Àwọn Ọmọ Ìbílẹ̀ America—Òpin Sànmánì kan
TA NI kò tí ì wo fíìmù ìforígbárí láàárín àwọn adamàlúù àti àwọn ará India rí? Kárí ayé ni àwọn ènìyàn ti gbọ́ nípa Wyatt Earp, Buffalo Bill, àti Lone Ranger, tí wọ́n sì gbọ́ nípa Geronimo, Sitting Bull, Crazy Horse, àti Olóyè Joseph, ti India, pa pọ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn. Ṣùgbọ́n báwo gan-an ni àwọn ipò ti a ń fi hàn ní Hollywood ṣe ṣeé gbà gbọ́ tó? Báwo sì ni bí wọ́n ṣe ń fi àwọn ará India hàn ṣe jẹ́ àìṣègbè tó?
Ìtan bí àwọn ará Europe ṣe ṣẹ́gun àwọn Ọmọ Ìbílẹ̀ Àríwá America (àwọn ará India) ń gbé ìbéèrè dìde.a Àwọn ìwé ìtàn kò ha ṣègbè ní ọ̀nà tí wọ́n gbà sọ̀rọ̀ nípa àwọn ará India bí? Ẹ̀kọ́ kankan ha wà tí a lè kọ́ nípa ìwọra, ìnilára, ẹ̀yà ìran tèmi lọ̀gá, àti ìwà ìkà bíburú jáì bí? Kí ni òtítọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ láàárín àwọn tí a sábà ń pè ní adamàlúù àti àwọn ará India?
Ìlòdìsí Ìkẹyìn ti Custer àti Ìpakúpa ní Wounded Knee
Ní ọdún 1876, babaláwo Sitting Bull ti Lakota (ọ̀kan lára àwọn ìpín mẹ́ta pàtàkì ti àwọn Sioux) jẹ́ aṣáájú kan nínú ogun Odò Little Bighorn ní Montana. Ọ̀gágun Custer “Onírun Gígùn” rò pé ó lè rọrùn fún òun láti fi 650 ọmọ ogun ṣẹ́gun 1,000 àwọn jagunjagun Sioux àti Cheyenne. Àṣìṣe búburú gbáà nìyí. Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ àwùjọ jagunjagun Ọmọ Ìbílẹ̀ America títóbi jù lọ tí ó tí ì kóra jọ pọ̀ rí ló dojú kọ—nǹkan bí 3,000.
Custer pín Ìpín Keje Ọmọ Ogun Ẹlẹ́sẹ̀ rẹ̀ sí ọ̀nà mẹ́ta. Láìdúró de ìrànwọ́ àwọn méjì tó kù, àwùjọ tirẹ̀ kọ lu ohun tí ó rò pé yóò jẹ́ ìpín tí ó rọrùn láti ṣẹ́gun jù lọ nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará India. Lábẹ́ ìdarí Crazy Horse, Gall, àti Sitting Bull, tí wọ́n jẹ́ aṣáájú wọn, àwọn ará India pa Custer àti ẹgbẹ́ ogun rẹ̀ tí ó ní nǹkan bí 225 ọmọ ogun nínú run. Ó jẹ́ ìṣẹ́gun onígbà díẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè India, ṣùgbọ́n ó jẹ́ àdánù líle koko fún Ẹgbẹ́ Ogun United States. Bí ó ti wù kí ó rí, ìgbẹ̀san kíkàmàmá wáyé ní ọdún 14 péré lẹ́yìn náà.
Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, Sitting Bull juwọ́ sílẹ̀, lẹ́yìn tí wọ́n ti ṣèlérí àforíjì fún un. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n fi sí àhámọ́ fún àkókò díẹ̀ ní Fort Randall, ní Agbègbè Ìpínlẹ̀ Dakota. Ní ọjọ́ ogbó rẹ̀, ó fara hàn ní gbangba nínú àfihàn sinimá Ìhà Ìwọ̀ Oòrùn Nígbà Ìdàgbàsókè Rẹ̀ tí Buffalo Bill ṣe. Aṣáájú alákitiyan nígbà kan rí náà ti pàdánù okun àti agbára ìdarí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí babaláwo olókìkí tí o ti jẹ́ tẹ́lẹ̀ rí.
Ní 1890, àwọn ọlọ́pàá India tí wọ́n rán lọ mú Sitting Bull (tí orúkọ rẹ̀ ní èdè Lakota ń jẹ́ Tatanka Iyotake) yìnbọn pa á. Àwọn “Onímẹ́táàlì Láyà” (oníbáàjì ọlọ́pàá) ti Sioux, Ọ̀gá Ọlọ́pàá Bull Head àti Sájẹ́ǹtì Red Tomahawk, ló pa á.
Ní ọdún yẹn kan náà, ìlòdì àwọn ará India sí ìjẹgàba àwọn aláwọ̀ funfún fọ́ yángá níbi ìpakúpa tí ó ṣẹlẹ̀ ní Wounded Knee Creek ní Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ńlá ti America. Níbẹ̀ ni àwọn ẹgbẹ́ ogun ìjọba àpapọ̀ ti fi ohun ìjà ayárarọ̀jò ọta Hotchkiss pa nǹkan bí 320 ọkùnrin, obìnrin, àti ọmọdé Sioux, tí ń sá lọ. Àwọn jagunjagun náà dánnu pé èyí ni àwọ́n fi gbẹ̀san ikú àwọn ẹlẹgbẹ́ àwọn, Custer àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀, ní àwọn òkè tí ó dojú kọ Odò Little Bighorn. Báyìí ni ogun àti gbọ́nmisi-omi-ò-tó tí ó gbà ju 200 ọdún lọ láàárín àwọn akóguntini abulẹ̀dó America àti àwọn ẹ̀yà ìbílẹ̀ tí a kógun tì wá sí òpin.
Ṣùgbọ́n lákọ̀ọ́kọ́ ná, báwo ni àwọn Ọmọ Ìbílẹ̀ America ṣe di èyí tí ó dó sí Àríwá America? Irú ọ̀nà ìgbésí ayé wo ni wọ́n ní kí àwọn aláwọ̀ funfun tóó dé sí Àríwá America?b Kí ló ṣamọ̀nà sí ṣíṣẹ́gun wọn àti títẹ̀ wọ́n lórí ba níkẹyìn? Kí sì ni ipò àwọn ará India ní lọ́wọ́lọ́wọ́ ní orílẹ̀-èdè kan tí àwọn àtìrandíran àwọn aláṣìíkiri ará Europe ń jẹ gàba lé lórí nísinsìnyí? A óò jíròrò lórí ìbéèrè wọ̀nyí àti àwọn mìíràn nínú àwọn ọ̀rọ̀ àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kán wáá yan èdè ọ̀rọ̀ náà, “Ọmọ Ìbílẹ̀ America,” láàyò nísinsìnyí, ọ̀pọ̀ ìwé ìtọ́kasí ṣì ń lo “àwọn ará India” lọ́nà wíwọ́pọ̀. A óò máa lo èdè ọ̀rọ̀ méjèèjì lọ́nà tí wọn yóò máa gbapò fúnra wọn. “Àwọn ará India” ni àṣìsọ orúkọ tí Columbus sọ àwọn ọmọ ìbílẹ̀ náà, nítorí tí ó ró pé òún ti dé India nígbà tí ó gúnlẹ̀ sí ibi tí a mọ̀ sí West Indies nísinsìnyí.
b A ń jíròrò lórí àwọn Amerind ti Àríwá nìkan nínú àwọn ọ̀rọ̀ àpilẹ̀kọ wọ̀nyí. A óò jíròrò lórí àwọn Amerind ti Mexico, Àárín Gbùngbùn America, àti Gúúsù America—àwọn Aztec, Maya, Inca, Olmec, àti àwọn mìíràn—nínú àwọn ìtẹ̀jáde ìwé ìròyìn yìí lọ́jọ́ iwájú.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]
Sísin àwọn òkú ní Wounded Knee
[Credit Line]
Montana Historical Society