Ní Ẹni 80 Ọdún Iṣẹ́ Àyànfúnni Mi Yí Padà
GẸ́GẸ́ BÍ GWENDOLINE MATTHEWS ṢE SỌ Ọ́
Ní ẹni 80 ọdún, èmi àti ọkọ mi pinnu láti palẹ̀ gbogbo ẹrù wa mọ́ sínú ọkọ̀ kan tí a háyà, a sì gbéra láti England lọ sí Sípéènì. A kò gbọ́ èdè Spanish, a sì ń lọ sí gúúsù ìwọ̀ oòrùn Sípéènì, ibi tí àwọn arìnrìn àjò afẹ́ tí ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì kì í sábà ṣèbẹ̀wò sí. Ọ̀pọ̀ jù lọ nínú àwọn ọ̀rẹ́ wa rò pé orí wa ti dàrú, ṣùgbọ́n mo fi ìdùnnú rán ara mi létí pé ẹni ọdún 75 ni Ábúráhámù nígbà tí ó fi Úrì sílẹ̀.
ÀBÁJÁDE rẹ̀ ni pé, àwọn ọdún tí a ti lò ní Sípéènì láti ìgbà tí a ti dé síhìn-ín láti April 1992 ti jẹ́ èyí tí ó ní èrè jù lọ nínú ìgbésí ayé wa. Ṣùgbọ́n kí n tó ṣàlàyé ohun tó fa sábàbí ṣíṣí tí a ṣí wá síhìn-ín, ẹ jẹ́ kí n sọ fún yín nípa bí ìgbésí ayé wa nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ṣe mú kí a ṣe ìpinnu ńlá yìí.
Òtítọ́ Bíbélì Yí Ìgbésí Ayé Wa Padà
Ilé tí wọ́n ti fọwọ́ dan-in dan-in mú ìsìn ní gúúsù ìwọ̀ oòrùn London, England, ni a ti tọ́ mi dàgbà. Màmá sábà máa ń mú èmi àti ẹ̀gbọ́n mi obìnrin lọ sí onírúurú ibi ìjọsìn bí ó ti ń wá ìtẹ́lọ́rùn nípa tẹ̀mí kiri. Bàbá mi, tí ikọ́ ẹ̀gbẹ ń yọ lẹ́nu gidigidi, kì í tẹ̀ lé wa. Ṣùgbọ́n ó fẹ́ràn kíka Bíbélì gan-an, ó sì máa ń fàlà sí i nígbàkigbà tí ó bá rí ẹsẹ kan tí ó là á lóye. Ọ̀kan lára àwọn ohun ìní mi tí mo ṣìkẹ́ jù lọ ni Bíbélì ògbólógbòó nì, tí kì í fi í báni ṣeré rárá.
Ní ọdún 1925, nígbà tí mo jẹ́ ọmọ ọdún 14, a bá ìwé àṣàrò kúkúrú kan lábẹ́ ilẹ̀kùn wa, tí ó ké sí wa sí àwíyé fún gbogbo ènìyàn ní gbọ̀ngàn ìlú West Ham. Aládùúgbò wa kan àti màmá mi pinnu láti lọ síbi àwíyé náà, àbúrò mi obìnrin sì tẹ̀ lé wọn. Àwíyé náà, “Àràádọ́ta Ọ̀kẹ́ Tí Ó Wà Láàyè Nísinsìnyí Kì Yóò Kú Láé,” fún irúgbìn òtítọ́ sínú ọkàn-àyà Màmá.
Ní oṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà, Bàbá dolóògbé ní ẹni ọdún 38. Ikú rẹ̀ gbò wá jìgìjìgì, níwọ̀n bí ó ti bà wá lọ́kàn jẹ́, tí ó sì sọ wá di aláìní. Níbi ètò ìsìnkú, tí a ṣe ní Ṣọ́ọ̀ṣì England tí ó wà ládùúgbò wa, ẹ̀rù ba Màmá láti gbọ́ tí àlùfáà náà ń sọ pé ọkàn Bàbá ti lọ sí ọ̀run. Ó mọ̀ láti inú Bíbélì pé àwọn òkú ń sùn nínú ibojì, ó sì gbà gbọ́ dájú pé lọ́jọ́ kan, a óò jí Bàbá dìde sí ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé. (Sáàmù 37:9-11, 29; 146:3, 4; Oníwàásù 9:5; Ìṣe 24:15; Ìṣípayá 21:3, 4) Lẹ́yìn tí ó ti gbà dájú pé òun ní láti dara pọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn tí ń kọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó pinnu láti di ojúlùmọ̀ Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Kárí-Ayé, gẹ́gẹ́ bí a ti ń pe Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà náà.
Níwọ̀n bí a kò ti lówó ọkọ̀ lọ́wọ́, lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ a máa ń fẹsẹ̀ rìn fún wákàtí méjì láti ilé wa sí ìpàdé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lẹ́yìn náà, a óò tún lo wákàtí méjì mìíràn láti fẹsẹ̀ rìn padà sílé. Ṣùgbọ́n a mọ ìníyelórí àwọn ìpàdé wọ̀nyí gidigidi, a kò sì pa ọ̀kan jẹ rí, àní nígbà tí kùrukùru tí ó sábà máa ń bo London bo ìlú náà. Kò pẹ́ púpọ̀ tí Màmá pinnu láti ya ìgbésí ayé ara rẹ̀ sí mímọ́ sí Jèhófà, tí ó sì ṣèrìbọmi, ní ọdún 1927, èmi náà ṣèrìbọmi.
Láìka ipò ọrọ̀ ajé wa tí kò fara rọ sí, ìgbà gbogbo ni Màmá ń kọ́ mi ní ìjẹ́pàtàkì fífi ohun tẹ̀mí sí ipò àkọ́kọ́. Mátíù 6:33 jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí ó yàn láàyò, ó sì ‘wá ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́’ ní tòótọ́. Nígbà tí àrùn jẹjẹrẹ pa á láìpọ́jọ́ ní ọdún 1935, ó ń wéwèé láti dáhùn sí ìkésíni náà fún àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún tí yóò ṣí lọ láti lọ sìn ní ilẹ̀ Faransé.
Àwọn Àpẹẹrẹ Tí Ó fún Wa Lókun
Ní àwọn ọdún ìbẹ̀rẹ̀ wọ̀nyẹn, àwọn kan lára àwọn tí ń wá sí àwọn ìpàdé ní London fẹ́ láti gbé èrò tiwọn lárugẹ, àwọn wọ̀nyí sì dá aáwọ̀ àti wàhálà ńlá sílẹ̀. Síbẹ̀, Màmá máa ń wí pé yóò jẹ́ ìwà àìdúróṣinṣin láti fi ètò àjọ Jèhófà sílẹ̀ lẹ́yìn gbogbo ohun tí a ti kọ́ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ìbẹ̀wò tí Joseph F. Rutherford, ààrẹ Watch Tower Bible and Tract Society nígbà náà ṣe, sún wa láti máa bá a nìṣó ní fífi ìdúróṣinṣin sìn.
Mo rántí pé Arákùnrin Rutherford jẹ́ onínú rere, tí ó ṣeé sún mọ́. Nígbà tí mo ṣì jẹ́ ọ̀dọ́langba, Ìjọ London ṣètò ìjáde ìgbafẹ́ kan tí òun náà wà níbẹ̀. Ó rí èmi—ọ̀dọ́langba kan tí ń tijú—pẹ̀lú kámẹ́rà lọ́wọ́, ó sì béèrè bí n óò bá fẹ́ láti ya òun ní fọ́tò. Fọ́tọ̀ yẹn di ohun ìrántí tí mo ṣìkẹ́ gidigidi.
Lẹ́yìn náà, ìrírí kan tẹ ìyàtọ̀ tí ó wà láàárín àwọn tí ń mú ipò iwájú nínú ìjọ Kristẹni àti àwọn ènìyàn olókìkí nínú ayé mọ́ mi lọ́kàn. Mo ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí agbáwo nínú ilé ńlá kan ní London, níbi tí a pe Franz von Papen, ọ̀kan lára àwọn aṣojú Hitler sí, láti wá jẹun. Bí ó ti ń jẹun lọ́wọ́, ó kọ̀ láti yọ idà tí ó tẹ̀ bọ aṣọ ogun rẹ̀ kúrò, ó kọ́ mi lẹ́sẹ̀, ọbẹ tí mo gbé dání sì dànù. Ó sì fi ìbínú sọ pé tí ó bá jẹ́ Germany ni mo ti dán irú rẹ̀ wò, ìwà àìbìkítà bẹ́ẹ̀ yóò mú kí a yìnbọn pa mí. Fún àkókò tí ó kù tí wọ́n fi jẹ oúnjẹ náà, mo yáa ta kété sí i!
A ṣe àpéjọpọ̀ mánigbàgbé kan ní Alexandra Palace ní ọdún 1931, níbi tí mo ti gbọ́ ọ̀rọ̀ Arákùnrin Rutherford. Níbẹ̀ a fi ìtara gba orúkọ tuntun náà, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. (Aísáyà 43:10, 12) Ọdún méjì lẹ́yìn náà, ní ọdún 1933, mo wọnú iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà, gẹ́gẹ́ bí a ti ń pe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Ìbùkún mìíràn tí mo tún rántí pé mo rí gbà ní àwọn ọdún wọ̀nyẹn ni níní àǹfààní láti lè kẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àtàtà tí wọ́n di míṣọ́nnárì lẹ́yìn ìgbà náà ní àwọn apá ìpẹ̀kun ayé. Claude Goodman, Harold King, John Cooke, àti Edwin Skinner wà lára àwọn wọ̀nyí. Irú àpẹẹrẹ ìṣòtítọ́ bẹ́ẹ̀ mú kí n fẹ́ sìn ní ilẹ̀ òkèèrè.
Ṣíṣe Aṣáájú Ọ̀nà Ní Ìlà Oòrùn Angilia
Ìlà Oòrùn Angilia (ìlà oòrùn England) ni ibi iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà tí a yàn fún mi, wíwàásù níbẹ̀ sì béèrè ọ̀yàyà àti ìtara. Láti kárí ìpínlẹ̀ wa tí ó tóbi, a fi kẹ̀kẹ́ rìnrìn àjò láti ìlú kan sí ìkejì àti láti abúlé dé abúlé, a sì gbé inú àwọn iyàrá tí a háyà. Kò sí ìjọ kankan ní àgbègbè náà, nítorí náà, èmi àti alábàáṣiṣẹ́ mi máa ń jíròrò gbogbo apá inú àwọn ìpàdé ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ papọ̀ déédéé. Nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, a fi ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìwé ńlá àti ìwé pẹlẹbẹ síta tí ó ṣàlàyé ète Ọlọ́run.
Ìbẹ̀wò kan tí a ṣe sí ilé àlùfáà jẹ́ mánigbàgbé, níbi tí a ti bá àlùfáà àdúgbò ti Ṣọ́ọ̀ṣì ti England sọ̀rọ̀. Ní àgbègbè tí ó pọ̀ jù lọ, àlùfáà Áńgílíkà ni a máa ń bẹ̀ wò gbẹ̀yìn nítorí pé ó sábà máa ń bá wa fa wàhálà nígbà tí ó bá mọ̀ pé a ń wàásù ìhìn rere náà ní àgbègbè ibẹ̀. Ṣùgbọ́n ní abúlé yìí gbogbo ènìyàn ni ó sọ̀rọ̀ àlùfáà náà ní rere. Ó ń bẹ àwọn aláìsàn wò, ó ń yá àwọn tí wọ́n fẹ́ràn ìwé kíkà ní ìwé, ó tilẹ̀ tún ń ṣèbẹ̀wò abẹ́lé sí àwọn ọmọ ìjọ rẹ̀ láti ṣàlàyé Bíbélì fún wọn.
Dájúdájú, nígbà tí a bẹ̀ ẹ́ wò, ó yá mọ́ wa gidigidi, ó sì tẹ́wọ́ gba púpọ̀ nínú àwọn ìwé wa. Ó tún mú un dá wa lójú pé bí ẹnikẹ́ni ní abúlé náà bá nífẹ̀ẹ́ sì àwọn ìwé wa kan, ṣùgbọ́n tí onítọ̀hún kò lówó lọ́wọ́, òun yóò bá a san owó rẹ̀. A gbọ́ pé ìrírí amúnifòyà ti ó ní nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní ti mú kí ó pinnu láti gbé àlàáfíà àti inú rere lárugẹ ní àgbègbè rẹ̀. Kí a tó kúrò níbẹ̀, ó súre fún wa, ó sì rọ̀ wá láti máa bá iṣẹ́ rere wa lọ. Àwọn ọ̀rọ̀ tí ó fi dágbére fún wa ni ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú Númérì 6:24 pé: “Kí OLÚWA kí ó bù sí i fún ọ, kí ó sì pa ọ́ mọ́.”—Bibeli Mimọ.
Màmá kú lẹ́yìn ọdún méjì tí mo ti di aṣáájú ọ̀nà, mo sì padà sí London láìní owó lọ́wọ́, tí n kò sì ní ìdílé. Ẹlẹ́rìí ọ̀wọ́n kan tí ó jẹ́ ará Scotland gbà mí sọ́dọ̀, ó sì ràn mí lọ́wọ́ láti kojú wàhálà ikú Màmá mi, ó sì fún mi níṣìírí láti máa bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún lọ. Nítorí náà, mo bá Julia Fairfax, aṣáájú ọ̀nà alábàáṣiṣẹ́pọ̀ tuntun, padà sí Ìlà Oòrùn Angilia. A tún ọkọ̀ àfiṣelé kan tí a ti ń lò tipẹ́ ṣe láti jẹ́ ilé àgbérìn wa kejì; a lo katakata tàbí ọkọ̀ ẹrù láti máa gbé e káàkiri. Àwa pẹ̀lú tọkọtaya àgbàlagbà kan, Albert àti Ethel Abbott, tí wọ́n ní ọkọ̀ àfiṣelé kékeré kan, ń bá iṣẹ́ ìwàásù lọ. Albert àti Ethel di òbí fún mi.
Nígbà tí mo ń ṣe aṣáájú ọ̀nà ní Cambridgeshire, mo pàdé John Matthews, Kristẹni arákùnrin àtàtà kan tí ó ti fi ìwà títọ́ rẹ̀ hàn fún Jèhófà tẹ́lẹ̀ lábẹ́ àwọn ipò nínira. Kò pẹ́ púpọ̀ lẹ́yìn tí Ogun Àgbáyé Kejì bẹ̀rẹ̀, ní ọdún 1940, a ṣègbéyàwó.
Ogun àti Ìdílé
Nígbà tí a ṣì jẹ́ tọkọtaya alárédè, ọkọ̀ kékeré kan tí kò ju yàrá ìdáná kékeré lọ ni a ń gbé, a sì ń fi alùpùpù kan tí ó ṣeé gbára lé ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Ọdún kan lẹ́yìn tí a ṣègbéyàwó, nítorí tí John kọ̀ láti ṣe iṣẹ́ ológun, nítorí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ tí a fi Bíbélì kọ́, a rán an lọ sí oko fún iṣẹ́ àṣekára. (Aísáyà 2:4) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí mú òpin dé bá iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà wa, ó dà bí ẹni pé Ọlọ́run lọ́wọ́ sí rírán tí a rán John lọ sí ibi tí a rán an lọ, nítorí pé mo ti lóyún, yóò sì ṣeé ṣe fún un láti gbọ́ bùkátà wa.
Ní àwọn ọdún ìgbà ogun, a gbádùn àwọn ìpàdé àkànṣe tí a ṣe láìka àwọn ìnira sí. Ní ọdún 1941, alùpùpù wa gbé èmi àti John lọ sí Manchester, 300 kìlómítà sí wa, mo wà nínú oyun ọmọ wa àkọ́kọ́ nígbà náà. Lójú ọ̀nà, a kọjá ọ̀pọ̀ ìlú tí bọ́ǹbù ti bà jẹ́, a sì ṣe kàyéfì bí ìpàdé yóò bá ṣeé ṣe lábẹ́ irú ìpò bẹ́ẹ̀. A kúkú ṣe é. Gbọ̀ngàn Free Trade tí ó wà ní àárín gbùngbùn Manchester kún fọ́fọ́ fún Àwọn Ẹlẹ́rìí láti apá ibi púpọ̀ ní England, a sì gbé gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà kalẹ̀.
Nígbà tí ọ̀rọ̀ olùbánisọ̀rọ̀ àsọparí ní àpéjọpọ̀ náà ń parí lọ, ó sọ fún àwùjọ pé kí wọ́n kúrò lágbègbè náà kíákíá, níwọ̀n bí ogun ojú òfuurufú kò ti ní pẹ́ bẹ̀rẹ̀. Ìkìlọ̀ náà bọ́ sákòókò. A kò tí ì rìn jìnnà púpọ̀ sí gbọ̀ngàn náà nígbà tí a gbọ́ ariwo ọkọ̀ àti ìró ìbọn tí wọ́n ń yìn sí ọkọ̀ òfuurufú. Ẹ̀yìn tí a óò bojú wò, a rí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ọkọ̀ òfuurufú tí ń ju bọ́ǹbù sí àárín gbùngbùn ìlú náà. Lókèèrè, láàárín iná àti èéfín, a rí gbọ̀ngàn náà tí a jókòó sínú rẹ̀ láìpẹ́ yìí; ó ti run kanlẹ̀ pátápátá! A dúpẹ́ pé, kò sí èyíkéyìí nínú àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin wa tí a pa.
Nígbà tí a tọ́ àwọn ọmọ wa dàgbà, kò ṣeé ṣe fún wá láti máa ṣe aṣáájú ọ̀nà, ṣùgbọ́n ilé wa wà ní ṣíṣí sílẹ̀ fún àwọn alábòójútó arìnrìn àjò àti àwọn aṣáájú ọ̀nà tí kò ní ibùgbé. Nígbà kan, aṣáájú ọ̀nà mẹ́fà wà ní ilé wa fún oṣù díẹ̀. Kò sí iyè méjì pé ìfararora pẹ̀lú irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni ó mú kí ọmọbìnrin wa, Eunice, yàn láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà ní ọdún 1961 nígbà tí ó ṣì jẹ́ ẹni ọdún 15. Ó bani nínú jẹ́ pé, ọmọkùnrin wa, David, kò bá a nìṣó láti máa sin Jèhófà nígbà tí ó dàgbà, ọmọbìnrin wa, Linda, sì kú lábẹ́ ipò bíbani nínú jẹ́ nígbà ogun.
Ìpinnu Wa Láti Ṣí Lọ sí Sípéènì
Àpẹẹrẹ Màmá àti ìṣírí tí ó ń fún mi ti ru ìfẹ́ láti di míṣọ́nnárì sókè nínú mi, n kò sì gbàgbé góńgó yẹn pátápátá. Nípa báyìí, inú wa dùn ní ọdún 1973, nígbà tí Eunice ti England lọ sí Sípéènì níbi tí àìní gbé pọ̀ fún àwọn olùpòkìkí Ìjọba. Àmọ́ ṣáá o, inú wa kò dùn pé ó ń fi wá sílẹ̀, ṣùgbọ́n inú wa tún dùn pé ó fẹ́ lọ sìn ní ilẹ̀ àjèjì.
Láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá, a ti bẹ Eunice wò, ó sì ṣeé ṣe fún wa láti mọ Sípéènì dáradára. Ní tòótọ́, èmi àti John bẹ̀ ẹ́ wò ní ibi mẹ́rìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí ó ti sìn. Lẹ́yìn náà, bí ọdún ti ń gorí ọdún, okun wa bẹ̀rẹ̀ sí dínkù. John ṣubú, ó sì nípa lórí ìlera rẹ̀ gidigidi, èmi náà sì ní ìṣòro ọkàn-àyà àti èkùrọ́ ọrùn. Yàtọ̀ sí ìyẹn, àwa méjèèjì ni àrùn oríkèé ríro ń bá jà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a nílò ìrànlọ́wọ́ Eunice, a kò fẹ́ kí ó fi iṣẹ́ àyànfúnni rẹ̀ sílẹ̀ nítorí tiwa.
A jíròrò èrò wa pẹ̀lú Eunice, a sì gbàdúrà fún ìtọ́sọ́nà. Ó múra tán láti wá ràn wá lọ́wọ́, ṣùgbọ́n a pinnu pé ojútùú tí ó dára jù lọ ni pé kí èmi àti John máa gbé pẹ̀lú rẹ̀ ní Sípéènì. Bí n kò bá lè jẹ́ míṣọ́nnárì fúnra mi, ó kéré tán n óò lè ran ọmọ mi àti àwọn aṣáájú ọ̀nà alábàáṣiṣẹ́pọ̀ rẹ̀ méjèèjì lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Nígbà tí yóò fi di àkókò yẹn, èmi àti John ti mú Nuria àti Ana, àwọn aṣáájú ọ̀nà alábàáṣiṣẹ́pọ̀ Eunice fún ọdún 15, gẹ́gẹ́ bí ọmọ wa. Inú wọn sì dùn pé a wá gbé pẹ̀lú wọn níbikíbi tí a bá yàn wọ́n sí.
Ọdún mẹ́fà ti kọjá nísinsìnyí tí a ti ṣe ìpinnu yẹn. Ìlera wa kò jó rẹ̀yìn sí i, ìgbésí ayé wa sì ti túbọ̀ dùn sí i. N kò tí ì lè sọ èdè Spanish dáadáa, ṣùgbọ́n ìyẹn kò ní kí n má wàásù. Èmi àti John ń gbádùn ìjọ kékeré tí a wà ní Extremadura, gúúsù ìwọ̀ oòrùn Sípéènì.
Gbígbé ní Sípéènì ti kọ́ mi ní ọ̀pọ̀ nǹkan nípa bí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba wa ti jẹ́ iṣẹ́ tí ó kárí ayé tó, mo sì wá lóye rẹ̀ ní kedere nísinsìnyí, ohun tí Jésù Kristi sọ pé, “pápá náà ni ayé.”—Mátíù 13:38.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà ní àwọn ọdún 1930