Ọwọ́ Tí Dáfídì Ọba Fi Mú Orin Kíkọ
TÁ A bá ń sọ̀rọ̀ nípa orin kíkọ láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, Dáfídì kò ṣe é fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn. Ó jẹ́ ọkùnrin tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tó gbé ayé ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] ọdún sẹ́yìn. Kódà èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ohun tá a mọ̀ nípa bí wọ́n ṣe ń kọrin láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì ló wá látinú ìtàn nípa Dáfídì, bẹ̀rẹ̀ látìgbà tó ṣì jẹ́ ọ̀dọ́mọdé olùṣọ́ àgùntàn títí dìgbà tó di ọba, tó sì mọ bí wọ́n ṣe ń ṣe kòkáárí.
Tá a bá kà nípa Dáfídì, ọ̀pọ̀ nǹkan la lè mọ̀ nípa orin kíkọ láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, irú àwọn ohun èlò wo ni wọ́n fi ń kọrin, irú àwọn orin wo ni wọ́n sì kọ? Ipa wo ni orin kíkọ kó nínú ìgbésí ayé Dáfídì àti lórí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì lápapọ̀?
Ọwọ́ Tí Wọ́n Fi Mú Orin Ní Ísírẹ́lì Ìgbàanì
Téèyàn bá ń ka àwọn ọ̀rọ̀ inú orin kan, ó lè jẹ́ kí onítọ̀hún rántí bí ohùn orin náà ṣe lọ. Àwọn ọ̀rọ̀ inú onírúurú orin ló wà nínú Bíbélì, àmọ́ ó ṣeni láàánú pé a kò mọ ohùn àwọn orin náà. Àwọn orin yìí ti ní láti jẹ́ orin tó dùn-ún gbọ́ létí tó sì dára gan-an. Bí wọ́n ṣe kọ àwọn ọ̀rọ̀ inú ìwé Sáàmù bí ẹní kọ ewì jẹ́ ká mọ̀ pé orin aládùn tó dùn-ún gbọ́ létí ni àwọn orin náà.
Bíbélì kò fi bẹ́ẹ̀ sọ púpọ̀ nípa àwọn ohun èlò ìkọrin tí wọ́n ń lò nígbà àtijọ́. (Wo àpótí tá a pe àkọlé rẹ̀ ní “Àwọn Ohun Èlò Ìkọrin Láyé Ìgbà Tí Wọ́n Ń Kọ Bíbélì.”) Kódà, a kò fi bẹ́ẹ̀ mọ irú háàpù tí Dáfídì lò. Àmọ́, ó dùn mọ́ wa nínú láti mọ̀ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe onírúurú ohun èlò ìkọrin, irú bíi háàpù tí wọ́n fi igi ṣe tí irú rẹ̀ ṣọ̀wọ́n tó sì ṣeyebíye.—2 Kíróníkà 9:11; Ámósì 6:5.
Síbẹ̀, ohun kan dájú. Ìyẹn sì ni pé, ipa pàtàkì ni orin kíkọ kó nínú ìgbésí ayé àwọn Hébérù, pàápàá jù lọ nínú ìjọsìn wọn sí Ọlọ́run. Wọ́n máa ń kọrin nígbà tí wọ́n bá ń joyè, tí wọ́n bá ń ṣe àwọn ààtò ìjọsìn àti nígbà ogun. Wọ́n tún máa ń fi orin dá àwọn èèyàn lára yá ní ààfin ọba, níbi ìgbéyàwó, níbi àpèjẹ ìdílé àti láwọn ìgbà tí wọ́n bá ń ṣe àjọ̀dún èso àjàrà àti ìkórè ọkà. Àmọ́, wọ́n tún máa ń kọrin láwọn ibi tí nǹkan kò bá ti bára dé. Nígbà tí ẹnì kan bá sì ṣaláìsí, wọn tún máa ń fi orin tu àwọn èèyàn rẹ̀ nínú.
Àwọn nǹkan pàtàkì míì tún wà tí wọ́n máa ń fi orin ṣe nílẹ̀ Ísírẹ́lì. Ó máa ń jẹ́ kí ara yá gágá, ó sì máa ń mú kí ọkàn àwọn wòlíì wà ní sẹpẹ́ láti gba nǹkan tẹ̀mí. Ìgbà tí wòlíì Èlíjà gbọ́ ohùn orin ló rí ìtọ́ni gbà látọ̀dọ̀ Jèhófà. (2 Àwọn Ọba 3:15) Wọ́n tún máa ń lo orin láti fi jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ̀ pé àsìkò ti tó fún àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì kan tó máa ń wáyé lọ́dọọdún. Kàkàkí méjì tí wọ́n fi fàdákà ṣe ni wọ́n máa fi ń kéde òṣùpá tuntun àti àwọn àjọ̀dún. Tó bá di ọjọ́ Júbílì, ìró ìwo ni wọ́n máa fi ń kéde ìtúsílẹ̀ fún àwọn ẹrú, tí wọ́n sì máa fi ń jẹ́ kí àwọn tó bá ti pàdánù ilẹ̀ tàbí ilé wọn mọ̀ pé àsìkò ti tó láti gbà á pa dà. Fojú inú yàwòrán bí inú àwọn tálákà ti máa dùn tó nígbà tí wọ́n bá gbọ́ ohùn orin tó ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé àsìkò òmìnira wọn ti tó tàbí àsìkò láti gba àwọn ohun ìní wọn pa dà!—Léfítíkù 25:9; Númérì 10:10.
Ó dájú pé àwọn kan lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ní láti jẹ́ ògbóǹkangí olórin tàbí akọrin. Kódà, àwòrán kan tí wọ́n gbẹ́ sára ògiri nílẹ̀ Asíríà jẹ́ ká mọ̀ pé, Senakéríbù Ọba sọ fún Hesekáyà Ọba pé kó fi àwọn akọrin lọ́kùnrin àti lóbìnrin san ìṣákọ́lẹ̀ fóun. Ó ṣeé ṣe kí àwọn akọrin yìí jẹ́ àwọn olórin tó gbayì jù lọ láyé ìgbà náà. Síbẹ̀, Dáfídì ta gbogbo wọn yọ.
Olórin Tó Gbàfiyèsí
Ohun tó mú kí Dáfídì gbàfiyèsí ni pé, ó jẹ́ olórin, ó sì tún jẹ́ akéwì. Òun ló kọ èyí tó ju ìdajì lọ nínú ìwé Sáàmù. Nígbà tó wà lọ́mọdé, iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn ló ń ṣe, àwọn pápá oko tútù tó wà yíká ilẹ̀ Bẹ́tílẹ́hẹ́mù sì máa ń mú kí òye rẹ̀ túbọ̀ kún kó sì lè ronú jinlẹ̀. Ó mọ ayọ̀ tí fífetí sí ìró omi tó ń bì lu ara wọn máa ń fún èèyàn àti bí àwọn àgùntàn ṣe máa ń dáhùn nígbà tó bá pè wọ́n. Ìró tó dà bí ohùn orin tó ń dún láyìíká rẹ̀ yìí máa ń wọ̀ ọ́ lọ́kàn, èyí máa ń mú kó gbé háàpù rẹ̀, kó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọrin ìyìn sí Ọlọ́run. Fọkàn yàwòrán bí orin tó wà nínú Sáàmù 23 ṣe máa wọni lọ́kàn tó, ká ní ò ń gbọ́ bí Dáfídì fúnra rẹ̀ ṣe ń kọ ọ́!
Nígbà tí Dáfídì ṣì wà lọ́dọ̀ọ́, ó mọ háàpù ta débi pé wọ́n dábàá rẹ̀ fún Sọ́ọ̀lù Ọba, ọba sì ní kó máa wá kọrin fún òun ní ààfin. Nígbà tí ṣìbáṣìbo àti ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn bá Sọ́ọ̀lù, Dáfídì wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì fi háàpù kọ àwọn orin tó fi tu Sọ́ọ̀lù Ọba lára. Àwọn èròkerò tó ń da Sọ́ọ̀lù láàmù kúrò lọ́kàn rẹ̀, ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn sì fi í sílẹ̀.—1 Sámúẹ́lì 16:16.
Àmọ́ ṣá o, láìka bí Dáfídì ṣe fẹ́ràn orin tó, tí orin sì máa ń mú inú rẹ̀ dùn, ìgbà míì wà tí orin máa ń kó Dáfídì sínú wàhálà. Lọ́jọ́ kan, wọ́n kọ orin ayọ̀ àti ìṣẹ́gun fún Dáfídì àti Sọ́ọ̀lù lẹ́yìn tí wọ́n pa dà dé láti ojú ogun kan tí wọ́n ti ṣẹ́gun àwọn Filísínì. Àwọn obìnrin ń kọrin pé: “Sọ́ọ̀lù ti ṣá ẹgbẹẹgbẹ̀rún tirẹ̀ balẹ̀, àti Dáfídì ẹgbẹẹgbẹ̀rún mẹ́wàá-mẹ́wàá tirẹ̀.” Orin yẹn jẹ́ kí inú bí Sọ́ọ̀lù gidigidi, ó sì ń jowú Dáfídì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí “wo Dáfídì tìfuratìfura láti ọjọ́ yẹn lọ.”—1 Sámúẹ́lì 18:7-9.
Orin Máa Ń Sọ Sí Dáfídì Lọ́kàn
Àwọn orin tí Ọlọ́run mí sí Dáfídì láti kọ ta yọ ní onírúurú ọ̀nà. Ó kọ àwọn orin tó lè jẹ́ kí èèyàn ronú jinlẹ̀ àtàwọn sáàmù tó sọ nípa iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn agbo ẹran. Ó tún kọ àwọn orin ìyìn àtàwọn orin tó fi sọ ìtàn, àwọn orin tó jẹ́ ká mọ bí inú àwọn èèyàn ti máa ń dùn tó nígbà ìkórè èso àjàrà àti nígbà tí wọ́n bá ń ṣí ààfin ọba, àwọn orin tó ń jẹ́ kéèyàn rántí àwọn ohun àtijọ́ àtàwọn orin tó ń fún wa nírètí, àwọn orin ẹ̀bẹ̀ àti ti àrọwà. (Wo Sáàmù 32, 23, 145, 8, 30, 38, 72, 51, 86 àtàwọn àkọlé wọn.) Nígbà tí Sọ́ọ̀lù àti Jónátánì ọmọ rẹ̀ kú, Dáfídì kọ orin arò tó pe àkọlé rẹ̀ ní: “Ọrun,” àwọn ọ̀rọ̀ tó fi bẹ̀rẹ̀ orin arò náà níyì: “Ìwọ Ísírẹ́lì, ẹwà ni a pa lórí àwọn ibi gíga rẹ.” Ohùn orin yìí bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà mu. Dáfídì mọ béèyàn ṣe lè fi ọ̀rọ̀ tàbí orin tó fi háàpù rẹ̀ kọ gbé oríṣiríṣi ìmọ̀lára jáde.—2 Sámúẹ́lì 1:17-19.
Torí pé Dáfídì jẹ́ ẹni tára rẹ̀ yá mọ́ àwọn èèyàn, ó fẹ́ràn orin amóríyá gágá, tó máa ń múnú ẹni dùn, tó sì dùn-ún gbọ́ létí. Nígbà tó gbé àpótí májẹ̀mú wá sí Síónì, gbogbo agbára ló fi ń fò sókè tó sì ń jó kárakára bí wọ́n ti ń ṣe àjọyọ̀ náà. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé orin aládùn tó mórí yá gágá ni orin tí wọ́n kọ lọ́jọ́ náà. Ṣó o lè fọkàn yàwòrán ohun tó wáyé lọ́jọ́ tá à ń wí yìí? Ohun tí Dáfídì ṣe yìí mú kí Míkálì, ìyàwó rẹ̀ tẹ́ńbẹ́lú rẹ̀. Àmọ́ ìyẹn kò já mọ́ nǹkan kan lójú Dáfídì. Dáfídì fẹ́ràn Jèhófà, orin tó sì ń múnú rẹ̀ dùn yìí ń mú kó máa fi gbogbo ara jó níwájú Ọlọ́run rẹ̀.—2 Sámúẹ́lì 6:14, 16, 21.
Yàtọ̀ síyẹn, nǹkan míì tó tún mú kí Dáfídì ta yọ nínú iṣẹ́ orin kíkọ ni pé ó ṣe àwọn ohun èlò ìkọrin tuntun fúnra rẹ̀. (2 Kíróníkà 7:6) Ju gbogbo rẹ̀ lọ, oníṣẹ́-ọ̀nà tó ní àwọn ẹ̀bùn tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ni Dáfídì, ó máa ń ṣe àwọn ohun èlò ìkọrin, akéwì ni, ó máa ń kọ àwọn ọ̀rọ̀ inú orin, ó sì máa ń fi orin dá bírà. Àmọ́, Dáfídì tún ṣe àwọn nǹkan míì tó tún ju ìyẹn lọ.
Orin Kíkọ Nínú Tẹ́ńpìlì
Ọ̀kan lára àwọn ohun tí Dáfídì fi lélẹ̀ ni ètò nípa orin àti bí wọ́n á ṣe máa kọ ọ́ nínú ilé Jèhófà. Ó fi Ásáfù, Hémánì àti Jédútúnì (tí wọ́n tún ń pè ní Étánì) ṣe olórí fún àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́rin [4,000] akọrin àti olórin. Abẹ́ àbójútó àwọn mẹ́ta yìí ni Dáfídì fi ọ̀rìnlérúgba-ó-lé-mẹ́jọ [288] ògbóǹkangí akọrin tó ń fún àwọn akọrin tó kù ní ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n sì ń ṣe kòkáárí sí. Gbogbo àwọn akọrin àti olórin tí wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin yìí ni wọ́n máa ń pésẹ̀ sí tẹ́ńpìlì fún àjọ̀dún ńláńlá mẹ́ta tí wọ́n máa ń ṣe lọ́dọọdún. Fọkàn yàwòrán bí orin tí àwọn akọrin yìí máa ń kọ ṣe máa dùn-ún gbọ́ létí tó!—1 Kíróníkà 23:5; 25:1, 6, 7.
Àwọn ọkùnrin nìkan ló máa ń kọrin nínú tẹ́ńpìlì. Gbólóhùn náà, “lórí Àwọn Omidan,” tó wà nínú àkọlé Sáàmù 46, jẹ́ ká mọ̀ pé ohùn tàbí ohun èlò orin tó dún ròkè lala ni wọ́n fi kọ sáàmù yìí. Wọ́n pa ohùn wọn pọ̀ láti kọrin gẹ́gẹ́ bí ìwé 2 Kíróníkà 5:13 ṣe sọ pé ohùn “àwọn akọrin ṣe ọ̀kan.” Ó ṣeé ṣe kí àwọn orin náà jẹ́ àwọn orin atunilára, irú èyí tó wà ní Sáàmù 3 àtàwọn sáàmù míì tó jẹ́ ti Dáfídì tàbí kó jẹ́ ègbè, irú èyí tó wà nínú Sáàmù 42:5, 11 àti 43:5. Àwọn èèyàn tún máa ń gbádùn bí ẹgbẹ́ akọrin àti àwọn olórin ṣe máa ń gbe orin láàárín ara wọn. Ó dájú pé irú orin yìí ló wà ní Sáàmù 24 tí wọ́n kọ nígbà tí Dáfídì gbé àpótí májẹ̀mú wá sí Síónì.—2 Sámúẹ́lì 6:11-17.
Kì í ṣe àwọn ọmọ Léfì nìkan ló máa ń kọrin. Gbogbo àwọn tó bá wá sí Jerúsálẹ́mù fún àjọ̀dún ọdọọdún náà máa ń kọrin. Orin tí wọ́n máa ń kọ ni wọ́n pè ní “Orin Ìgòkè.” (Sáàmù 120 sí 134) Bí àpẹẹrẹ, nínú Sáàmù 133 Dáfídì sọ̀rọ̀ nípa ìkórajọpọ̀ ẹgbẹ́ ará tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń gbádùn láwọn àkókò yìí. Ó bẹ̀rẹ̀ orin náà báyìí pé: “Wò ó! Ó mà dára o, ó mà dùn o, pé kí àwọn ará máa gbé pa pọ̀ ní ìṣọ̀kan!” Gbìyànjú láti fọkàn yàwòrán bí orin yẹn ṣe máa dùn-ún gbọ́ létí tó!
Ipa Tí Orin Kíkọ Ń Kó Nínú Ìjọsìn Jèhófà
Ìdá kan nínú mẹ́wàá àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì ló jẹ́ orin tí wọ́n fi ń jọ́sìn Jèhófà, ìwé Sáàmù sì rọ gbogbo èèyàn láti máa yin Jèhófà. (Sáàmù 150) Orin lágbára láti mú kéèyàn gbàgbé àwọn ìṣòro ìgbésí ayé, ó sì máa ń dà bí òróró atunilára lójú ọgbẹ́. Síbẹ̀, Bíbélì tún rọ àwọn tí ara wọn bá yá gágá pé kí wọ́n máa fi àwọn sáàmù ṣe orin kọ.—Jákọ́bù 5:13.
Èèyàn lè fi ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ tó ní fún Ọlọ́run hàn nípa kíkọrin. Lálẹ́ ọjọ́ tó ṣáájú ọjọ́ tí wọ́n pa Jésù, òun àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ kọ orin lẹ́yìn tí wọ́n jẹ oúnjẹ alẹ́ tán. (Mátíù 26:30) Fọkàn yàwòrán bí ohùn Jésù, Ọmọ Dáfídì ti máa dùn tó, ẹni to ti mọ bí àwọn ẹ̀dá Ọlọ́run tó wà lọ́run ṣe máa ń fi ohùn dídùn kọrin! Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ Hálẹ́lì ni wọ́n kọ, ìyẹn Sáàmù 113 sí 118. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe kí Jésù fi taratara kọrin sókè pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ti wọn kò mọ ohunkóhun nípa àwọn ohun tó fẹ́ ṣẹlẹ̀ pé: “Èmi nífẹ̀ẹ́, nítorí pé Jèhófà ń gbọ́ ohùn mi, àti àwọn àrọwà mi. . . . Àwọn ìjàrá ikú ká mi mọ́, àwọn ipò tí ó kún fún wàhálà ti Ṣìọ́ọ̀lù pàápàá sì wá mi rí. . . . ‘Áà, Jèhófà, pèsè àsálà fún ọkàn mi!’”—Sáàmù 116: 1-4.
Àwa èèyàn kọ́ la kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í kọrin. Bíbélì ṣàpèjúwe orin àti bí wọ́n ṣe ń kọ ọ́ lókè ọ̀run, níbi tí àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí ti ń ta háàpù ìṣàpẹẹrẹ, tí wọ́n sì ń kọ orin ní àyíká ìtẹ́ Jèhófà. (Ìṣípayá 5:9; 14:3; 15:2, 3) Jèhófà Ọlọ́run ló fún àwa èèyàn ní ẹ̀bùn orin kíkọ, òun ló jẹ́ ká lè máa gbádùn fífetí sí orin látọkàn wá, òun náà ló sì jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti máa fi ohun èlò ìkọrin tàbí orin kíkọ sọ ohun tó wà lọ́kàn wa. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni orin kíkọ jẹ́ fún gbogbo ẹni tó bá nígbàgbọ́.— Jákọ́bù 1:17.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 27]
“Ní ọjọ́ ayọ̀ yíyọ̀ yín àti ní àwọn àkókò àjọyọ̀ yín . . . kí ẹ sì fun kàkàkí.”—NÚMÉRÌ 10:10
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 28]
“Jèhófà ni Olùṣọ́ Àgùntàn mi. Èmi kì yóò ṣaláìní nǹkan kan. Ó ń mú mi dùbúlẹ̀ ní pápá ìjẹko tí ó kún fún koríko; ó ń darí mi lẹ́bàá àwọn ibi ìsinmi tí ó lómi dáadáa.”—SÁÀMÙ 23:1, 2
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 29]
“Ẹgbàajì olùfi ìyìn fún Jèhófà [ló wà] lórí àwọn ohun èlò tí Dáfídì sọ pé ‘Mo ṣe fún bíbu ìyìn.’”—1 KÍRÓNÍKÀ 23:4, 5
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 29]
Nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ àti orin, Dáfídì jẹ́ ká mọ onírúurú ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 30]
“Ẹ yin Jáà! Ẹ fi ìlù tanboríìnì àti ijó àjóyípo yìn ín. Gbogbo ohun eléèémí—kí ó yin Jáà.”—SÁÀMÙ 150:1, 4, 6
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Àwọn Ohun Èlò Ìkọrin Láyé Ìgbà Tí Wọ́n Ń Kọ Bíbélì
Lára àwọn ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín ni gòjé, háàpù àti ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín mẹ́wàá. (Sáàmù 92:3) Wọ́n máa ń yí wọn sí Álámótì àti Ṣẹ́mínítì tó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí àwọn ohùn orin tó ròkè lala àti ohùn tó lọ sílẹ̀. (1 Kíróníkà 15:20, 21; NW) Lára àwọn ohun èlò ìkọrin tí wọ́n ń fi idẹ ṣe tàbí èyí tí wọ́n máa ń fun ni ape, fèrè, ìwo àti kàkàkí, wọ́n sábà máa ń dún “kíkankíkan.” (2 Kíróníkà 7:6; 1 Sámúẹ́lì 10:5; Sáàmù 150:3, 4) Nígbà tí wọ́n ń ṣe ìyàsímímọ́ tẹ́ńpìlì, ìró kàkàkí àti ohùn àwọn akọrin ṣọ̀kan láti mú “kí a gbọ́ ìró kan.” (2 Kíróníkà 5:12, 13) Ó ṣeé ṣe kí èyí túmọ̀ sí pé wọ́n jọ fi ohùn kan náà gbe orin, ìró ohùn wọn sì báramu. Lára àwọn ohun èlò ìkọrin tí wọ́n máa ń lù kó tó lè mú ohùn jáde ni tanboríìnì, sítírọ́mù, àwọn ohun èlò ìkọrin tó ń dún woroworo àti “gbogbo onírúurú ohun èlò orin tí [wọ́n] fi igi júnípà ṣe.” Wọ́n tún máa ń lo àwọn aro kéékèèké tí ó ní àwọn “ìró orin atunilára,” àti àwọn aro ńláńlá tí Bíbélì pè ní “aro tí ń dún gooro.”—2 Sámúẹ́lì 6:5; Sáàmù 150:5.
[Àwọn àwòrán]
Lókè: Àwọn kàkàkí tí wọ́n mú nínú tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù ní ọdún 70 Sànmánì Kristẹni, a rí i lára ògiri tí wọ́n ń pè ní “Arch of Titus” nílùú Róòmù lórílẹ̀-èdè Ítálì. Owó ẹyọ tí wọ́n ná ní ọdún 130 Sànmánì Kristẹni, wọ́n ya àwọn ohun èlò ìkọrin àwọn Júù sí i lára
[Credit Line]
Owó ẹyọ: © 2007 látọwọ́ David Hendin. Gbogbo ẹ̀tọ́ jẹ́ tiwa.