ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwyp àpilẹ̀kọ 49
  • Ṣé Mo Lè Yan Orin Tó Bá Ṣáà Ti Wù Mí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Mo Lè Yan Orin Tó Bá Ṣáà Ti Wù Mí?
  • Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn àǹfààní tó wà níbẹ̀
  • Àwọn àǹfààní tó wà níbẹ̀
  • Àwọn ewu tó wà níbẹ̀
  • Báwo Ni Mi Ò Ṣe Ní Ki Àṣejù Bọ Orin Gbígbọ́?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Ẹ Ṣọra fun Awọn Orin ti Kò Sunwọn!
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ní Ojú Ìwòye Tó Wà Níwọ̀ntúnwọ̀nsì Nípa Orin
    Jí!—1999
  • Orin Tí Ń Múnú Ọlọ́run Dùn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
ijwyp àpilẹ̀kọ 49
Ọ̀dọ́bìnrin kan ń gbọ́ orin lórí fóònù rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Ṣé Mo Lè Yan Orin Tó Bá Ṣáà Ti Wù Mí?

“Tí n bá ti fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìgbòkègbodò mi láàárọ̀, mo máa ń gbọ́ orin. Tí n bá wọnú ọ̀kọ̀, mo máa ń gbọ́ orin. Kódà tí n bá wà nílé tí mò ń sinmi, tí mò ń tún ilé ṣe tàbí kàwé, orin ni mo máa ń gbọ́. Gbogbo ìgbà ni mo máa ń gbọ́ orin.”​—Carla.

Ṣé bí Carla ṣe fẹ́ràn orin gan-an ni ìwọ náà ṣe fẹ́ràn ẹ̀? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, àpilẹ̀kọ yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mọ àwọn àǹfààní tó wà nínú gbígbọ́ orin, bó o ṣe lè yẹra fún ewu tó wà níbẹ̀ àti bó o ṣe lè fọgbọ́n yan irú orin tí wàá máa gbọ́.

  • Àwọn àǹfààní tó wà níbẹ̀

  • Àwọn ewu tó wà níbẹ̀

  • Ohun táwọn ojúgbà rẹ sọ

Àwọn àǹfààní tó wà níbẹ̀

Kéèyàn máa gbọ́ orin dà bí ìgbà tí èèyàn ń jẹun. Bóyá èèyàn ń gbọ́ orin tàbí ó ń jẹun, ohun tó dáa jù ni pé kéèyàn ṣe èyí tó dáa, kó sì jẹ́ ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì. Àwọn àǹfààní tó wà nínú orin rèé:

  • Orin lè múnú ẹ dùn.

    “Lọ́jọ́ tí inú mi ò bá dùn, tí mo bá ti gbọ́ orin tí mo fẹ́ràn, ńṣe ni ara mi á yá gágá lójú ẹsẹ̀.”​—Mark.

  • Orin lè jẹ́ kó o rántí àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn.

    “Lọ́pọ̀ ìgbà, tí n bá ti gbọ́ àwọn orin kan, ó máa ń jẹ́ kí n rántí àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà kan, inú mi sì máa ń dùn pé mo gbọ́ irú orin bẹ́ẹ̀.”​—Sheila.

  • Orin máa ń jẹ́ kí ìṣọ̀kan àwa àtàwọn ẹlòmíì lágbára.

    “Bí mo ṣe ń gbọ́ táwọn àlejò tó wá sí àpéjọ àgbáyé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọrin ìparí ní àpéjọ náà, ńṣe ni orí mi wú tí omijé sì ń bọ́ lójú mi. Èdè wa yàtọ̀ síra lóòótọ́, àmọ́ orin tá a jọ kọ yẹn mú ká wà níṣọ̀kan.”​—Tammy.

  • Orin lè jẹ́ kó o ní àwọn ànímọ́ tó ṣeyebíye.

    “Tó o bá ń kọ́ bí wọ́n ṣe ń lo ohun èlò orin kan, o lè wá di ẹni tó ń fara balẹ̀ ṣe nǹkan, tó sì ní sùúrù. Torí pé díẹ̀díẹ̀ ni wàá mọ ohun èlò orin yẹn lò. Bó o bá ṣe ń fi ohun èlò orin náà dánra wò ni wàá máa mọ̀ ọ́n lò.”​—Anna.

Ǹjẹ́ o mọ̀? Ìwé Sáàmù ló gùn jù lọ nínú àwọn ìwé tó wà nínú Bíbélì, àádọ́jọ orin [150] ló sì wà nínú ẹ̀.

Ọ̀dọ́kùnrin kan ń wo àwọn èso ápù tó ti bàjẹ́

Bó o ṣe máa ń fọgbọ́n yan irú oúnjẹ tí wàá jẹ ni kó o máa fọgbọ́n yan irú orin tí wàá máa gbọ́

Àwọn ewu tó wà níbẹ̀

Àwọn orin kan dà bí oúnjẹ tí wọ́n da májèlé sí, ó lè pa èèyàn. Jẹ́ ká wo ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀.

  • Àwọn orin kan ní ọ̀rọ̀ ìṣekúṣe nínú.

    “Ó jọ pé gbogbo àwọn orin tó gbajúmọ̀ ló dá lórí ìṣekúṣe. Àwọn èèyàn ò tiẹ̀ fi bò mọ́.”​—Hannah.

    Bíbélì sọ pé: “Kí a má tilẹ̀ mẹ́nu kan àgbèrè àti ìwà àìmọ́ onírúurú gbogbo tàbí ìwà ìwọra láàárín yín.” (Éfésù 5:3) Bi ara rẹ pé, ‘Ṣé irú orin tí mò ń gbọ́ fi hàn pé mò ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí?’

  • Àwọn orin kan lè kó ìbànújẹ́ bá ẹ.

    “Nígbà míì tí oorun bá dá lójú mi lóru, mo máa ń tẹ́tí sí àwọn orin tó máa ń jẹ́ kí n ronú nípa àwọn nǹkan tó lè bà mí lọ́kàn jẹ́. Orin burúkú máa ń gbé èròkerò sọ́kàn mi.”​—Tammy.

    Bíbélì sọ pé: “Ju gbogbo ohun mìíràn tí a ní láti ṣọ́, fi ìṣọ́ ṣọ́ ọkàn-àyà rẹ.” (Òwe 4:​23) Bi ara rẹ pé, ‘Ṣé irú orin tí mò ń gbọ́ máa ń gbé èròkerò sí mi lọ́kàn?’

  • Àwọn orin kan lè sọ ẹ́ di oníbìínú èèyàn.

    “Ewu tí mi ò tètè fura sí ni àwọn orin tó jẹ́ kí inú máa bí mi àti èyí tó jẹ́ kí n máa kórìíra ara mi. Mo rí i pé inú mi kì í dùn tí n bá ti gbọ́ irú àwọn orin bẹ́ẹ̀ tán. Àwọn ara ilé mi pàápàá kíyè sí i bẹ́ẹ̀.”​—John.

    Bíbélì sọ pé: “Ẹ mú gbogbo wọn kúrò lọ́dọ̀ yín, ìrunú, ìbínú, ìwà búburú, ọ̀rọ̀ èébú, àti ọ̀rọ̀ rírùn kúrò lẹ́nu yín.” (Kólósè 3:8) Bi ara rẹ pé, ‘Ṣé orin tí mò ń gbọ́ ti jẹ́ kí n di onínú fùfù tàbí ẹni tó burú gan-an sí àwọn èèyàn?’

Kí ló yẹ kó o fi sọ́kàn? Máa fọgbọ́n yan irú orín tí wàá máa gbọ́. Ohun tí ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Julie ṣe nìyẹn, ó sọ pé: “Gbogbo ìgbà ni mo máa ń ṣàyẹ̀wò àwọn orin tí mò ń gbọ́, tí n bá ti rí èyí tí ò dáa nínú wọn, ńṣe ni màá yọ ọ́ dànù. Lóòótọ́ kò rọrùn, àmọ́ mo mọ̀ pé ohun tó yẹ kí n ṣe nìyẹn.”

Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Tara náà ti ń ṣe bíi ti Julie. Ó sọ pé: “Nígbà míì, wọ́n máa gbé orin tó ní àwọn àlùjó tó dùn gan-an sáfẹ́fẹ́ lórí rédíò, àmọ́ tí n bá ti gbọ́ ọ̀rọ̀ orin náà tí mo sì rí i pé kò dáa, ńṣe ni màá tètè yí ìkànnì rédíò náà síbòmíì. Ohun tí mò ń ṣe yìí dà bí ìgbà tí mo tọ́ oyin wò tán tí mo wá dà á nù! Tí mo bá lè pinnu pé mi ò ní gbọ́ orin tó dá lórí ìṣekúṣe, kò ní ṣòro fún mi láti sá fún ṣíṣe ìṣekúṣe ṣáájú ìgbéyàwó. Mí ò fẹ́ máa ronú pé irú orin tí mò ń gbọ́ ò lè ní ipa búburú lórí mi.”

OHUN TÁWỌN OJÚGBÀ RẸ SỌ

Abigail

“Orin lè ní ipa tó lágbára gan-an lórí ìrònú wa, tá ò bá sì ṣọ́ra orin tá a fẹ́ràn lè ṣe àkóbá fún wa débi pé a lè má mọ̀, àfi ìgbà tó bá ti bọ́ sórí tán.”​—Abigail.

Robert

“Kódà orin tó o gbọ́ lẹ́ẹ̀mejì péré lè má kúrò lọ́pọlọ ẹ títí ayé. Torí náà, ojú ẹsẹ̀ ló yẹ kó o pa orin tí ò dáa náà. Láìjẹ́ bẹ́ẹ̀, kò ní ṣeé pa rẹ́ kúrò lọ́kàn ẹ tó o bá gbọ́ ọ.”​—Robert.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́