ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • yp2 ojú ìwé 257
  • Àwòkọ́ṣe—Dáfídì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwòkọ́ṣe—Dáfídì
  • Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọwọ́ Tí Dáfídì Ọba Fi Mú Orin Kíkọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Báwo Ni Mi Ò Ṣe Ní Ki Àṣejù Bọ Orin Gbígbọ́?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Ṣé Mo Lè Yan Orin Tó Bá Ṣáà Ti Wù Mí?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ẹ Ṣọra fun Awọn Orin ti Kò Sunwọn!
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
Àwọn Míì
Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
yp2 ojú ìwé 257

Àwòkọ́ṣe—Dáfídì

Dáfídì nífẹ̀ẹ́ sí orin. Ó lẹ́bùn orin kíkọ, ó sì mọ béèyàn ṣe ń kọ ọ̀rọ̀ tó máa wá di orin. Kódà, òun fúnra ẹ̀ ló máa ń ṣe àwọn ohun èlò orin tó ń lò. (2 Kíróníkà 7:6) Dáfídì mọ orin kọ débi pé ọba Ísírẹ́lì máa ń pè é pé kó wá ṣeré fún wọn láàfin. (1 Sámúẹ́lì 16:15-23) Dáfídì sì máa ń gbà láti ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ kò sọ orin kíkọ di ohun tó ṣe pàtàkì jù nígbèésí ayé ẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò jẹ́ kí orin tó ń kọ gbà á lọ́kàn débi tá á fi bẹ̀rẹ̀ sí í gbéra ga. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló fi ẹ̀bùn tó ní yin Jèhófà.

Ṣó o fẹ́ràn orin? O lè máà lẹ́bùn orin kíkọ, àmọ́ o ṣì lè fara wé Dáfídì. Lọ́nà wo? Ìyẹn tíwọ náà ò bá jẹ́ kí orin tó ò ń gbọ́ máa darí ohun tó ò ń ṣe tàbí kó mú kó o bẹ̀rẹ̀ sí ṣohun tí ò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kó o máa fi orin gbádùn ara ẹ. Ọlọ́run ló fún wa lẹ́bùn láti kọ orin àti láti máa tẹ́tí sí i. (Jákọ́bù 1:17) Ọ̀nà tó múnú Jèhófà dùn ni Dáfídì gbà lo ẹ̀bùn yìí. Ṣéwọ náà á ṣe bẹ́ẹ̀?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́