ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 11/22 ojú ìwé 21-23
  • Orin Rọ́ọ̀kì Àfidípò—Ó Ha Wà fún Mi Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Orin Rọ́ọ̀kì Àfidípò—Ó Ha Wà fún Mi Bí?
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ní Ń Wuni Nínú Rẹ̀?
  • Ọ̀rọ̀ Ìṣọ́ra
  • Máa Ṣàṣàyàn
  • Ẹ Ṣọra fun Awọn Orin ti Kò Sunwọn!
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Báwo Ni Mi Ò Ṣe Ní Ki Àṣejù Bọ Orin Gbígbọ́?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Ṣé Mo Lè Yan Orin Tó Bá Ṣáà Ti Wù Mí?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ní Ojú Ìwòye Tó Wà Níwọ̀ntúnwọ̀nsì Nípa Orin
    Jí!—1999
Jí!—1996
g96 11/22 ojú ìwé 21-23

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Orin Rọ́ọ̀kì Àfidípò—Ó Ha Wà fún Mi Bí?

“Mo lè lóye àwọn orin tí ń sọ nípa onírúurú ìṣòro àti ìrírí tí àwa ọ̀dọ́ ń ní.” —George, ọmọ ọdún 15.a

“Ó wà lágbede méjì orin lílókìkí àti orin onílù kíkankíkan.”—Dan, ọmọ ọdún 19.

“Ọ̀tun ni. Ó yàtọ̀. Kì í ṣe orin lílókìkí, tí a ṣe lọ́pọ̀ jaburata.”—Maria, ọmọ ọdún 17.

ORIN rọ́ọ̀kì àfidípò. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀dọ́ ń gbádùn títẹ́tí sí i. Ó ń da àwọn àgbàlagbà kan láàmú. Ọ̀pọ̀ jù lọ òbí kò sì tilẹ̀ mọ ohun tí ń jẹ́ bẹ́ẹ̀ rárá.

Láìsí sísẹ́, kò rọrùn láti ṣàlàyé ohun tí orin rọ́ọ̀kì àfidípò jẹ́ ní ti gidi. Ní ìbẹ̀rẹ̀, orin àwọn ọ̀dọ́ tí ń fẹ́ nǹkan tí ó yàtọ̀ ni, àfidípò kan sí gbajúmọ̀ orin lílókìkí tí wọ́n ń gbọ́ lórí rédíò. Àwọn kán sọ pé ó bẹ̀rẹ̀ nígbà tí àwọn ilé iṣẹ́ rédíò kọ́lẹ́ẹ̀jì àdúgbò bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ohùn àwọn ẹgbẹ́ olórin tí kò gbajúmọ̀ jáde—àwọn ẹgbẹ́ olórin tí ń fi ara wọn yangàn ní ti pé wọn kò ṣe àwọn orin wọn fún ilé iṣẹ́ ìṣòwò orin láti mú èrè owó wọlé. Àwọn ìsọ̀wọ́ olórin tuntun wọ̀nyí ta kété sí àwọn orúkọ ìdánimọ̀ ìgbáwojáde lílókìkí àti àwọn ọ̀nà ìṣòwò rẹpẹtẹ, bíi ti fídíò orin. Bákan náà ni wọ́n ń kọrin nípa àwọn kókó tí 40 Orin Agbégbá Orókè kì í sábà mẹ́nu bà.

Láìdàbí orin onílù kíkankíkan tàbí orin ọlọ́rọ̀ wótòwótò, orin rọ́ọ̀kì àfidípò kì í sábà rọrùn láti dá mọ̀ tàbí láti pín sí ìsọ̀rí. Àwọn ògbógi nínú iṣẹ́ orin pàápàá kò fohùn ṣọ̀kan lórí ohun tí orin rọ́ọ̀kì àfidípò jẹ́. Ìyẹ́n jẹ́ nítorí pé, gẹ́gẹ́ bí orúkọ rẹ̀ ti fi hàn, ó ní onírúurú ìró, àfihàn ipò ọkàn, àti ìmọ̀lára nínú. Ọ̀dọ́kùnrin kán sọ pé: “Ó ṣòro gan-an láti pín in sí ìsọ̀rí. Ó kó ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ apá nínú àwọn orin òde òní mọ́ra.” Ọ̀dọ́ mìíràn ṣàlàyé pé: “Kì í fìgbà gbogbo le tàbí kí ó ṣe jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, kí ó yá tàbí kí ó fà, kí ó dáni lára yá tàbí kí ó múni rẹ̀wẹ̀sì.” Ọ̀dọ́ kan tilẹ̀ jẹ́wọ́ pé: “Kò dá mi lójú pé mo lè sọ pé mo fẹ́ràn orin rọ́ọ̀kì àfidípò nítorí pé ohun tí ó jẹ́ gan-an kò dá mi lójú.”

Bí ó ti wù kí ó rí, òkìkí orin rọ́ọ̀kì àfidípò ti kàn débi pé púpọ̀ lára àwọn gbajúmọ̀ tí ń kọ ọ́ ni a ti kà mọ́ àwọn olókìkí akọrin. Bákan náà, ó jọ pé ìtẹ̀sí tí àwọn òbí ní láti ṣàtakò sí i kò pọ̀ tó èyí tí wọ́n ní sí orin onílù kíkankíkan tàbí àwọn oríṣi orin rọ́ọ̀kì adinilétí mìíràn. Ní gidi, ó jọ pé ìwọ̀nba òbí díẹ̀ ló tilẹ̀ mọ irú ọ̀wọ́ orin tàbí àwọn àkọlé orin tí wọ́n ń pè ní àfidípò. Síbẹ̀síbẹ̀, ó pọn dandan fún ọ láti lo ìṣọ́ra nígbà tí ọ̀rán bá kan irú orin yìí.

Kí Ní Ń Wuni Nínú Rẹ̀?

Fún àpẹẹrẹ, ṣàyẹ̀wò ìdí tí ọ̀pọ̀ àwọn èwé fi ní òòfà ọkàn sí orin yìí. Púpọ̀ nínú wọ́n wulẹ̀ rí i bí ọ̀ràn títẹ̀ síbi tí àwọn ọ̀rẹ́ ẹní tẹ̀ sí. Ó tún pèsè ìpìlẹ̀ àjùmọ̀ní fún ìjíròrò àti àwọn ìgbòkègbodò, bíi ṣíṣe pàṣípààrọ̀ àwọn kásẹ́ẹ̀tì àti àwọn ike ìkósọfúnnisi CD.

Bí ó ti wù kí ó rí, ìró ìlù àti ọ̀rọ̀ orin rọ́ọ̀kì àfidípò ló ń fa àwọn èwe púpọ̀ jù lọ mọ́ra tó bẹ́ẹ̀. Ní pàtàkì, ọ̀pọ̀ èwé rí i pé àwọn lóye àwọn ìrírí àti ìmọ̀lára àwọn akọrin náà. Àwọn ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ nípa kókó ọ̀ràn yìí tí a fi sẹ́yìn ìwé ìròyìn Time kan, tí a sì jíròrò nínú rẹ̀ gan-an, ṣàlàyé pé: “Nígbà tí àwọn orin lílókìkí sábà máa ń jẹ́ nípa ìfẹ́, àwọn orin àfidípò sábà máa ń jẹ́ nípa àwọn ìmọ̀lára jíjinlẹ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ: ìsọ̀rètínù, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, ìdàlọ́kànrú. . . . Bí o bá wà láàárín ọmọ ọdún mẹ́tàlá sí mọ́kàndínlọ́gbọ́n, ó ṣeé ṣe kí ìkọ̀sílẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ nínú ìdílé rẹ. Orin àfidípò ti di ohùn orin àgbàsílẹ̀ tí ń fi èrò ìmọ̀lára hàn, tí ó sì ń sọ̀rọ̀ ṣàkó nípa àwọn ọ̀ràn ìpatì àti àìṣẹ̀tọ́ tí a kò yanjú.” Nípa bẹ́ẹ̀, ọmọ ọdún 21 kan tí ó jẹ́ ajáyọ̀sórin ní kọ́lẹ́ẹ̀jì sọ pé: “Ó fa èmi àti àwọn ọ̀rẹ́ mi lọ́kàn mọ́ra nítorí pé ìran tiwá ti dágunlá sí ayé. Kò sí ohun kankan fún wa nígbà tí a bá parí ẹ̀kọ́ wa.”

Àwọn èwe Kristẹni kan ti di ẹni tí ń kúndùn orin rọ́ọ̀kì àfidípò bákan náà. Lọ́nà ti ẹ̀dá, ọ̀pọ̀ jù lọ ti yẹra fún àwọn orin líle koko, ẹlẹ́mìí ọ̀tẹ̀, oníwà ipá, tàbí oníṣekùṣe ju ìyẹn lọ. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn kan nínú àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni wọ̀nyí ti sọ àwọn èrò yíyàtọ̀ jáde nípa àwọn orin tí ó jọ pé wọn kò léwu tó bẹ́ẹ̀. Dan ọ̀dọ́ sọ pé: “A mọ àwọn kan lára àwọn akọrin náà bí ọkùnrin tàbí obìnrin abẹ́yàkannáàlòpọ̀ tàbí ajoògùnyó, àwọn orin wọ́n sì ń gbé àwọn ọ̀nà ìgbésí ayé wọn lárugẹ.” Èwe mìíràn, tí ń jẹ́ Jack, sọ pé: “Àwọn kan nínú àwọn ẹgbẹ́ akọrin náà ní èrò pé kò sí ẹnikẹ́ni tí ó bìkítà nípa wọn, ìṣòro wọn, tàbí ọjọ́ ọ̀la àwọn èwe ìwòyí, wọ́n sì ń fi èyí hàn nínú àwọn orin wọn. Ọ̀pọ̀ nínú wọn kò ní ète ìsúnniṣe tàbí ìrètí kankan.”

Ọ̀rọ̀ Ìṣọ́ra

Bíbélì sọ fún wa pé “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú naa,” Sátánì Èṣù. (Jòhánù Kìíní 5:19) Kò gbọdọ̀ yà ọ́ lẹ́nu nígbà náà pé, orín jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọ̀nà tí Sátánì ń gbà ṣi àwọn ọ̀dọ́ lọ́nà. Àwọn àpilẹ̀kọ tí a ti kọ sẹ́yìn nínú ìwé agbéròyìnjáde yìí àti ìwé ìròyìn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, Ilé Ìṣọ́, ti ṣàfihàn kókó yìí léraléra.b Àwọn ọ̀rọ̀ ìkìlọ̀ tí a ti fúnni nípa eré onílù kíkankíkan àti orin ọlọ́rọ̀ wótòwótò tún bá a mu wẹ́kú bí ó bá kan orin rọ́ọ̀kì àfidípò. Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ ọ́, “amòye ènìyán yẹ ọ̀nà rẹ̀ wò rere.”—Òwe 14:15.

Bí àpẹẹrẹ kan, kì yóò fọgbọ́n hàn tó bẹ́ẹ̀ láti tẹ̀ síbi tí ọ̀pọ̀ ènìyán tẹ̀ sí bí ọ̀rán bá kan orin tí o fẹ́. Ṣàkíyèsí ìlànà Bíbélì yìí, tí ó lè kan jíjẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn ṣe ìpinnu fún ọ, pé: “Ẹ̀yin kò ha mọ̀ pé bí ẹ bá ń jọ̀wọ́ ara yín fún ẹnikẹ́ni gẹ́gẹ́ bí ẹrú láti ṣègbọràn sí i, ẹ̀yín jẹ́ ẹrú rẹ̀ nítorí ẹ̀ ń ṣègbọràn sí i?” (Róòmù 6:16) Fún èwe Kristẹni kan, ọ̀ràn náà kì í ṣe ti ohun tí ó ṣètẹ́wọ́gbà láàárín àwọn ojúgbà ẹni, bí kò ṣe ti “ohun tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa.” (Éfésù 5:10) Yàtọ̀ sí ìyẹn, irú àwọn èwe wo ni orin rọ́ọ̀kì àfidípò ń fà mọ́ra? Ṣé àwọn èwe tí ó jọ pé wọ́n láyọ̀, wọ́n wà déédéé, tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ sí àwọn ohun ti ẹ̀mí ni? Tàbí ó jọ pé, àwọn olùtẹ́tísí rẹ̀ jẹ́ àwọn èwe aláìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn, aláìláyọ̀, tàbí tí inú ń bí pàápàá, ní pàtàkì?

Lóòótọ́, orin rọ́ọ̀kì àfidípò ṣì lè fa àwọn èwe tí wọ́n ní àkópọ̀ ìwà ìtúraká, olójú ìwòye nǹkan yóò dára mọ́ra. Ṣùgbọ́n gbé èyí yẹ̀ wò: Àwọn Kristẹni, tèwetàgbà, ní ọjọ́ iwájú dáradára kan nípamọ́. (Pétérù Kejì 3:13) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rán wa létí nípa bí ìmúṣẹ àwọn ìlérí Ọlọ́run ṣe dáni lójú tó, wí pé: “Kò ṣeé ṣe fún Ọlọ́run láti purọ́.” (Hébérù 6:18) Nígbà náà, kí ni àǹfààní tí ó wà nínú ṣíṣí ara rẹ payá sí ojú ìwòye dídà gùdẹ̀, tí ó lòdì, tí ó wà nínú ọ̀pọ̀ orin rọ́ọ̀kì àfidípò? Dídi ẹni tí ó fara jin àwọn orin tí ń sọ̀rọ̀ nípa ìbẹ̀rù, ìsọ̀rètínù, àti àìnírètí ha lè jin ìgbàgbọ́ rẹ lẹ́sẹ̀ bí? Síwájú sí i, ipa wo ni fífetí sí irú orin bẹ́ẹ̀ déédéé lè ní lórí èrò ìmọ̀lára rẹ?

Máa Ṣàṣàyàn

Èyí kò túmọ̀ sí pé gbogbo orin tí wọ́n bá kọ “àfidípò” sí lára jẹ́ eléwu tàbí amúnibínú. Ṣùgbọ́n jẹ́ ká sọ pé o gbọ́ pé ẹnì kan ń gbìyànjú láti gbé májèlé fún ọ jẹ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, o kò níí ṣíwọ́ oúnjẹ jíjẹ, ó dájú pé ìwọ yóò máa fìṣọ́ra kíyè sí oúnjẹ rẹ, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Mímọ̀ pé Sátánì ń gbìyànjú láti pàkúta sí ojú ìwòye àti ìṣarasíhùwà rẹ gbọ́dọ̀ mú kí o ṣọ́ra nípa orin tí o ń yàn láàyò bákan náà. Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe wí, “etí a máa dán ọ̀rọ̀ wò, bí adùn ẹnú ti í tọ́ oúnjẹ wò.” (Jóòbù 34:3) Kàkà kí o ṣáà máa tẹ̀ síbi tí ọ̀pọ̀ ènìyán tẹ̀ sí, dán orin tí o fẹ́ràn wò.

Báwo ni o ṣe lè ṣe ìyẹn? Àpótí tí ó ní àkọlé “Ìtọ́sọ́nà Lórí Yíyan Orin” ní àwọn ìdámọ̀ràn ṣíṣàǹfààní tí o lè gbìyànjú wò. Pẹ̀lúpẹ̀lú, gbìyànjú láti wádìí ohun tí àwọn Kristẹni òbí rẹ rò nípa orin tí o fẹ́ràn. (Òwe 4:1) Ìdáhùn wọ́n lè yà ọ́ lẹ́nu! Dájúdájú, àwọn òbí rẹ dàgbà jù ọ́ lọ. A lè lóye rẹ̀ pé, wọ́n lè ṣàìní ìmọ̀lára kan náà tí o ní nípa orin. Ṣùgbọ́n bí wọ́n bá kórìíra orin tí o fẹ́ dé àyè pé wọ́n kà á sí amúnibínú, arẹnisílẹ̀, tàbí eléwu, ó ha yẹ kí o ṣàìka ohun tí wọ́n bá ní láti sọ sí bí? Bíbélì wí pé: “Ọlọgbọ́n yóò gbọ́, yóò sì máa pọ̀ sí i ní ẹ̀kọ́.”—Òwe 1:5.

Ṣàyẹ̀wò bí orin náà ṣe ń nípa lórí rẹ. Ó ha ń mú ọ nímọ̀lára ìbínú, ẹ̀mí ọ̀tẹ̀, tàbí ìkárísọ bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn àmì ìkìlọ̀ tí o kò gbọdọ̀ ṣàìkàsí nìwọ̀nyí! O kò ṣe wá orin tí ń fún ọ ní ìdẹ̀ra, tàbí tí ń tù ọ́ lára, tàbí tí ń dá ọ lára yá?

Àṣà orín máa ń yí padà léraléra. Láìpẹ́, àwọn oríṣi orin mìíràn yóò tún gbòde. Ṣùgbọ́n, má ṣe jẹ́ kí àwọn ìjì orin tí ń yí padà wọ̀nyí gbá ọ lọ. Jẹ́ olóye àti aláṣàyàn bí ó bá kan orin tí o fẹ́ràn. Rí i dájú pé orin tí o ń tẹ́tí sí gbámúṣé, ó sì ń gbéni ró. (Fílípì 4:8) Nígbà náà ni orín lè jẹ́ apá tí ó níye lórí, tí ó sì gbádùn mọ́ni nínú ìgbésí ayé rẹ!

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.

b Wo àwọn àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .” tí ó wà nínú ìtẹ̀jáde Jí!, February 8, February 22, àti March 22, 1993. Tún wo “Ẹ Ṣọra fun Awọn Orin Ti Kò Sunwọn!,” nínú ìtẹ̀jáde Ilé-Ìṣọ́nà, April 15, 1993.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 22]

“Nígbà tí àwọn orin lílókìkí sábà máa ń jẹ́ nípa ìfẹ́, àwọn orin àfidípò sábà máa ń jẹ́ nípa àwọn ìmọ̀lára jíjinlẹ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ: ìsọ̀rètínù, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, ìdàlọ́kànrú.”—Ìwé ìròyìn Time

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 23]

Ìtọ́sọ́nà Lórí Yíyan Orin

◆ Ṣàyẹ̀wò páálí rẹ̀. Èyí yóò sábà sọ púpọ̀ fún ọ nípa orin náà àti àwọn akọrin náà fúnra wọn. Ṣọ́ra fún àwọn èèpo ẹ̀yìn páálí tí ń gbé ìwà ipá, àwọn àmì ẹ̀mí èṣù, ìwọṣọ àti ìmúra ṣíṣàjèjì, tàbí ìhòòhò jáde.

◆ Gbé àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ yẹ̀ wò. Ìwọ̀nyí ń fi èrò àti ọ̀nà ìgbésí ayé àwọn akọrin náà hàn. Irú èrò wo ni wọ́n fẹ́ kí o tẹ́wọ́ gbà?

◆ Àpapọ̀ ìró orin náà ń ṣàfihàn èrò ìmọ̀lára àti ìmọ̀lára tí àwọn òṣèré náà ń fẹ́ kí o ní—ìkárísọ, ìdùnnú, ẹ̀mí ìpeniníjà, ìrusókè ìbálòpọ̀, ìparọ́rọ́ ọkàn, tàbí ìsọ̀rètínù.

◆ Gbé irú àwọn olùtẹ́tísí tí ẹgbẹ́ olórin náà ń fà mọ́ra yẹ̀ wò. Ìwọ yóò ha fẹ́ kí a kà ọ́ mọ́ ẹgbẹ́ irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ àti ìṣarasíhùwà wọn?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èwe ń loye àwọn ọ̀rọ̀ orin òde òní

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́