ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 9/8 ojú ìwé 17-18
  • Ṣíṣàyẹ̀wò Àwọn Igi Rírẹwà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣíṣàyẹ̀wò Àwọn Igi Rírẹwà
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹwà àti Ìtóbilọ́lá
  • Àwọn Ohun Ìdùnnú Tí Ó Ní Ìgbà
  • Àbójútó ti Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀
  • “Àwọn Igi Jèhófà Ní Ìtẹ́lọ́rùn”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Àwọn Igi Tó Rọ́kú
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
Jí!—1996
g96 9/8 ojú ìwé 17-18

Ṣíṣàyẹ̀wò Àwọn Igi Rírẹwà

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ BRITAIN

WESTONBIRT, abúlé kan ní agbègbè Cotswolds ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, lókìkí nítorí àwọn arboretuma (ibi ìṣọ̀gbìn) rẹ̀. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àkójọ igi àti irúgbìn tí ó tí ì pẹ́ jù lọ, tí ó fẹ̀ jù lọ, tí ó sì dára jù lọ lágbàáyé. Ẹ jẹ́ kí a wò ó fín ná.

Ẹwà àti Ìtóbilọ́lá

Hugh Angus, alábòójútó ọgbà náà sọ pé: “Kò sí ẹni tí ìmọ̀lára rẹ̀ kì í sọ kúlú nípa ẹwà, ìtóbilọ́lá, àti ògo àkójọ yìí.” Tí a bá si fi ojú iye àwọn àlejò tí ń wá síbẹ̀ léraléra wò ó, ó jọ pé òtítọ́ ló ń sọ.

Ibi ìṣọ̀gbìn igi náà ní 18,000 igi àti irúgbìn, tí ń dúró fún ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdajì 9,000 irú ọ̀wọ́ oríṣiríṣi tí ń hù ní àwọn Agbègbè Títutù lágbàáyé. Ìwé ìfinimọlẹ̀ tí a fàṣẹ sí ṣàlàyé pé àwọn àlejò lè rìn fàlàlà káàkiri inú ọgbà tí ó jẹ́ 240 hẹ́kítà náà, àmọ́ láti jẹ́ kí wọ́n gbádun rẹ̀ gan-an, “a ti pín Ibi Ìṣọ̀gbìn Igi náà sí ẹ̀ka mẹ́rin, a sì dámọ̀ràn àkókò yíyẹ rẹ́gí láti bẹ ọ̀kọ̀ọ̀kan wò.” Ní àfikún, àwọn apá fífani mọ́ra pàtàkì wà, bí Ipa Ọ̀nà Ìgbà Ìwọ́wé Aláwọ̀ Mèremère, Àkójọ Cherry Ibi Gígagíga, àti Àkójọ Irú Ọ̀wọ́ Àbáláyé, tí a fi àkọlé àti àwòrán àbùdá wọn sí ara gbogbo wọn.

Àwọn Ohun Ìdùnnú Tí Ó Ní Ìgbà

Àyípoyípo ìgbà ní Àríwá Ìlàjì Ayé jẹ́ ohun ìdùnnú àdánidá. Ní ibi ìṣọ̀gbìn igi náà, ìgbà kọ̀ọ̀kan ní ohun tí ń fani mọ́ra nínu rẹ̀. Ìgbà òtútù ni àkókò tí ó dárà jù lọ láti gbádùn oríṣiríṣi àwọn igi conifer àti láti rí àwọn ìwò jíjojú ní gbèsè, ìṣemúlọ́múlọ́ lọ́nà fífani mọ́ra, àti àwọ̀ yíyani lẹ́nu àwọn igi arẹ̀dànù tí wọ́n ti wọ́wé. Lẹ́yìn náà, àwọn igi wẹ́wẹ́ àti àwọn igi tí ń yọ òdòdó nígbà ìrúwé—àwọn azalea, cherry, camellia, magnolia, àti rhododendron—ń gbé ògo wọn yọ, ìtẹ́rẹrẹ àwọn òdòdó ẹgàn sì ń fi kún ẹwà ìran náà.

A máa ń rí àwọn ewé ní ibi ìṣọ̀gbìn igi náà ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn láìsí ìdíwọ́, ṣáájú àfihàn àpéwò ohun ọ̀gbin ti ìgbà ìwọ́wé, tàbí ti ìrẹ̀dànù. Àlejò 90,000 ló rọ́ wá sí Westonbirt ní October láti wo ohun àfiṣèranwò yìí, tí ó mú un lókìkí bẹ́ẹ̀. Níhìn-ín, oríṣiríṣi igi maple ilẹ̀ Japan, pẹ̀lú àwọ̀ wọn pupa rokoṣo, ló gbàfiyèsí jù lọ níbi àfihàn náà.

Ọ̀pọ̀ lára àwọn ògbólógbòó àpẹẹrẹ oríṣi igi maple ilẹ̀ Japan láti Westonbirt lè jẹ́ ojúlówó tí a kó wọlé lákòókò Edo, ní 1603 sí 1867. Ó bani nínú jẹ́ pé kò sí àkọsílẹ̀ orúkọ àwọn oríṣi tí ó jẹ́ ògbólógbòó wọ̀nyí lédè Japan. Igi maple kò fi bẹ́ẹ̀ lókìkí mọ́ ní Japan láìpẹ́ lẹ́yìn tí a kó wọn wọ Europe, nítorí náà, a kò lè fi àwọn yòó kù lára èyí tí a kọ́kọ́ kó wọlé wéra pẹ̀lú àwọn àkójọ tó wà ní Japan tàbí níbi tí a ti ń dọ́gbìn wọn. Bí àwọn ògbólógbòó igi maple ti Japan ti ń kú lọ, bẹ́ẹ̀ ni a ń gbin àwọn igi tuntun kéékèèké sínú àkámọ́. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé igi kọ̀ọ̀kan ni ewé rẹ̀ ní ìrísí àti àwọ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Àwọn hóró èso tí a kó jọ láti inú àwọn ògbólógbòó igi maple tí a gbìn ló dàgbà di àwọn igi náà, a sì ṣà wọ́n nítorí àwọn àwọ̀ ìgbà ìwọ́wé tí wọ́n ní. Láti pèsè ààbò àti ìbòòji fún wọn, a gbin àwọn igi maple náà sáàárín àwọn igi apádò àti conifer. Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú mú ìrísí oníwúrà àti àwọ̀ ewé wá láti ọwọ́ ẹ̀yìn tí àwọn ìtànṣán oòrùn ìgbà ìwọ́wé ń gbà tànmọ́lẹ̀ sára àwọn igi maple náà.

Àbójútó ti Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀

Ibi Ìṣọ̀gbìn Igi ní Westonbirt bẹ̀rẹ̀ bí ìgbòkègbodò àfipawọ́ ara ẹni kan ní 1829, Ìgbìmọ̀ Aṣọ́gbó ní Britain sì gbà á ní 1956. Ète rẹ̀ ju pípèsè ìnàjú fún àwọn aráàlú lọ. Ní ti gidi, lájorí ète rẹ̀ jẹ́ láti mú àkójọ lọ́nà ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ tí ó bá ipò àdúgbò mu jù lọ dàgbà. Nítorí èyí, wọ́n ṣe àwọn ìwádìí nípa ìlànà ìsọdipúpọ̀, àwọn ìyọrísí rẹ̀—ìkẹ́sẹjárí àti ìjákulẹ̀—ni wọ́n sì ṣàjọpín pẹ̀lú àwọn ọgbà ọ̀gbìn mìíràn.

Westonbirt ti mú iwájú nínú ìlànà ìṣàkọsílẹ̀ lóri kọ̀m̀pútà tí ń ṣàkọsílẹ̀ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa àpẹẹrẹ oríṣi kọ̀ọ̀kan—orírun rẹ̀, ìdàgbàsókè rẹ̀ láti hóró títí yóò fi gbó, ìlera àti ìtọ́jú nítorí àrùn èyíkéyìí, àti okùnfa kíkú rẹ̀ pàápàá. Ọ̀nà ìgbàṣiṣẹ́ pàtàkì míràn ni ìsọdipúpọ̀ àwọn irú ọ̀wọ́ ṣíṣọ̀wọ́n tàbí tí ó ṣàjèjì, títí kan àwọn tí Àjọ Àgbáyé fún Ìdáàbòbò Ìṣẹ̀dá àti Ohun Àmúṣọrọ̀ Àdánidá ṣàkọsílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí èyí tí a wu léwu ní àyíká àdánidá wọn. A ń rí hóró èso mú jáde láti orísun tí ó jẹ́ ojúlówó láti dènà ṣíṣe àdàmọ̀dì, a sì pèsè àwọn àpẹẹrẹ oríṣi fún àwọn ibi ìṣọ̀gbìn igi mìíràn.

Westonbirt tún jẹ́ ibùdó ìdánilẹ́kọ̀ọ́. A ní àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún dídá àwọn igi mọ̀, àwọn ìjíròrò lóri pípa igbó run, ìrìnkiri fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́, àti àwòran sinimá ara ògiri. Ní àwọn àkókò kan láàárín ọdún, àwọn ìjíròrò àfàwòránṣe ń wà lójoojúmọ́ fún àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ tí ń ṣèbẹ̀wò.

Bí a ti ń fi ibi ìṣọ̀gbìn igi náà sílẹ̀ pẹ̀lú ìlọ́ra, tí a sì jèrè ìrírí mánigbàgbé, a nímọ̀lára ìrusókè láti padà wá láti gbádùn àwọn ògo ẹwà rẹ̀ ní ìgbà mìíràn. Ṣíṣàyẹ̀wò àwọn igi rírẹwà yìí ti jẹ́ kí a túbọ̀ wà lójúfò nípa ìtóbilọ́lá wọn, títí kan ìjẹ́pàtàki wọn nínú ìṣètò ìwàláàyè orí ilẹ̀ ayé.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ọ̀rọ̀ kan tí a fà yọ láti inú ọ̀rọ̀ latin náà, arbor, tí ó túmọ̀ sí “igi.”

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Lókè: Àwọn igi “cypress” ti Lawson

Láàárín: Igi “maple” ilẹ̀ Japan

Nísàlẹ̀: Kédárì ti Lẹ́bánónì

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́