ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w24 October ojú ìwé 30
  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọwọ́ Tí Dáfídì Ọba Fi Mú Orin Kíkọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Orin Tí Ń Múnú Ọlọ́run Dùn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Ṣé Mo Lè Yan Orin Tó Bá Ṣáà Ti Wù Mí?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Báwo Ni Mi Ò Ṣe Ní Ki Àṣejù Bọ Orin Gbígbọ́?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
w24 October ojú ìwé 30
Àwọn akọrin tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì gbóhùn sókè, wọ́n ń fun kàkàkí, wọ́n sì ń fi háàpù kọrin sí Jèhófà.

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Báwo ni orin ti ṣe pàtàkì tó nígbà ayé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì?

ORIN jẹ́ apá pàtàkì nínú àṣà ìbílẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn orin tí wọ́n fi ohun ìkọrin kọ àtèyí tí wọ́n fẹnu kọ. Kódà tá a bá pín Bíbélì sọ́nà mẹ́wàá, ìdá kan nínú ẹ̀ ló jẹ́ orin. Bí àpẹẹrẹ, orin ni ìwé Sáàmù, Orin Sólómọ́nì àti Ìdárò. Ìdí nìyẹn tí ìwé Music in Biblical Life fi sọ pé Bíbélì “fi hàn kedere pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń lo orin nínú ọ̀pọ̀ nǹkan tí wọ́n máa ń ṣe.”

Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń kọrin déédéé. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń kọrin, wọ́n sì máa ń lo ohun ìkọrin kí wọ́n lè fi hàn pé inú wọn máa ń dùn. (Àìsá. 30:29) Àwọn obìnrin máa ń fi ìlù tanboríìnì kọrin tó dùn, wọ́n sì máa ń jó nígbà tí wọ́n bá ń fi ẹnì kan joyè, nígbà àjọyọ̀ àti ìgbà táwọn ọmọ ogun bá ṣẹ́gun. (Oníd. 11:34; 1 Sám. 18:6, 7; 1 Ọba 1:39, 40) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún máa ń kọrin arò tí wọ́n bá ń ṣọ̀fọ̀. (2 Kíró. 35:25) Nínú ìwé Cyclopedia tí McClintock àti Strong ṣe, wọ́n ní kò sí àní-àní pé “àwọn Hébérù fẹ́ràn orin gan-an.”

Wọ́n máa ń kọrin fáwọn ọba Ísírẹ́lì. Àwọn ọba Ísírẹ́lì máa ń gbádùn orin gan-an. Ìgbà kan wà tí Ọba Sọ́ọ̀lù ní kí Dáfídì wá máa kọrin fóun láàfin. (1 Sám. 16:18, 23) Nígbà tí Dáfídì náà di ọba, ó ṣe àwọn ohun ìkọrin, ó sì ṣàkọsílẹ̀ àwọn orin tó dùn gan-an. Ó tún ṣètò ẹgbẹ́ akọrin tó ń kọrin nínú tẹ́ńpìlì Jèhófà nígbà tó yá. (2 Kíró. 7:6; Émọ́sì 6:5) Bákan náà, Ọba Sólómọ́nì láwọn akọrin lọ́kùnrin àti lóbìnrin nínú ààfin ẹ̀.—Oníw. 2:8.

Wọ́n máa ń kọrin nígbà ìjọsìn. Ìgbà tó ṣe pàtàkì jù táwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń kọrin ni ìgbà tí wọ́n bá ń jọ́sìn Jèhófà. Kódà ẹgbẹ̀rún mẹ́rin (4,000) àwọn akọrin ló ń kọrin nínú tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù. (1 Kíró. 23:5) Wọ́n máa ń lo síńbálì, àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín, háàpù àti kàkàkí. (2 Kíró. 5:12) Àmọ́ kì í ṣe àwọn ọ̀jáfáfá akọrin yìí nìkan ló máa ń forin yin Jèhófà. Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń kọ Orin Ìgòkè tí wọ́n bá ń rìnrìn àjò lọ síbi àjọyọ̀ ọdọọdún ní Jerúsálẹ́mù. (Sm. 120–134) Bákan náà, àwọn ìwé táwọn Júù kọ sọ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń kọ àwọn Sáàmù tí wọ́n ń pè ní Hálẹ́lìa tí wọ́n bá ń jẹ Ìrékọjá.

Bákan náà, orin ṣe pàtàkì gan-an sáwa èèyàn Ọlọ́run lónìí. (Jém. 5:13) Ìdí sì ni pé orin wà lára ìjọsìn wa. (Éfé. 5:19) Orin tún máa ń jẹ́ ká wà níṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn ará wa. (Kól. 3:16) Ó sì máa ń fún wa lókun tá a bá níṣòro. (Ìṣe 16:25) Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa kọrin yin Jèhófà ká lè fi hàn pé a nígbàgbọ́ nínú ẹ̀, a sì nífẹ̀ẹ́ ẹ̀.

a Àwọn Júù máa ń pe Sáàmù 113 sí 118 ní Hálẹ́lì, wọ́n sì máa ń kọ ọ́ kí wọ́n lè fi yin Jèhófà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́