ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g99 10/8 ojú ìwé 9-10
  • Ní Ojú Ìwòye Tó Wà Níwọ̀ntúnwọ̀nsì Nípa Orin

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ní Ojú Ìwòye Tó Wà Níwọ̀ntúnwọ̀nsì Nípa Orin
  • Jí!—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Wà Níwọ̀ntúnwọ̀nsì
  • Báwo Ni Mi Ò Ṣe Ní Ki Àṣejù Bọ Orin Gbígbọ́?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Ṣé Mo Lè Yan Orin Tó Bá Ṣáà Ti Wù Mí?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ẹ Ṣọra fun Awọn Orin ti Kò Sunwọn!
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
Àwọn Míì
Jí!—1999
g99 10/8 ojú ìwé 9-10

Ní Ojú Ìwòye Tó Wà Níwọ̀ntúnwọ̀nsì Nípa Orin

IṢẸ́ orin kíkọ ti di iṣẹ́ àṣelà tó ń pa òbìtìbiti owó wálé láyé táa wà yìí. Àwọn gbajúmọ̀ olórin àti àwọn baba ìsàlẹ̀ wọn ti di olówó yaágbó-yaájù. Síbẹ̀, kò ṣeé sẹ́ pé ìgbé-ayé àwọn gbajúgbajà olórin kan ti dorí kodò, òmíràn ti kú ikú àìtọ́jọ́, àwọn mí-ìn sì ti fọwọ́ ara wọn pa ara wọn. Ó sì ti hàn gbangba-gbàǹgbà pé àwọn orin kan lè ṣàkóbá fún ìwà rere, èrò ìmọ̀lára, àti ipò tẹ̀mí, ó sì lè yọrí sí ìwà ìpáǹle àti ìwà agánnigàn láwùjọ.

Ṣùgbọ́n, ó dára láti ní ojú ìwòye tó wà déédéé nípa orin. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ orin ni kò dáa, tó sì lè ṣèpalára, àwọn orin kan lè mú kí ayé ẹni sunwọ̀n sí i, ó sì lè mú ayọ̀ àti ìgbádùn wá. Ó lè gbé wa ró ní ti èrò ìmọ̀lára àti nípa tẹ̀mí. Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò.

Oyinmọmọ ni Sáàmù àádọ́jọ ti inú Bíbélì—ó ní ewì nínú, àwọn orin mímọ́ ń bẹ ńbẹ̀, àdúrà pẹ̀lú ò gbẹ́yìn. Àkàgbádùn làwọn èèyàn ń kà á lóde òní ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún èdè. Ṣùgbọ́n kíkà lásán kọ́ làwọn Hébérù ayé ijọ́un ń ka sáàmù yìí; ṣe ni wọ́n ń kọ ọ́ lórin. Bí wọ́n ti ń kọ ọ́ ni wọ́n tún máa ń lu àwọn ohun èlò orin adùnyùngbà sí i—ó jẹ́ ọ̀nà lílágbára táwọn akọrin olóhùn iyọ̀ wọnnì lò, láti fi mú ọgbọ́n Jèhófà, Ọlọ́run wọn, tó wà nínú ọ̀rọ̀ orin wọ̀nyẹn, wọnú ọkàn àwọn olùgbọ́. Orin àwọn Hébérù kò sì kẹ̀rẹ̀ rárá, kì í ṣe orin àwọn aláìlajú, àní kì í ṣẹgbẹ́ orin àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká nígbà yẹn.

Lẹ́yìn ìgbà yẹn, àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní fi àwọn sáàmù ṣorin kọ, wọ́n sì tún ń kọ àwọn orin mímọ́ mìíràn láti fi yin Ọlọ́run lógo àti láti fi túra ká. Nípa báyìí, orin tún ayé wọn ṣe. Àti pé nípa kíkọ àwọn orin táa gbé ka Bíbélì, wọ́n jẹ́ kí ìmọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n nílò fún títọ́ ayé wọn sọ́nà, túbọ̀ wọlé jinlẹ̀-jinlẹ̀ sínú ọkàn wọn.—Mátíù 26:30; Ìṣe 16:25.

Àwọn Gíríìkì ìgbàanì gbà gbọ́ pé orin ń tún ìwà ẹ̀dá ṣe, àti pé ó ń jẹ́ kí ọkùnrin tàbí obìnrin túbọ̀ kúnjú ìwọ̀n. Nínú ayé ọ̀rúndún ogún yìí, tó jẹ́ pé ẹ̀kọ́ sáyẹ́ǹsì, ẹ̀kọ́ ọrọ̀ ajé, àti ọgbọ́n orí ni wọ́n mú ní ọ̀kúnkúndùn, wọn kì í ṣújá fífi iṣẹ́ tó jẹ mọ́ iṣẹ́ ọnà gbé èrò ìmọ̀lára ènìyàn lárugẹ.

Wà Níwọ̀ntúnwọ̀nsì

Fífetí sí orin tó dáa lè ṣàǹfààní, kó sì gbádùn mọ́ni. Síbẹ̀, ìgbádùn ọ̀hún tún lè kún sí i tó bá ṣe pé èèyàn fúnra rẹ̀ ló ń lu ohun èlò ìkọrin náà tàbí tó jẹ́ pé òun àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ló jùmọ̀ ń kọrin. Mímọ̀ nípa orin lè jẹ́ kéèyàn mọ ọ̀pọ̀ nǹkan tí ń máyọ̀ wá.

Àmọ́ o, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí pẹ̀lú àwọn nǹkan fàájì mìíràn nínú ìgbésí ayé, ẹ jẹ́ ká yẹra fún àṣejù, ká fọgbọ́n ṣé e, ká sì mọ bí a ti í ṣe àṣàyàn eré ìnàjú. Ẹ jẹ́ ká máa ṣe bẹ́ẹ̀ nípa irú orin tí a yàn, ṣùgbọ́n ìyẹn nìkan kọ́ o, ẹ jẹ́ ká tún máa ṣe bẹ́ẹ̀ nípa iye àkókò tí a ń lò nídìí orin pẹ̀lú.

Bí irú orin kan bá ń ní ìyọrísí búburú lórí ìmọ̀lára rẹ, ìṣesí rẹ, àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ, dákun pawọ́ dà, kí o sì yan irú orin mí-ìn. Dáàbò bo etí rẹ kí o lè dáàbò bo ìmọ̀lára rẹ kí o sì lè dáàbò bo ọkàn àti èrò inú rẹ!

Àgàgà tó bá ti dọ̀ràn àwọn ọ̀rọ̀ orin. Ó lè bẹ̀rẹ̀ sí darí rẹ sípa ọ̀nà àwọn tí ìgbésí ayé àti ìwà wọ́n yàtọ̀ sí tìrẹ, ó sì lè jẹ́ pé ìgbésí ayé tó lòdì sí ìfẹ́ Ọlọ́run, ti ìṣekúṣe, ni wọ́n ń gbé lárugẹ. Nígbà mí-ìn, àní àkọlé orin lè mú kéèyàn bẹ̀rẹ̀ sí ròròkurò.

Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, gba àwọn tó bá fẹ́ mú inú rẹ̀ dùn nímọ̀ràn pé kí wọ́n “fi ara [wọn] fún Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè, mímọ́, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ pẹ̀lú agbára ìmọnúúrò [wọn].” (Róòmù 12:1) Láìsí àní-àní, ìmọ̀lára wa jẹ́ ara “ẹbọ ààyè” yẹn. Nítorí náà, bí a bá rí i pé agbára orin ti ń jẹ́ kí ìmọ̀lára wa dabarú làákàyè àti ọgbọ́n orí wa, tó sì fẹ́ mú wa ṣìnà, a jẹ́ pé àkókò ti tó láti yí irú orin táa ń gbọ́ padà. Rántí o: Agbára orin lè nípa lórí ọkàn rẹ àti èrò inú rẹ—ó lè jẹ́ ipa rere, ó sì lè jẹ́ ipa búburú!

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Ó Ń Mú Agbára Ẹ̀kọ́ Kíkọ́ Sunwọ̀n Sí I

“Ìwádìí fi hàn pé gbígbọ́ àwọn orin adúnbárajọ déédéé lè mú kí agbára ẹ̀kọ́ kíkọ́ ọmọ ọwọ́ sunwọ̀n sí i. Àmọ́, nínú ọ̀pọ̀ ilé, wọn ò gbọ́ irú orin yẹn rí.”—Audio, March 1999.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́