A Fún Wa Ní Péálì Tí Ìníyelórí Rẹ̀ Ga
GẸ́GẸ́ BÍ RICHARD GUNTHER ṢE SỌ Ọ́
September 1959 ni. A wà nínú ọkọ̀ ojú-omi ilẹ̀ Itali Julio Caesar tí a ń rìnrìn-àjò rékọjá Òkun-Ńlá Atlantic láti New York sí Cádiz, Spania. Watch Tower Society ti yàn mí, papọ̀ pẹ̀lú aya mi, Rita, àti Paul òun Evelyn Hundertmark, tọkọtaya míṣọ́nnárì mìíràn, sí orílẹ̀-èdè àwọn ará Iberia yẹn. A óò dojúkọ ọ̀pọ̀ ìpèníjà. Ṣùgbọ́n báwo ni a ṣe pinnu láti dáwọ́lé iṣẹ́ ìgbésí-ayé míṣọ́nnárì?
ÈMI àti Rita ṣe ìrìbọmi gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jehofa ní 1950 ní New Jersey, U.S.A. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, a ṣe ìpinnu kan tí yóò jẹ́ kí ọwọ́ wa lè tètè tẹ péálì tí ìníyelórí rẹ̀ ga. A wà nínú ìjọ kan tí ó ní àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí ó tó láti ṣiṣẹ́sìn ní agbègbè ìpínlẹ̀ náà. Nítorí náà a nímọ̀lára àìgbọdọ̀máṣe láti yọ̀ǹda láti ṣiṣẹ́sìn níbi tí àìní púpọ̀ síi wà fún àwọn oníwàásù. Ní àpéjọ àgbáyé ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní New York City ní ìgbà ẹ̀rùn 1958, a kọ̀wé béèrè fún iṣẹ́-ìsìn míṣọ́nnárì.
Kété lẹ́yìn náà, a pè wá sí Watchtower Bible School of Gilead, láàárín ọdún kan a sì ti ń múra láti lọ sí Spania gẹ́gẹ́ bí míṣọ́nnárì. Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣètò tí a ń ṣe lọ́tùn-ún lósì tí ìdùnnú sì ṣubú layọ̀ fún wa, a kò tètè mọ ohun tí a fún wa nígbà náà. Jesu ti sọ̀rọ̀ nípa péálì tí ìníyelórí rẹ̀ ga. (Matteu 13:45, 46) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àǹfààní míṣọ́nnárì wa kì í ṣe kókó inú òwe àkàwé rẹ̀, lójú tiwa àǹfààní wa ti ṣíṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí míṣọ́nnárì ni a lè fi wé péálì. Bí a bá ronú nípa ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn, a mọrírì ní kíkún nísinsìnyí ẹ̀bùn ṣíṣeyebíye yìí ti iṣẹ́-ìsìn nínú ètò-àjọ Jehofa.
Ìrírí Mánigbàgbé
Nígbà yẹn lọ́hùn-ún ipa ẹ̀kọ́ Gilead fún àwọn míṣọ́nnárì ni a ń ṣe ní àyíká ìgbèríko rírẹwà ní ẹkùn Finger Lakes ti Ìpínlẹ̀ New York. Níbẹ̀, a lo oṣù mẹ́fà tí ó jẹ́ àgbàyanu nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli tí ó jinlẹ̀ gidigidi àti ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ tòótọ́ ti Kristian, a yà wá sọ́tọ̀ kúrò nínú àwọn àlámọ̀rí ayé àti wàhálà. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ wa wá láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ibi nínú ayé, títí kan Australia, Bolivia, Britain, ilẹ̀ Griki, àti New Zealand. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, wẹ́rẹ́ ni ọjọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́yege dé. Ní August 1959, a dágbére pé ó dìgbà kan ná pẹ̀lú omijé lójú wa bí a ṣe ń tukọ̀ lọ sí àwọn ibi iṣẹ́ àyànfúnni wa lẹ́nìkọ̀ọ̀kan. Oṣù kan lẹ́yìn náà a gúnlẹ̀ sí Spania.
Àṣà Ìbílẹ̀ Titun
A gúnlẹ̀ sí èbúté ìhà gúúsù ti Algeciras, lẹ́gbẹ̀ẹ́ Àpáta Gibraltar kàbìtì-kabiti náà. Ní alẹ́ ọjọ́ yẹn àwa mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, èmi àti Rita pẹ̀lú àwọn Hundertmark, wọ ọkọ̀ ojú-irin lọ sí Madrid. A lọ sí Hòtẹ́ẹ̀lì Mercador, láti lè dúró síbẹ̀ títí tí àwọn mẹ́ḿbà ọ́fíìsì ẹ̀ka bòókẹ́lẹ́ ti Society yóò fi kàn sí wa. Spania wà lábẹ́ àkóso bóofẹ́-bóokọ̀ ti Ọ̀gágun Àgbà Francisco Franco nígbà náà. Èyí túmọ̀ sí pé kìkì ìsìn kanṣoṣo tí a fọwọ́ sí ní orílẹ̀-èdè náà ni Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Katoliki. Ó lòdì sófin láti ṣe ìsìn mìíràn ní gbangba, iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni a sì fòfindè. Àní a tilẹ̀ ka àwọn ìpàdé ìsìn léèwọ̀, tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, tí iye wọn tó nǹkan bí 1,200 ní 30 ìjọ ní Spania nígbà náà lọ́hùn-ún, kò lè pàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba bíi ti àwọn ilẹ̀ mìíràn. A níláti máa pàdé ní bòókẹ́lẹ́ ní àwọn ilé àdáni.
Kíkọ́ Èdè Spanish àti Bíbẹ̀rẹ̀
Ìpèníjà wa àkọ́kọ́ ni láti kọ́ èdè náà. Ní oṣù àkọ́kọ́ a lo wákàtí 11 lójúmọ́ láti kọ́ èdè Spanish—wákàtí 4 láràárọ̀ ní kíláàsì, lẹ́yìn náà wákàtí 7 fún kíkẹ́kọ̀ọ́ fúnra wa. Bẹ́ẹ̀ náà ni oṣù kejì ṣe rí láràárọ̀, ṣùgbọ́n a ya àwọn ọwọ́ ọ̀sán sọ́tọ̀ fún ìwàásù ilé-dé-ilé. O ha lè gba èyí gbọ́ bí? Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé a kò tí ì mọ èdè náà tí ó sì jẹ́ pé pẹ̀lú kìkì ìnasẹ̀-ọ̀rọ̀ tí a kọ sórí káàdì tí a ti há sórí nìkan ni, èmi àti Rita jáde lọ fún iṣẹ́ ilé-dé-ilé fúnra wa!
Mo rántí kíkan ilẹ̀kùn kan ní Vallecas, apá ibi tí àwọn òṣìṣẹ́ ń gbé ní Madrid. Nítorí àíbaàámọ̀, mo mú káàdì mi dání, mo sọ ní èdè Spanish pé: “Ẹ káàárọ̀ o. A ń ṣe iṣẹ́ Kristian níhìn-ín ni o. Bibeli sọ pé (a óò ka ẹsẹ̀ ìwé mímọ́ kan). Àwa yóò fẹ́ kí ẹ ní ìwé pẹlẹbẹ yìí.” Ó dára, obìnrin náà wulẹ̀ ń wò ni, lẹ́yìn náà ó gba ìwé pẹlẹbẹ náà. Nígbà tí a ṣe ìpadàbẹ̀wò, ó késí wa wọlé, bí a sì ṣe sọ̀rọ̀, ó ṣáà ń wò wá ni. A bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú rẹ̀ níbi tí òye wa mọ, nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, ó ṣáà tẹ́tísílẹ̀ tí ó sì ń wò. Lẹ́yìn àkókò kan ó sọ fún wa nígbẹ̀yìn gbẹ́yín pé òun kò lóye ohun tí a sọ nígbà ìbẹ̀wò wa àkọ́kọ́ ṣùgbọ́n òun gbọ́ ọ̀rọ̀ náà Dios (Ọlọrun) àti pé èyí ti tó fún òun láti mọ̀ pé ohun dáradára ni. Nígbà tí ó yá, ó gba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìmọ̀ Bibeli ó sì ṣe ìrìbọmi, ní dídi ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa.
Kíkọ́ èdè Spanish ṣòro fún mi gidigidi. Nígbà tí mo bá ń rìnrìn-àjò láàárín ìlú, mo máa ń há bí a ṣe ń ṣẹ̀dá ọ̀rọ̀-ìṣe sórí. Ohun tí mo bá há sórí lọ́sẹ̀ kan n óò ti gbàgbé rẹ̀ ní ọ̀sẹ̀ tí ó tẹ̀lé e! Ó múni rẹ̀wẹ̀sì púpọ̀. Mo fẹ́rẹ̀ẹ́ juwọ́ sílẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ìgbà. Níwọ̀n bí èdè Spanish mi kò ti dán mọ́rán, àwọn arákùnrin tí wọ́n jẹ́ ará Spania níláti mú sùúrù gidigidi bí mo ṣe ń mú ipò iwájú láàárín wọn. Ní àpéjọpọ̀ àgbègbè kan, arákùnrin kan fún mi ní ìfilọ̀ kan tí a fi ọwọ́ kọ láti kà lórí pèpéle. Níwọ̀n bí ó ti ṣòro fún mi láti ka ìkọ̀wé rẹ̀, mo ṣe ìfilọ̀ pé: “Ẹ mú muletas (ọ̀pá ìkẹ́sẹ̀) yin wá sí pápá ìṣeré lọ́la.” Ohun tí ó yẹ kí ó jẹ́ ni pé, “Ẹ kó maletas (ẹrù) yin wá sí pápá ìṣeré lọ́la.” Gẹ́gẹ́ bí a ti lè retí, àwùjọ náà bú sẹ́rìn-ín, àti lọ́nà tí ó bá ìwà ẹ̀dá mu ojú tì mí.
Ìdánwò Ìgbà Àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ní Madrid
Àwọn ọdún díẹ̀ àkọ́kọ́ wọ̀nyẹn ní Madrid jẹ́ èyí tí ó ṣòro gidigidi níti èrò ìmọ̀lára fún èmi àti Rita. Àárò ilé wa àti àwọn ọ̀rẹ́ wa sọ wá gan-an ni. Ìgbàkígbà tí a bá rí lẹ́tà gbà láti United States, àárò ilé yóò tún sọ wá gan-an. Àwọn sáà tí àárò ilé ń sọ wá yẹn mú ọkàn wa pòrúrùu, ṣùgbọ́n wọ́n kọjá lọ. Ó ṣetán, a ti fi ilé, ìdílé, àti àwọn ọ̀rẹ́ sílẹ̀ láti gba péálì tí ìníyelórí rẹ̀ ga dípò. A níláti mú ara wa bá ipò mu.
Nígbà tí a kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí gbé ní Madrid, a bá ara wa nínú ilé àyágbé wúruwùru kan. A ní iyàrá a sì ń jẹ oúnjẹ ẹ̀ẹ̀mẹ́ta lóòjọ́. Iyàrá kékeré kan tí ó ṣókùnkùn ni, koríko gbígbẹ ni a sì fi ṣe àwọn ibùsùn náà. Owó ilé oṣooṣù ni ó ń gba èyí tí ó pọ̀jù lọ nínú owó ìyọ̀ǹda wa tí ó mọ níwọ̀n. A sábà máa ń jẹ oúnjẹ ọ̀sán nínú ilé náà, ìyá onílé náà sábà máa ń fi oúnjẹ wa sínú ààrò tí ń lo iná mànàmáná kí ó má baà tutù kí ó baà lè jẹ́ pé nígbà tí o bá di alẹ́ a óò ní nǹkan láti jẹ. Bí ó ti wù kí ó rí, bí a ṣe ń rin òpópónà lọ́sàn-án àti lálẹ́, ebi yóò máa pa wá gan-an. Bí owó ìyọ̀ǹda wa bá ti tán, a óò ná ìwọ̀nba owó tiwa fúnra wa láti ra ọ̀pá ṣokoléètì èyíkéyìí tí a bá rí tí owó rẹ̀ mọ níwọ̀n jùlọ. Bí ó ti wù kí ó rí, kò pẹ́ púpọ̀ tí ipò yìí fi yípadà nígbà tí alábòójútó ẹ̀ka ti Society ṣèbẹ̀wò. Ó rí ìṣòro wa ó sì sọ pé a lè wá ilé kékeré kan láti lò gẹ́gẹ́ bí ilé àwọn míṣọ́nnárì. Ó dára, èyí yóò dára ju wíwẹ̀ lórí ìdúró nínú ọpọ́n ìwẹ̀ lórí ilẹ̀ẹ́lẹ̀ nínú ilé ìdáná lọ. Nísinsìnyí omi ẹ̀rọ yóò máa dà lé wa lórí yàà, a óò ní ẹ̀rọ amóhuntutù láti lè máa tọ́jú oúnjẹ sí, àti ẹ̀rọ ìdáná tí ń lo iná mànàmáná tí a óò fi lè máa se oúnjẹ wa. A mọrírì ìgbatẹnirò náà lọ́pọ̀lọpọ̀.
Àwọn Ìrírí Àgbàyanu ní Madrid
Ìṣọ́ra gidigidi ni a fi ń ṣe iṣẹ́ ilé-dé-ilé. Rògbòdìyàn ojoojúmọ́ tí ń ṣẹlẹ̀ ní Madrid jẹ́ àǹfààní kan, ó ń dáàbòbò wá kí ó má baà rọrùn láti tètè rí wa. A gbìyànjú láti múra kí a sì hùwà bíi ti àwọn mìíràn kí a má baà dá yàtọ̀ gẹ́gẹ́ bí àjòjì. Ọ̀nà tí a gbà ń wàásù láti ilé-dé-ilé ni láti wọnú ilé kan, kí a kan ilẹ̀kùn, kí a bá ẹni náà sọ̀rọ̀, kí a sì fi ilé náà, àdúgbò, àti agbègbè náà sílẹ̀. Ó máa ń ṣeé ṣe pé kí onílé náà késí àwọn ọlọ́pàá, nítorí náà kò bọ́gbọ́n mu láti dúró ní àdúgbò náà. Ní tòótọ́, àní bí Paul àti Evelyn Hundertmark ṣe ṣọ́ra tó nínú lílo ọgbọ́n yìí, a fàṣẹ ọba mu wọn tí a sì lé wọn jáde kúrò ní orílẹ̀-èdè náà ní 1960. Wọ́n lọ sí Portugal tí ó múlégbè é, wọ́n ṣiṣẹ́sìn níbẹ̀ fún ọdún mélòókan, tí Paul sì ń bójútó ọ́fíìsì ẹ̀ka lábẹ́lẹ̀. Lónìí òun ni alábòójútó ìlú-ńlá ní San Diego, California.
Bí ó ti wù kí ó rí, ohun kan náà ṣẹlẹ̀ sí wa. Oṣù díẹ̀ péré lẹ́yìn náà, a pàṣẹ pé kí àwọn míṣọ́nnárì mẹ́fà tí a yàn sí Portugal fi orílẹ̀-èdè náà sílẹ̀! Èyí mú ìdàgbàsókè aláyọ̀ wá nítorí pé Eric àti Hazel Beveridge, tí àwọn pẹ̀lú jẹ́ ọmọ kíláàsì wa ní Gilead, ní a ti pàṣẹ fún báyìí láti fi Portugal sílẹ̀ kí wọ́n sì wá sí Spania. Nítorí náà a wà ní Hòtẹ́ẹ̀lì Mercador lẹ́ẹ̀kan síi, ní February 1962—lọ́tẹ̀ yìí láti kí Eric àti Hazel káàbọ̀ bí wọ́n ti gúnlẹ̀.
Àwọn ọjọ́ ìbẹ̀rẹ̀ wọ̀nyí gan-an ní Madrid ni èmi àti Rita ní ìrírí ti ara-ẹni nípa àgàbàgebè ìsìn. A kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú tọkọtaya kan, Bernardo àti Maria, tí wọ́n ń gbé nínú ilé wúruwùru tí a fi àwọn ohun-èlò ìkọ́lé tí kò wúlò mọ́ tí Bernardo lè rí kọ́. A kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú wọn ní òrugànjọ́, lẹ́yìn ìkẹ́kọ̀ọ́, wọn yóò fún wa ní búrẹ́dì, wáìnì, àti wàràkàṣì díẹ̀ tàbí ohunkóhun tí wọ́n bá ní. Mo ṣàkíyèsí pé wàràkàṣì náà dàbí ti America gẹ́lẹ́. Ní alẹ́ ọjọ́ kan lẹ́yìn ìkẹ́kọ̀ọ́, wọ́n mú agolo wàràkàṣì náà jáde. Wọ́n kọ ọ́ sí i lára gàdàgbà, ní èdè Gẹ̀ẹ́sì pé, “Láti ọ̀dọ̀ àwọn ará America sí àwọn ará Spania—a kò gbọ́dọ̀ tà á.” Báwo ni àwọn ìdílé tí ó tòṣì yìí ṣe rí wàràkàṣì náà gbà? Ìjọba lo Ṣọ́ọ̀ṣì Katoliki láti pín in fún àwọn òtòṣì. Ṣùgbọ́n àwọn àlùfáà náà ń tà á!
Iṣẹ́-Òjíṣẹ́ Tí Ó Méso Wá Pẹ̀lú Àwọn Ológun
Láìpẹ́ ohun kan tí ó yanilẹ́nu ṣẹlẹ̀ tí yóò yọrí sí ìbùkún jìgbìnnì fún wa àti fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ mìíràn. Ọ́fíìsì ẹ̀ka fi tó wa létí pé kí a bẹ ọ̀dọ́kùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Walter Kiedaisch wò, ẹni tí ń gbé ní ibùdó Ọmọ-Ogun Òfúúrufú ti United States ní Torrejón, tí ó wà ní ibùsọ̀ díẹ̀ lẹ́yìn ìlú Madrid. A bẹ òun àti aya rẹ̀ wò, a bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú wọn àti tọkọtaya mìíràn níbẹ̀ tí wọ́n jẹ́ Ọmọ-Ogun Òfúúrufú.
Nígbà yẹn, mo ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli bíi márùn-ún pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ Ọmọ-Ogun Òfúúrufú ti United States, àmọ́ ṣáá o, gbogbo rẹ̀ jẹ́ ní èdè Gẹ̀ẹ́sì. Lára àwọn wọ̀nyẹn, méje ṣe ìrìbọmi lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, lẹ́yìn tí wọ́n sì padà sí United States, mẹ́rin lára àwọn ọkùnrin náà di alàgbà ìjọ.
Èyí jẹ́ ní àkókò náà nígbà tí ó jẹ́ pé ọ̀nà díẹ̀ ni ó wà láti gbà mú àwọn ìwé-ńlá, ìwé ìròyìn, àti Bibeli wọ orílẹ̀-èdè náà nítorí ìfòfindè tí ó wà lórí iṣẹ́ náà. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn arìnrìn-àjò àti àwọn ońṣẹ́ wa sí America mú àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ díẹ̀ wá. Ẹ̀ka náà yàn mí láti máa bójútó ibùdó bòókẹ́lẹ́ ti ìkówèé-ìkẹ́kọ̀ọ́-sí. Ó jẹ́ ní iyàrá ìkẹ́rù sí kan lẹ́yìn ilé ìkówèé sí kan ní Vallecas. Aya ẹni tí ó ni ín jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun kì í ṣe Ẹlẹ́rìí, ẹni tí ó ni ín náà bọ̀wọ̀ fún iṣẹ́ wa, àní ní fífi ara rẹ̀ àti òwò rẹ̀ wewu pàápàá, ó fàyè gbà mí láti lo ẹ̀yìnkùlé tí ó ga yìí láti ṣètò àwọn ìdìpọ̀ ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ láti fi ránṣẹ́ sí àwọn ìlú-ńlá jákèjádò orílẹ̀-èdè náà. Níwọ̀n bí iyàrá yìí tí máa ń fìgbà gbogbo rí bí ó ṣe yẹ kí ó rí—iyàrá kan tí eruku bò, tí ó rí wúruwùru tí àwọn páálí sì kún fọ́fọ́—mo níláti kan tábìlì ìfiṣiṣẹ́ àti pẹpẹ ìkówèésí tí a lè tètè tò papọ̀ kí ó sì wà ní sẹpẹ́ fún iṣẹ́ kíákíá tí a sì lè tú palẹ̀ lẹ́yìn náà láàárín ìṣẹ́jú àáyá. Bí ilẹ̀ bá ń ṣú lọ, èmi yóò dúró títí di ìgbà tí kò bá sí ẹnikẹ́ni ní ilé ìkẹ́rù-sí n óò sì yára jáde pẹ̀lú àwọn ẹrù mi.
Àǹfààní gidi ni ó jẹ́ láti nípìn-ín nínú pípín àwọn ohun-èlò tẹ̀mí, irú bí àwọn ìwé ìròyìn Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí! àti àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ mìíràn, fún àwọn ìjọ jákèjádò orílẹ̀-èdè náà. Àwọn àkókò tí ó mú ayọ̀ wá ni ìwọ̀nyẹn jẹ́.
Rita ní ìdùnnú-ayọ̀ ti dídarí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé 16, nǹkan bí ìdajì lára wọn di Ẹlẹ́rìí fún Jehofa tí ó ti ṣe ìrìbọmi. Dolores jẹ́ obìnrin adélébọ̀ kékeré kan tí ó lo àkókò òtútù ọ̀gìnnìtìn lórí ibùsùn nítorí ìṣòro ọkàn-àyà tí ó ní. Ní ìgbà ìrúwé ó lè dìde kí ó sì ṣe ṣámúṣámú díẹ̀. Ìgbàgbọ́ Dolores lágbára, nítorí náà nígbà tí àkókò náà dé fún àpéjọpọ̀ àgbègbè ní Toulouse, France, ó fẹ́ láti lọ dandan. Dókítà kìlọ̀ fún un pé yóò jẹ́ ohun tí kò bọ́gbọ́n mu nítorí ipò tí ọkàn-àyà rẹ̀ wà. Pẹ̀lú aṣọ ìwọ́lẹ̀ àti sálúbàtà, tí kò sì gbé ẹrù kankan, ó lọ sí ibùdó ọkọ̀ ojú-irin láti kí ọkọ rẹ̀, ìyá rẹ̀, àti àwọn mìíràn pé ó dàbọ̀. Omi dà pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀ lójú rẹ̀, ara rẹ̀ kò gbà á mọ́ pé kí wọ́n lọ láì mú òun dáni, nítorí náà o wọnú ọkọ̀ ojú-irin náà, bí ó sì ṣe lọ sí France nìyẹn! Rita kò mọ̀ pé èyí ṣẹlẹ̀. Ṣùgbọ́n níbẹ̀ ní àpéjọpọ̀ náà, ẹ wo irú ìyàlẹ́nu tí ó jẹ́ nígbà tí ó rí Dolores, tí ó bù sẹ́rìn-ín!
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli Tí Ó Ṣàrà-Ọ̀tọ̀
A kò lè parí àkọsílẹ̀ nípa iṣẹ́ àyànfúnni wa ní Madrid láì mẹ́nu kan Don Benigno Franco, “el profesor.” Ẹlẹ́rìí kan ní àdúgbò mú mi lọ ṣe ìbẹ̀wò sí ọ̀dọ̀ ọ̀gbẹ́ni àgbàlagbà kan tí ń gbé pẹ̀lú aya rẹ̀ nínú ilé kan tí kò bójúmu rárá. Mo bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú rẹ̀. Lẹ́yìn kíkẹ́kọ̀ọ́ fún nǹkan bí ọdún kan àti ààbọ̀, ó ní òun yóò ṣe ìrìbọmi òun yóò sì di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa.
Ọ̀gbẹ́ni àgbàlagbà yìí, Don Benigno Franco, jẹ́ ìbátan Francisco Franco, aláṣẹ bóofẹ́ bóokọ̀ ti Spania ní àkókò náà. Ó dàbí ẹni pé ẹni tí ó fìgbà gbogbo nífẹ̀ẹ́ òmìnira ni Don Benigno jẹ́. Nígbà Ogun Abẹ́lé Spania, ó bá Orílẹ̀-Èdè Aláààrẹ náà kẹ́dùn ó sì lòdì sí ìbátan rẹ̀—ọ̀gágun tí ó jagunmólú nínú ogun náà tí ó sì dá ìṣàkóso bóofẹ́ bóokọ̀ Katoliki sílẹ̀. Láti 1939, Don Benigno ni a ti fi ẹ̀tọ́ iṣẹ́ ṣíṣe dù, ìwọ̀nba owó ìgbọ́bùkátà díẹ̀ ni a sì ń fún un. Nítorí náà bí ìbátan Ọ̀gágun Àgbà Francisco Franco, oníjọba ológun bóofẹ́ bóokọ̀ ti Spania, ṣe di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nìyẹn.
Ìkésíni Yíyanilẹ́nu
Ní 1965 ẹ̀ka ọ́fíìsì ní Spania ké sí wa láti bẹ̀rẹ̀ ìrìn-àjò nínú iṣẹ́ àyíká ní Barcelona. Èyí túmọ̀ sí fífi gbogbo àwọn arákùnrin onífẹ̀ẹ́ tí a ti súnmọ́ pẹ́kípẹ́kí ní Madrid sílẹ̀. Kì í ṣe kìkì ìrírí titun ni n óò bẹ̀rẹ̀ síí ní báyìí, ṣùgbọ́n n óò tún fojú winá ìdánwò pẹ̀lú. Ìrírí náà ń dáyà fò mí nítorí pé mo ti máa ń fìgbà gbogbo ṣiyèméjì nípa agbára-ìṣe mi. Mo mọ̀ dájú pé Jehofa ni ó ràn mí lọ́wọ́ láti jẹ́ ẹni tí ó jáfáfá nínú iṣẹ́-ìsìn pápá.
Bíbẹ ìjọ kan wò lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ túmọ̀ sí gbígbé nínú ilé àwọn arákùnrin. A níláti máa ṣí káàkiri, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ọ̀sẹ̀ méjì-méjì, ni a máa ń ṣí lọ sí ilé mìíràn. Èyí ṣòro gidigidi fún obìnrin. Ṣùgbọ́n láìpẹ́ José àti Roser Escudé, tí wọ́n ń gbé ní Barcelona, késí wa láti wá lo ọjọ́ mélòókan pẹ̀lú wọn lẹ́ẹ̀kan náà. Èyí jẹ́ ohun tí ó fi ìfẹ́ wọn hàn, nítorí ó túmọ̀ sí pé a óò ní ibi kan tí ó wà fún ìgbà pípẹ́ láti tọ́jú àwọn ohun-ìní wa pamọ́ sí àti ibi kan tí a óò lè máa fàbọ̀ sí déédéé ní ìrọ̀lẹ́ Sunday.
Èmi àti Rita lo ọdún mẹ́rin tí ó tẹ̀lé e nínú iṣẹ́ àyíká ní ẹkùn Catalonia, tí ó wà ní Etíkun Mediterranean. Bòókẹ́lẹ́ ni a ń ṣe gbogbo àwọn ìpàdé Bibeli wa ní àwọn ilé àdáni, a sì ń ṣe ìwàásù ilé-dé-ilé wa pẹ̀lú ọgbọ́n-inú kí a má baà pé àfiyèsí. Nígbà mìíràn a máa ń kó odidi ìjọ pọ̀ ní Sunday fún “ìjáde fàájì kólóúnjẹ-gbóúnjẹ” nínú igbó, ní pàtàkì nígbà tí a bá ń ṣe àpéjọ àyíká.
Títí láé ni a óò máa kansáárá sí àwọn arákùnrin nípa tẹ̀mí tí wọ́n jẹ́ olùfọkànsìn tí wọ́n fi iṣẹ́ wọn àti òmìnira wọn wewu, tí wọ́n tiraka láti mú kí ìjọ náà wà ní ìṣọ̀kan kí ó sì jẹ́ aláápọn. Púpọ̀ lára wọn mú ipò iwájú nínú nínasẹ̀ iṣẹ́ náà dé àwọn ìlú tí ó wà lẹ́yìn òde ìlú-ńlá náà. Èyí ni ó di ìpìlẹ̀ fún ìbísí ńláǹlà ní Spania lẹ́yìn tí a mú ìfòfindè náà kúrò tí a sì fàṣẹ sí òmìnira ìsìn ní 1970.
Fífi Tí A Níláti Fi Iṣẹ́ Àyànfúnni Wa ní Ilẹ̀ Àjèjì Sílẹ̀
Fún ọdún mẹ́wàá tí a lò ní Spania, ipò tí àwọn òbí wa wà ti dín gbígbádùn tí à bá gbádùn àwọn ìbùkún àkànṣe ti ṣísiṣẹ́sin Jehofa kù. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, a fẹ́rẹ̀ẹ́ fi iṣẹ́ àyànfúnni wa sílẹ̀ kí a sì lọ sílé láti bójútó màmá àti bàbá mi. Bí ó ti wù kí ó rí, ọpẹ́lọpẹ́ àwọn arákùnrin àti arábìnrin onífẹ̀ẹ́ nínú àwọn ìjọ tí ó wà nítòsí àwọn òbí mi, ó ṣeé ṣe fún wa láti máa bá a nìṣó ní Spania. Bẹ́ẹ̀ni, àǹfààní ṣíṣiṣẹ́sìn fún àwọn ọdún wọnnì nínú iṣẹ́ míṣọ́nnárì lápákan jẹ́ nítorí àwọn mìíràn tí wọ́n bá wa lọ́wọ́ nínú fífi ire Ìjọba Ọlọrun sí ipò àkọ́kọ́.
Lákòótán, ní December 1968, a lọ sí ilé láti bójútó màmá mi. Ní oṣù náà gan-an bàbá mi kú, ó sì ku màmá mi nìkan nìsinsìnyí. Níwọ̀n bí a sì ti ní òmìnira díẹ̀ láti ṣiṣẹ́sìn ní àkókò kíkún síbẹ̀, a gba iṣẹ́ àyànfúnni kan láti ṣiṣẹ́sìn nínú iṣẹ́ àyíká, ṣùgbọ́n lọ́tẹ̀ yìí ní United States. Fún 20 ọdún tí ó tẹ̀lé e, a ṣiṣẹ́sìn ní àwọn àyíká tí ń sọ èdè Spanish. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti pàdánù iṣẹ́ míṣọ́nnárì wa péálì tí ìníyelórí rẹ̀ ga, òmíràn ni a fi lé wa lọ́wọ́.
Wíwàásù Láàárín Oògùn àti Ìwà-Ipá
Nísinsìnyí a ń ṣiṣẹ́sìn ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ arákùnrin àti arábìnrin tí wọ́n ń gbé ní àwọn ìlú-ńlá tí ìwà-ọ̀daràn ti fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ. Èéṣe, ọ̀sẹ̀ àkọ́kọ́ gan-an nínú iṣẹ́ àyíká ní Brooklyn, New York, wọ́n já àpamọ́wọ́ Rita mọ́ ọn lọ́wọ́.
Ní àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ kan èmi àti Rita wà pẹ̀lú àwùjọ kan tí a ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé ní apá mìíràn ní New York City. Bí a ṣe ń rìn gba igun òpópónà kan lọ, a ṣàkíyèsí àwọn ènìyàn kan tí wọ́n tó síwájú ihò kan lára ògiri ilé ahoro kan. Bí a ti rin òpópónà náà sókè díẹ̀, a ṣàkíyèsí ọ̀gbẹ́ni ọ̀dọ́ kan tí ó dúró sí ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà tí ó sì ń wò wá. Òmíràn wà ní igun tí ó jìnnà tí ó ń ṣọ àwọn ọkọ ayọ́kẹ́lẹ́ àwọn ọlọ́pàá. Àárín àwọn tí ń ṣòwò oògùn ni a wà! Ẹ̀rù bà á nígbà tí ó kọ́kọ́ wò wá, ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí ó rí ìwé ìròyìn Ilé-Ìṣọ́nà ọkàn rẹ̀ balẹ̀. Ó ṣetán, mo lè ti jẹ́ ọ̀gá ọlọ́pàá! Ó ké jáde ní èdè Spanish pé, “¡Los Atalayas! ¡Los Atalayas!” (Àwọn Ilé-Ìṣọ́nà! Àwọn Ilé-Ìṣọ́nà!). Wọ́n mọ irú ẹni tí a jẹ́, wọ́n sì fi orúkọ ìwé ìròyìn wa pè wá, kò sì sí láburú kankan. Bí mo ṣe súnmọ́ ọn, mo wí pé, “¿Buenos dias, como está?” (Káàárọ̀ o, ṣé àlàáfíà ni?) Ó fèsì pẹ̀lú sísọ fún mi pé kí n gbàdúrà fún òun!
Ìpinnu Lílekoko
Ní 1990 ó fara hàn gbangba pé mo níláti máa wà pẹ̀lú màmá mi lójoojúmọ́. A ti gbìyànjú púpọ̀ láti máa bá iṣẹ́ arìnrìn-àjò nìṣó, ṣùgbọ́n ọgbọ́n fi hàn pé kò ṣeé ṣe kí a mú ẹrù-iṣẹ́ méjèèjì ṣẹ. Láìṣe àníàní a fẹ́ láti rí i dájú pé a tọ́jú Màmá lọ́nà onífẹ̀ẹ́. Ṣùgbọ́n lẹ́ẹ̀kan síi a níláti fi péálì tí ìníyelórí rẹ̀ ga sílẹ̀, ohun kan tí ó ṣeyebíye gidigidi sí wa. Gbogbo ohun iyebíye tí ara nínú ayé àti gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe fún ẹnì kan kéré púpọ̀ ní ìfiwéra pẹ̀lú àwọn ohun iyebíye ti ṣíṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí míṣọ́nnárì tàbí gẹ́gẹ́ bí alábòójútó arìnrìn-àjò nínú ètò-àjọ Jehofa.
Èmi àti Rita ti lè ní ọgọ́ta ọdún nísinsìnyí. A ní ìtẹ́lọ́rùn gidigidi a sì ń gbádùn ṣíṣiṣẹ́sìn pẹ̀lú ìjọ àdúgbò tí ń sọ èdè Spanish. Bí a ti ń bojú wẹ̀yìn wo àwọn ọdún wa nínú iṣẹ́-ìsìn Jehofa, a dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún fífi péálì tí ìníyelórí rẹ̀’ ga sí ìkáwọ́ wa.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Pẹ̀lú Rita àti Paul òun Evelyn Hundertmark (ní apá ọ̀tún) lẹ́yìn gbàgede tí akọ màlúù ti ń jà ní Madrid
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Ṣíṣiṣẹ́sin ìjọ kan ní ibi “ìjáde fàájì kólóúnjẹ-gbóúnjẹ” nínú igbó