede naa, niwọn igba ti a ko tii ka iṣẹ wa sí labẹ ofin nibẹ.

El Salvador—iru ibi ayanfunni wo ni eyi jẹ! Ipindọgba 1,290 awọn akede, papọ pẹlu 114 awọn aṣaaju-ọna ti wọn nrohin loṣooṣu ni wọn wa. Awọn eniyan naa jẹ olubẹru Ọlọrun, olufẹ Bibeli, ati ẹlẹmii alejo ṣiṣe. Ni ohun ti o fẹrẹẹ jẹ gbogbo ẹnu ọna, wọn yoo kesi wa wọle lati ba wọn sọrọ. Laipẹ laijinna, a ni ọpọlọpọ awọn ikẹkọọ Bibeli de ibi ti apa wa le ká a dé.

Gẹgẹ bi a ti nṣakiyesi ibisi ati aini titobi nibẹ, ó bà wá ninu jẹ pe awa yoo nilati fi ibi ayanfunni yii silẹ lẹhin kiki ọdun marun un pere. Nitori naa a pinnu rẹ pe a gbọdọ gbiyanju lati jẹ ki a ka iṣẹ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa sí labẹ ofin. A kó awọn iwe lelẹ fun ijọba ni December 1971, ati ni April 26, 1972, o dun mọ wa ninu lati ka ninu iwe irohin ijọba, Diario Oficial, pe ẹbẹ wa ni a ti tẹwọgba. Awọn ojihin iṣẹ Ọlọrun naa ni ki yoo nilati lọ lẹhin ọdun marun un ṣugbọn wọn le gba iwe olugbe onigba pipẹ ninu orilẹ-ede naa.

Awọn Idanwo ati Ibukun

Lati awọn ọdun wọnyi wá ninu oniruuru awọn ibi ayanfunni wa, a ti ni ọpọlọpọ awọn ọrẹ a si ti ri eso ninu iṣẹ-ojiṣẹ wa. Elsa niriiri daradara kan ni San Salvador pẹlu olukọ ile-ẹkọ kan ati ọkọ rẹ ti o jẹ sójà. Ọkan lara awọn ọrẹ olukọ ile-ẹkọ naa tun di ẹni ti o nifẹẹ otitọ. Lakọọkọ ọkọ naa ko fi ifẹ han ninu Bibeli; sibẹ, a nṣebẹwo sọdọ rẹ nigba ti o wa ni ile iwosan, o si jẹ ẹni bi ọrẹ. Asẹhinwa asẹhinbọ o kẹkọọ Bibeli, o fi iṣẹ igbesi-aye ologun rẹ̀ silẹ, o si bẹrẹ iwaasu papọ pẹlu wa.

Laaarin akoko naa, ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ obinrin kan wá sí Gbọngan Ijọba o si sọ fun Elsa bi o ba nkẹkọọ pẹlu sójà tẹlẹri naa. O jẹ jade pe oun ti jẹ àlè rẹ̀! Oun pẹlu nkẹkọọ Bibeli pẹlu awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ni apejọpọ agbegbe, ọkunrin ologun tẹlẹri naa, aya rẹ, ọrẹ aya rẹ̀, ati ale rẹ̀ tẹlẹri naa ni gbogbo wọn ṣe baptisi papọ!

Imugbooro ni El Salvador

Nitori ibisi ńláǹlà naa, ọpọlọpọ Gbọngan Ijọba ni a ti kọ́, orilẹ-ede naa si ni ohun ti o ju 18,000 awọn Ẹlẹrii agbekankan ṣiṣẹ nisinsinyi. Bi o ti wu ki o ri, itẹsiwaju yii ni ko ti ṣẹlẹ laini awọn idanwo ati idẹwo tirẹ̀. Fun ọdun mẹwaa, awọn ara ti nilati ṣe ifẹ inu Jehofa laaarin ogun abẹle. Ṣugbọn wọn ti pa aidasi tọtun tosi wọn mọ́ wọn si wa ni aduroṣinṣin ti Ijọba Jehofa.

Laaarin awa mejeeji, emi ati Elsa ti wa ninu iṣẹ-isin alakooko kikun fun 85 ọdun. A ti ri i pe nigba ti a ba nduro de Jehofa ti a si fetisilẹ ‘si ọrọ lati ẹhin ti nwi pe, “Eyi ni ọna naa. Ẹ rin ninu rẹ̀, ẹyin eniyan,”’ awa ni a ko jakulẹ rí lae. Nitootọ ni awa ti gbadun igbesi-aye ti ntẹnilọrun ti o si kun fun ẹsan rere gẹgẹ bi iranṣẹ Jehofa alakooko kikun.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fun alaye kikun, wo 1978 Yearbook of Jehovah’s Witnesses, oju-iwe 177 si 179.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Apejọ ninu igbo ẹgan kan ni Spain, 1956

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

A ti waasu fun awọn ti kii ṣe Musulumi rí ni Morocco

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Ẹka ni El Salvador, ibi ayanfunni wa ti lọọlọọ

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́