ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 9/8 ojú ìwé 12-16
  • Kí Ni Ìrètí Wọn Fún Ọjọ́ Ọ̀la?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ni Ìrètí Wọn Fún Ọjọ́ Ọ̀la?
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìmọ̀ Ẹ̀kọ́ Ìbílẹ̀ America
  • Àwọn Ilẹ̀ Mímọ́ Ọlọ́wọ̀
  • Àwọn Ìpèníjà Òde Òní
  • Bíbá Oògùn Líle àti Ọtí Líle Jìjàkadì
  • Àwọn Ilé Tẹ́tẹ́ àti Tẹ́tẹ́ Títa Ni Ojútùú Náà Bí?
  • Kí Ni Ìrèti Wọn fún Ọjọ́ Ọ̀la?
  • Ìgbésí Ayé Nínú Ayé Tuntun ti Ìṣọ̀kan àti Ìdájọ́ Òdodo
  • Orúkọ Ọlọ́run Ló Yí Ìgbésí Ayé Mi Padà!
    Jí!—2001
  • Bí Wọ́n Ṣe Pàdánù Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Wọn
    Jí!—1996
  • Àwọn Àmẹ́ríńdíà Àti Bíbélì
    Jí!—1999
  • Orin, Oògùn Líle, àti Ìmutípara Ló Jàrábà Ìgbésí Ayé Mi Tẹ́lẹ̀ Rí
    Jí!—1997
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 9/8 ojú ìwé 12-16

Kí Ni Ìrètí Wọn Fún Ọjọ́ Ọ̀la?

NÍNÚ ìfọ̀rọ̀ wáni lẹ́nu wò kan pẹ̀lu Jí!, olóyè atúnlùútò àwọn Cheyenne, Lawrence Hart, sọ pé, ọ̀kan lára àwọn ìṣòro tí ń kojú àwọn ará India “ni pé a ń kojú agbára ìyáṣàpadà àti agbára ìgbàmọ́ra. Fún àpẹẹrẹ, a ń pàdánù èdè wa. Nígbà kan, èyí jẹ́ ìlànà àmọ̀ọ́mọ̀ṣe ìjọba. Wọ́n sapá gidigidi láti fi ẹ̀kọ́ ìwé ‘là wá lójú.’ A rán wa lọ sílé ẹ̀kọ́ oníbùgbé, a sì fòfin dè wá láti má ṣe sọ èdè ìbílẹ wa.” Sandra Kinlacheeny rántí pé: “Bí mo bá sọ ède Navajo ní ilé ẹ̀kọ́ oníbùgbé tí mo lọ, àwọn olùkọ́ máa ń fi ọṣẹ fọ ẹnu mi!”

Olóyè Hart ń bá ọ̀rọ̀ lọ pé: “Kókó afúnni níṣìírí kan ní lọ́ọ́lọ́ọ́ ni pé àwọn ẹ̀yà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ti ń nímọ̀lára ọ̀tun. Wọ́n ń mọ̀ pé èdè àwọn yóò pa run bí àwọn kò bá ṣe ohun kan láti dáàbò bò wọ́n.”

Ènìyàn mẹ́wàá péré ló kù tí ń sọ Karuk, èdè ọ̀kan lára àwọn ẹ̀yà California. Ní January 1996, Red Thunder Cloud (Carlos Westez), ará India tí ó sọ ède Catawba kẹ́yìn, kú ní ẹni ọdún 76. Kò sí ẹni tí ó lè bá sọ èdè yẹn fún ọ̀pọ̀ ọdún.

Ní àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àwọn ibi ìyàsọ́tọ̀ àwọn Navajo àti Hopi ní Arizona, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ẹni gbogbo ní ń sọ ède Navajo tàbí Hopi àti Gẹ̀ẹ́sì. Kódà, àwọn Ẹlẹ́rìí tí kì í ṣe ará India ń kọ́ ède Navajo. Ó yẹ kí àwọn Ẹlẹ́rìí gbọ́ Navajo kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọn, níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ àwọn Navajo ti gbọ́ èdè ìbílẹ wọn nìkan yanjú. Èdè Hopi àti Navajo ṣì wà dáadáa, a sì ń fún àwọn ọ̀dọ́ níṣìírí láti máa sọ wọ́n nílé ẹ̀kọ́.

Ìmọ̀ Ẹ̀kọ́ Ìbílẹ̀ America

Mọ́kàndínlọ́gbọ̀n ni kọ́lẹ́ẹ̀jì àwọn ará India ní United States, wọ́n sì ní 16,000 akẹ́kọ̀ọ́. Wọ́n ṣí àkọ́kọ́ ní Arizona, ní 1968. Ọ̀mọ̀wé David Gipp, ti Ìgbìmọ̀ Ẹ̀kọ́ Gíga Àwọn Amerind, sọ pé: “Èyí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìgbòkègbodò kíkàmàmà tí ó kan àwọn ará India, ẹ̀tọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ lábẹ́ àwọn ipò tí àwa fúnra wá pinnu.” Ní Yunifásítì Sinte Gleska, èdè Lakota jẹ́ àìgbọdọ̀mákọ̀ọ́.

Gẹ́gẹ́ bí Ron McNeil (Hunkpapa Lakota), ààrẹ Ìgbìmọ̀ Kọ́lẹ́ẹ̀jì Àwọn Amerind, ṣe sọ, àwọn aláìríṣẹ́ṣe Ọmọ Ìbílẹ̀ America wà láàárín ìpín 50 nínú ọgọ́rùn-ún sí ìpín 85 nínú ọgọ́rùn-ún, àwọn ará Íńdíà sì ní ìfojúsọ́nà ìgbésí ayé tí ó kéré jù lọ àti ìwọ̀n àtọ̀gbẹ, ikọ́ ẹ̀gbẹ, àti ìmukúmu ọtí, tí ó pọ̀ ju èyí tí ẹ̀yà èyíkéyìí ní United States ní lọ. Ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó sàn jù wulẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìgbésẹ̀ tí ó lè ṣàǹfààní.

Àwọn Ilẹ̀ Mímọ́ Ọlọ́wọ̀

Ọ̀pọ̀ Ọmọ Ìbílẹ̀ America ń wo ilẹ̀ àjogúnbá wọn bí ilẹ̀ mímọ́ ọlọ́wọ̀. Gẹ́gẹ́ bí White Thunder ṣe sọ fún aṣòfin àgbà kan pé: “Ilẹ̀ wa níhìn-ín ni ohun tí ó ṣọ̀wọ́n sí wa jù lọ lórí ilẹ̀ ayé.” Nígbà tí wọ́n bá ń ṣe àdéhùn àti ìfohùnṣọ̀kan, àwọn ará India sábà máa ń lérò pé ìwọ̀nyí wà fún bí àwọn aláwọ̀ funfun yóò ṣe lo ilẹ̀ àwọn, kì í ṣe fún gbígbà á àti níni ín pátápátá. Àwọn ẹ̀yà Sioux ti India pàdánù ilẹ̀ ṣíṣeyebíye ní Black Hills ti Dakota ní àwọn ọdún 1870, nígbà tí àwọn awakùsá ya dé, tí wọ́n ń wá wúrà. Ní 1980, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ United States pàṣẹ pé kí ìjọba United States san nǹkan bíi mílíọ̀nù 105 dọ́là bí owó gbà máà bínú fún àwọn ẹ̀yà Sioux mẹ́jọ. Di báyìí, àwọn ẹ̀yà náà ti kọ̀ láti gba owó náà—ilẹ̀ mímọ́ ọlọ́wọ̀ wọn, ilẹ̀ Black Hills tí ó wà ní Gúúsù Dakota, ni wọ́n fẹ́ẹ́ gbà padà.

Ọ̀pọ̀ àwọn ará India, ẹ̀yà Sioux, ni kò tẹ́ lọ́rùn láti máa rí ojú àwọn ààrẹ aláwọ̀ funfun tí wọ́n ń yá ère wọn sí Òkè Ńlá Rushmore, tí ó wà ní Black Hills. Lórí òkè ńlá kan nítòsí, àwọn agbẹ́gilére ń yá ère kan tí ó tilẹ̀ tóbi ju èyí. Ó jẹ́ ère Crazy Horse, ti ẹ̀yà Oglala, tí ó jẹ́ olórí ogun àwọn Sioux. Wọn yóò parí ère náà títí June, 1998.

Àwọn Ìpèníjà Òde Òní

Láti máa gbé ayé nìṣó nínú ayé òde òní, àwọn Ọmọ Ìbílẹ̀ America ní láti yí padà ní onírúurú ọ̀nà. Ọ̀pọ̀ lára wọ́n ti ní ìmọ̀ ẹ̀kọ́ gidi, wọ́n sì ti lọ kẹ́kọ̀ọ́ ní kọ́lẹ́ẹ̀jì, wọ́n ní agbára láti ṣe nǹkan tí ó wúlò ní àyíká ẹ̀yà wọn. Àpẹẹrẹ kan ni ti asọ̀rọ̀jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, Burton McKerchie, ti ẹ̀yà Chippewa láti Michigan. Ó ti ṣe àwọn fíìmù fún Ilé Iṣẹ́ Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ Ará Ìlú, ó sì ń ṣiṣẹ́ ní ilé ẹ̀kọ́ gíga kan ní Agbègbè Ìyàsọ́tọ̀ àwọn Hopi ní Arizona, níbi tí ó ti ń bójú tó àwọn àkókò ìjókòó ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ń lo fídíò ní kọ́lẹ́ẹ̀jì jákèjádò ìpínlẹ̀ náà. Àpẹẹrẹ mìíràn ni ti Ray Halbritter, aṣíwájú ẹ̀yà Oneida, tí ó kẹ́kọ̀ọ́ jáde ní Harvard.

Nígbà tí Arlene Young Hatfield ń kọ̀wé nínú ìwé agbéròyìnjáde Navajo Times, ó sọ pé bí àwọn ọ̀dọ́ ẹ̀yà Navajo ṣe ń dàgbà, wọn kò fojú winá tàbí pàdánù ohunkóhun bí àwọn òbí àti òbí wọn àgbá ti ṣe. Ó kọ̀wé pé: “Nítorí àwọn ohun amáyédẹrùn [ìgbàlódé], wọn kò fìgbà kankan rí ṣẹ́gi tàbí lagi, pọnmi, tàbí bójú tó àgùntàn bí àwọn baba ńlá wọ́n ti ṣe. Wọn kì í kó ipa kan láti gbọ́ bùkátà ìdílé bí àwọn ọmọdé ti ń ṣe lọ́jọ́ ọjọ́un.” Ó parí ọ̀rọ̀ pé: “A kò lè sá fún ọ̀pọ̀ ìṣòro ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà tí yóò nípa lórí àwọn ọmọ wa láìṣeé yẹ̀ sílẹ̀. A kò lè dá yọ ìdílé wa, tàbí agbègbè ìyàsọ́tọ̀ wa kúrò lára àgbáyé, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì lè padà sí ìgbésí ayé àwọn baba ńlá wa.”

Ibi tí ìpèníjà wà fún àwọn Ọmọ Ìbílẹ̀ America nìyẹn—ọ̀nà tí wọn yóò fi rọ̀ mọ́ àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àti ohun ìníyelórí aláìlẹ́gbẹ́ ti ẹ̀yà wọn, kí wọ́n sì máa mú ara wọn bá ìgbà mu nígbà kan náà, pẹ̀lú ohun tí ń lọ láyé òde ẹ̀yà wọn tí yára kánkán yí padà.

Bíbá Oògùn Líle àti Ọtí Líle Jìjàkadì

Títí di òní, ìmukúmu ọtí ń ṣèpalára fún àwùjọ àwọn Ọmọ Ìbílẹ̀ America. Nínú ìfọ̀rọ̀ wáni lẹ́nu wò kan pẹ̀lú Jí!, Dókítà Lorraine Lorch, tí ó ti ṣiṣẹ́ bí oníṣègùn àrùn àwọn ọmọdé àti gbogbo àrùn láàárín àwọn Hopi àti Navajo fún ọdún 12, sọ pé: “Ìmukúmu ọtí jẹ́ ìṣòro ńlá kan láàárín tọkùnrin tobìnrin bákan náà. Àwọn abarapá ń jìyà ìsúnkì ẹ̀dọ̀, ikú òjijì, ìpara-ẹni, àti ìpànìyàn. Ó bani nínú jẹ́ pé a ń yan ìmukúmu ọtí láàyò ju ọmọ, alábàáṣègbéyàwó, àní Ọlọ́run pàápàá lọ. Ẹ̀rín ń yí padà di omijé, ìwà pẹ̀lẹ́ ń di ìwà ipá.” Ó fi kún un pé: “Kódà, a ti ń fi ìmùtípara àti àwọn ọ̀rọ̀ àlùfààṣá ba àwọn ayẹyẹ tí àwọn Navajo àti Hopi kà sí mímọ́ ọlọ́wọ̀ nígbà kan rí jẹ́ báyìí. Ọtí líle ń ja àwọn ènìyàn dáadáa wọ̀nyí lólè ìlera wọn, ìlọ́gbọ́nlóye wọn, ìhùmọ wọn, àti àkópọ̀ ìwa wọn tòótọ́.”

Philmer Bluehouse, apẹtùsíjà kan ní Ẹ̀ka Ìdájọ́ ẹ̀yà Navajo, ní Window Rock, Arizona, fi ọ̀rọ̀ dídùn gbé láabi jáde nígbà tí ó pe ìlòkulò oògùn àti ọtí líle ní “dídá egbòogi lò fúnra ẹni.” Ìlòkulò yìí ni wọ́n fi ń pa ìbànújẹ́, tí wọ́n sì fi ń yẹ òkodoro òtítọ́ ìgbésí ayé àìníṣẹ́ àti ti àìní ète pàtó kan sílẹ̀.

Bí ó ti wù kí ó rí, ọ̀pọ̀ Ọmọ Ìbílẹ̀ America ti ṣàṣeyọrí nínú ìjà lòdì sí “èṣù” ọtí líle tí àwọn aláwọ̀ funfún kó wáá bá wọn, wọ́n sì ti tiraka láti ṣẹ́gun oògùn líle. Àpẹẹrẹ méjì ni ti Clyde àti Henrietta Abrahamson, láti Agbègbè Ìyàsọ́tọ̀ Àwọn Ará India ti Ẹ̀ya Spokane ní Ìpínlẹ̀ Washington. Clyde síngbọnlẹ̀, ó ní irun àti ojú dúdú. Ó ṣàlàyé fún Jí! pé:

“A ti lo apá púpọ̀ jù lọ nínú ìgbésí ayé wa ní agbègbè ìyàsọ́tọ̀, kí a tóó wá sí kọ́lẹ́ẹ̀jì ní ìlú ńlá Spokane. A kò fẹ́ ọ̀nà ìgbésí ayé wa, tí ó ní ọtí líle àti oògùn líle nínú. Gbogbo irú ọ̀nà ìgbésí ayé tí a mọ̀ nìyí. Bí a ti ń dàgbà ni a ń kórìíra àwọn nǹkan méjì wọ̀nyí, nítorí àwọn ìṣòro tí a ti rí tí wọ́n ń fà nínú ìdílé.

“Nígbà náà ni a pàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. À kò gbọ́ nípa wọn rí kí a tóó lọ sí ìlú ńlá. Ìtẹ̀síwájú wa kò mọ́yán lórí. Bóyá nítorí pé a kò fọkàn tán àwọn ènìyàn tí a kò mọ̀, ní pàtàkì, àwọn aláwọ̀ funfun. A lo nǹkan bí ọdún mẹ́ta lẹ́nu ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ìdákúrekú. Àṣà tí ó ṣòro fún mi jù lọ láti jù sílẹ̀ ni igbó mímu. Mo ti ń mu ún láti ọmọ ọdún 14, mo sì ti di ọmọ ọdún 25 kí n tóó gbìyànjú láti ṣíwọ́. Mo máa ń gbà á pé ní apá púpọ̀ jù lọ nínú ìgbà ìbàlágà mi. Ní 1986, mo ka àpilẹ̀kọ kan nínú ìtẹ̀jáde Jí!, January 22 (Gẹ̀ẹ́sì), tí àkọlé rẹ̀ jẹ́, “Ẹni Gbogbo Ń Mugbó—Èmi Ò Ṣe Gbọdọ̀ Mu Ún?” Ó mú mi ronú lórí bí ó ṣe jẹ́ ìwa wèrè tó láti máa mugbó—ní pàtàkì, lẹ́yìn tí mo ka ìwé Òwe 1:22, tí ó wí pé: ‘Yóò ti pẹ́ tó, ẹ̀yin aláìmọ̀kan, tí ẹ̀yin ó fi máa fẹ́ àìmọ̀kan? àti tí àwọn ẹlẹ́gàn yóò fi máa ṣe inú dídùn nínú ẹ̀gan wọn, àti tí àwọn aṣiwèrè yóò fi máa kórìíra ìmọ̀?’

“Mo ṣíwọ́ àṣà náà, nígbà tí ó sì di ìgbà ìrúwé ọdún 1986, èmi àti Henrietta ṣègbéyàwó. A ṣe batisí ní November 1986. Ní 1993, mo di alàgbà nínú ìjọ. Àwọn ọmọbìnrin wa méjèèjí ṣe batisí gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí ní 1994.”

Àwọn Ilé Tẹ́tẹ́ àti Tẹ́tẹ́ Títa Ni Ojútùú Náà Bí?

Kò sí tẹ́tẹ́ títa tí ará India kankan ń darí ní United States ní 1984. Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde The Washington Post ṣe sọ, lọ́dún yìí, 200 ẹ̀yà ti ní 220 ilé iṣẹ́ tẹ́tẹ́ ní ìpínlẹ̀ 24. Ìyàtọ̀ agbàfiyèsí ni ti àwọn Navajo àti àwọn Hopi, tí wọ́n ti gbéjà ko ìdẹwò náà títí di báyìí. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ àwọn ilé tẹ́tẹ́ àti gbọ̀ngan tẹ́tẹ́ bingo ni yóò ṣínà ọlà fún àwọn tí ń gbé àwọn agbègbè ìyàsọ́tọ̀, tí yóò sì pèsè iṣẹ́ púpọ̀ sí i fún wọn bí? Philmer Bluehouse sọ fún Jí! pé: “Idà olójú méjì ni tẹ́tẹ́ títa. Ìbéèrè náà ni pé, Yóò ha ṣe àwọn ènìyàn láǹfààní ju bí yóò ṣe ṣe wọ́n níbi lọ bí?” Ìròyìn kán sọ pé àwọn ilé tẹ́tẹ́ àwọn ará India ti pèsè 140,000 iṣẹ́ jákèjádò orílẹ̀-èdè, ṣùgbọ́n, ó tọ́ka sí i pé, kìkì ìpín 15 nínú ọgọ́rùn-ún lára ìwọ̀nyí ni àwọn ará India ń ṣe.

Olóyè Hart ti ẹ̀yà Cheyenne sọ ojú ìwòye rẹ̀ fún Jí! lóri bí àwọn ilé tẹ́tẹ́ àti tẹ́tẹ́ títa ṣe ń nípa lórí àwọn agbègbè ìyàsọ́tọ̀. Ó sọ pé: “Ọ̀nà méjì ni ìmọ̀lára mi pín sí. Ohun rere kan ṣoṣo tí ó wà ni pé, ó ń pèsè iṣẹ́ àti owó àpawọlé fún àwọn ẹ̀yà náà. Ní ọ̀nà kejì, mo ti kíyè sí i pé ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn oníbàárà náà jẹ́ àwọn ènìyàn wa fúnra wa. Tẹ́tẹ́ bingo ti wọ àwọn kan tí mo mọ̀ lẹ́wù, wọ́n sì máa ń tètè kúrò nílé láti lọ síbẹ̀, àní ṣáájú kí àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ tóó darí délé. Àwọn ọmọ wọ̀nyí wáá di adálégbé títí di ìgbà tí àwọn òbi wọ́n bá darí dé láti ibi tí wọ́n ti lọ ta tẹ́tẹ́ bingo.

“Ìṣòro pàtàkì náà ni pé àwọn ìdílé ń rò pé àwọn yóò jẹ tẹ́tẹ́, yóò sì fi kún owó àpawọlé àwọn. Lọ́pọ̀ ìgbà, wọn kì í jẹ; wọ́n ń pàdánù. Mo ti ń rí wọn tí wọn ń ná owó tí wọ́n ti yà sọ́tọ̀ láti fi ra oúnjẹ tàbí aṣọ àwọn ọmọ.”

Kí Ni Ìrèti Wọn fún Ọjọ́ Ọ̀la?

Tom Bahti ṣàlàyé pé ìhà méjì ló wà fún jíjíròrò ọjọ́ ọ̀la àwọn ẹ̀yà ìhà Ìlà Oòrun Gúúsù. “Èkíní sọ àsọtẹ́lẹ̀ dájú ṣáká pé àwọn àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àbáláyé yóò pa rẹ́ mọ́ ipa ọ̀nà ìgbésí ayé ará America. Èkejì kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe kedere . . . Ó ń yọ́ ọ̀rọ̀ sọ nípa ìgbésẹ̀ ìyáṣàpadà, tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìdàpọ̀ àfìrònúṣe ti ‘apá dídára jù ọ̀nà àṣà àbáláyé àti apá dídára jù ọ̀nà àṣà tuntun,’ nǹkan bí ìkásẹ̀nílẹ̀ oníyebíye ti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ nínú èyí tí ará India lè máa bá a lọ gẹ́gẹ́ bí aláṣà àtijọ́ lọ́nà títẹ́ni lọ́rùn nínú iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, ajojúnígbèsè nínú ìsin rẹ̀ àti ọlọ́gbọ́n nínú ọgbọ́n èrò orí rẹ̀—ṣùgbọ́n, kí ó jẹ́ afòyebánilò síbẹ̀, nínú àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú wa (àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ [ti àwọn aláwọ̀ funfun] lílọ́lá jù), láti máa ní ojú ìwòye kan náà pẹ̀lú wa.”

Bahti wáá béèrè ìbéèrè kan. “Ìyípadà kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀, ṣùgbọ́n ta ni yóò yí pada, fún ète wo si ni? . . . A [aláwọ̀ funfun] ní àṣà amúnibínú kan, ti kíka gbogbo àwọn ènìyàn míràn sí aláìlajú ará America lásán. A gbà pé ọ̀nà ìgbésí ayé wọ́n gbọ́dọ̀ ṣàìtẹ́ wọn lọ́rùn, kí wọ́n sì máa yán hànhàn láti gbé ìgbésí ayé àti láti máa ronú bí àwá ti ń ṣe.”

Ó ń bá ọ̀rọ̀ lọ pé: “Ohun kán dájú—ìtàn àwọn Amerind kò ì parí, ṣùgbọ́n, a kò tí ì lè pinnu bí yóò ṣe parí tàbí bóyá yóò parí. Àkókò ṣì wà, bóyá, láti bẹ̀rẹ̀ sí í ronú lórí àwọn àwùjọ ará India yòó kù gẹ́gẹ́ bí orísun àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ ṣíṣeyebíye kàkà kí a máa wò wọ́n bí ìṣòro ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà tí ń pinni lẹ́mìí.”

Ìgbésí Ayé Nínú Ayé Tuntun ti Ìṣọ̀kan àti Ìdájọ́ Òdodo

Láti inú ojú ìwòye Bíbélì, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ ohun tí ọjọ́ ọ̀la lè jẹ́ fún àwọn Ọmọ Ìbílẹ̀ America àti fún àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹ̀yà, àti èdè. Jèhófà Ọlọ́run ti ṣèlérí láti dá “ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun.”—Aísáyà 65:17; Pétérù Kejì 3:13; Ìṣípayá 21:1, 3, 4.

Ìlérí yìí kò túmọ̀ sí pílánẹ́ẹ̀tì tuntun. Gẹ́gẹ́ bí àwọn Ọmọ Ìbílẹ̀ America ti mọ̀ dunjú, ohun ọ̀ṣọ́ iyebíye ni ilẹ̀ ayé yìí, bí a bá bójú tó o, tí a sì lò ó dáradára. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìlérí Bíbélì ń tọ́ka sí ìṣàkóso tuntun ti ọ̀run kan láti rọ́pò àwọn ìjọba akóninífà ti ẹ̀dá ènìyàn. Ilẹ̀ ayé yóò yí padà sí párádísè pẹ̀lú àwọn igbó, pẹ̀tẹ́lẹ̀, odò, àti àwọn ohun alààyè tí a kò fi dọ́sìn. Gbogbo ènìyàn yóò nípìn-ín nínú ṣíṣàbójútó ilẹ̀ láìní ìmọtara ẹni nìkan. Ìkóninífà àti ìwọra kì yóò sí mọ́. Ọ̀pọ̀ oúnjẹ dídára àti ìgbòkègbodò tí ń gbéni ró yóò wà.

Nígbà tí a bá sì jí àwọn òkú dìde pẹ̀lú, gbogbo àìṣèdájọ́ òdodo àtijọ́ yóò ré kọjá lọ. Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn Anasazi (“àwọn ẹni ìgbàanì” ní èdè Navajo) pàápàá, àwọn baba ńlá àwọn ará India tí ń sọ èdè Pueblo, tí ń gbé Arizona àti New Mexico, yóò padà wá láti ní àǹfààní ìyè àìnípẹ̀kun níhìn-ín lórí ilẹ̀ ayé tí a mú bọ̀ sípò. Àwọn aṣáájú gbígbajúmọ̀ nínú ìtàn àwọn ará India pẹ̀lú—Geronimo, Sitting Bull, Crazy Horse, Tecumseh, Manuelito, àwọn Olóyè Joseph àti Seattle—àti ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn lè padà wá nínú àjíǹde tí a ṣèlérí yẹn. (Jòhánù 5:28, 29; Ìṣe 24:15) Ẹ wo irú ìfojúsọ́nà àgbàyanu tí àwọn ìlérí Ọlọ́run ń fi fún àwọn àti gbogbo àwọn tí ń jọ́sìn rẹ̀ nísinsìnyí!

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Àpẹẹrẹ irú “hogan” àwọn Navajo, tí a fi gẹdú tí a fi ilẹ̀ bò ṣe

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Àwòrán Crazy Horse, tí a fi ṣe ìpìlẹ̀ fún ère ara òkè ńlá tí ó wà lẹ́yìn

[Credit Line]

Fọ́tò tí Robb DeWall yà, pẹ̀lú ìyọ̀ọ̀da onínúure Crazy Horse Memorial Foundation (nonprofit)

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Àwọn Ẹlẹ́rìí ẹ̀ya tí wọ́n jẹ́ Hopi àti Navajo ní Keams Canyon, Arizona, ń pàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn, ibùdó ìtajà àtijọ́ kan

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Ibùgbé àwọn Anasazi láti èyí tí ó lé ní 1,000 ọdún sẹ́yìn (Mesa Verde, Colorado)

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Geronimo (1829 sí 1909), gbajúmọ̀ olóyè ẹ̀yà Apache

[Credit Line]

Pẹ̀lú ìyọ̀ọ̀da onínúure Mercaldo Archives/ Dictionary of American Portraits/Dover

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́