ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 2/1 ojú ìwé 20-25
  • ‘Níwọ̀n Bí A Ti Ní Iṣẹ́-òjíṣẹ́ Yìí, Àwa Kò Juwọ́sílẹ̀’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ‘Níwọ̀n Bí A Ti Ní Iṣẹ́-òjíṣẹ́ Yìí, Àwa Kò Juwọ́sílẹ̀’
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Aya Tí Ó Jẹ́ Ará Spania àti Iṣẹ́-Àyànfúnni ní Spania
  • Ìlékúrò
  • Wíwọ̀jà Pẹ̀lú Ìsoríkọ́
  • A Fún Wa Ní Péálì Tí Ìníyelórí Rẹ̀ Ga
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ohun Ìyanu Lọ́tùn-Ún Lósì Nínú Iṣẹ́ Ìsìn Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Ní Ẹni 80 Ọdún Iṣẹ́ Àyànfúnni Mi Yí Padà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • ‘Alayọ ni Gbogbo Awọn Wọnni Ti Nduro De Jehofa’
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 2/1 ojú ìwé 20-25

‘Níwọ̀n Bí A Ti Ní Iṣẹ́-òjíṣẹ́ Yìí, Àwa Kò Juwọ́sílẹ̀’

GẸ́GẸ́ BÍ RONALD TAYLOR ṢE SỌ Ọ́

Ní ìgbà ẹ̀rùn ọdún 1963, ó ṣẹlẹ̀ pé mo ń jà fitafita láti lè wàláàyè. Bí mo ṣe ń rìn lọ ní etí bèbè òkun, mo tẹsẹ̀ bọ kòtò fótóró kan mo sì re sínú odò jínjìn lójijì. Èmi tí ń kò mọ̀wẹ̀, díẹ̀ ló kù kí n rì ní nǹkan bíi ẹsẹ̀ bàtà mélòókan kan sí etí bèbè òkun náà. Mo ti mòòkùn nígbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ mo sì ti mu omi òkun yo bámúbámú nígbà tí ọ̀rẹ́ mi kan ṣàkíyèsí ipò tí mo wà tí ó sì wọ́ mi lọ sí etí bèbè òkun. Ọpẹ́lọpẹ́ fífi tí ó fi ẹnu fẹ́ atẹ́gùn sí mi nímú, ni mo fi yè é.

KÌ Í ṣe ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí mo mọrírì ìjẹ́pàtàkì ṣíṣàì juwọ́sílẹ̀—àní nígbà tí ó bá dàbí ẹni pé kò sí ìrètí kankan mọ́. Láti kékeré, ni mo ti níláti jà fitafita láti lè wàláàyè nípa tẹ̀mí.

Lákòókò àwọn ọjọ́ ìdágùdẹ̀ ogun àgbáyé kejì ni mo ti kọ́kọ́ bá òtítọ́ Kristian pàdé. Mo wà lára ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọmọdé tí a kó jáde kúrò ní London láti bọ́ lọ́wọ́ ewu bọ́m̀bù jíjù. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ọmọ ọdún 12 péré ni mí, ogun náà kò fi bẹ́ẹ̀ jámọ́ nǹkankan lójú mi; ń ṣe ni ó wulẹ̀ dàbí eré ọmọdé.

Tọkọtaya àgbàlagbà kan ní Weston-super-Mare, ní gúúsù ìwọ̀-oòrùn England, ni ó tọ́jú mi. Kò pẹ́ púpọ̀ tí mo dé sí ilé àwọn tọkọtaya náà, tí àwọn òjíṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà kan fi bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀ wá wò. Ìdílé àwọn Hargreaves ni; àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin—Reg, Mabs, Pamela, àti Valeri—jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. Àwọn òbí mi tí ó fi mi ṣọmọ tẹ́wọ́gba òtítọ́, lẹ́yìn tí mo sì ti kẹ́kọ̀ọ́ ìwé náà Duru Ọlọrun, èmi pẹ̀lú pinnu láti ṣiṣẹ́sin Jehofa. Ní ọ̀sẹ̀ mẹ́fà péré lẹ́yìn náà, a késí mi láti lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù.

Mo ṣì lè rántí ọjọ́ àkọ́kọ́ yẹn nínú iṣẹ́-ìsìn pápá. Láìsí ìmúrasílẹ̀ kankan, a kó àwọn ìwé pẹlẹbẹ díẹ̀ lé mi lọ́wọ́ a sì sọ fún mi pé: “Ìwọ lọ sí apá ìsàlẹ̀ òpópónà yẹn.” Bí nǹkan ṣe rí ní ọjọ́ tí mo kọ́kọ́ wàásù nìyẹn. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, a sábà máa ń lo ẹ̀rọ tí ń lu àwo rẹ́kọ́ọ̀dù tí ó ní ìwàásù lílágbára nínú. Àkókò tí mo máa ń láyọ̀ jùlọ ni ìgbà tí mo bá ń gbé ẹ̀rọ tí ń lu àwo rẹ́kọ́ọ̀dù náà kiri láti ilé dé ilé tí mo sì ń lu àwọn rẹ́kọ́ọ̀dù tí àwíyé ti wà nínú rẹ̀. Mo kà á sí àǹfààní gidi kan pé a lò mí ní ọ̀nà yẹn.

Mo jẹ́rìí lọ́pọ̀lọpọ̀ ní ilé-ẹ̀kọ́, mo sì rántí pé mo fi àwọn ìwé tí ó dá lórí àkòrí Bibeli sóde lọ́dọ̀ ọ̀gá-àgbà ilé-ẹ̀kọ́. Ní ọmọ ọdún 13, mo ṣe ìrìbọmi ní àpéjọ etílé kan ní Bath. Àpéjọpọ̀ mìíràn ni àkókò ogun tí èmi kò jẹ́ gbàgbé láéláé ni èyí tí ó wáyé ní Leicester ní 1914 ní Gbọ̀ngàn De Montfort. Mo gun orí pèpéle lọ láti gba ẹ̀dà ìwé Children tèmi, èyí tí ó ní ìsọfúnni ti ara-ẹni láti ọ̀dọ̀ Arákùnrin Rutherford, ẹni tí ó jẹ́ ààrẹ Watch Tower Society nígbà náà nínú. Ọ̀rọ̀-àsọyé tí ń runisókè tí a sọ fún gbogbo àwọn èwe tí ó wà níbẹ̀ fún ìfẹ́-ọkàn mi láti ṣiṣẹ́sin Jehofa títíláé lókun.

Nípa bẹ́ẹ̀ mo lo ọdún méjì tí ó kún fún ayọ̀ ní dídàgbà nínú òtítọ́ pẹ̀lú àwọn òbí mi tí wọ́n fi mi ṣọmọ. Ṣùgbọ́n ni ẹni ọdún 14, mo níláti padà sí London láti bẹ̀rẹ̀ sí ṣíṣẹ́ láti gbọ́ bùkátà ìgbésí-ayé mi. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo tún wà papọ̀ pẹ̀lú ìdílé mi, mo níláti dá dúró fúnra mi nípa tẹ̀mí, níwọ̀n bí kò ti sí ẹnikẹ́ni nílé tí ó ní èrò-ìgbàgbọ́ kan náà pẹ̀lú mi. Láìpẹ́ láìjìnnà, Jehofa pèsè ìrànlọ́wọ́ tí mo nílò. Ní ọ̀sẹ̀ mẹ́ta péré lẹ́yìn tí mo ti dé sí London, arákùnrin kan wá sí ilé wa láti gba ìyọ̀ǹda lọ́wọ́ bàbá mi láti mú mi lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba tí ń bẹ ládùúgbò. John Barr ni arákùnrin náà, ẹni tí ó jẹ́ ọ̀kan lára mẹ́ḿbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nísinsìnyí. Ó di ọ̀kan lára “àwọn bàbá” mi nípa tẹ̀mí lákòókò àwọn ọdún ìgbà ìbàlágà tí ó lekoko wọ̀nyẹn.—Matteu 19:29.

Mo bẹ̀rẹ̀ sí darapọ̀ mọ́ Ìjọ Paddington, tí ń pàdé ní Craven Terrace lẹ́bàá Ilé Beteli ti London. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ọmọ òrukàn nípa tẹ̀mí ni mí, a yan arákùnrin àgbàlagbà kan tí ó jẹ́ ẹni-àmì-òróró, “Bàbá” Humphreys, láti ní àkànṣe ọkàn-ìfẹ́ nínú mi. Dájúdájú ìbùkún ńlá gbáà ni ó jẹ́ láti lè darapọ̀ mọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí wọ́n jẹ́ ẹni-àmì-òróró tí wọ́n ń ṣiṣẹ́sìn nínú ìjọ yẹn. Àwa—tí a ń pè ní àwọn Jonadabu—tí a ní ìrètí tí orí ilẹ̀-ayé ni a kéré jù. Ní tòótọ́, èmi nìkan ni “Jonadabu” tí ń bẹ nínú Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ tí mo ń darapọ̀ mọ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kò fi bẹ́ẹ̀ ní ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ojúgbà mi, àjọṣepọ̀ ṣíṣeyebíye yẹn pẹ̀lú àwọn arákùnrin tí wọ́n dàgbàdénú kọ́ mi ní ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n tí ó wúlò. Bóyá èyí tí ó ṣe pàtàkì jùlọ ni ti ṣíṣàì pa iṣẹ́-ìsìn Jehofa tì láé.

Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, a máa ń ya odindi òpin ọ̀sẹ̀ sọ́tọ̀ fún ìgbòkègbodò ìwàásù. A yàn mi láti máa bójútó “ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tí ń gbóhùn sáfẹ́fẹ́,” èyí tí ó jẹ́ kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́ta níti gidi láti gbé àwọn ohun èlò tí ń gbé ohùn sáfẹ́fẹ́ àti bátìrì ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́. Ní gbogbo ọjọ́ Saturday, èmi yóò talé kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́ta náà èmi yóò sì lọ sí ìkangun òpópónà tí ó yàtọ̀ síra, níbi tí a óò ti lu àwo orin díẹ̀ tí a óò sì gbé ọ̀kan lára àwọn ọ̀rọ̀-àsọyé Arákùnrin Rutherford sí i. A tún máa ń lo Saturday fún iṣẹ́ òpópónà pẹ̀lú àwọn àpò ìwé ìròyìn wa lọ́wọ́. Àwọn ọjọ́ Sunday ni a yà sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ ilé-dé-ilé, láti fi àwọn ìwé pẹlẹbẹ àti ìwé ńlá lọni.

Ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ mi pẹ̀lú àwọn arákùnrin àgbàlagbà tí wọ́n jẹ́ onítara tanná ran ìfẹ́-ọkàn mi láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà. Ìfẹ́-ọkàn yìí ni a mú lókun nígbà tí mo tẹ́tí sí àwọn ọ̀rọ̀-àsọyé lórí ṣíṣe aṣáájú-ọ̀nà ní àwọn àpéjọpọ̀ àgbègbè. Àpéjọpọ̀ kan tí ó ní ipa tí ó jinlẹ̀ lórí ìgbésí-ayé mi ni èyí tí a ṣe ní Earl’s Court, London, ní 1947. Ní oṣù méjì lẹ́yìn náà, mo forúkọ sílẹ̀ fún iṣẹ́-ìsìn aṣáájú-ọ̀nà, mo sì ti làkàkà láti pa ẹ̀mí aṣáájú-ọ̀nà mọ́ láti ìgbà yẹn. Ìdùnnú-ayọ̀ tí mo rí nínú dídarí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli tí ń tẹ̀síwájú ṣiṣẹ́ láti fún mi ní ìdánilójú pé èyí ni ìpinnu tí ó tọ́.

Aya Tí Ó Jẹ́ Ará Spania àti Iṣẹ́-Àyànfúnni ní Spania

Ní ọdún 1957, nígbà tí mo ṣì ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà nínú Ìjọ Paddington, mo pàdé arábìnrin òrékelẹ́wà ará Spania tí ń jẹ́ Rafaela. Lẹ́yìn oṣù díẹ̀, a ṣe ìgbéyàwó. Góńgó wa ni láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà papọ̀, ṣùgbọ́n lákọ̀ọ́kọ́ a lọ sí Madrid kí n baà lè lọ pàdé àwọn òbí Rafaela. Ó jẹ́ ìbẹ̀wò kan tí ó yí ìgbésí-ayé mi padà. Nígbà tí a wà ní Madrid, Arákùnrin Ray Dusinberre, alábòójútó ẹ̀ka Spania, béèrè lọ́wọ́ mi bí mo bá lè gbé ṣíṣiṣẹ́sìn ní Spania yẹ̀wò, níbi tí àìní púpọ̀ ti wà fún àwọn arákùnrin tí wọ́n jẹ́ onírìírí.

Báwo ni a ṣe lè kọ irú ìkésíni bẹ́ẹ̀? Fún ìdí yìí, ní 1958 a bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́-ìsìn alákòókò kíkún wà papọ̀ ní Spania. Nígbà yẹn orílẹ̀-èdè náà wà lábẹ́ àkóso Franco, a kò sì fọwọ́sí ìgbòkègbodò wa lábẹ́ òfin, èyí tí ó mú kí iṣẹ́ ìwàásù nira gidigidi. Síwájú síi, fún àwọn ọdún mélòókan tí ó ṣáájú mo níláti jìjàkadì pẹ̀lú kíkọ́ èdè Spanish. Lẹ́ẹ̀kan síi, ó jẹ́ ọ̀ràn ṣíṣàì juwọ́sílẹ̀, àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ju ẹ̀ẹ̀kan lọ ti mo sọkún nítorí ìjákulẹ̀ púpọ̀ tí mo ní nítorí àìlèbá àwọn arákùnrin tí ń bẹ nínú ìjọ sọ̀rọ̀pọ̀.

Àìní fún àwọn alábòójútó pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ débi pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé agbára káká ni mo fi lè sọ èdè Spanish, láàárín oṣù kan mo ti ń bójútó àwùjọ kékeré kan. Nítorí ṣíṣe iṣẹ́ tí a ń ṣe ní bòókẹ́lẹ́, a ṣètò wa sí àwọn àwùjọ kéékèèké tí ó ní àwọn akéde 15 sí 20, tí ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìjọ kéékèèké. Lákọ̀ọ́kọ́, ó nira láti máa darí àwọn ìpàdé, níwọ̀n bí èmi kò ti lè lóye ìdáhùn tí àwọn àwùjọ ń mú wá. Bí ó ti wù kí ó rí, aya mi jókòó sẹ́yìn, bí ó bá sì fura pé ó rú mi lójú, òun yóò fi ọgbọ́n mirí láti jẹ́rìí sí ìdáhùn náà pé ó tọ̀nà.

Èmi kò ni ẹ̀bùn ti kíkọ́ èdè, ó sì ju ìgbà kàn lọ tí mo nímọ̀lára bí ẹni pé kí n padà sí England, níbi tí mo ti lè máa ṣe ohun gbogbo lọ́nà tí ó rọrùn gan-an. Síbẹ̀síbẹ̀, láti ìbẹ̀rẹ̀, ìfẹ́ àti ìbánidọ́rẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àti arábìnrin ará Spania wa ọ̀wọ́n jẹ́ àsanpadà fún ìjákulẹ̀ tí àìgbédè ń mú wá. Jehofa sì bùkún mi pẹ̀lú àwọn àkànṣe àǹfààní tí ó mú kí gbogbo rẹ̀ dàbí ohun tí ìsapá náà yẹ fún. Ní 1958, a késí mi láti wá sí àpéjọpọ̀ àgbáyé ní New York gẹ́gẹ́ bí àyànṣaṣojú láti Spania. Nígbà tí ó sì di 1962, mo gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí kò ṣeé díyelé ní Ilé-Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́-Òjíṣẹ́ Ìjọba tí a ṣètò fún wa ní Tangier, Morocco.

Ìṣòro mìíràn tí mo dojúkọ, yàtọ̀ sí ti èdè, ni àníyàn léraléra pé kí àwọn ọlọ́pàá má he mí. Gẹ́gẹ́ bí àjòjì, mo mọ̀ pé bí ọwọ́ bá lè tẹ̀ mí yóò túmọ̀ sí lílé mi kúrò ní orílẹ̀-èdè náà ní ojú-ẹsẹ̀. Láti lè dín ewu náà kù, a ń ṣiṣẹ́ ní méjì-méjì. Nígbà tí ẹnì kan bá ń jẹ́rìí, ẹnì kejì yóò máa tẹ́tíléko bí àmì ewu èyíkéyìí bá wà. Lẹ́yìn ṣíṣèbẹ̀wò sí ilé kan tàbí méjì, lọ́pọ̀ ìgbà ní òkè ilé gbígbé, a óò lọ sì àdúgbò kejì tàbí ìkẹta sí i a óò sì kàn sí ilé méjì tàbí mẹ́ta mìíràn. A ń lo Bibeli lọ́nà gbígbòòrò, a sì ń kó kìkì àwọn ìwé pẹlẹbẹ díẹ̀ sínú kóòtù àwọ̀lékè wa láti fún àwọn olùfìfẹ́hàn.

Lẹ́yìn ọdún kan ní Madrid, a yàn wá sí Vigo, ìlú-ńlá kan ní ìhà àríwá ìwọ̀-oòrùn Spania, níbi ti kò ti sí Ẹlẹ́rìí kankan rárá. Fún nǹkan bí oṣù àkọ́kọ́, Society dábàá pé kí aya mi máa ṣe èyí tí ó pọ̀ jù nínú ìjẹ́rìí náà—láti gbin èrò náà síni lọ́kàn pé a ń ṣe ìbẹ̀wò gẹ́gẹ́ bí arìnrìn-àjò. Láìka ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀pọ̀ tí kò jọjú náà sí, ìwàásù wa tún pe àfiyèsí. Láàárín oṣù kan àwọn àlùfáà Katoliki bẹ̀rẹ̀ sí bú wa lórí rédíò. Wọ́n kìlọ̀ fún àwọn ọmọ ìjọ tí ń bẹ lágbègbè wọn pé àwọn tọkọtaya kan ti ń lọ láti ojúlé dé ojúlé láti sọ̀rọ̀ nípa Bibeli—ìwé tí òfin kò fẹ́rẹ̀ẹ́ fàyègbà nígbà yẹn. “Àwọn tọkọtaya tí àwọn ọlọ́pàá ń wá” náà ni àjòjì kan àti aya rẹ̀ tí ó jẹ́ ará Spania, tí ó ń sọ èyí tí ó pọ̀ jù nínú gbogbo ọ̀rọ̀ náà!

Àwọn àlùfáà náà ṣòfin pé wíwulẹ̀ bá àwọn tọkọtaya tí wọ́n léwu yìí sọ̀rọ̀ jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí a lè dárí rẹ̀ jini kìkì bí a bá tètè jẹ́wọ́ rẹ̀ fún àlùfáà. Bí ẹnì kan sì ṣe lè retí, lẹ́yìn ìjíròrò gbígbádùnmọ́ni tí a ní pẹ̀lú obìnrin kan, ó sọ fún wa pẹ̀lú ẹ̀bẹ̀ pé òun níláti lọ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ òun. Nígbà tí a fi ilé rẹ̀ sílẹ̀, a rí i tí ó ń kánjú gba ọ̀nà ṣọ́ọ̀ṣì lọ.

Ìlékúrò

Ní kìkì oṣù méjì lẹ́yìn tí a dé sí Vigo, àwọn ọlọ́pàá yọ sí wa lójijì. Ọlọ́pàá tí ó mú wa jẹ́ oníyọ̀ọ́nú kò sì kó ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ sí wa lọ́wọ́ títí tí a fi dé àgọ́ ọlọ́pàá. Ní àgọ́ náà, a rí ẹni-a-mọ̀-rí kan, òǹtẹ̀wé kan tí a jẹ́rìí fún láìpẹ́ púpọ̀. Ó hàn gbangba pé ara rẹ̀ kó tìọ̀ láti rí i bí wọ́n ṣe ń bá wa lò bí àwọn ọ̀daràn ó sì yára mú un dá wa lójú pé òun kọ́ ni òun fi ẹjọ́ wa sùn. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, a fẹ̀sùn kàn wá pé a ń fi “ìṣọ̀kan tẹ̀mí Spania” sínú ewu, wọ́n sì lé wa kúrò nílùú ní ọ̀sẹ̀ mẹ́fà lẹ́yìn náà.

Ìdálọ́wọ́kọ́ ni ó jẹ́, ṣùgbọ́n a kò ní èrò jíjuwọ́sílẹ̀. Iṣẹ́ púpọ̀ ṣì wà láti ṣe ní Iberia Ilẹ̀ Tí Omi Fẹ́rẹ̀ẹ́ Yíká. Lẹ́yìn oṣù mẹ́ta ní Tangier, a yàn wá sí Gibraltar—agbègbè ìpínlẹ̀ mìíràn kan tí a kò tí ì ṣe rí. Gẹ́gẹ́ bí aposteli Paulu ṣe sọ, bí iṣẹ́-òjíṣẹ́ wa bá ṣeyebíye fún wa, a óò máa bá a nìṣó a óò sì san èrè-ẹ̀san fún wa. (2 Korinti 4:1, 7, 8) Èyí jẹ́ òtítọ́ nínú ọ̀ràn tiwa. Ní ilé àkọ́kọ́ tí a bẹ̀wò ní Gibraltar, a bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú odindi àpapọ̀ ìdílé kan. Láìpẹ́ láìjìnnà, ọ̀kọ̀ọ̀kan wa ti ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ 17. Púpọ̀ lára àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan tí a bá ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ di Ẹlẹ́rìí, ìjọ kan tí ó ní akéde 25 nínú sì ti wà láàárín ọdún méjì.

Ṣùgbọ́n, bíi ti Vigo, àwọn àlùfáà bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ lòdìsí wa. Bíṣọ́ọ̀bù ìjọ Anglikan ti Gibraltar kìlọ̀ fún ọ̀gá àwọn ọlọ́pàá pátápátá pé “ènìyànkénìyàn” ni wá, ọ̀tẹ̀ rẹ̀ sì mú àwọn ìyọrísí wá nígbẹ̀yìn gbẹ́yín. Ní January 1962 a lé wa jáde kúrò ní Gibraltar. Níbo ni a óò tún gbà lọ? Àìní ṣì pọ̀ síbẹ̀síbẹ̀ ní Spania, a sì padà síbẹ̀ ní ìrètí pé kò ní sí àkọsílẹ̀ tí a ní pẹ̀lú àwọn ọlọ́pàá ní àrọ́wọ́tó mọ́.

Ìlú-ńlá Seville tí oòrùn ti ń mú hanhanhan ni ilé wa titun wà. Níbẹ̀ ni a ti ní ìdùnnú-ayọ̀ ti ṣíṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú tọkọtaya aṣáájú-ọ̀nà mìíràn, Ray àti Pat Kirkup. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Seville jẹ́ ìlú-ńlá kan tí ó ní olùgbé tí ó jẹ́ ìdajì million, akéde 21 péré ni ó wà níbẹ̀, nítorí náà a ní iṣẹ́ púpọ̀ láti ṣe. Nísinsìnyí ìjọ 15 ni ó wà níbẹ̀ tí wọ́n sì ní 1,500 akéde. Ní ọdún kan lẹ́yìn náà ohun ìyanu tí ó gbádùn mọ́ wa wáyé; a késí wá láti ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí arìnrìn-àjò ní agbègbè Barcelona.

Iṣẹ́ àyíká ní orílẹ̀-èdè kan níbi tí a kò ti fọwọ́ sí iṣẹ́ wa lábẹ́ òfin jẹ́ ohun tí ó yàtọ̀ pátápátá. A ń bẹ àwùjọ kéékèèké wo lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, àwọn tí ó pọ̀ jù nínú wọn ní àwọn arákùnrin díẹ̀ tí wọ́n tóótun. Àwọn arákùnrin òṣìṣẹ́ kára wọ̀nyí nílò gbogbo ìdálẹ́kọ̀ọ́ àti ìtìlẹ́yìn tí a lè fún wọn. A mà nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́-àyànfúnni yìí o! Lẹ́yìn tí a ti lo ọdún mélòókan ní àwọn agbègbè tí ó jẹ́ pè àwọn Ẹlẹ́rìí díẹ̀ ni ó wà níbẹ̀ bí wọ́n bá tilẹ̀ wà rárá, a láyọ̀ láti máa bẹ ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àti arábìnrin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wò. Síwájú síi, iṣẹ́ ìwàásù ní Barcelona tún rọrùn díẹ̀, ọ̀pọ̀ ènìyàn sí fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli.

Wíwọ̀jà Pẹ̀lú Ìsoríkọ́

Bí ó ti wù kí ó rí, ní oṣù mẹ́fà péré lẹ́yìn náà, ìgbésí-ayé mi yípadà lójijì. Họlidé wa àkọ́kọ́ ní etíkun fẹ́rẹ̀ẹ́ di ọ̀ràn ìbànújẹ́ nígbà tí mo ní ìrírí jàm̀bá tí mo ṣàlàyé ṣáájú. Nípa ti ara mo tètè kọ́fẹ padà láti inú ìjayà fífẹ́rẹ̀ẹ́ bá odò lọ, síbẹ̀ ìjàm̀bá náà kóbá ètò iṣan ìmọ̀lára mi.

Fún ìwọ̀nba oṣù díẹ̀, mo tiraka láti máa bá a nìṣó nínú iṣẹ́ àyíká, ṣùgbọ́n mo níláti padà sí England níkẹyìn láti gba ìtọ́jú ìṣègùn. Lẹ́yìn ọdún méjì mo kọ́fẹpadà dáradára tí ó fi ṣeé ṣe fún wa láti padà sí Spania, níbi tí a ti padà sẹ́nu iṣẹ́ àyíká lẹ́ẹ̀kan síi. Ṣùgbọ́n, ó wulẹ̀ jẹ́ fún ìgbà kúkúrú. Àwọn òbí aya mi ṣàìsàn gidigidi, a sì fi iṣẹ́-ìsìn alákòókò kíkún sílẹ̀ láti lè bójútó wọn.

Ìgbésí-ayé túbọ̀ nira síi nígbà tí ètò iṣan ìmọ̀lára mi kọṣẹ́ pátápátá ní 1968. Àwọn àkókò kan wà tí èmi àti Rafaela ti lérò pé n kò ní lè kọ́fẹpadà. Ńṣe ni ó dàbí ẹni pé mo tún ń rì lẹ́ẹ̀kan síi, ṣùgbọ́n ní ọ̀nà kan tí ó yàtọ̀! Yàtọ̀ sí mímú kí ń nímọ̀lára ìjákulẹ̀ nípasẹ̀ àwọn ìmọ̀lára òdì, ìsoríkọ́ náà gba gbogbo okun mi. Mo jìyà àárẹ̀ lílekoko, èyí tí ó fipá mú mi láti máa sinmi ní gbogbo ìgbà. Kì í ṣe gbogbo àwọn ará ni wọ́n lóye irú ìṣòro yìí nígbà yẹn; ṣùgbọ́n mo mọ̀ dájú pé Jehofa lóye rẹ̀. Ó ti jẹ́ ohun tí ń mù ìtẹ́lọ́rùn ńláǹlà wá fún mi láti ka àwọn àgbàyanu àkójọpọ̀-ọ̀rọ̀ inú ìwé ìròyìn Ilé-Ìsọ́nà àti Jí! tí wọ́n ti pèsè òye àti ìrànlọ́wọ́ fún àwọn wọnnì tí wọ́n ti jìyà ìsoríkọ́.

Jálẹ̀ gbogbo àkókò tí ó nira yìí, aya mi jẹ́ orísun ìṣírí fún mi nígbà gbogbo. Kíkojú àwọn ìṣòro ìdílé papọ̀ ń fún ìdè ìdílé lókun. Àwọn òbí Rafaela kú, lẹ́yìn ọdún 12, ìlera mi sunwọ̀n síi títí dé àyè tí a fi ronú pé a tún lè padà sẹ́nu iṣẹ́-ìsìn alákòókò kíkún. Ní 1981, sí ìyàlẹ́nu àti ayọ̀ wa, a tún késí wá láti sìn nínú iṣẹ́ àyíká lẹ́ẹ̀kan síi.

Àwọn ìyípadà ńláǹlà ti wáyé ní Spania láti ìgbà tí a tí kọ́kọ́ ní ìrírí iṣẹ́-òjíṣẹ́ arìnrìn-àjò wa àkọ́kọ́ níbẹ̀. Òmìnira ti débá ìwàásù nìsinsìnyí, nítorí náà mo níláti mú ara mi bá ìgbà mu. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ṣíṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká lẹ́ẹ̀kan síi jẹ́ àǹfààní ńláǹlà. Nítorí pé a tí ṣe aṣáájú-ọ̀nà láìka ìṣòro àyíká ipò sí ti ràn wá lọ́wọ́ láti fún àwọn aṣáájú-ọ̀nà tí wọ́n ní ìṣòro ní ìṣírí. Ó sì ṣeé ṣe fún wa láti ran àwọn mìíràn lọ́wọ́ láti ìgbà-dé-gbà láti darapọ̀ mọ́ òtú àwọn aṣáájú-ọ̀nà.

Lẹ́yìn ọdún 11 lẹ́nu iṣẹ́ arìnrìn-àjò ní Madrid àti Barcelona, lẹ́ẹ̀kan síi àìlera wa tí ń jagọ̀ mú kí ó pọndandan láti yí iṣẹ́-àyànfúnni wa padà. A yàn wá sí ìlú-ńlá Salamanca gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, níbi tí mo ti lè wúlò gẹ́gẹ́ bí alàgbà. Lójú-ẹsẹ̀ ni àwọn arákùnrin wa ní Salamanca gbà wá tọwọ́ tẹsẹ̀. Ní ọdún kan lẹ́yìn náà ìṣòro mìíràn kan yóò dán ìfaradà wa wò.

Sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀ pupa ni ara Rafaela ṣàdédé lọsílẹ̀, àyẹ̀wò sì fihàn pé ó ní àrùn jẹjẹrẹ lára agbẹ̀du. Nísinsìnyí èmi ni ó yẹ kí n jẹ́ alágbára kí n sì fún aya mi ní gbogbo ìtìlẹ́yìn tí mo bá lè fún un. Ìhùwàpadà wa àkọ́kọ́ ni àìkò lè gba ohun tí ń ṣẹlẹ̀ gbọ́, ìbẹ̀rù ni ó tẹ̀lé e. Rafaela yóò ha ru èyí là bí? Ní àwọn àkókò bí èyí, ìgbẹ́kẹ̀lé pátápátá nínú Jehofa ni ó ràn wá lọ́wọ́ láti máa bá a nìṣó. Mo láyọ̀ láti sọ pé iṣẹ́-abẹ náà yọrísírere fún Rafaela, a sì ní ìrètí pé àrùn jẹjẹrẹ náà kì yóò yọjú mọ́.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ní àwọn ìṣòro láàárín ọdún 36 tí a ti lò ní Spania, ó ti jẹ́ ohun tí ń mú wa lọ́kàn yọ̀ láti wàláàyè la àkókò ìdàgbàsókè tẹ̀mí yìí já. A ti rí ẹgbẹ́ kéréje ti àwọn 800 akéde ní 1958 tí ó ti dàgbà dé ẹgbẹ́ ọmọ-ogun tí ó lé ní 100,000 akéde lónìí. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ayọ̀ ti ṣíji bo àwọn ìṣòro wa mọ́lẹ̀—ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti tẹ́wọ́gba òtítọ́ kí wọ́n sì dàgbàdénú nípa tẹ̀mí, ṣíṣiṣẹ́ papọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọkọ àti aya, àti níní ìmọ̀lára pé a ti lo ìgbésí-ayé wa lọ́nà tí ó dára jùlọ.

Paulu sọ nínú lẹ́tà rẹ̀ kejì sí àwọn ará Korinti pé: ‘Níwọ̀n bí a ti ní iṣẹ́-òjíṣẹ́ yii ní ìbámu pẹlu àánú tí a fi hàn sí wa, àwa kò juwọ́sílẹ̀.’ (2 Korinti 4:1, NW) Ní wíwẹ̀yìn padà, mo gbàgbọ́ pé àwọn kókó abájọ mélòókan ń bẹ nínú ìgbésí-ayé mi tí kò yọ̀ǹda fún mi láti juwọ́sílẹ̀. Àpẹẹrẹ àwọn arákùnrin olùṣòtítọ́ ẹni-àmì-òróró tí wọ́n ní ọkàn-ìfẹ́ nínú mi nígbà tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dàgbà fún mi ní ìpìlẹ̀ rere. Níní alábàáṣègbéyàwó tí ó ní góńgó kan náà pẹ̀lú mi jẹ́ ìrànlọ́wọ́ àgbàyanu; nígbà tí mo bá ní ìsoríkọ́, Rafaela yóò fún mi ní ìṣírí, èmi pẹ̀lú sì ti ṣe bẹ́ẹ̀ fún un. Jíjẹ́ ẹni tí ó lé dẹ́rìn-ín pani pẹ̀lú jẹ́ dúkìá ńláǹlà. Láti lè rẹ́rìn-ín pẹ̀lú àwọn ará—kí a sì fi ara wa rẹ́rìn-ín—kì í jẹ́ kí àwọn ìṣòro tètè bò wá mọ́lẹ̀.

Ṣùgbọ́n ju gbogbo rẹ̀ lọ, ìfaradà lójú àwọn àdánwò ń béèrè fún okun Jehofa. Mo máa ń rántí àwọn ọ̀rọ̀ Paulu nígbà gbogbo pé: “Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye ẹni naa tí ń fi agbára fún mi.” Pẹ̀lú ìtìlẹ́yìn Jehofa, kò sí ìdí kankan fún wa láti juwọ́sílẹ̀ láé.—Filippi 4:13, NW.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Ronald àti Rafaela Taylor ní 1958

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24, 25]

Ṣíṣe ìpàdé lábẹ́ ìfòfindè ní Spania (1969)

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́