ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 4/15 ojú ìwé 19-24
  • Ẹ Ṣọra fun Awọn Orin ti Kò Sunwọn!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ Ṣọra fun Awọn Orin ti Kò Sunwọn!
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àṣìlò Orin
  • Idi kan fun Iṣọra
  • Orin Ọlọ́rọ̀-Wótòwótò—Orin Ọ̀tẹ̀
  • Orin Onílù-dídún Kíkankíkan—Ibalopọ Takọtabo, Iwa-ipa, ati Ijọsin Satani
  • Kíká Ohun Ti O Gbìn
  • Ẹ Maa Ṣọra
  • Báwo Ni Mi Ò Ṣe Ní Ki Àṣejù Bọ Orin Gbígbọ́?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Ṣé Mo Lè Yan Orin Tó Bá Ṣáà Ti Wù Mí?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Orin Rọ́ọ̀kì Àfidípò—Ó Ha Wà fún Mi Bí?
    Jí!—1996
  • Agbára Orin
    Jí!—1999
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 4/15 ojú ìwé 19-24

Ẹ Ṣọra fun Awọn Orin ti Kò Sunwọn!

“Ẹ kiyesi i lati maa rìn ni ìwà-pípé, kìí ṣe bi awọn alailọgbọn, ṣugbọn bi awọn ọlọgbọn; ẹ maa ra ìgbà pada, nitori buburu ni awọn ọjọ.” —EFESU 5:15, 16.

1. Eeṣe ti a fi lè pe orin ni “ẹbun atọrunwa”?

“ORIN . . . jẹ́ ẹbun atọrunwa.” Bẹẹ ni Lulu Rumsey Wiley kọ ninu iwe rẹ̀ Bible Music. Lati atetekọṣe wá, awọn ọkunrin ati obinrin olubẹru Ọlọrun ti mọ èrò yii. Nipasẹ orin, eniyan ti sọ ero-imọlara rẹ̀ ti o jinlẹ julọ jade—ayọ, ibanujẹ, ibinu, ati ifẹ. Orin tipa bayii kó ipa pataki kan ni akoko ti a kọ Bibeli, niwọn bi a ti mẹnukan an latokedelẹ ninu iwe mimọ yẹn.—Genesisi 4:21; Ìfihàn 18:22.

2. Bawo ni a ṣe lo orin lati yin Jehofa ni akoko ti a kọ Bibeli?

2 Ninu ijọsin Jehofa ni orin ti rí igbejade rẹ̀ ti ó lọ́lá julọ. Diẹ lara awọn ọ̀rọ̀ iyin titobi julọ ti a tii sọ jade rí si Jehofa Ọlọrun ni a kọ ni orin ni ipilẹṣẹ. “Emi ó fi orin yin orukọ Ọlọrun,” ni olorin naa Dafidi kọwe. (Orin Dafidi 69:30) Orin ni a lò nigba idanikanwa gẹgẹ bi alabaarin kan fun ironujinlẹ taduratadura. “Mo ranti orin mi ni òru: emi ń bá àyà mi sọrọ: ọkàn mi sì ń ṣe awari jọjọ,” ni Asafu kọwe. (Orin Dafidi 77:6) Ninu tẹmpili Jehofa, orin ni a ṣeto si iwọn kan ti o ga. (1 Kronika 23:1-5; 2 Kronika 29:25, 26) Nigba miiran, awọn ẹgbẹ́ awujọ olorin pupọ ni a ń ṣeto, gẹgẹ bi nigba iyasimimọ tẹmpili, nigba ti a lo awọn 120 olufọnfere. (2 Kronika 5:12, 13) A kò ni akọsilẹ kankan nipa bi orin titayọlọla yii ti dun, ṣugbọn iwe naa The Music of the Bible ṣakiyesi pe: “Kò níí ṣoro lati gbe ipinnu kan kalẹ nipa abayọri orin Tẹmpili ni gbogbogboo nigba ajọyọ gigadabu . . . Bi ọ̀kan ninu wa bá lè di ẹni ti a gbé lọ nisinsinyi saaarin iru iran kan bẹẹ, ẹmi amunikun fun ibẹru ati imọlara iyanu ti o lekenka ni yoo jẹ́ eyi ti a kì yoo lè yẹ silẹ.”a

Àṣìlò Orin

3, 4. Ni ọ̀nà wo ni awọn eniyan Ọlọrun ati awọn aladuugbo wọn abọriṣa gbà ṣi ẹbun orin lò?

3 Orin ni a kìí figba gbogbo fi si ilo ti o galọla bẹẹ, bi o ti wu ki o ri. Ni ori Oke Sinai, orin ni a lò lati ru ijọsin oloriṣa ọmọ-maluu oniwura soke. (Eksodu 32:18) Orin tun jẹ́ akoko iṣẹlẹ kan ti a sopọ mọ iwa-imutipara ati iṣekaruwa paapaa. (Orin Dafidi 69:12; Isaiah 23:15) Awọn aladuugbo Israeli ni wọn jẹbi aṣilo ẹbun atọrunwa yii pẹlu. “Ni Fenike ati Siria,” ni The Interpreter’s Dictionary of the Bible sọ, “ó fẹrẹẹ jẹ pe gbogbo awọn orin lilokiki ni wọn ṣagbeyọ ijọsin Ishtar, abo-ọlọrun ibimọ. Nipa bayii, orin lilokiki sábà maa ń jẹ́ ìtọ́wò-àfiṣaájú kan fun awọn ariya ẹhanna onibaalopọ takọtabo.” Awọn ara Griki igbaani bakan naa lo orin lati bá “ijó arunisoke” lilokiki rìn.

4 Bẹẹni, orin ní agbara lati wọnilara, gbanilafiyesi, ati lati nipa lenilori. Ni awọn ẹwadun sẹhin, iwe John Stainer, The Music of the Bible tilẹ lọ jinna debi jijẹwọ paapaa pe: “Kò si iṣẹ ti ó lo iru inipalenilori ti o lagbara tobẹẹ lori iran-eniyan ni akoko ti a wà yii gẹgẹ bi iṣẹ Orin.” Orin ń baa lọ lati maa lo ipá alabaajade lilagbara kan lonii. Nitori idi eyi, oriṣi orin ṣiṣaitọ kan lè jẹ́ ewu gidi fun awọn èwe olubẹru Ọlọrun.

Idi kan fun Iṣọra

5. (a) Bawo ni ipa ti orin kó ti tobi tó ninu igbesi-aye ọpọ awọn ọ̀dọ́langba? (b) Ki ni oju-iwoye Ọlọrun nipa awọn ọ̀dọ́ eniyan ti wọn ń gbadun araawọn?

5 Bi iwọ bá jẹ́ ọ̀dọ́ kan, nigba naa iwọ mọ̀ daradara bi orin ṣe ṣe pataki tó—ni pataki julọ oriṣiriṣi iru orin gbigbajumọ tabi alariwo jìnjinjìn—fun ọpọlọpọ ti wọn jẹ́ ojugba rẹ. Orin ni a tilẹ ti pè ni “ọ̀kan lara awọn ohun ti o ṣe pataki fun awọn ọdọlangba.” A ṣiro rẹ̀ pe ninu ọdun mẹfa rẹ̀ ti o kẹhin ni ile-ẹkọ, èwe kan ti a lè lo bi apẹẹrẹ ni United States yoo fetisilẹ si orin alariwo jìnjinjìn fun iye ti o rekọja wakati mẹrin lọjọ kọọkan! Iyẹn dajudaju fi aisi iwadeedee hàn. Kìí ṣe pe ohun kan ṣaitọ pẹlu gbigbadun ohun ti ń mú ki o nimọlara didara tabi alayọ. Dajudaju Jehofa, Ẹlẹdaa orin amunilayọ, kò reti pe ki awọn ọ̀dọ́ eniyan jẹ́ ẹni ti ó wúgbọ tabi ti kò layọ. Nitootọ, ó paṣẹ fun awọn eniyan rẹ̀ pe: “Ki inu yin ki o dun niti Oluwa, ẹ sì maa yọ̀, ẹyin olódodo.” (Orin Dafidi 32:11) Si awọn ọ̀dọ́ eniyan Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ́ pe: “Maa yọ̀, iwọ ọdọmọde ninu èwe rẹ; ki o sì jẹ ki ọkàn rẹ ki o mu ọ laraya ni ọjọ èwe rẹ.”—Oniwasu 11:9.

6. (a) Eeṣe ti awọn èwe fi nilati ṣọra nipa iru orin ti wọn yoo yàn? (b) Eeṣe ti ọpọlọpọ ninu orin lonii fi jẹ́ eyi ti a lodisi ju orin awọn iran ti ó wà tẹlẹ lọ?

6 Bi o tilẹ ri bẹẹ, idi rere wà fun ọ lati jẹ́ oniṣọọra ninu orin ti iwọ bá yàn. Aposteli Paulu sọ ninu Efesu 5:15, 16 pe: “Ẹ kiyesi lati maa rin ni iwa pípé, kìí ṣe bi awọn alailọgbọn, ṣugbọn bi awọn ọlọgbọn; ẹ maa ra ìgbà pada, nitori buburu ni awọn ọjọ.” Awọn èwe melookan lè takò ó, gẹgẹ bi ọdọmọdebinrin kan ṣe ṣe pe: “Awọn òbí wa tẹtisilẹ si orin tiwọn nigba ti wọn wà ni ọ̀dọ́. Eeṣe ti awa kò lè tẹtisi tiwa?” Diẹ ninu awọn orin ti awọn òbí rẹ gbadun niwọn ọjọ-ori rẹ lè ti ní apa-iha ti o ṣeetako pẹlu. Nipa iṣayẹwo finnifinni, ọpọ ninu awọn ọpa-idiwọn pataki naa lọna yiyanilẹnu wá jásí iye ẹ̀dà-ọ̀rọ̀ idibajẹ ti ibalopọ takọtabo ati idọgbọn tọkasi iwapalapala. Ṣugbọn ohun ti a ń pẹ́sọ nigba kan ni a ń ṣapejuwe rẹ̀ láìfọ̀rọ̀bò nisinsinyi. Onkọwe kan ṣakiyesi pe: “Awọn ọmọde ni a bomọlẹ bamu nisinsinyi pẹlu awọn ihin-iṣẹ ṣiṣe kedere lori iwọn kan ti kò dabi ohunkohun ti aṣa wa tii fi ìgbà kan rí rí.”

Orin Ọlọ́rọ̀-Wótòwótò—Orin Ọ̀tẹ̀

7, 8. (a) Ki ni orin ọlọ́rọ̀-wótòwótò jẹ́, ki ni ó sì jẹ́ idi fun ìlókìkí rẹ̀? (b) Ki ni o lè fi ẹnikan hàn yatọ gẹgẹ bi ẹni ti ń dirọ mọ ọ̀nà ìgbà gbé igbesi-aye orin ọlọ́rọ̀-wótòwótò?

7 Fun apẹẹrẹ, gbé igbódekan orin ọlọ́rọ̀wótòwótò yẹwo ní lọ́ọ́lọ́ọ́ yii. Gẹgẹ bi iwe-irohin Time ti wi, orin ọlọ́rọ̀-wótòwótò ti di “iyipada ojiji ti a tẹwọgba, yika ayé ninu orin adúnbárajọ” ti ó sì lokiki ti o ga ni Brazil, Europe, Japan, Russia, ati United States. Lọpọ ìgbà ó sábà maa ń wà laisi orin patapata, awọn ọ̀rọ̀ inu orin rẹ̀ ni a ń sọ, kìí ṣe pe a ń kọ wọn, tẹle ilu ti ń dun kíkakíkan. Bi o ti wu ki o ri, dídún ìlù onisun-un-niṣe yẹn ni o dabi ẹni pe o jẹ́ okunfa aṣeyọri ninu ikẹsẹjari iṣowo giga ti orin ọlọ́rọ̀-wótòwótò. “Nigba ti mo tẹtisilẹ si orin ọlọ́rọ̀-wótòwótò,” ni èwe ilu Japan kan sọ “mo nimọlara irusoke, nigba ti mo bá sì ń jó, mo ń nimọlara ominira.”

8 Awọn ọ̀rọ̀ inu orin ọlọ́rọ̀-wótòwótò—ti ó sábà maa ń jẹ́ adalu oníwàdùwàdù ti ọ̀rọ̀ alaimọ ati awọn ẹnà ìgboro—jọbi idi miiran fun ìgbajúmọ̀ orin ọlọ́rọ̀-wótòwótò. Laidabi awọn ọ̀rọ̀ inu orin alariwo jìnjinjìn atọwọdọwọ, ọpọ ninu eyi ti o níí ṣe pẹlu koko-ọrọ ere-ifẹ awọn ọ̀dọ́langba, awọn ọ̀rọ̀ inu orin ọlọ́rọ̀-wótòwótò maa ń sábà ní ihin-iṣẹ ti o tubọ léwu. Awọn orin ọlọ́rọ̀-wótòwótò kan ń sọrọ lodi si aiṣedajọ-ododo, kẹlẹyamẹya, ati ìrorò awọn ọlọpaa. Nigba miiran, bi o ti wu ki o ri, awọn ègbè rẹ̀ ti ó dun barajọ ni a ń fi awọn èdè rirun eyikeyii, ti ń muni takìjí ti a lè ronu nipa rẹ̀ kọ. Orin ọlọ́rọ̀-wótòwótò tun dabi eyi ti o dakun iṣọtẹ lodisi ọpa-idiwọn aṣọ, imura, ati iwarere ibalopọ takọtabo. Kò yanilẹnu, orin ọlọ́rọ̀-wótòwótò ti di ọ̀nà ìgbà gbé igbesi-aye funraarẹ. Awọn ti wọn fẹ́ ẹ ni a ń damọ yatọ nipasẹ ifaraṣapejuwe alafẹfẹyẹyẹ, ẹnà ìgboro, ati ẹwu—jeans gbàgìẹ̀-gbagiẹ, awọn bata tẹniisi ti kò ni dídè loke, ṣéènì oniwura, awọn fila oníbẹntigọ́ọ̀, ati awò olójú dúdú.

9, 10. (a) Awọn kókó wo ni awọn èwe nilati gbeyẹwo ninu ṣiṣe ipinnu bi orin ọlọ́rọ̀-wótòwótò ati ọ̀nà ìgbà gbé igbesi-aye rẹ̀ bá jẹ́ eyi ti o “ṣe itẹwọgba fun Oluwa”? (b) Ki ni ohun ti o dabi ẹni pe awọn èwe Kristian kan ń fọwọ yẹpẹrẹ mu?

9 Ninu Efesu 5:10, awọn Kristian ni a sọ fun lati “maa wadii ohun tii ṣe itẹwọgba fun Oluwa.” Ni ṣiṣagbeyẹwo orukọ ti orin ọlọ́rọ̀-wótòwótò ti ṣe fun araarẹ, iwọ ha rò pe yoo jẹ́ “ohun tii ṣe itẹwọgba fun Oluwa” fun ọ lati di ẹni ti o kówọnú rẹ̀ bi? Ǹjẹ́ Kristian èwe kan yoo ha fẹ́ lati di ẹni ti a damọ yatọ pẹlu ọ̀nà ìgbà gbé igbesi-aye ti a kàsí eyi ti kò ni itẹwọgba lọdọ ọpọ awọn eniyan ayé paapaa bi? Ṣakiyesi bi onkọwe alatun-unṣe kan ṣe ṣapejuwe agbo ẹgbẹ́ orin ọlọ́rọ̀-wótòwótò kan pe: “Awọn akọrin ọlọ́rọ̀-wótòwótò naa fagagbaga pẹlu ẹnikinni keji lati jẹ́ ẹni ti ń muni takìjí julọ pẹlu awọn ọ̀rọ̀ alaimọ ati awọn ọ̀rọ̀ inu orin onibaalopọ takọtabo ṣiṣe kedere. . . . Awọn onijo ọkunrin ati obinrin faraṣapejuwe iṣe ibalopọ takọtabo lori ìtàgé.” Nipa olewaju oṣere kan bayii, ọ̀kan ninu awọn agbátẹrù oṣere naa sọ pe: “Gbogbo ọ̀rọ̀ ti ń ti ẹnu wọn jade jẹ́ (rírùn).”

10 Bi o tilẹ ri bẹẹ paapaa, agbara káká ni orin ti a kọ ni alẹ́ ọjọ yẹn fi ṣàìjẹ́ orin ọlọ́rọ̀ wótòwótò niti gidi. Oluṣekokaari gbọngan ẹgbẹ́ akọrin naa sọ pe: “Ohun ti ẹ ń gbọ́ jẹ́ ọmọ-ìyá orin ọlọ́rọ̀-wótòwótò—ọ̀kan naa bi iwọnyi ti wọn ń rà ninu awọn ile itaja.” Ó ti banininujẹ tó lati rohin pe laaarin awọn 4,000 ati pupọ sii awọn èwe ti o pesẹ sibẹ nigba orin kíkan yẹn ni awọn melookan ti wọn jẹwọ pe awọn jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jehofa wà! Awọn kan ti fọwọ dẹngbẹrẹ mu otitọ naa pe Satani ni “alaṣẹ agbara oju ọrun.” Ó ń ṣakoso “ẹmi [tabi, ẹmi-ironu ọpọlọ ti o wọ́pọ̀ julọ] ti ń ṣiṣẹ nisinsinyi ninu awọn ọmọ alaigbọran.” (Efesu 2:2) Ire ta ni iwọ yoo ṣiṣẹsin fun bi iwọ bá di ẹni ti o lọwọ ninu orin ọlọ́rọ̀-wótòwówò tabi ọ̀nà ìgbà gbé igbesi-aye orin ọlọ́rọ̀-wótòwótò? A gbà pe, awọn orin ọlọ́rọ̀-wótòwótò melookan lè dabi eyi ti a kò fi bẹẹ lodisi niti akojọpọ orin inu wọn. Ṣugbọn ó ha lọgbọn-ninu lati mú ikundun dagba fun iru orin eyikeyii ti o wọ́pọ̀ julọ ni ṣiṣe laifi si awọn ọpa-idiwọn Kristian bi?

Orin Onílù-dídún Kíkankíkan—Ibalopọ Takọtabo, Iwa-ipa, ati Ijọsin Satani

11, 12. Ki ni orin onílù-dídún kíkankíkan jẹ́, apa ti kò fanimọra wo ninu rẹ̀ ni a fi ń dá a mọ̀?

11 Iru oriṣi orin lilokiki miiran ni orin onílù-dídún kíkankíkan. Orin onílù-dídún kíkankíkan ju orin alariwo jìnjinjìn ti ń hannilétí gooro lọ. Akọsilẹ kan ninu The Journal of the American Medical Association sọ pe: “Orin onílù-dídún kíkankíkan . . . a maa gbé ìlùkìkì alariwo ti ń dún barajọ jade ó sì kún fun awọn ọ̀rọ̀ inu orin ti ó gbé ikoriira, àṣìlò, àṣerégèé ibalopọ takọtabo, ati ni awọn ìgbà kọọkan ijọsin Satani larugẹ.” Họwu, orukọ diẹ ninu awọn ẹgbẹ́ ti o tubọ gbajúmọ̀ nikan ti tó lati jẹrii si idibajẹ iru orin onílù-dídún kíkankíkan yii. Ninu wọn ni a rí iru awọn orukọ bii “majele,” “ìbọn,” ati “iku.” Sibẹ, awọn orin onílù-dídún kíkankíkan dabi eyi ti o rọjú diẹ ni ifiwera pẹlu orin rọ́ọ̀kì alariwo ati orin rọ́ọ̀kì iku—apakan itolẹsẹẹsẹ orin ti o ti inu orin onilù-dídún kíkankíkan jade wá. Orukọ awọn ẹgbẹ́-òṣèré wọnyi lo awọn èdè-ìsọ̀rọ̀ bi “ajẹ̀nìyàn” ati “ìtúfọ̀.” Awọn èwe ni ọpọ ilẹ lè má mọ bi awọn orukọ wọnyi ti kóninírìíra tó ni èdè Gẹẹsi tabi èdè ajeji miiran.

12 Orin onílù-dídún kíkankíkan ni a ti sopọ lemọlemọ pẹlu ifọwọ ara-ẹni para-ẹni, ikimọlẹ, ati aṣilo oogun awọn èwe. Isopọ rẹ̀ pẹlu iwa oniwa-ipa mú ki oṣiṣẹ ile redio kan pè é ni “orin ti o gbayì lati pa awọn òbí rẹ.” Isopọ ti o ni pẹlu ijọsin Satani ni ó kó ipaya bá ọpọ awọn òbí—ati awọn oṣiṣẹ ọlọpaa. Oluwadii kan jẹwọ pe awọn èwe melookan ti ń lọwọ ninu ijọsin Satani laiduro ronu ni a mú wọnu ẹgbẹ́ ohun ijinlẹ awo nipasẹ orin yii. “Wọn kò mọ ohun ti wọn ń kowọnu rẹ,” ni ó fi pari ọ̀rọ̀.

13. Ki ni ewu ti o wà ninu didi ẹni ti o lọwọ ninu orin onílù-dídún kíkankíkan?

13 Bi o ti wu ki o ri, awọn èwe Kristian kò gbọdọ jẹ́ “aláìmọ arekereke [Satani].” (2 Korinti 2:11) Ó ṣetan, ‘awa ń jijakadi . . . lodisi awọn alaṣẹ ibi okunkun ayé yii, ati awọn ẹmi buburu ni oju ọrun.’ (Efesu 6:12) Yoo ti jẹ́ iwa òmùgọ̀ tó, nipa orin ti ẹnikan yàn, lati késí awọn ẹmi eṣu sinu igbesi-aye rẹ! (1 Korinti 10:20, 21) Sibẹ, awọn èwe Kristian diẹ ni o ṣe kedere pe wọn kundun orin yii pupọ. Awọn kan tilẹ ti pari rẹ̀ si lilo ọ̀nà onibookẹlẹ paapaa lati tẹ́ adun orin wọn lọ́rùn. Ọdọmọdebinrin kan jẹwọ pe: “Mo maa ń tẹtisi orin onílù-dídún kíkankíkan, nigba miiran ó fẹrẹẹ jẹ́ jálẹ̀ gbogbo òru. Emi yoo ra awọn iwe-irohin [olufẹ] orin onílù-dídún kíkankíkan emi yoo sì fi wọn pamọ sinu paali bata ki awọn òbí mi ma baa rí wọn. Mo purọ fun awọn òbí mi. Mo mọ pe inu Jehofa kò dun si mi.” Ori rẹ̀ ni a pè wálé nipasẹ ọrọ-ẹkọ kan ninu iwe-irohin Ji! Awọn èwe meloo sii ni a ṣì lè dẹkùn mú nipa iru orin bẹẹ?

Kíká Ohun Ti O Gbìn

14, 15. Eeṣe ti a fi lè nidaaniloju pe titẹtisilẹ si orin ti kò sunwọn yoo ni iyọrisi buburu? Ṣakawe.

14 Maṣe foju kéré ewu ti iru orin bẹẹ lè mú dani. Loootọ, iwọ lè má ni itẹsi lati pa ẹnikan tabi lati dẹ́ṣẹ̀ iwapalapala ibalopọ takọtabo kìkì nitori pe o tẹtisi orin kan. Bi o tilẹ ri bẹẹ, Galatia 6:8 sọ pe: “Ẹni ti o bá ń funrugbin sipa ti ara rẹ̀, nipa ti ara ni yoo ká idibajẹ.” Titẹti si orin ti o jẹ́ ti ayé, oniwa ẹranko, ati ẹlẹmii-eṣu paapaa wulẹ lè ní ipa buburu lori rẹ̀. (Fiwe Jakọbu 3:15.) Ọjọgbọn nipa orin Joseph Stuessy ni a ṣayọlo ọ̀rọ̀ rẹ̀ pe o sọ pe: “Iru orin eyikeyii a maa nipa lori iwa wa, ero-imọlara wa, iṣarasihuwa ati ìṣesí wa . . . Ẹnikẹni ti o bá sọ pe, ‘mo lè tẹtisilẹ si orin onílù-dídún kíkankíkan, ṣugbọn kìí nipa lori mi,’ kò tọna rara. Ó wulẹ ń nipa lori awọn eniyan yiyatọ sira ni iwọn yiyatọ sira ati ni ọ̀nà yiyatọ sira ni.”

15 Èwe kan ti o jẹ́ Kristian gbà pe: “Mo kó araami wọnu iru oriṣi orin onílù-dídún kíkankíkan gidi gan-an debi pe gbogbo akopọ animọ mi yipada.” Laipẹ ó bẹrẹ sii ni awọn iṣoro pẹlu awọn ẹmi-eṣu. “Nigbẹhin-gbẹhin mo kó gbogbo awọn ohun-eelo orin mi danu awọn ẹmi-eṣu naa sì fi mi silẹ.” Èwe miiran jẹwọ pe: “Orin ti mo maa ń tẹtisilẹ si nii ṣe pẹlu yala ibẹmiilo, oogun, tabi ibalopọ takọtabo. Ọpọ awọn èwe sọ pe kìí nipa lori awọn, ṣugbọn ó ń ṣe bẹẹ niti gidi. Mo fẹrẹẹ kuro ninu otitọ patapata.” Owe kan beere pe: “Ọkunrin lè gbé iná [lé] àyà rẹ̀ ki aṣọ rẹ̀ ki o ma jona?”—Owe 6:27.

Ẹ Maa Ṣọra

16. Ki ni a lè sọ nipa awọn onkọwe ati onṣewe ọpọ julọ ninu awọn orin lonii?

16 Paulu kọwe si awọn Kristian ni Efesu igbaani pe: “Eyi ni mo ń wí, ti mo sì ń jẹrii ninu Oluwa pe, lati isinsinyi lọ ki ẹyin ki o maṣe rìn mọ́, àní gẹgẹ bi awọn Keferi ti ń rìn ninu ironu asán wọn, òye awọn ẹni ti o ṣokunkun, awọn ti o sì ti di ajeji si iwa-bi-Ọlọrun nitori aimọ ti ń bẹ ninu wọn, nitori lile ọkàn wọn.” (Efesu 4:17, 18) A kò ha lè sọ eyi nipa awọn onkọwe ati oṣere ọpọ julọ orin lonii bi? Ju ti igbakigba ri lọ, gbogbo ohun ti o parapọ jẹ́ apakan itolẹsẹẹsẹ orin ń fi agbara idari “ọlọrun ayé yii,” Satani Eṣu hàn.—2 Korinti 4:4.

17. Bawo ni awọn èwe ṣe lè ṣedajọ tabi dán orin wo?

17 Nipa “ikẹhin ọjọ,” Bibeli sọ asọtẹlẹ pe: “Awọn eniyan buburu, ati awọn ẹlẹtan yoo maa gbilẹ siwaju sii.” (2 Timoteu 3:1, 13) Ju ti igbakigba ri lọ, nigba naa, iwọ nilati kiyesi iru orin ti o yan gidigidi. Lọpọ ìgbà, akọle akóninírìíra naa yoo mú ki awọn orin naa ṣaitootun. Jobu 12:11 beere pe: “Eti kìí dán ọ̀rọ̀ wo bi? tabi adùn ẹnu kìí sìí tọ́ ounjẹ rẹ̀ wò?” Ni ọ̀nà kan-naa, iwọ lè dán orin wo nipa titẹtisilẹ si apẹẹrẹ rẹ̀ pẹlu etí iṣelameyitọ. Iru imọlara wo ni orin-adunyungba naa gbé dide ninu rẹ? Ó ha ṣe igbelarugẹ iwa-ẹhanna, arẹnisilẹ—ẹmi ariya alariwo bi? (Galatia 5:19-21) Ki ni nipa ti ọ̀rọ̀ inu rẹ̀? Wọn ha ń gbe iwapalapala ibalopọ takọtabo, lilo oogun, tabi awọn ohun aitọ miiran ti o jẹ ‘itiju lati maa sọrọ rẹ̀’ larugẹ bi? (Efesu 5:12) Bibeli sọ pe iru awọn nǹkan bawọnni ni a kò gbọdọ “darukọ rẹ̀” laaarin awọn eniyan Ọlọrun, ki a má tilẹ wá sọ ọ́ di dídún ilu ki a sì maa lù ú lemọlemọ nigba gbogbo. (Efesu 5:3) Ki ni nipa ọnà ara epo-ẹhin paali àwo naa? Ó ha ni awọn ẹṣin-ọrọ ibẹmiilo tabi awọn aworan ti ń runisoke niti ibalopọ takọtabo ninu bi?

18. (a) Iru iyipada wo ni awọn èwe kan nilati ṣe nigba ti o bá kan ọ̀ràn orin? (b) Bawo ni awọn èwe ṣe lè mú adùn fun orin ti o tubọ jẹ́ eyi ti o sunwọn sii dagba?

18 Boya o nilati ṣe awọn iyipada diẹ ninu iru orin ti o yàn. Bi iwọ bá ni awọn rẹkọọdu, teepu, ati awọn àwo orin ti o ni awọn ẹṣin-ọrọ iwapalapala ati ti ẹlẹmii-eṣu ninu, iwọ nilati kó gbogbo wọn danu lójú-ẹsẹ̀. (Fiwe Iṣe 19:19.) Eyi kò tumọsi pe iwọ kò lè gbadun orin; kìí ṣe gbogbo orin ti o lokiki ni ó jẹ́ eyi ti a lodisi. Awọn èwe miiran tilẹ ti kẹkọọ lati mú adun orin wọn gbooro sii ti wọn sì ń gbadun orin atijọ, orin ibilẹ, orin jazz fẹẹrẹfẹ, ati iru oriṣi orin miiran nisinsinyi. Teepu Kingdom Melodies ti ran ọpọlọpọ èwe lọwọ lati mú ìfẹ́-ọkàn dagba fun orin awọn awujọ akọrin ti ń gbeniro.

19. Eeṣe ti o fi ṣe pataki lati pa orin mọ́ si ààyè rẹ̀?

19 Orin jẹ́ ẹbun atọrunwa kan. Fun ọpọlọpọ, bi o ti wu ki o ri, ó ń di iṣẹ ti kò nilaari kan ti ń gba gbogbo afiyesi ẹni. Iwọnyi dabi awọn ọmọ Israeli igbaani ti wọn gbadun lilo ‘harpu, ati harpu kekere, ilu, fèrè, . . . ṣugbọn wọn kò ka iṣẹ Oluwa sí.’ (Isaiah 5:12) Fi ṣe gongo rẹ lati pa orin mọ́ si ààyè rẹ̀ ki o sì jẹ́ ki igbokegbodo Jehofa jẹ́ lajori aniyan rẹ. Mọ bi a tii ṣe àṣàyàn ki o sì ṣọra nipa orin ti o yàn. Nipa bayii yoo ṣeeṣe fun ọ lati lo—kìí ṣe lati ṣi—ẹbun atọrunwa yii lò.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Orilẹ-ede Israeli ni ó hàn kedere pe ó lékè ninu iṣẹ orin. Aworan gbígbẹ́ awọn ara Assiria kan ṣí i payá pe Ọba Sennakeribu beere fun awọn olorin ọmọ Israeli gẹgẹ bi owó-òde lati ọ̀dọ̀ Ọba Hesekiah. Grove’s Dictionary of Music and Musicians ṣakiyesi pe: “Lati beere fun awọn akọrin gẹgẹ bi owó-òde . . . jẹ ohun ti o ṣara-ọtọ niti gidi.”

Iwọ Ha Ranti Bi?

◻ Eeṣe ti a fi lè pe orin ni ẹbun atọrunwa?

◻ Bawo ni a ṣe lo orin ni ilokulo ni awọn akoko igbaani?

◻ Iru awọn ewu wo ni orin ọlọ́rọ̀-wótòwótò ati orin onílù-dídún kíkankíkan gbe jade fun awọn èwe Kristian?

◻ Bawo ni awọn èwe Kristian ṣe lè lo iṣọra ninu orin ti wọn bá yàn?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Ni awọn akoko ti a kọ Bibeli, orin ni a sábà maa ń lò gẹgẹ bi ọ̀nà ìgbàmú iyin wá fun Jehofa

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́