ORÍ 31
Báwo Ni Mi Ò Ṣe Ní Ki Àṣejù Bọ Orin Gbígbọ́?
Báwo lo ṣe fẹ́ràn orin tó?
□ Kò pọn dandan.
□ Mi ò lè ṣe kí n má gbọ́ ọ.
Ìgbà wo lo máa ń gbọ́ orin?
□ Bí mo bá ń rìnrìn àjò
□ Bí mo bá ń kàwé
□ Gbogbo ìgbà
Irú orin wo lo fẹ́ràn jù, kí sì nìdí tó o fi fẹ́ràn ẹ̀? ․․․․․
Ó JỌ pé Ọlọ́run ti dá ìfẹ́ láti gbádùn orin mọ́ wa. Dandan sì lorin fáwọn ọ̀dọ́ kan. Ọmọ ọdún mọ́kànlélógún [21] kan tó ń jẹ́ Amber sọ pé: “Mo fẹ́ràn ẹ̀ ju oúnjẹ lọ. Rédíò mi ò dákẹ́ orin kíkọ rí kódà kó jẹ́ pé ńṣe ni mò ń túnlé ṣe, tí mò ń dáná, tí wọ́n rán mi níṣẹ́ tàbí tí mò ń kàwé.”
Ó ṣeé ṣe káwọn ìlànà kan wà táwọn èèyàn máa ń tẹ̀ lé láti mọ irú ohùn tó máa bá orin kan mu, àmọ́ orin fúnra ẹ̀ kọjá ìrònú ẹ̀dá, ó sì máa ń nípa lórí bí nǹkan ṣe ń rí lára èèyàn. Bó ṣe jẹ́ pé ‘ọ̀rọ̀ tó bọ́ sí àkókò dára,’ bẹ́ẹ̀ náà lorin tá a bá gbọ́ lásìkò rẹ̀ máa ń tuni lára! (Òwe 15:23) Ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16] kan tó ń jẹ́ Jessica sọ pé: “Nígbà míì, o lè máa rò pé kò sẹ́ni tó mọ bó ṣe ń ṣe ẹ́. Àmọ́ nígbà tí mo bá gbọ́ orin àwọn ẹgbẹ́ olórin tí mo fẹ́ràn jù, mo máa ń mọ̀ pé èmi nìkan kọ́ ló nílò ìtùnú.”
Ṣóhun Tó Yẹ Kẹ́ Ẹ Máa Jà sí Ni?
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń gbádùn orin tó o fẹ́ràn gan-an, èrò àwọn òbí ẹ lè yàtọ̀ sí tìẹ lórí ọ̀ràn náà. Ọmọkùnrin kan tí ò tíì pọ́mọ ogún [20] ọdún sọ pé: “Dádì mi á sọ pé, ‘Lọ pa kásẹ́ẹ̀tì yẹn! Ariwo yẹn ti pọ̀ jù!’” Bí wàhálà wọn bá ti sú ẹ, o lè rò pé nǹkan tí ò tó nǹkan làwọn òbí ẹ ń kà sí bàbàrà. Ọmọbìnrin kan tí ò tíì pọ́mọ ogún [20] ọdún sọ pé: “Ìgbà táwọn náà wà lọ́mọdé ńkọ́? Ṣé orin táwọn náà fẹ́ràn ò jọ ariwo létí àwọn òbí wọn ni?” Ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16] kan tó ń jẹ́ Ingred ṣàwáwí pé: “Àwọn àgbàlagbà kì í fẹ́ gbàgbé àwọn orin tó layé nígbà tí wọ́n wà lọ́dọ̀ọ́. Ó máa dáa tí wọ́n bá lè gbà pé àwa náà láwọn orin tó layé nígbà tiwa náà!”
Ingred ò kúkú parọ́. Ó ṣeé ṣe kó o mọ̀ pé látayébáyé làwọn ọmọdé àtàwọn àgbàlagbà ti máa ń jiyàn tó bá dọ̀ràn ohun tí kálukú fẹ́ràn. Àmọ́, ìyẹn ò wá sọ pé kí orin máa dájà sílẹ̀ nígbà gbogbo. Ohun tó o lè ṣe ni pé kó o wá orin kan tíwọ àtàwọn òbí ẹ fẹ́ràn. Àǹfààní ńlá ló jẹ́ fún ẹ táwọn òbí ẹ bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì. Ìdí ni pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa jẹ́ kíwọ àtàwọn òbí ẹ lè mọ irú orin tẹ́ ò gbọ́dọ̀ kọ àtèyí tó jẹ́ pé kálukú ló máa pinnu ohun tó máa ṣe. Láti ṣe bẹ́ẹ̀, o máa ní láti gbé àwọn kókó pàtàkì méjì kan yẹ̀ wò: (1) ohun tí orin tó ò ń gbọ́ dá lé lórí àti (2) iye àkókò tó o máa fi gbọ́ orin ọ̀hún. Jẹ́ ká kọ́kọ́ gbé ìbéèrè pàtàkì kan yẹ̀ wò ná.
Kí Ni Orin Náà Dá Lé Lórí?
Ńṣe ni orin dà bí oúnjẹ. Oúnjẹ tó dáa tí kò sì pọ̀ jù ló máa ń ṣara lóore. Àmọ́ kò sí ìwọ̀n téèyàn jẹ lára oúnjẹ tí kò dáa, tó máa ṣara lóore. Ó ṣeni láàánú pé orin tí ò dáa gan-an làwọn èèyàn máa ń gbádùn jù. Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Steve figbe ta, ó ní: “Kí ló tiẹ̀ dé gan-an tó fi jẹ́ pé àwọn orin tọ́rọ̀ inú wọn ò dáa làwọn olórin máa ń lu àlùjó sí.”
Bó o bá gbádùn ìlù tí wọ́n lù sórin kan, ṣó yẹ kó o tún fara balẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ tó wà nínú ẹ̀? Láti dáhùn ìbéèrè yẹn, bi ara ẹ pé: ‘Bẹ́nì kan bá fẹ́ gbé májèlé fún mi jẹ́, kí ló lè ṣe tí màá fi gbà láti jẹ ẹ́? Ṣé inú nǹkan tó korò bí ewúro ló máa fi sí àbí inú nǹkan tó dùn bí oyin?’ Jóòbù, olóòótọ́ ọkùnrin náà béèrè pé: “Etí kò ha ń dán ọ̀rọ̀ wò bí òkè ẹnu ti ń tọ́ oúnjẹ wò?” (Jóòbù 12:11) Torí náà èyí tó o fi máa gbọ́ orin nítorí pé ìlù tí wọ́n lù sí i wà pa bí ìgbà tó ò ń lá oyin nítorí adùn ẹ̀, kúkú fara balẹ̀ ‘tọ́ àwọn ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ wò’ nípa wíwo àkọlé orin náà àtàwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú ẹ̀. Ìdí ni pé ọ̀rọ̀ orin yẹn máa nípa lórí ìrònú ẹ àtìwà tí wàá máa hù.
Ó bani nínú jẹ́ pé púpọ̀ lára àwọn orin tó dùn tó sì ń tuni lára lóde òní làwọn ọ̀rọ̀ inú wọn ń gbé ìṣekúṣe, ìwà ipá àti lílo oògùn nílòkulò larugẹ. Táwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú irú àwọn orin bẹ́ẹ̀ ò bá ṣe ẹ́ ní nǹkan kan mọ́, a jẹ́ pé “májèlé” yẹn ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ lára ẹ nìyẹn.
Pinnu Ohun Tó O Máa Ṣe
Àwọn ojúgbà ẹ lè nípa tó lágbára lórí ẹ kí wọ́n sì mú kó o bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ́tí sáwọn orin tí ò dáa. Àwọn iléeṣẹ́ tó ń gbé àwọn orin ọ̀hún jáde náà ò tún ní fi ẹ́ lọ́rùn sílẹ̀. Àwọn iléeṣẹ orin ti lo rédíò, Íńtánẹ́ẹ̀tì àti tẹlifíṣọ̀n láti gbé orin lárugẹ, wọ́n sì ti wá lówó lọ́wọ́ bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀. Wọ́n ti gba àwọn ògbóǹkangí nídìí ọjà títà síṣẹ́, kí wọ́n bàa lè jẹ́ kó o máa nífẹ̀ẹ́ sáwọn orin tí wọ́n ń ṣe jáde.
Àmọ́, bó o bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ́ káwọn ojúgbà ẹ tàbí ohun tó ò ń wò lórí tẹlifíṣọ̀n tó o sì ń gbọ́ lórí rédíò máa darí irú orin tí wàá máa gbọ́, a jẹ́ pé o ti pàdánù agbára tó o ní láti yan ohun tó o bá fẹ́ nìyẹn. Wọ́n á sì wá sọ ẹ́ dẹrú tí ò lọ́pọlọ. (Róòmù 6:16) Bíbélì sì ti gbà ẹ́ nímọ̀ràn pé kó o jáwọ́ nínú fífara wé àwọn èèyàn ayé lórí irú ọ̀ràn yìí. (Róòmù 12:2) Torí náà, ó máa dáa gan-an tó o bá lè “kọ́ agbára ìwòye [rẹ] láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.” (Hébérù 5:14) Báwo lo ṣe lè lo agbára ìwòye ẹ láti yan irú orin tí wàá máa gbọ́? Àwọn kókó wọ̀nyí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́:
Wo ohun tó wà lẹ́yìn àwo orin tó o fẹ́ gbọ́. Lọ́pọ̀ ìgbà tó o bá ti wo àwọn ọ̀rọ̀ àtàwòrán tó wà lẹ́yìn àwo orin, wàá ti mọ ohun tó ṣeé ṣe kó wà nínú orin ọ̀hún. Bó o bá ti ráwọn àwòrán tó gbé ìwà ipá, ìṣekúṣe tàbí iṣẹ́ òkùnkùn lárugẹ lẹ́yìn àwo orin tó o fẹ́ gbọ́, ó yẹ kíyẹn ti ta ẹ́ lólobó pé orinkórin ló máa wà nínú ẹ̀.
Fara balẹ̀ gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú orin ọ̀hún. Kí ni olórin yẹn ń sọ? Ṣó o rò pé orin tó o lè gbọ́ tó o sì lè máa kọ nígbà gbogbo ni? Ṣáwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú ẹ̀ ṣeé gbọ́ lẹ́nu ẹ, ṣé kò sì tako àwọn ìlànà Kristẹni?—Éfésù 5:3-5.
Ṣàkíyèsí ipa tó ń ní lórí ẹ. Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Philip sọ pé: “Mo wá rí i pé ọ̀pọ̀ lára àwọn orin àtàwọn ọ̀rọ̀ orin tí mò ń gbọ́ máa ń jẹ́ kí n sorí kọ́.” Òótọ́ ni pé bí orin ṣe máa ń ṣèèyàn máa ń yàtọ̀ síra. Àmọ́, báwo ló ṣe máa ń ṣe ẹ́ lẹ́yìn tó o bá gbọ́ orin tó o fẹ́ràn jù? Bi ara ẹ pé: ‘Ṣé mo máa ń ròròkurò lẹ́yìn tí mo bá gbọ́ orin tàbí àwọn ọ̀rọ̀ inú orin kan? Ṣé àwọn ọ̀rọ̀ rírùn tó wà nínú àwọn orin tí mò ń gbọ́ ò ti bẹ̀rẹ̀ sí hàn nínú àwọn ọ̀rọ̀ mi báyìí?’—1 Kọ́ríńtì 15:33.
Gba tàwọn ẹlòmíì rò. Kí làwọn òbí ẹ máa ń sọ nípa orin tó o fẹ́ràn? Béèrè èrò wọn nípa ẹ̀. Tún ronú lórí ohun táwọn Kristẹni bíi tìẹ máa rò nípa orin yẹn. Ṣé orin yẹn ò ní da ẹ̀rí ọkàn àwọn míì láàmú? Tíwọ náà bá ti ń ronú lórí bó o ṣe lè yí ìwà ẹ pa dà torí pé o ò fẹ́ ṣẹ àwọn èèyàn, ìwọ náà ti ń dàgbà nìyẹn.—Róòmù 15:1, 2.
Bó o bá bi ara ẹ láwọn ìbéèrè tá a tò sókè yìí, wàá lè yan orin tó máa múnú ẹ dùn tí ò sì ní ba àjọṣe ẹ pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́. Àmọ́, ohun kan tún wà tó o ní láti gbé yẹ̀ wò.
Ìgbà Wo Ló Dàṣejù?
Orin gidi máa ń ṣàǹfààní bí oúnjẹ gidi. Àmọ́, òwe olọ́gbọ́n kan kìlọ̀ pé: “Ṣé oyin ni o rí? Jẹ èyí tí ó tó ọ, kí o má bàa jẹ ẹ́ jù tí ìwọ yóò sì ní láti bì í.” (Òwe 25:16) Ọ̀pọ̀ àǹfààní ni oyin máa ń ṣe lára. Àmọ́, àpọ̀jù ohun tó dáa pàápàá lè ṣe ẹ́ ní jàǹbá. Ìyẹn kọ́ wa pé ìwọ̀nba lèèyàn gbọ́dọ̀ máa gbádùn ohun tó dáa mọ.
Àmọ́, àwọn ọ̀dọ́ kan ti jẹ́ kí orin máa darí ìgbésí ayé wọn. Bí àpẹẹrẹ, Jessica tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan jẹ́wọ́ pé: “Kò sígbà tí mi ò kí ń gbọ́ orin, kódà tí mo bá ń ka Bíbélì. Mo máa ń sọ fáwọn òbí mi pé ohun tó ń jẹ́ kí n lè pọkàn pọ̀ nìyẹn. Àmọ́ wọn ò gbà mí gbọ́.” Ṣó o ti gbọ́ ohun tí Jessica sọ yẹn rí?
Báwo lo ṣe máa mọ̀gbà tí àṣejù bá wọ orin tó ò ń gbọ́? Bí ara ẹ láwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí:
Báwo làkókò tí mo fi ń gbọ́ orin lójoojúmọ́ ṣe pọ̀ tó? ․․․․․
Èló ni mò ń ná sórí orin lóṣù? ․․․․․
Ṣé orin tí mò ń gbọ́ ò jẹ́ kí n ráyè gbọ́ tàwọn aráalé mi mọ́? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, kọ ohun tó o lè ṣe láti mú kí nǹkan túbọ̀ dáa síbí. ․․․․․
Ṣiṣẹ́ Lórí Bó O Ṣe Ń Gbọ́ Orin
Bó bá jẹ́ pé orin ló ń gba èyí tó pọ̀ jù nínú àkókò ẹ, ó máa dáa tó o bá lè díwọ̀n iye àkókò tí wàá máa fi gbọ́ orin, kó o sì ṣe é níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Bí àpẹẹrẹ, o lè ní láti jáwọ́ nínú àṣà kíki ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń gbọ́ orin sétí ní gbogbo ìgbà tàbí títan rédíò gbàrà tó o bá ti délé.
O ò ṣe gbìyànjú láti gbádùn àwọn àkókò tó dákẹ́ rọ́rọ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan? Ìyẹn lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti kàwé. Steve tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Ìgbà tó o bá pa rédíò lohun tó ò ń kà máa yé ẹ dáadáa.” Gbìyànjú láti kàwé láìgbọ́ orin, kó o sì kíyè sí ìyàtọ̀ tó o máa rí.
Wàá tún fẹ́ wá àkókò láti ka Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde tó dá lórí Bíbélì kó o sì kẹ́kọ̀ọ́ wọn. Jésù Kristi náà máa ń wá ibi tó pa rọ́rọ́ láti gbàdúrà àti láti ṣàṣàrò. (Máàkù 1:35) Ṣé ibi tó o ti máa ń ṣèkẹ́kọ̀ọ́ máa ń pa rọ́rọ́? Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, o lè má lè tètè dàgbà nípa tẹ̀mí.
Yan Orin Tó Dáa
Ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni orin jẹ́, àmọ́ o gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kó o má lọ ṣì í lò. Má fìwà jọ ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Marlene, ó jẹ́wọ́ pé: “Mo láwọn orin kan tí mo mọ̀ pé ó yẹ kí n sọ nù, àmọ́ àlùjó inú ẹ̀ ti lọ wà jù.” Ronú lórí àkóbá tí gbígbọ́ àwọn orin burúkú wọ̀nyẹn máa ṣe fún ọkàn àti àyà rẹ̀! Má ṣe jìn sínú irú ọ̀fìn bẹ́ẹ̀. Má ṣe jẹ́ kí orin sọ ẹ́ dìdàkudà má sì jẹ́ kó bà ẹ́ láyé jẹ́. Fàwọn ìlànà Kristẹni sílò tó o bá fẹ́ yan orin tí wàá máa gbọ́. Gbàdúrà sí Ọlọ́run fún ìtọ́sọ́nà àti ìrànlọ́wọ́. Àwọn tí ohun tó ò ń ṣe sì yé ni kó o máa bá rìn.
Orin lè tù ẹ́ lára, ó sì lè jẹ́ kára ẹ balẹ̀. Ó lè fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀ nígbà tó o bá ronú pé o dá nìkan wà. Àmọ́ bí orin bá tán, wàá rí i pé ìṣòro ẹ ṣì wà ńbẹ̀. Má sì gbàgbé pé o ò lè fi orin rọ́pò àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́. Torí náà, má sọ orin di nǹkan bàbàrà nígbèésí ayé ẹ. Máa gbádùn orin, àmọ́ má ṣe jẹ́ kó máa darí ẹ.
Ó yẹ kó o máa sinmi lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Báwo làwọn ìlànà inú Bíbélì ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti lo àkókò ìgbádùn ẹ dáadáa?
ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́
“Etí kò ha ń dán ọ̀rọ̀ wò bí òkè ẹnu ti ń tọ́ oúnjẹ wò?”—Jóòbù 12:11.
ÌMỌ̀RÀN
Bó o bá fẹ́ káwọn òbí ẹ mọ̀dí tó o fi nífẹ̀ẹ́ sí orin tàbí àwọn olórin kan, àfi kó o yáa wá bó o ṣe máa nífẹ̀ẹ́ sí díẹ̀ lára àwọn orin tó gbádùn mọ́ wọn.
ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?
Bí kì í bá yá ẹ lára láti jẹ́ káwọn òbí ẹ tẹ́tí sáwọn orin tó o nífẹ̀ẹ́ sí, ó lè jẹ́ pé orin tó o yàn láàyò kù díẹ̀ káàtó nìyẹn.
OHUN TÍ MÀÁ ṢE!
Bí mi ò bá fẹ́ kí àṣejù wọ orin tí mò ń gbọ́, màá ․․․․․
Báwọn ojúgbà mi bá fẹ́ sún mi gbọ́ àwọn orin tí ò wúlò, màá sọ fún wọn pé ․․․․․
Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․
KÍ LÈRÒ Ẹ?
● Kí nìdí tí irú orin tó o yàn láàyò fi ṣe pàtàkì?
● Báwo lo ṣe lè mọ̀ bóyá orin kan dáa tàbí kò dáa?
● Kí ló lè mú kó o máa tẹ́tí sí irú àwọn orin míì?
[Ìsọfúnni tó wà ní ojú ìwé 259]
“Nígbà míì mo kàn máa ń rí i pé àwọn orin tí mo mọ̀ pé kò dáa ni mo máa ń gbọ́. Mo sì máa ń pa á lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Bí mi ò bá pa á, ńṣe ni màá bẹ̀rẹ̀ sí ṣàwáwí pé kò sóhun tó burú ńbẹ̀.”—Cameron
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 258]
Wá Irú Orin Míì Tẹ́tí Sí
Ṣó o ti ń jẹ irú àwọn oúnjẹ kan tí o kì í jẹ́ nígbà tó o wà lọ́mọ ọdún márùn-ún? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé o ti kọ́ béèyàn ṣe ń jẹ irú àwọn oúnjẹ míì nìyẹn o. Bọ́ràn orin náà ṣe rí nìyẹn. Má kàn wulẹ̀ máa gbọ́ irú orin kan ṣáá. Kọ́ láti máa tẹ́tí sí irú àwọn orin míì.
Ọ̀nà kan tó o lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kó o kọ́ bí wàá ṣe mọ ohun èlò orin kan lò. Òótọ́ ni pé ó lè má rọrùn láti mọ̀, ó sì máa ń tẹ́ni lọ́rùn, àmọ́ ó tún máa jẹ́ kó o mọ irú orin míì yàtọ̀ séyìí táwọn olórin ayé máa ń kọ. Báwo lo ṣe máa rí àkókò tí wàá fi máa kọ́ bí wọ́n ṣe ń lo ohun èlò orin? O lè lo àwọn àkókò tó o fi ń wo tẹlifíṣọ̀n tàbí tó o fi ń ṣeré orí kọ̀ǹpútà. Gbọ́ nǹkan táwọn ọ̀dọ́ wọ̀nyí sọ.
“Lílo ohun èlò orin láti gbafẹ́ máa ń gbádùn mọ́ni gan-an, o sì lè lò ó láti sọ bí nǹkan ṣe ń rí lára ẹ. Kíkọ́ béèyàn ṣe lè kọ orin tuntun ti jẹ́ kí n fẹ́ràn oríṣiríṣi orin.”—Brian, ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] tó lè lo gìtá, ìlù àti pianó.
“Tó o bá fẹ́ mọ bí wọ́n ṣe ń lo ohun èlò orin kan, àfi kó o máa fi dánra wò dáadáa. Ìyẹn kì í sì í fìgbà gbogbo gbádùn mọ́ni. Àmọ́, mímọ bó o ṣe lè fi ohun èlò yẹn kọrin kan dáadáa máa múnú ẹ dùn, á sì jẹ́ kó o mọ̀ pé ìwọ náà dáa síbì kan.”—Jade, ọmọ ọdún mẹ́tàlá [13] tó mọ bí wọ́n ṣe ń lo “viola.”
“Bí mo bá ti ṣe wàhálà lọ látàárọ̀ tàbí tí nǹkan tojú sú mi, ńṣe lara mi máa wálẹ̀ tí mo bá ti fi gìtá mi kọrin. Inú mi máa ń dùn láti kọ orin tó gbádùn mọ́ni tó sì ń tuni lára.”—Vanessa, ọmọ ogún ọdún [20] tó mọ bí wọ́n ṣe ń lo gìtá, pianó àti “clarinet.”
“Mo sábà máa ń ronú pé, ‘Mi ò lè dáa tó lágbájá tàbí tàmẹ̀dù.’ Àmọ́ nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í fàwọn ohun tí wọ́n ti kọ́ mi dánra wò, inú tèmi náà wá bẹ̀rẹ̀ sí dùn tí mo bá kọ orin kan dáadáa. Ìyẹn sì jẹ́ kí n túbọ̀ mọyì iṣẹ́ táwọn olórin tó kù ń ṣe.”—Jacob, ọmọ ogún ọdún [20] tó mọ gìtá ta.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 255]
Orin ò yàtọ̀ sí oúnjẹ. Oúnjẹ tó dáa tí kò sì pọ̀ jù ló máa ń ṣara lóore. Àmọ́ kò sí ìwọ̀n téèyàn jẹ lára oúnjẹ tí kò dáa, tó máa ṣara lóore