Agbára Orin
“Àní orin lásán, tí ń tani jí, lè pe orí ẹni wálé, kí ó sì fini lọ́kàn balẹ̀.”
ÈYÍ ni ohun tí William Congreve kọ ní nǹkan bí ọ̀ọ́dúnrún ọdún sẹ́yìn nínú ìwé rẹ̀ tó pè ní Hymn to Harmony. Ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ṣáájú rẹ̀, àwọn ìwé Gíríìkì ìgbàanì tilẹ̀ sọ pé “ohun èlò alágbára tí kò láfiwé ni ẹ̀kọ́ orin jẹ́, nítorí pé orin tí ń lọ ní mẹ̀lọmẹ̀lọ àti àwọn ohùn tí ń dún bára jọ a máa wọni lákínyẹmí ara.”
Òdodo ọ̀rọ̀ lèyí o, nítorí pé àwọn òbí kan ti ṣàkíyèsí pé ṣe làwọn ọmọ wọn tó jẹ́ ọ̀dọ́langba, máa ń dijú mágbárí kiri, tí wọ́n sì máa ń ya kìígbọ́-kìígbà, lẹ́yìn tí wọ́n bá ti gbọ́ orin rọ́ọ̀kì onílù dídún kíkankíkan tán. Bẹ́ẹ̀ náà lọ̀ràn rí láwọn ọdún 1930 àti àwọn ọdún 1940 ní Jámánì nígbà tí ìjọba Násì lo àwọn orin ológun amóríwú láti fi fa ogunlọ́gọ̀ lọ́kàn mọ́ra kí wọ́n lè tẹ́tí sáwọn ọ̀rọ̀ amúnimúyè tí Adolf Hitler ní í sọ.
Àkíìkà, orin lágbára o, àní ó lè gba gbogbo èrò inú àti ọkàn, ó sì ṣeé fi darí wọn, fún ète rere tàbí búburú. Fún àpẹẹrẹ, bí àwọn ògo wẹẹrẹ bá ń gbọ́ irú àwọn orin kan, ó lè mú kí agbára ìmòye àti èrò ìmọ̀lára wọn sunwọ̀n sí i. Kódà nígbà mí-ìn, àwọn akólòlò lè fi àwọn gbólóhùn tí wọn kò lè sọ lọ́rọ̀ ẹnu ṣe orin kọ.
Gẹ́gẹ́ bí Anthony Storr ti wí nínú ìwé rẹ̀ Music and the Mind, agbára orin tún gadabú lórí àwọn aláìsàn tí iṣan ara wọ́n ti dẹ̀ jọ̀wọ̀lọ̀, tó wá jẹ́ kó ṣòro fún wọn láti gbéra ńlẹ̀. Ọ̀gbẹ́ni Storr mú àpẹẹrẹ obìnrin aláìsàn kan wá, ó ní: “Níwọ̀n bí àrùn [Parkinson] ti sọ ọ́ di aláìlègbápá-gbẹ́sẹ̀, ṣe ni yóò kàn dùbúlẹ̀ láìlègbérasọ, àfìgbà tó bá rántí àwọn orin kan tó ti gbọ́ nígbà èwe rẹ̀. Gbàrà tó bá rántí orin wọ̀nyí ni ara rẹ̀ á tún jí pépé.”
Ó Gba Ìṣọ́ra
Bẹ́ẹ̀ ni, ó jọ pé àǹfààní ò ṣàìsí nínú agbára orin. Àmọ́, ewu ń bẹ, nítorí pé àwọn oníwà ìbàjẹ́ tàbí àwọn ọ̀kánjúà lè fi agbára orin ṣekú pani. Àwọn ìwádìí kan ti fi hàn pé irú àwọn orin kan ń fa ìwà jàgídíjàgan láwùjọ.
Láti ti irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn, ìwé ìròyìn Psychology of Women Quarterly ròyìn pé: “Ẹ̀rí rẹpẹtẹ wà tó fi hàn pé wíwo fídíò orin rọ́ọ̀kì, kò yàtọ̀ sí wíwo àwọn nǹkan tí ń ru ìfẹ́ ìṣekúṣe sókè, nítorí pé àwọn ọkùnrin tó wo fídíò orin rọ́ọ̀kì tó kún fún ìwà ipá bẹ̀rẹ̀ sí hùwà ọ̀dájú àti ìwà kèéta sáwọn obìnrin ju bí àwọn ọkùnrin tó wo fídíò orin rọ́ọ̀kì tí kò ní ìwà ipá ti ṣe lọ.”
Kì í ṣe àwọn ọkùnrin nìkan ló ń nípa lórí wọn o. Ó kan àwọn obìnrin pẹ̀lú. Ìròyìn yẹn fi kún un pé: “Àtọkùnrin àtobìnrin lè bẹ̀rẹ̀ sí tẹ́wọ́ gba èrò burúkú tí orin wọ̀nyí ń gbìn síni lọ́kàn pé obìnrin ò wúlò rárá.”
Ìwé ìròyìn Sex Roles jẹ́rìí sí èyí, ó ní: “Ìwádìí àìpẹ́ yìí kan . . . fi hàn pé nǹkan méjì, èyíinì ni ṣíṣàì ti ilé rere wá àti fífi ojoojúmọ́ ayé wo fídíò àwọn olórin, ló sábà máa ń fa ìrìn ìranù àti ìwà ìṣekúṣe láàárín àwọn ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ obìnrin.” Ìwà ipá tó lè jẹ́ kára èèyàn bù máṣọ àti ọ̀rọ̀kọ́rọ̀, ọ̀rọ̀ àlùfààṣá tí wọ́n ń kọ jáde nínú àwọn orin ọlọ́rọ̀ wótòwótò kan, mú kí adájọ́ kan ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà pàṣẹ pé àwo orin ọlọ́rọ̀ wótòwótò kan báyìí “burú, ó tún bògìrì, lójú ìwòye ohun tó bójú mu láwùjọ.”
Adájọ́ yẹn kọjá àyè ẹ̀ bí? Ó tì o! Àlàyé ìwé ìròyìn Adolescence ni pé “àwọn ọ̀dọ́ àtàwọn òbí wọn ṣàkíyèsí pé pákáǹleke púpọ̀ sí i máa ń ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí ayé àwọn ọ̀dọ́ tó ń gbọ́ orin onílù dídún kíkankíkan àti orin ọlọ́rọ̀ wótòwótò.” Irú àwọn pákáǹleke bẹ́ẹ̀ máa ń fa “ìwà jàgídíjàgan àti ìwà bàsèjẹ́,” ó sì tún máa ń fa gbígbòdo níléèwé.
Àní, ẹ̀rí pelemọ wà tó fi hàn pé irú àwọn orin kan máa ń fa ìṣekúṣe, ìpara-ẹni, àti yíya ìpátá. Ṣùgbọ́n ṣé ohun táa wá ń sọ ni pé gbogbo orin ló ń fa irú àwọn nǹkan burúkú bẹ́ẹ̀? Jọ̀ọ́ ka ohun tí àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e ní í sọ nípa èyí.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 4]
Orin lè ní ipa lórí ọkàn àti èrò inú wa, fún ète rere tàbí búburú