Ta Ni Ìkàléèwọ̀ Lórí Jíjẹ Ẹ̀jẹ̀ Kàn?
JÈHÓFÀ yọ̀ǹda fún Nóà àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ láti fi ẹran kún oúnjẹ wọn lẹ́yìn Ìkún Omi, ṣùgbọ́n ó pàṣẹ fún wọn gidigidi pé wọn kò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 9:1, 3, 4) Níbí, Ọlọ́run gbé ìlànà kan kalẹ̀, tí kì í wulẹ̀ ṣe Nóà àti ìdílé rẹ̀ nìkan ló kàn, ṣùgbọ́n tí ó kan gbogbo aráyé láti ìgbà náà wá, nítorí pé gbogbo àwọn tí ó gbé ayé láti ìgbà Ìkún Omi náà jẹ́ àtọmọdọ́mọ ìdílé Nóà.
Nípa bí ìkàléèwọ̀ náà ti wà láìyípadà tó, Joseph Benson sọ pé: “Ó yẹ láti kíyè sí i, pé a kò tí ì fìgbà kankan yí ìkàléèwọ̀ yí, tí a fún Nóà àti gbogbo àtọmọdọ́mọ rẹ̀ lórí jíjẹ ẹ̀jẹ̀, tí a sì tún sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́nà kan tí ó gbàrònú jù lọ, lábẹ́ ìṣètò ti Mósè, pa dà, ṣùgbọ́n ní ìhà kejì, a ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ lábẹ́ Májẹ̀mú Tuntun, Ìṣe xv.; tí ó sì tipa bẹ́ẹ̀ di àìgbọ́dọ̀máṣe ayérayé.”—Benson’s Notes, 1839, Ìdìpọ̀ Kíní, ojú ìwé 43.
Lábẹ́ Òfin Mósè
Nínú májẹ̀mú Òfin tí Jèhófà bá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì dá, ó fi òfin tí ó fún Nóà tẹ́lẹ̀ sí i. Ó mú kí ó ṣe kedere pé ẹnikẹ́ni tí kò bá ka ìlànà tí òfin Ọlọ́run fi lélẹ̀ sí, títí kan pípa ẹran pàápàá, yóò ‘jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀.’ (Léfítíkù 17:3, 4) A gbọ́dọ̀ ro ẹ̀jẹ̀ ẹran tí a óò bá jẹ dà nù sórí ilẹ̀, kí a sì fi erùpẹ̀ bò ó. (Léfítíkù 17:13, 14) Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ẹ̀jẹ̀kẹ́jẹ̀ ti ẹran ara ni a óò ‘ké kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.’ Mímọ̀ọ́mọ̀ rú òfin yìí nípa ìjẹ́mímọ́ ẹ̀jẹ̀ túmọ̀ sí ‘ìkékúrò’ nínú ikú.—Léfítíkù 17:10; 7:26, 27; Númérì 15:30, 31.
Nígbà tí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Cyclopaedia (1882, Ìdìpọ̀ Kíní, ojú ìwé 834) ti M’Clintock àti Strong ń ṣàlàyé lórí Léfítíkù 17:11, 12, ó wí pé: “Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nìkan kọ́ ni àṣẹ aláìgbagbẹ̀rẹ́ yìí kàn, ṣùgbọ́n, ó kan àwọn àlejò tí ń ṣe àtìpó nínú wọn pàápàá. Ìjìyà tí ó rọ̀ mọ́ ìrékọjá rẹ̀ ni ‘kíkénikúrò nínú àwọn ènìyàn náà,’ èyí tí ó jọ pé ó ní èrò ikú nínú (fi wé Héb. x, 28), bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣòro láti mọ̀ dájú bóyá idà ni a fi ń pani tàbí a ń sọni lókùúta pa ni.”
Ní Diutarónómì 14:21, a fàyè sílẹ̀ fún títa ẹran kan tí ó tìkára rẹ̀ kú, tàbí tí ẹranko kan fà ya fún àtìpó olùgbé tàbí àjèjì. Nípa bẹ́ẹ̀, a fi ìyàtọ̀ sáàárín irú ẹran bẹ́ẹ̀ àti èyí tí ẹnì kan pa fún jíjẹ. (Fi wé Léfítíkù 17:14-16.) Ó di dandan fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, pa pọ̀ mọ́ àwọn àtìpó olùgbé tí ó tẹ́wọ́ gba ìjọsìn tòótọ́, tí ó sì wá sábẹ́ májẹ̀mú Òfin náà, láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun àbéèrèfún gígalọ́lá inú Òfin yẹn. Àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè ni ó wà lábẹ́ ohun àbéèrèfún tí ó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 9:3, 4, ṣùgbọ́n Ọlọ́run fi àwọn tí ó wà lábẹ́ Òfin sábẹ́ ọ̀pá ìdiwọ̀n gíga láti rọ̀ mọ́ ohun àbéèrèfún yẹn ju àwọn àjèjì àti àwọn àtìpó olùgbé tí kò ì di olùsìn Jèhófà lọ.
Lábẹ́ Ìṣètò ti Kristẹni
Ẹgbẹ́ olùṣàkóso ìjọ Kristẹni ọ̀rúndún kìíní, lábẹ́ ìdarí ẹ̀mí mímọ́, pàṣẹ lórí ọ̀ràn ẹ̀jẹ̀. Àṣẹ tí wọ́n pa sọ pé: “Nítorí ẹ̀mí mímọ́ àti àwa fúnra wa ti fara mọ́ ṣíṣàìtún fi ẹrù ìnira kankan kún un fún yín, àyàfi àwọn nǹkan pípọndandan wọ̀nyí, láti máa takété sí àwọn ohun tí a fi rúbọ sí òrìṣà àti sí ẹ̀jẹ̀ àti sí ohun tí a lọ́ lọ́rùn pa àti sí àgbèrè. Bí ẹ bá fi tìṣọ́ratìṣọ́ra pa ara yín mọ́ kúrò nínú nǹkan wọ̀nyí, ẹ óò láásìkí. Kí ara yín ó le o!” (Ìṣe 15:22, 28, 29) Ìkàléèwọ̀ náà kan ẹran tí ó ní ẹ̀jẹ̀ nínú (“ohun tí a lọ́ lọ́rùn pa”).
Níkẹyìn pátápátá, àṣẹ yìí sinmi lórí àṣẹ Ọlọ́run láti má jẹ ẹ̀jẹ̀, bí a ṣe fi fún Nóà àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, àti nítorí náà, fún gbogbo aráyé. Nípa èyí, a rí àlàyé tí ó tẹ̀ lé e yìí nínú ìwé The Chronology of Antient Kingdoms Amended, láti ọwọ́ Alàgbà Isaac Newton (Dublin, 1728, ojú ìwé 184) pé: “Òfin yìí [ti títakété sí ẹ̀jẹ̀] ti wà tipẹ́ ṣáájú ọjọ́ Mósè, a ti fi fún Nóà àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, tipẹ́tipẹ́ ṣáájú ọjọ́ Ábúráhámù: nítorí náà, nígbà tí àwọn Àpọ́sítélì àti àwọn Alàgbà nínú Ìgbìmọ̀ tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù polongo pé àwọn Kèfèrí kò sí lábẹ́ àìgbọdọ̀máṣe láti kọlà, kí wọ́n sì pa òfin Mósè mọ́, wọ́n yọ òfin títakété sí ẹ̀jẹ̀, àti sí ohun tí a lọ́ lọ́rùn pa yìí sílẹ̀, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ òfin tí Ọlọ́run ti ṣe ṣáájú, tí a kò ṣe fún àwọn ọmọkùnrin Ábúráhámù nìkan, ṣùgbọ́n tí a ṣe fún gbogbo orílẹ̀-èdè, nígbà tí wọ́n ń gbé pọ̀ ní Ṣínárì lábẹ́ ìṣàkóso Nóà: tí òfin títakété sí ẹran tí a fi rúbọ sí Òrìṣà tàbí àwọn Ọlọ́run èké, àti sí àgbèrè sì jẹ́ irú kan náà.”—Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tirẹ̀.
A Pa Á Mọ́ Láti Ìgbà Àwọn Àpọ́sítélì
Ìgbìmọ̀ tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù náà fi ìpinnu rẹ̀ ránṣẹ́ sí àwọn ìjọ Kristẹni láti pa á mọ́. (Ìṣe 16:4) Ní nǹkan bí ọdún méje lẹ́yìn tí ìgbìmọ̀ tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù náà ti gbé àṣẹ náà jáde, àwọn Kristẹni ń bá a lọ láti máa ṣègbọ́ràn sí “ìpinnu . . . pé kí wọ́n pa ara wọn mọ́ kúrò nínú nǹkan tí a fi rúbọ sí àwọn òrìṣà àti pẹ̀lú kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ àti ohun tí a lọ́ lọ́rùn pa àti kúrò nínú àgbèrè.” (Ìṣe 21:25) Ní èyí tí ó lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn náà, ní ọdún 177 Sànmánì Tiwa, ní Lyons (ilẹ̀ Faransé ti ìsinsìnyí), nígbà tí àwọn ọ̀tá ìsìn fẹ̀sùn èké kan àwọn Kristẹni pé wọ́n ń pa ọmọ jẹ, obìnrin kan tí ń jẹ́ Biblis sọ pé: “Báwo ni irú àwọn ọkùnrin bẹ́ẹ̀ ṣe lè máa pa ọmọ jẹ, nígbà tí a kò yọ̀ǹda fún wọn láti jẹ ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹranko aláìlérò-lórí pàápàá?”—The Ecclesiastical History, láti ọwọ́ Eusebius, V, I, 26.
Àwọn Kristẹni ìjímìjí takété sí jíjẹ èjẹ̀kẹ́jẹ̀. Nípa èyí, Tertullian (c. 155 sí a. 220 Sànmánì Tiwa) tọ́ka sí i nínú ìwé rẹ̀, Apology (IX, 13, 14) pé: “Jẹ́ kí àṣìṣe rẹ jẹ́ ohun ìtìjú lójú àwọn Kristẹni, nítorí pé a kì í fi ẹ̀jẹ̀ ẹranko pàápàá sínú oúnjẹ wa. Ní ti ìyẹn, a ta kété sí ohun tí a lọ́ lọ́rùn pa tàbí èyí tí ó fúnra rẹ̀ kú, kí a má baà di ẹlẹ́gbin nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀, kódà, bí ó bá tilẹ̀ fara sin sínú ẹran. Níkẹyìn, nígbà tí o ń dẹ àwọn Kristẹni wo, o fún wọn ní àdíndùn ẹran ẹlẹ́jẹ̀; dájúdájú, o mọ̀ dáradára pé, èèwọ̀ ni fún wọn; ṣùgbọ́n o fẹ́ mú wọn dẹ́ṣẹ̀.” Minucius Felix, amòfin ọmọ ilẹ̀ Róòmù kan, tí ó gbé ayé títí di nǹkan bí ọdún 250 Sànmánì Tiwa, sọ kókó kan náà, ó kọ̀wé pé: “Ní tiwa, a kò gbà wá láyè láti rí dídúńbú ẹ̀dá ènìyàn tàbí kí a gbọ́ nípa rẹ̀; a yẹra fún ẹ̀jẹ̀ ènìyàn tó bẹ́ẹ̀ tí a kì í fi í lo ẹ̀jẹ̀ ẹranko nínú oúnjẹ wa.”—Octavius, XXX, 6.
Ó Kan Ìwà Títọ́
Láti ìgbà tí a ti fi májẹ̀mú tuntun náà lọ́lẹ̀ lórí ẹ̀jẹ̀ Jésù Kristi, àwọn Kristẹni ti mọ ìníyelórí afúnniníyè ẹ̀jẹ̀ yí nípasẹ̀ ìṣètò Jèhófà àti nípasẹ̀ Jésù gẹ́gẹ́ bí Àlùfáà Àgbà títóbi tí ó “wọlé sínú ibi mímọ́, rárá, kì í ṣe pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ àwọn ewúrẹ́ àti ti àwọn ẹgbọrọ akọ màlúù, bí kò ṣe pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ òun fúnra rẹ̀, lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún tún un ṣe mọ́ láé ó sì gba ìdáǹdè àìnípẹ̀kun fún wa.” Nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ Kristi, a ti wẹ ẹ̀rí ọkàn àwọn Kristẹni mọ́ kúrò nínú àwọn òkú iṣẹ́, kí wọ́n lè máa ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún Ọlọ́run alààyè. Ọ̀ràn ìlera ara wọn jẹ wọ́n lọ́kàn, àmọ́ nípìlẹ̀, àti lọ́nà tí ó túbọ̀ ṣe kókó jù, ìlera wọn nípa tẹ̀mí àti ipò wọn níwájú Ẹlẹ́dàá náà jẹ wọ́n lọ́kàn jù. Wọ́n fẹ́ láti rọ̀ mọ́ ìwà títọ́ wọn sí Ọlọ́run alààyè náà, láìsẹ́ ìrúbọ Jésù, láìkà á sí aláìníye-lórí, àti láìfẹsẹ̀ gbo ó mọ́lẹ̀. Nítorí pé, kì í ṣe ìwàláàyè tí kì í dúró pẹ́ ni wọ́n ń wá kiri, àmọ́ ìyè àìnípẹ̀kun.—Hébérù 9:12, 14, 15; 10:28, 29.