ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g99 3/8 ojú ìwé 26-27
  • Ó Ha Lòdì Láti Máa Pe Orúkọ Ọlọ́run Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ó Ha Lòdì Láti Máa Pe Orúkọ Ọlọ́run Bí?
  • Jí!—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ni Èrò Ọlọ́run Nípa Rẹ̀?
  • Òfin Kẹta Náà
  • Ó Ha Já Mọ́ Nǹkan Kan Bí?
  • Ìtumọ̀ Orúkọ Ọlọ́run àti Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Lò Ó
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Orúkọ Ọlọ́run
    Jí!—2017
  • Máa Gbé Orúkọ Ńlá Jèhófà Ga
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Bí O Ṣe Lè Mọ Orúkọ Ọlọ́run
    Jí!—2004
Àwọn Míì
Jí!—1999
g99 3/8 ojú ìwé 26-27

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ó Ha Lòdì Láti Máa Pe Orúkọ Ọlọ́run Bí?

FÚN ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ni ìsìn àwọn Júù ti ń fi kọ́ni pé orúkọ àtọ̀runwá náà, Jèhófà, jẹ́ mímọ́ ju ohun tí a lè máa pè lọ.a (Sáàmù 83:18) Ọ̀pọ̀ àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ló ti ronú pé kò fi ọ̀wọ̀ hàn láti pe Ẹlẹ́dàá ológo lọ́nà kan ṣáá bẹ́ẹ̀, tàbí pé ó tilẹ̀ jẹ́ rírú òfin kẹta nínú Òfin Mẹ́wàá tí ó ka ‘pípe orúkọ Olúwa lásán’ léèwọ̀. (Ẹ́kísódù 20:7, King James Version) Ní ọ̀rúndún kẹta Sànmánì Tiwa, Mishnah polongo pé “ẹnikẹ́ni tó bá pe Orúkọ àtọ̀runwá náà bí a ṣe kà á jáde lọ́kọ̀ọ̀kan” kò ní ní “ìpín kankan nínú ayé tí ń bọ̀.”—Sanhedrin 10:1.

Ní ti tòótọ́, ọ̀pọ̀ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ Kirisẹ́ńdọ̀mù ló tẹ̀ lé ìlànà àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn Júù yìí nígbà tí wọ́n ń túmọ̀ Bíbélì. Fún àpẹẹrẹ, ohun tí The New Oxford Annotated Bible sọ nínú ọ̀rọ̀ ìṣáájú rẹ̀ ni pé: “Lílo orúkọ pàtó kan fún Ọlọ́run kan ṣoṣo náà, bí ẹni pé àwọn ọlọ́run mìíràn wà, tí a fi ní láti fi Ọlọ́run tòótọ́ hàn yàtọ̀ lára wọn, ní a bẹ̀rẹ̀ sí dá dúró nínú ẹ̀sìn àwọn Júù ṣáájú sànmánì àwọn Kristẹni tí kò sì yẹ fún ìgbàgbọ́ gbogbo gbòò ti Ṣọ́ọ̀ṣì Kristẹni.” Nítorí náà, “OLÚWA” ní a fi dípò orúkọ àtọ̀runwá náà nínú ìtumọ̀ yẹn.

Kí Ni Èrò Ọlọ́run Nípa Rẹ̀?

Àmọ́, ǹjẹ́ ojú ìwòye irú àwọn olùtúmọ̀ àti àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn bẹ́ẹ̀ fi èrò inú Ọlọ́run hàn? Ó ṣe tán, Ọlọ́run kò fi orúkọ rẹ̀ pa mọ́ fún ìran ènìyàn; kàkà bẹ́ẹ̀, ó fi í hàn fún wọn. Orúkọ Ọlọ́run, Jèhófà, fara hàn ní ìgbà tí ó lé ní ẹgbẹ̀rìnlélọ́gbọ̀n [6,800] nínú apá tó jẹ́ ti Hébérù nínú Bíbélì, tí a máa ń pè ní Májẹ̀mú Láéláé. Àkọsílẹ̀ Bíbélì fi hàn pé àwọn ènìyàn méjì àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà, wà lára àwọn tí ó mọ orúkọ Ọlọ́run tí wọ́n sì lò ó. Nígbà tí Éfà bí ọmọkùnrin rẹ̀ àkọ́kọ́, ó polongo pé: “Mo ti mú ọkùnrin kan jáde nípasẹ̀ àrànṣe Jèhófà.”—Jẹ́nẹ́sísì 4:1.

Ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn náà, nígbà tí Ọlọ́run pe Mósè láti lọ kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní oko ẹrú ni Íjíbítì, Mósè bi Ọlọ́run pé: “Ká ní mo wá dé ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí mo sì sọ fún wọn pé, ‘Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín ni ó rán mi sí yín,’ tí wọ́n sì sọ fún mi pé, ‘Kí ni orúkọ rẹ̀?’ Kí ni èmi yóò sọ fún wọn?” Mósè ti lè máa ṣiyèméjì bóyá Ọlọ́run yóò lo àwọn orúkọ tuntun kan láti fi ara rẹ̀ hàn. Ọlọ́run sì wí fún Mósè pé: “Èyí ni ohun tí ìwọ yóò sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ‘Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín, Ọlọ́run Ábúráhámù, Ọlọ́run Ísákì àti Ọlọ́run Jékọ́bù, ni ó rán mi sí yín.’ Èyí ni orúkọ mi fún àkókò tí ó lọ kánrin, èyí sì ni ìrántí mi láti ìran dé ìran.” (Ẹ́kísódù 3:13, 15) Ó ṣe kedere pé, Ọlọ́run tòótọ́ kò wo orúkọ ara rẹ̀ bí ohun tí ó jẹ́ mímọ́ jù fún àwọn ènìyàn rẹ̀ láti pè.

Ní tòótọ́, àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run ní gbogbo ìran ti fi òmìnira pe orúkọ Ọlọ́run tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Bóásì, tí ó jẹ́ adúróṣinṣin ìránṣẹ́ Ọlọ́run máa ń kí àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ nínú oko pé, “Kí Jèhófà wà pẹ̀lú yín.” Ǹjẹ́ irú ìkíni bẹ́ẹ̀ mú kí àwọn òṣìṣẹ́ náà wárìrì? Rárá. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Ẹ̀wẹ̀, wọ́n wí fún un pé: ‘Kí Jèhófà bù kún ọ.’” (Rúùtù 2:4) Kàkà kí wọ́n wo ìkíni yìí bíi ṣíṣe àfojúdi sí Ọlọ́run, wọ́n wò ó bí ọ̀nà kan láti fi ògo àti ọlá fún un nínú àwọn àlámọ̀rí wọn ojoojúmọ́. Pẹ̀lú ojú ìwòye kan náà yìí, Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti gbàdúrà pé: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.”—Mátíù 6:9.

Òfin Kẹta Náà

Àmọ́, ìkàléèwọ̀ tí a mẹ́nu kàn nínú òfin kẹta nínú àwọn Òfin Mẹ́wàá ńkọ́? Ẹ́kísódù 20:7 sọ ní kedere pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ lo orúkọ Jèhófà Ọlọ́run rẹ lọ́nà tí kò ní láárí, nítorí Jèhófà kò ní ṣàìfi ìyà jẹ ẹni tí ó lo orúkọ rẹ̀ lọ́nà tí kò ní láárí.”

Kí ló túmọ̀ sí gan-an láti lo orúkọ Ọlọ́run “lọ́nà tí kò ní láárí”? Ìwé The JPS Torah Commentary, tí Jewish Publication Society tẹ̀ jáde, ṣàlàyé pé ọ̀rọ̀ Hébérù tí a lò lókè yìí bíi “lọ́nà tí kò ní láárí” (lash·shaw’ʹ) lè túmọ̀ sí “ní ẹ̀tàn” tàbí “láìnídìí, lásán.” Ìwé kan náà sọ síwájú sí i pé: “Àìṣetààrà [ọ̀rọ̀ Hébérù yìí] mú kí a lè ká àwọn tí ń jẹ́jọ́ lọ́wọ́ kò [kà á léèwọ̀ fún wọn] láti má ṣe jẹ́rìí èké, tàbí búra èké, kí wọ́n má sì lo Orúkọ àtọ̀runwá náà láìyẹ tàbí lọ́nà ṣiréṣiré.”

Ìwé àlàyé àwọn Júù yìí tẹnu mọ́ ọn lọ́nà tí ó tọ́ pé ‘lílo orúkọ Ọlọ́run lọ́nà tí kò ní láárí’ wé mọ́ lílo orúkọ náà lọ́nà tí kò yẹ. Síbẹ̀, ǹjẹ́ a lè sọ pé pípe orúkọ Ọlọ́run nígbà tí a bá ń kọ́ àwọn ẹlòmíràn nípa rẹ̀ tàbí nígbà tí a bá ń gbàdúrà sí Baba wa ọ̀run jẹ́ ‘àìyẹ tàbí ṣiréṣiré’? Jèhófà sọ èrò rẹ̀ jáde nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú Sáàmù 91:14 pé: “Nítorí pé òun darí ìfẹ́ni rẹ̀ sí mi, èmi pẹ̀lú yóò pèsè àsálà fún un. Èmi yóò dáàbò bò ó nítorí pé ó ti wá mọ orúkọ mi.”

Ó Ha Já Mọ́ Nǹkan Kan Bí?

Ìwé atúmọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì òde òní tí a pe àkọlé rẹ̀ ní The Five Books of Moses, tí Everett Fox ṣe, yẹra fún àṣà àtọwọ́dọ́wọ́. Ìtumọ̀ yìí kò lo “OLÚWA” tí ó ti di àṣà, ṣùgbọ́n ó lo “YHWH” fún orúkọ Ọlọ́run “láti fi bí yóò ṣe rí lójú ọmọ Hébérù tó bá ń ka ìwé náà hàn.” Fox tẹnu mọ́ ọn pé: “Lọ́gán ni òǹkàwé náà yóò mọ̀ pé Ọlọ́run Bíbélì fara hàn nínú ìwé yìí bíi ‘YHWH.’” Ó gbà pé rírí orúkọ Ọlọ́run lè “rí bákan” sí ẹni tí ń kà á. Àmọ́, lẹ́yìn tí ó gbé ìgbésẹ̀ tí a gbóríyìn fún náà pé kò jẹ́ kí orúkọ Ọlọ́run fara sin nínú ìtumọ̀, ó fi kún un pé: “Èmi yóò dábàá lílo ‘OLÚWA’ tí ó jẹ́ àṣà àbáláyé nígbà tí a bá ń kàwé sókè, ṣùgbọ́n àwọn mìíràn lè tẹ̀ lé àṣà tiwọn.” Bí ó ti wù kí ó rí, ǹjẹ́ èyí jẹ́ ọ̀ràn ohun tí ó bá wù ọ́ ni kí o lò, ní títẹ̀lé àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ tàbí àṣà ti ara ẹni ni?

Rárá. Kì í ṣe pé Bíbélì fún lílo orúkọ Ọlọ́run níṣìírí nìkan ni, ńṣe ló pa á láṣẹ! Ní Aísáyà 12:4a, a fi àwọn ènìyàn Ọlọ́run hàn pé wọ́n ń kígbe jáde ní lílo ọ̀rọ̀ tí kò fi iyèméjì hàn, pé: “Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà! Ẹ ké pe orúkọ rẹ̀.” Ní àfikún sí i, onísáàmù náà sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí ìdájọ́ Ọlọ́run tọ́ sí pé: “Da ìhónú rẹ sórí àwọn orílẹ̀-èdè tí kò mọ̀ ọ́, àti sórí àwọn ìjọba tí kò ké pe orúkọ rẹ.”—Sáàmù 79:6; tún wo Òwe 18:10; Sefanáyà 3:9.

Nítorí náà, bí àwọn kan tilẹ̀ kọ̀ láti máa pe orúkọ ológo Jèhófà nítorí àṣìlóye òfin kẹta, àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ní ti tòótọ́ ń fẹ́ láti máa pe orúkọ rẹ̀. Ó dájú pé, ní gbogbo ìgbà tí wọ́n ní àǹfààní rẹ̀ ni wọ́n ‘ń sọ àwọn ìbánilò rẹ̀ di mímọ̀ láàárín àwọn ènìyàn, ní mímẹ́nu kàn án pé orúkọ rẹ̀ ni a gbé ga’!—Aísáyà 12:4b.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ní apá tí ó jẹ́ ti Hébérù nínú Bíbélì (Májẹ̀mú Láéláé), lẹ́tà mẹ́rin tí a lè pè ní YHWH ni a lò fún orúkọ Ọlọ́run. Níwọ̀n bí a kò ti mọ bí a ti ń pe orúkọ Ọlọ́run gan-an, ohun tí a sábà máa ń pè é ní èdè Yorùbá ni “Jèhófà.”

[Àwọ̀n àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Apá kan lára ìwé Sáàmù tí a mú jáde láti inú Àkájọ Ìwé Òkun Òkú. Orúkọ Ọlọ́run, Jèhófà (YHWH), fara hàn ní ọ̀nà tí ó rí bíi ti Hébérù ìgbàanì níbẹ̀ ju ti àwọn àkájọ ìwé yòókù lọ

[Credit Line]

Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda onínúure Shrine of the Book, Israel Museum, Jerusalem

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́