A Pe Orúkọ Àtọ̀runwá náà ní Ísírẹ́lì
FÚN ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ni ẹ̀sìn àbáláyé àwọn Júù ti ka pípe orúkọ àtọ̀runwá náà, Jèhófà, léèwọ̀ pátápátá fún àwọn mẹ́ńbà rẹ̀. Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí Mishnah sọ, ẹnikẹ́ni tó bá pe orúkọ Ọlọ́run kò ní ní “ìpín kankan nínú ayé tí ń bọ̀.”—Sanhedrin 10:1.a
Ní January 30, 1995, olórí àwọn rábì Sẹ́fádíkì ní Ísírẹ́lì tẹ́lẹ̀ mọ̀ọ́mọ̀ pe orúkọ àtọ̀runwá náà. Ó ṣe èyí nígbà tó ń ka tíkúnì kan, ìyẹn àdúrà ìtọ́sọ́nà tí ọmọ ilé ẹ̀kọ́ Kàbálì kan máa ń kà. Wọ́n ń gba àdúrà yìí kí Ọlọ́run lè mú ìṣọ̀kan wá sí àgbáálá ayé, èyí tí àwọn onísìn náà gbà pé ipá àwọn ẹ̀mí búburú ti dènà rẹ̀. Ìwé ìròyìn Yedioth Aharonoth ti February 6, 1995, sọ pé: “Èyí jẹ́ ìlànà ẹ̀sìn kan tí agbára rẹ̀ kàmàmà débi pé inú àkànṣe ìwé kékeré kan tí a kì í tà fún gbogbo ènìyàn nìkan ni àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ ti fara hàn.” Pípe orúkọ Ọlọ́run nínú àyíká ọ̀rọ̀ yìí ni wọ́n rò pé ó túbọ̀ ń fi ìjẹ́pàtàkì ohun tí wọ́n ń béèrè fún hàn.
Ó jẹ́ ohun tó yẹ fún àfiyèsí pé Bíbélì pa á láṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run láti lo orúkọ àtọ̀runwá náà, Jèhófà. (Ẹ́kísódù 3:15; Òwe 18:10; Aísáyà 12:4; Sefanáyà 3:9) Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìgbà ẹgbẹ̀rún méje [7,000] tí orúkọ yẹn fara hàn nínú apá ibi tó jẹ́ ti Hébérù ìpilẹ̀ṣẹ̀ nínú Bíbélì. Àmọ́ ṣá o, Bíbélì kìlọ̀ lòdì sí ṣíṣi orúkọ Ọlọ́run lò. Ẹ̀kẹta nínú Àṣẹ Mẹ́wàá náà sọ pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ lo orúkọ Jèhófà Ọlọ́run rẹ lọ́nà tí kò ní láárí, nítorí Jèhófà kò ní ṣàìfi ìyà jẹ ẹni tí ó lo orúkọ rẹ̀ lọ́nà tí kò ní láárí.” (Ẹ́kísódù 20:7) Báwo la ṣe lè lo orúkọ Ọlọ́run lọ́nà tí kò ní láárí? Ìwé alálàyé kan tí The Jewish Publication Society tẹ̀ jáde sọ pé ọ̀rọ̀ Hébérù náà tí a túmọ̀ sí “lọ́nà tí kò ní láárí” lè má jẹ́ kìkì “ìlò” orúkọ àtọ̀runwá náà “láìbọ̀wọ̀ fún un” nìkan, àmọ́, kó tún jẹ́ “kíka àdúrà ìsúre kan tí kò pọndandan ní àkàtúnkà.”
Nítorí náà, ojú wo ló yẹ ká fi wo àdúrà ìtọ́sọ́nà tí wọ́n ń pè ní tíkúnì tí àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ Kàbálì máa ń kà? Ibo ló ti bẹ̀rẹ̀? Ọ̀rúndún kejìlá sí ìkẹtàlá Sànmánì Tiwa, ni ẹ̀sìn awo àwọn Júù, tí a ń pè ní Kàbálà, bẹ̀rẹ̀ sí i di èyí tó lókìkí. Ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún, rábì kan tó ń jẹ́ Isaac Luria, mú “tíkúnímù” wọnú ìlànà ìsìn Kàbálì. Wọ́n wá ń fi orúkọ Ọlọ́run pidán nípasẹ̀ àwọn agbára àrà ọ̀tọ̀ kan, èyí sì wá di apá kan ààtò Kàbálì. Ṣé o rò pé ọ̀nà tó tọ́ láti lo orúkọ Ọlọ́run nìyí?—Diutarónómì 18:10-12.
Bó ti wù kóo dáhùn ìbéèrè yẹn, wàá ṣáà gbà pé pípe orúkọ Ọlọ́run ní gbangba ní Ísírẹ́lì òde òní jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí a kò retí. Síbẹ̀, Ọlọ́run fúnra rẹ̀ sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Dájúdájú, ẹ ó sọ ní ọjọ́ yẹn pé: ‘Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà! Ẹ ké pe orúkọ rẹ̀. Ẹ sọ àwọn ìbánilò rẹ̀ di mímọ̀ láàárín àwọn ènìyàn. Ẹ mẹ́nu kàn án pé orúkọ rẹ̀ ni a gbé ga. Ẹ kọ orin atunilára sí Jèhófà, nítorí pé ó ti ṣe ohun tí ó ta yọ ré kọjá. Èyí ni a sọ di mímọ̀ ní gbogbo ilẹ̀ ayé.’”—Aísáyà 12:4, 5.
A mà dúpẹ́ o, pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń sa gbogbo ipá wọn ní ríran àwọn aládùúgbò wọn lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ nípa Jèhófà ní Ísírẹ́lì, bíi ti àwọn ilẹ̀ tó lé ní ọgbọ̀nlénígba jákèjádò ayé. Ìrètí wọn ni pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ṣì ń bọ̀ wá mọrírì ìtumọ̀ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ bíi Sáàmù 91:14, tó kà pé: “Nítorí pé òun darí ìfẹ́ni rẹ̀ sí mi [Jèhófà], èmi pẹ̀lú yóò pèsè àsálà fún un. Èmi yóò dáàbò bò ó nítorí pé ó ti wá mọ orúkọ mi.”
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Mishnah jẹ́ àkópọ̀ àwọn ìwé ìtumọ̀ tó jẹ́ àfikún òfin inú Ìwé Mímọ́, a gbé e karí àlàyé àwọn rábì tí a ń pè ní Tánnáímù (àwọn olùkọ́). Ó di ohun tí a kọ sínú ìwé ní òpin ọ̀rúndún kejì sí ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kẹta Sànmánì Tiwa.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Níhìn-ín ní Négébù, àwọn ènìyàn Jèhófà sọ orúkọ rẹ̀ àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀ di mímọ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Àwọn ìwé tí a lẹ̀ mọ́ ògiri tí ń fi orúkọ àtọ̀runwá náà hàn