Orin, Oògùn Líle, àti Ìmutípara Ló Jàrábà Ìgbésí Ayé Mi Tẹ́lẹ̀ Rí
ÀWỌN òbí mi jẹ́ Ọmọ Ìbílẹ̀ America. Bàbá mi, tí ó kú ní ọdún mẹ́rin sẹ́yìn, jẹ́ ẹ̀yà Chippewa, láti Erékùṣù Sugar, Michigan, U.S.A. Ìyá mi, tí ó wá láti ẹkùn ìpínlẹ̀ Ontario, Kánádà, jẹ́ ti ẹ̀yà Ottawa àti Ojibwa ti àwọn orílẹ̀-èdè Íńdíà. Nídìí bàbá mi, mo jẹ́ mẹ́ńbà ará ìlú Sault Sainte Marie ti Chippewa àwọn Íńdíà. Nítorí ipa tí iṣẹ́ míṣọ́nnárì àwọn Kátólíìkì àti ilé ẹ̀kọ́ oníbọ́dà ní, wọ́n tọ́ wa dàgbà bíi Kátólíìkì, tí ó túmọ̀ sí lílọ sí Máàsì ní gbogbo ọjọ́ Sunday.
Ìgbà ọmọdé mi ní àgbègbè àdágbé àwọn Íńdíà rọrùn, ó sì kún fún ayọ̀. Ní ojú ìwòye ti ọmọdé, àwọn ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn máa ń gùn, wọ́n máa ń falẹ̀, wọ́n sì ń ní àlàáfíà. A ń gbé àgbègbè àdádó kan—a kò ní omi ẹ̀rọ, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ibi ìgbọ̀nsẹ̀ nínú ilé, a sì má ń wẹ̀ nínú adágún omi tàbí nínú ọpọ́n. Ìta ilé ni ibi ìṣiré wa. Àwọn ẹṣin, màlúù, àti àwọn ẹran ọ̀sìn míràn ni ohun ìṣiré wa. Nígbà náà, mo dàníyàn kí gbogbo ayé lè rí bẹ́ẹ̀ títí ayérayé.
Àwọn Ìpèníjà Dídàgbà
Nígbà tí mo túbọ̀ dàgbà sí i, tí mo sì lọ sí ilé ẹ̀kọ́ ìjọba, ìbẹ̀wò mi sí àgbègbè àdágbé náà kò ṣe lemọ́lemọ́ mọ́. Ilé ẹ̀kọ́, eré ìdíje, àti orin bẹ̀rẹ̀ sí í gba èyí tí ó pọ̀ jù lọ nínú àkókò mi. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́langba kan ní àwọn ọdún 1960, ẹ̀mí tí ó gbòde lákòókò náà ní ipa lórí mi. Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún 13, oògùn líle àti ọtí líle jẹ́ ohun tí kò gbẹ́yìn nínú ìgbésí ayé mi. Ẹ̀mí ọ̀tẹ̀ lòdì sí ẹgbẹ́ àwùjọ wọ́pọ̀, mo sì kórìíra gbogbo ohun tí ẹgbẹ́ àwùjọ bá gbé lárugẹ. N kò lè lóye ìdí tí àwọn ènìyàn fi ń hùwà àìláàánú sí àwọn ẹlòmíràn.
Ní àárín àkókò yí ni mo ra gìtá mi àkọ́kọ́. Ìdílé olórin ni ìdílé wa. Bàbá mi máa ń tẹ dùùrù, ó sì ń jó ijó ìfẹsẹ̀tálẹ̀, àwọn arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú sì nífẹ̀ẹ́ sí orin. Nítorí náà, nígbà tí Dádì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ bá kóra jọ pọ̀, a máa ń kọ orin jig, a sì ń jó ijó pípagbo onígun mẹ́rin títí di fẹ̀ẹ̀rẹ̀. Mo fẹ́ràn rẹ̀. Láìpẹ́, mo mọ gìtá ta, mo sì dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ olórin rọ́ọ̀kì kan. A máa ń ṣeré ní ibi ijó ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ àti níbi àwọn ìgbòkègbodò ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà míràn. Ìyẹn ṣamọ̀nà sí lílọ sí ilé ọtí àti ilé ìgbafàájì alaalẹ́, tí ó túmọ̀ sí mímu ọtí líle àti oògùn líle púpọ̀ sí i. Igbó àti methamphetamine (speed) jẹ́ apá kan ọ̀nà ìgbésí ayé mi.
Iṣẹ́ Ológun ní Vietnam
Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún 19, mo ti gbéyàwó, ìyàwó mi sì ti lóyún. Ní ọjọ́ orí yẹn kan náà, mo forúkọ sílẹ̀ nínú Ẹgbẹ́ Ológun Ojú Omi ti U.S. Gbogbo rẹ̀ jẹ́ pákáǹleke púpọ̀ jọjọ fún mi. Láti lè kápá rẹ̀, mo máa ń gba oògùn líle àti ọtí líle pé tọ̀sántòru.
Wọ́n yàn mí sí àgọ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ìpìlẹ̀ ní Ibùdó Ẹ̀ka Ìgbanisíṣẹ́ Ológun Ojú Omi ní San Diego, California, lẹ́yìn náà, wọ́n yàn mí síbi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ gíga ológun orí ilẹ̀ ní Àgọ́ Pendleton, California. Wọ́n dá mi lẹ́kọ̀ọ́ gẹ́gẹ́ bí amojú-ẹ̀rọ ìfìsọfúnni-ránṣẹ́ lójú ogun. Èyí jẹ́ ní ìparí ọdún 1969. Ní báyìí, ojúlówó ìdánrawò yóò dé—iṣẹ́ ológun ní Vietnam. Nípa bẹ́ẹ̀, ní ọmọ ọdún 19, ní oṣù díẹ̀ lẹ́yìn tí mo jáde ilé ẹ̀kọ́ gíga, mo bá ara mi lórí ilẹ̀ pupa Vietnam. Bí ó ti rí nípa púpọ̀ lára àwọn Ọmọ Ìbílẹ̀ America míràn, ìfọkànsìn orílẹ̀-èdè ẹni ti sún mi láti ṣiṣẹ́ ológun láìka ìwà àìsídàájọ́ òdodo tí ẹgbẹ́ àwùjọ ti hù sí wa gẹ́gẹ́ bíi mẹ́ńbà àwùjọ tí kò tó nǹkan.
Ibi tí wọ́n kọ́kọ́ yàn mí sí Ẹ̀ka Ológun Òfuurufú Kìíní, tí ó wà ní òde Da Nang. Nǹkan bí 50 ọkùnrin—àwọn ọmọkùnrin kéékèèké, ní gidi—ni wọ́n ń bójú tó ìgbékalẹ̀ ìfìsọfúnni-ránṣẹ́ fún ọgbà ológun náà. Àgbègbè tí ó wà láti DMZ (àyíká tí a fòfin dè fún ìlò ológun) láàárín Àríwá Vietnam àti Gúúsù Vietnam dé nǹkan bí 80 kìlómítà sí ìsàlẹ̀ Da Nang wà níkàáwọ́ wa.
Àwọn olùwá-ibi-ìsádi ń rọ́ wá sí Da Nang, a sì ń dá àwọn abúlé sílẹ̀ láyìíká. Ọ̀pọ̀ ilé ìtọ́jú àwọn ọmọ òrukàn sì wà pẹ̀lú. Rírí tí mo rí àwọn ọmọ kéékèèké, tí ọ̀pọ̀ lára wọn ti di aláàbọ̀-ara, ní ipa jíjinlẹ̀ lórí mi. Ó yà mí lẹ́nu pé gbogbo wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ọmọdébìnrin tàbí àwọn ọmọdékùnrin kéékèèké. Kò pẹ́ tí mo mọ ohun tí ó fà á. Àwọn ọmọdékùnrin láti ọdún 11 sókè ń jagun. Nígbà tó yá, mo pàdé ọ̀dọ́ jagunjagun ọmọ Vietnam kan, mo sì bi í léèrè ọjọ́ orí rẹ̀. Ó ní “ọmọ ọdún 14” ni òun. Ó ti pé ọdún mẹ́ta tí ó ti wà lójú ogun! Èyí dà mí lọ́kàn rú. Ó mú mi rántí àbúrò mi ọkùnrin ọlọ́dún 14, yàtọ̀ sí pé ọkàn-ìfẹ́ àbúrò mi kì í ṣe pípànìyàn bí kò ṣe Ìdíje Ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ Ọmọdé nínú bọ́ọ̀lù àfigigbá.
Láàárín ìgbà tí mo ń ṣiṣẹ́ nínú ẹgbẹ́ ológun ojú omi, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ní àwọn ìbéèrè tí ń fẹ́ ìdáhùn. Ní alẹ́ ọjọ́ kan, mo lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì tó wà nínú ọgbà wa. Àlùfáà Kátólíìkì náà ṣe ìwàásù nípa Jésù, àlàáfíà, àti ìfẹ́! Mo fẹ́ láti kígbe. Ìwàásù rẹ̀ yàtọ̀ pátápátá sí gbogbo ohun tí ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀. Lẹ́yìn ètò ìsìn náà, mo bi í léèrè ọ̀nà tí ó fi lè sọ pé òun jẹ́ Kristẹni, kí ó sì máa lọ́wọ́ nínú jíjagun yìí nígbà kan náà. Kí ni ìdáhùn rẹ̀? “Ní gidi, Ọmọ Ogun, bí a ṣe ń jagun fún Olúwa nìyí.” Mo jáde, mo sì sọ sínú pé n kò fẹ́ láti ní ohunkóhun láti ṣe pẹ̀lú ṣọ́ọ̀ṣì náà mọ́ láé.
Nígbà tí iṣẹ́ àyànfúnni ológun mi parí, mo mọ̀ pé ìrìnnàkore ló jẹ́ fún mi láti ṣì wà láàyè; àmọ́ mo ti jìyà púpọ̀ jọjọ ní ti èrò orí àti ìwà rere. Gbígbọ́ nípa ogun àti ikú, rírí wọn, àti gbígbóòórùn wọn lójoojúmọ́ fi ohun àtẹ̀mọ́nilọ́kàn jíjinlẹ̀ kan sí èrò inú àti ọkàn àyà ọmọdé tí mo ní. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo rẹ̀ ṣẹlẹ̀ ní ohun tí ó ti lé ní ọdún 25 sẹ́yìn, mo ń rántí bíi pé àná ni.
Ìlàkàkà Láti Mú Ara Bá Ìgbésí Ayé Aráàlú Mu
Nígbà tí mo pa dà délé, mo bẹ̀rẹ̀ sí í pọkàn pọ̀ sórí iṣẹ́ orin mi. Ìgbésí ayé mi rí rúdurùdu—mo ti gbéyàwó, mo sì ti bímọ kan, síbẹ̀ mo ń lo oògùn líle àti ọtí líle lọ́pọ̀ rẹpẹtẹ. Ipò ìbátan mi pẹ̀lú ìyàwó mi kò fararọ, ó sì yọrí sí ìkọ̀sílẹ̀. Bóyá àkókò yẹn ni mo sorí kọ́ jù lọ nínú ìgbésí ayé mi. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í ya ara mi sọ́tọ̀, mo sì ń wá ìtura níta, ní pípẹja trout ní àwọn àgbègbè àdádó Minnesota àti Upper Michigan.
Ní 1974, mo kó lọ sí Nashville, Tennessee, pẹ̀lú ète títẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ orin mi gẹ́gẹ́ bí atagìtá àti akọrin. Mo kọrin ní ọ̀pọ̀ ilé ìgbafàájì alaalẹ́, pẹ̀lú èrò àtidi olókìkí nínú orin kíkọ nígbà gbogbo. Ṣùgbọ́n ìpèníjà líle koko ni—àwọn atagìtá tí wọ́n ní ẹ̀bùn àbínibí pọ̀, tí gbogbo wọn ń gbìyànjú láti di olókìkí akọrin.
Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí nǹkan bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹnuure fún mi, tí mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í róye dídi gbajúgbajà amọsẹ́dunjú, ohun kan tí ó gbò mí jìgìjìgì ṣẹlẹ̀.
Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tí Ó Léwu
Mo lọ kí ojúlùmọ̀ mi àtijọ́ kan tí a ti jùmọ̀ lọ́wọ́ nínú oògùn líle rí. Ó fi ìbọn ìléwọ́ 12-gauge kí mi káàbọ̀ lẹ́nu ilẹ̀kùn. Wọ́n fi amọ̀ gbá ara rẹ̀ pọ̀ lápá kan, wọ́n sì fi wáyà so ẹnu rẹ̀ pọ̀ nítorí pé párì rẹ̀ fà ya. Bí ó ti ń fi eyín rẹ̀ tí ó wà pọ̀ pinpin sọ̀rọ̀, ó sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún mi. Láìjẹ́ pé mo mọ̀, ó ti kó wọnú ẹgbẹ́ olówò oògùn apanilọ́bọlọ̀ kan tí kò bófin mu ní Nashville, ìwọ̀n kokéènì púpọ̀ kan sì ti pòórá. Àwọn ògbóǹtarìgì nínú oògùn líle náà fẹ̀sùn kàn án. Wọ́n rán àwọn afipámúni-jẹ́wọ́, tàbí àwọn jàgídíjàgan, láti lọ lù ú. Wọ́n ní kí ó dá kokéènì náà pa dà tàbí kí ó san 20,000 dọ́là tí a fi lè rí i rà lọ́jà fàyàwọ́. Kì í ṣe pé wọ́n halẹ̀ mọ́ ọn nìkan ni, ìyàwó àti ọmọ rẹ̀ wà nínú ewu. Ó wí fún mi pé ó léwu tí wọ́n bá rí mi pẹ̀lú òun àti pé mo lè máa lọ. Mo lóye ohun tí ó ní lọ́kàn, mo sì kúrò níbẹ̀.
Ohun tó ṣẹlẹ̀ yí mú mi bẹ̀rù díẹ̀ fún ẹ̀mí mi. Láìmọ̀, mo ti di apá kan ayé oníwà ipá. Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ènìyàn tí mo mọ̀ lágbo orin àti oògùn líle tí mo wà ni wọ́n ní ìbọn ìléwọ́. Mo ti fẹ́rẹ̀ẹ́ ra ìbọn ìléwọ́ .38 kan fún ìdáàbòbò ara mi. Mo mọ̀ pé bí mo bá ṣe ń lókìkí sí i láwùjọ àwọn olórin ni ohun tí yóò ná mi yóò ṣe pọ̀ tó. Nítorí náà, mo tipa bẹ́ẹ̀ pinnu láti fi Nashville sílẹ̀, mo sì ń wéwèé láti lọ sí Brazil láti kẹ́kọ̀ọ́ orin Latin-America.
Ọ̀pọ̀ Ìbéèrè, Ìdáhùn Díẹ̀
Láìka ìrírí òdì tí mo ti ní nínú ìsìn sí, mo ní ìfẹ́ ọkàn tí ó lágbára láti jọ́sìn Ọlọ́run. Mo sì ní àwọn ìbéèrè tí n kò tí ì rí ìdáhùn sí. Nítorí náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í wá òtítọ́ kiri. Mo lọ sí onírúurú ṣọ́ọ̀sì tí a kò forúkọ wọn sílẹ̀ bí ẹ̀ya ìsìn ṣùgbọ́n n kò ní ìtẹ́lọ́rùn síbẹ̀. Mo rántí ṣọ́ọ̀ṣì kan tí mo lọ ní Minnesota. Pásítọ̀ gé ìwàásù rẹ̀ kúrú nítorí pé ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Minnesota Vikings ń gbá bọ́ọ̀lù lọ́jọ́ náà. Ó rọ gbogbo wá láti pa dà sílé, kí a sì gbàdúrà kí ẹgbẹ́ Vikings gbégbá orókè! Mo dìde, mo sì jáde. Ìrònú tí kò jinlẹ̀ tí ó fi Ọlọ́run hàn bí ẹni tí ó fara mọ́ àwọn ìgbòkègbodò eré ìdíje aláìjámọ́-ǹkan ṣì ń bí mi nínú títí di òní yìí.
Nígbà tí mo ń ṣiṣẹ́ ní Duluth, Minnesota, ọ̀rẹ́ kan fí ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ sí ilé mi. Mo ka ìjíròrò rẹ̀ nípa Mátíù orí 24, gbogbo rẹ̀ sì jẹ́ òtítọ́. Ó mú mi ronú pé, ‘Ta ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wọ̀nyí? Ta ni Jèhófà?’ N kò rí ìdáhùn títí ó fi di 1975. Ọ̀rẹ́ kan náà yẹn fi ìwé Otitọ ti Nsinni Lọ si Iye Aiyeraiyea àti Bíbélì kan sílẹ̀ fún mi.
Lálẹ́ ọjọ́ yẹn, mo ka ìwé náà. Lópin àkórí kìíní, mo mọ̀ pé mo ti rí òtítọ́. Ńṣe ló dà bíi pé a ṣí ìbòjú kan kúrò lórí èrò inú mi. Mo ka ìwé náà tán, nígbà tí ó sì di ọjọ́ kejì, mo lọ sọ́dọ̀ Àwọn Ẹlẹ́rìí kan ní òdì kejì òpópónà ilé mi, mo sì ní kí wọ́n wá máa bá mi kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Mo pa àwọn ìwéwèé mi láti rìnrìn àjò lọ sí Brazil tì, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí àwọn ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, mo jáwọ́ nínú lílo oògùn líle àti ọtí líle pátápátá, lẹ́yìn ọdún 12, mo ṣíwọ́ nínú àwọn ohun tí mo ti sọ di bárakú. Láàárín oṣù díẹ̀, mo ti ń kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ilé dé ilé.
Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìṣòro kan wà tí mo ní láti dojú kọ. N kò ní iṣẹ́ gidi tí ó dúró lọ́wọ́ rí, èrò títẹ̀ lé ìtòlẹ́sẹẹsẹ kan dan-indan-in ń kó mi nírìíra. Nísinsìnyí, mo ní láti di ẹni tí ó ní láárí, níwọ̀n bí Debi tún ti kó wọnú ìgbésí ayé mi pa dà. Mo ti ń ròde pẹ̀lú rẹ̀ tẹ́lẹ̀; ṣùgbọ́n ó lọ sí kọ́lẹ́ẹ̀jì láti kọ́ iṣẹ́ olùkọ́ni, èmi sì fẹ́ láti di akọrin. Nísinsìnyí, òun pẹ̀lú tẹ́wọ́ gba òtítọ́ Bíbélì, ọkàn wa sì tún fà mọ́ra wa lẹ́ẹ̀kan sí i. A ṣègbéyàwó, a sì ṣèrìbọmi gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí ní Sault Sainte Marie, Ontario, Kánádà, ní 1976. Bí àkókò ti ń lọ, a bí ọmọ mẹ́rin—ọkùnrin mẹ́ta àti obìnrin kan.
Láti pèsè fún ìdílé mi, mo ṣí ilé iṣẹ́ orin kan, mo sì ń kọ́ àwọn ènìyàn ní lílu jazz àti gìtá. Mo tún ṣí ṣọ́ọ̀bù iṣẹ́ ìgbohùnsílẹ̀, mo sì máa ń lọ kọrin ní àwọn ilé ìgbafàájì alaalẹ́ tí wọ́n ti ń ta oúnjẹ alẹ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Lẹ́yìn náà, pẹ̀lú ìyàlẹ́nu, mo ní àǹfààní láti pa dà ságbo iṣẹ́ àmọ̀dunjú bí olórin onípò gíga. Ẹ̀ẹ̀mẹ́ta ni wọ́n ké sí mi láti wá ṣèrànwọ́ ní lílùlù fún àwọn gbajúgbajà òṣèré tí a ń gbohùn wọn sílẹ̀. Àǹfààní ńlá ni èyí jẹ́ fún mi—ní gidi, ẹlẹ́ẹ̀kẹta rẹ̀ láàárín ọdún méjì. Wọ́n fi àǹfààní láti lọ sí Los Angeles, California, lọ̀ mí, láti lọ lùlù fún gbajúmọ̀ ẹgbẹ́ akọrin jazz kan. Ṣùgbọ́n mo mọ̀ pé yóò túmọ̀ sí pípada sórí rírìnrìn-àjò lemọ́lemọ́, agbo ijó, àti lílọ fún ìgbohùnsílẹ̀. Mo ronú nípa ìfilọni náà fún nǹkan bí ìṣẹ́jú àáyá márùn-ún, mo sì fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ sọ pé, “Rárá, ẹ ṣeun.” Wíwulẹ̀ rántí ìgbésí ayé ìlòkulò oògùn líle, ọtí líle, àti ewu lọ́wọ́ àwọn oníjàgídíjàgan, tí mo ti gbé sẹ́yìn, mú mi mọ̀ pé kò yẹ ṣáá ni. Ìgbésí ayé mi tuntun bíi Kristẹni pẹ̀lú ìyàwó àti àwọn ọmọ mi já mọ́ ohun púpọ̀ fún mi.
Fún ọdún bíi mélòó kan, mo ṣiṣẹ́ bí amojú-ẹ̀rọ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ fún àwọn ètò nípa ìmọ̀ ẹ̀kọ́ àti àgbéjáde ìṣẹ̀lẹ̀ tí a ń fi hàn lórí tẹlifíṣọ̀n PBS (Ètò Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ fún Aráàlú). Lẹ́nu iṣẹ́ tí mo wà ní lọ́wọ́lọ́wọ́, mo ń ṣe kòkárí ìfìsọfúnni-ráńṣẹ́ fídíò fún yunifásítì kan ní ìhà àríwá Arizona láti ṣèrànwọ́ fún Àgbègbè Àdágbé Hopi.
Lọ́dọ̀ Àwọn Ènìyàn Mi
Ó ti lé ní 20 ọdún tí mo ti ṣe ìyàsímímọ́ mi sí Jèhófà Ọlọ́run. Bákan náà ni mo ti wà nínú ìgbéyàwó aláyọ̀ fún 20 ọdún. Debi, ọmọkùnrin wa Dylan, ọmọ ọdún 19, àti ọmọbìnrin wa, Leslie, ọmọ ọdún 16, wà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Ní gidi, Dylan ń ṣiṣẹ́ sìn nísinsìnyí ní ilé iṣẹ́ ìtẹ̀wé àti oko Watchtower Society ní Wallkill, New York. Àwọn ọmọ wa ọkùnrin kékeré méjèèjì, Casey, ọmọ ọdún 12, àti Marshall, ọmọ ọdún 14, ṣe ìyàsímímọ́ wọn sí Jèhófà, wọ́n sì ṣèrìbọmi láìpẹ́ yìí.
Ní ọdún mẹ́ta sẹ́yìn, a tẹ́wọ́ gba ìkésíni láti kó lọ sí ibi tí àìní fún ìwàásù Kristẹni gbé pọ̀ jù, a sì wá sí Keams Canyon, Arizona, láti ṣiṣẹ́ sìn láàárín àwọn Íńdíà ẹ̀yà Navajo àti Hopi. Alàgbà ni mí nínú ìjọ náà. Ó jẹ́ orísun ìdùnnú láti tún máa gbé láàárín àwọn Ọmọ Ìbílẹ̀ America lẹ́ẹ̀kan sí i. Nítorí ìyàtọ̀ tí ó wà láàárín àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àti ipò ìgbésí ayé níhìn-ín àti èyí tí ó wà ní ìgbèríko ìlú ńlá America kan, a lóye ohun tí ó jẹ́ láti wà lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì. Àwa mẹ́fẹ̀ẹ̀fà fi ilé ńlá atura kan sílẹ̀ láti wá máa gbé nínú ilé alágbèérìn kan tí ó túbọ̀ kéré. Ìgbésí ayé nira gan-an níhìn-ín. Ọ̀pọ̀ ilé ni kò ní ìṣètò páìpù ìgbómikiri nínú ilé, ìta nìkan ni ilé ìgbọ̀nsẹ̀ wà. Àwọn ìdílé kan máa ń rìn jìnnà gan-an nígbà òtútù láti lè rí pákó àti èédú. A máa ń fami láti inú kànga àdúgbò. Ọ̀pọ̀ ọ̀nà kò lọ́dà, a kò sì yà wọ́n sórí àwòrán ilẹ̀. Nígbà tí mo jẹ́ ọmọdé tí mo wà ní àgbègbè àdágbé, n kò ka gbogbo ipò yí sí bàbàrà. Nísinsìnyí, èmi àti ìdílé mi mọyì bí iṣẹ́ aláápọn àti agbára tí a nílò kìkì láti lè ṣe àwọn iṣẹ́ ilé tí ó pọn dandan nínú ìgbésí ayé ṣe pọ̀ tó.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará Íńdíà ní àgbègbè tí wọ́n ń ṣàkóso ní àgbègbè àdágbé náà, wọ́n ṣì ń dojú kọ irú ìṣòro kan náà tí ń pọ́n àwọn ìjọba lójú—rògbòdìyàn abẹ́lé, ojúsàájú, àìtó owó, ìkówójẹ, àti ìwà ọ̀daràn pàápàá láàárín àwọn òṣìṣẹ́ àti àwọn olórí wọn. Àwọn ará Íńdíà dojú kọ àwọn ìgbóguntì ìmukúmu ọtí, ìjoògùnyó, àìríṣẹ́ṣe, ìfìyàjẹni nínú ilé, àti àwọn ìṣòro ìgbéyàwó àti ti ìdílé. Àwọn kan ṣì ń dẹ́bi fún òyìnbó nítorí ipò tí wọ́n wà nísinsìnyí, àmọ́ irú ìṣòro kan náà ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn òyìnbó. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, láìka pákáǹleke tí ń wá láti ọ̀dọ̀ ìdílé, àwọn ọ̀rẹ́, àti àwọn mẹ́ńbà àwùjọ wọn sí, ọ̀pọ̀ lára àwọn Ọmọ Ìbílẹ̀ America ń dáhùn pa dà sí iṣẹ́ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe. Wọ́n rí i pé ìbádọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run yẹ fún iyekíye. Ọ̀pọ̀ lára wọn ń rin ìrìn 120 kìlómítà lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni. A láyọ̀ láti máa ṣàjọpín ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run pẹ̀lú àwọn Navajo àti àwọn Hopi.
Mo ń fojú sọ́nà fún ọjọ́ tí ìṣàkóso Jèhófà yóò “mú àwọn wọnnì tí ń run ayé bà jẹ́ wá sí ìrunbàjẹ́” àti ìgbà tí gbogbo aráyé onígbọràn yóò máa gbé pọ̀ ní àlàáfíà àti ìṣọ̀kan bí ìdílé kan ṣoṣo tí ó ṣọ̀kan. Nígbà náà, ìgbésí ayé yóò dà bí mo ti dàníyàn pé kí ó rí nígbà tí mo jẹ́ ọmọdékùnrin ti ẹ̀yà Chippewa kan, ní Kánádà. (Ìṣípayá 11:18; 21:1-4)—Gẹ́gẹ́ bí Burton McKerchie ṣe sọ ọ́.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ṣe jáde; a kò tẹ̀ ẹ́ jáde mọ́.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Mo ń wá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè mi nípa Ọlọ́run
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Lókè: Ìdílé mi àti, lápá òsì, ọ̀rẹ́ kan tí ó jẹ́ ẹ̀yà Navajo
Nísàlẹ̀: Ilé alágbèéká wa nítòsí Gbọ̀ngàn Ìjọba