ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 11/22 ojú ìwé 18-20
  • Mímú Èrò Òdì Nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kúrò

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Mímú Èrò Òdì Nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kúrò
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Èé Ṣe Tí Ẹ Kì Í Lọ́wọ́ Nínú Ìṣèlú?”
  • ‘Ṣé Pé Ìwọ Yóò Jẹ́ Kí Ọmọkùnrin Rẹ Kú?’
  • Sísan Ohun Ti Kesari Padà fún Kesari
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Bí A Ṣe Lè Mọ Ẹni Tó Yẹ Kí Á Ṣègbọràn Sí
    Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà
  • Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kó O Máa San Owó Orí?
    Jí!—2003
  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 11/22 ojú ìwé 18-20

Mímú Èrò Òdì Nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kúrò

MÉJÌ lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá ọkùnrin kan tí ó sọ pé òun kò ní ọkàn-ìfẹ́ pàdé lẹ́nu iṣẹ́ ìjẹ́rìí ilé dé ilé wọn. Àwọn Ẹlẹ́rìí náà rọra lọ kúrò jẹ́ẹ́, ṣùgbọ́n bí wọ́n ti ń lọ, wọ́n kíyè sí i pé ọkùnrin náà ń tẹ̀ lé wọn. Ọkùnrin náà ké sí wọn pé: “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ dúró! Mo fẹ́ẹ́ tọrọ àforíjì. N kò mọ ohunkóhun nípa àwọn Ẹlẹ́rìí, mo sì gbà gbọ́ pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ni ó ti ní ìsọfúnni òdì nípa yín.”

Ó pe ara rẹ̀ ní Renan Dominguez, alága ìṣètò Ẹgbẹ́ Rotary ní Gúúsù San Francisco, California. Ó béèrè bóyá Ẹlẹ́rìí kan lè wá sílé ẹgbẹ́ náà, kí ó sì bá ẹgbẹ́ sọ̀rọ̀ lórí ìgbàgbọ́ àti ìgbòkègbodò àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. A ṣètò ìtòlẹ́sẹẹsẹ kan. Ẹlẹ́rìí náà yóò sọ̀rọ̀ fún 30 ìṣẹ́jú, yóò sì fàyè sílẹ̀ fún ìbéèrè láti ọ̀dọ̀ àwùjọ. A ké sí Ernest Garrett, tí ó ti jẹ́ Ẹlẹ́rìí fún ọ̀pọ̀ ọdún ní àdúgbò San Francisco, láti ṣe ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ náà fún Ẹgbẹ́ Rotary ní August 17, 1995, ó sì ròyìn pé:

“Mo ṣe kàyéfì lórí ohun tí ǹ bá sọ fún àwọn mẹ́ḿbà Ẹgbẹ́ Rotary, tí wọ́n jẹ́ àwọn aṣáájú oníṣòwò àti aṣáájú ìlú, àwọn bí òṣìṣẹ́ báńkì, amòfin, àti dókítà nínú, mo sì gbàdúrà nípa rẹ̀. Mo ṣe ìwádìí díẹ̀, mo sì rí i pé, ète ìlépa tí Ẹgbẹ́ Rotary tẹ̀ jáde ni láti fún àwùjọ àdúgbò lókun. Nítorí náà, mo lo ìsọfúnni tí ó wà ní ojú ìwé 23, nínú ìwé pẹlẹbẹ náà, Jehovah’s Witnesses in the Twentieth Century, tí ó ní àkọlé ‘Ìníyelórí Ìhìn Rere Náà fún Àwùjọ Àdúgbò Rẹ.’’’a

“Mo ṣàlàyé pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ agbára ìdarí kan ní ṣíṣe èyí. Ní gbogbo ọjọ́ àárín ọ̀sẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń jáde lọ, wọ́n ń kan ilẹ̀kùn àwùjọ àdúgbò wọn. Ìfẹ́ ọkàn wọn ni láti jẹ́ kí àwọn aládùúgbò wọ́n lè ní ìdílé tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀—ìdílé tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ sì máa ń yọrí sí àwùjọ àdúgbò tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀. Bí àwọn ẹnì kọ̀ọ̀kan àti ìdílé tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá ràn lọ́wọ́ láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Kristẹni bá ṣe pọ̀ tó, ni ìyapòkíì, ìwàpálapàla, àti ìwà ọ̀daràn tí yóò wà nínú àwùjọ àdúgbò yóò ṣe dín kù tó. Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ náà tẹ́wọ́ gba ìsọfúnni yìí dáradára nítorí pé ó bá àwọn ète ìlépa Ẹgbẹ́ Rotary mu.”

“Èé Ṣe Tí Ẹ Kì Í Lọ́wọ́ Nínú Ìṣèlú?”

“Nígbà tí a fàyè sílẹ̀ fún ìbéèrè, ọ̀kan lára àwọn ìbéèrè àkọ́kọ́ ni: ‘Èé ṣe tí ẹ kì í lọ́wọ́ nínú ìṣèlú àti ìṣèjọba?’ Ọkùnrin tí ó béèrè ìbéèrè yìí fi kún un pé: ‘Ẹ sáà mọ̀ pé Ìwé Dáradára náà sọ pé: “Ẹ fi ohun tí í ṣe ti Késárì fún Késárì.”’ Mo sọ fún un pé a fohùn ṣọ̀kan pátápátá pẹ̀lú gbólóhùn yẹn, a sì fara mọ́ ọn. Mo tọ́ka sí i pé ògìdìgbó àwọn ènìyàn tí mo ti gbọ́ tí wọ́n lo àyọlò yẹn kò fìgbà kankan ṣàyọlò ìdajì rẹ̀ tó kù, tí ó wí pé: ‘Ẹ san ohun tí í ṣe ti Ọlọ́run padà fún Ọlọ́run.’ (Mátíù 22:21) Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ parí èrò sí pé kì í ṣe ohun gbogbo ni ó jẹ́ ti Késárì. Àwọn ohun kán wà tí ó jẹ́ ti Ọlọ́run. A dojú kọ ọ̀ràn mímọ àwọn ohun tí ó jẹ́ ti Késárì àti àwọn ohun tí ó jẹ́ ti Ọlọ́run.

“Mo fi hàn án pé nígbà tí wọ́n bi Jésù léèrè pé ‘Ó ha bófin mu láti san owó orí fún Késárì tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́?’ kò dáhùn nípa sísọ pé bẹ́ẹ̀ ni tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Ó wí pé: ‘Ẹ fi ẹyọ owó ti owó orí hàn mí,’ owó denarius ti Róòmù. Ó béèrè pé: ‘Àwòrán àti àkọlé ta ni èyí?’ Wọ́n wí pé: ‘Ti Késárì.’ Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé: ‘Nítorí náà, ẹ san àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì.’ (Mátíù 22:17-21) Lédè míràn, ẹ san owó orí fún Késárì nítorí pé a ń rí àwọn àǹfààní kan gbà láti ọwọ́ Késárì, a sì ń sanwó orí fún ìwọ̀nyí bí ó ṣe yẹ. Mo ṣàlàyé pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń san owó orí wọn, wọn kì í sì í rẹ́ ìjọba jẹ ní ti ohun tí ó jẹ́ tirẹ̀ lọ́nà ẹ̀tọ́.

“Nígbà náà ni mo sọ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò gbà gbọ́ pé àwọ́n jẹ Késárì ní gbèsè ìwàláàyè wọn. Wọ́n gbà gbọ́ pé àwọ́n jẹ Ọlọ́run ní gbèsè ìjọsìn àwọn, wọ́n sì ń san èyí padà fún un bí ó ṣe tọ́. Nítorí náà, nígbà tí a mú ìdúró yìí, a kò pète láti ṣàìbọ̀wọ̀ fún Késárì lọ́nàkọnà. A ń ṣègbọràn sí gbogbo òfin Késárì, ṣùgbọ́n níbi tí ìforígbárí bá ti wà, a ń yàn tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ láti ṣègbọràn sí Ọlọ́run bí aláṣẹ ju ènìyàn lọ. Nígbà náà ni ọkùnrin tí ó béèrè ìbéèrè yìí sọ níwájú gbogbo àwùjọ náà pé: ‘N kò lè já ìyẹn ní koro!’

“Ó tún ṣeé ṣe fún wa láti dáhùn ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìbéèrè nípa iṣẹ́ ìwàásù wa. Púpọ̀ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ náà wáá bá wa lẹ́yìn ìpàdé náà, tí wọ́n sì bọ̀ wá lọ́wọ́, wọ́n sì wí pé àwọ́n fohùn ṣọ̀kan ní kíkún pẹ̀lú wa—pé ìdílé ni ìpìlẹ̀ fún àwùjọ tí ó dúró déédéé. Nígbà náà ni a fún ọmọ ẹgbẹ́ kọ̀ọ̀kan ní ìwé pẹlẹbẹ Jehovah’s Witnesses in the Twentieth Century.

“Lẹ́yìn ìpàdé yìí, alága ìṣètò ẹgbẹ́ náà, Ọ̀gbẹ́ni Dominguez, tẹ̀ mí láago, ó sì béèrè bí mo bá lè wá sí ọ́fíìsì òun, nítorí pé òún ní àwọn ìbéèrè púpọ̀ sí i láti béèrè nípa àwọn ohun tí a gbà gbọ́. A ní ìjíròrò dídán mọ́rán kan lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ mélòó kan. Ní pàtàkì, ó fẹ́ kí n ṣàlàyé ìdúró wa nípa ẹ̀jẹ̀. Ó jẹ́wọ́ pé òun fúnra òun kò jẹ́ gba ẹ̀jẹ̀ sára, àlàyé tí mo sì ṣe fún un láti inú ìwé pẹlẹbẹ How Can Blood Save Your Life? wọ̀ ọ́ lọ́kàn tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi rọ̀ mí láti padà wá, kí n sì bá àwọn ọmọ ẹgbẹ́ náà sọ̀rọ̀ lórí ìdúró wa nípa ẹ̀jẹ̀. Mo ké sí Ẹlẹ́rìí mìíràn, Don Dahl, láti dara pọ̀ mọ́ mi nínú ìṣètò yìí. Ó máa ń lọ sí àwọn ilé ìwòsàn láti jíròrò ọ̀ràn náà pẹ̀lú àwọn dókítà nígbà tí wọ́n bá ní láti ṣe iṣẹ́ abẹ fún àwọn Ẹlẹ́rìí. A jùmọ̀ ṣe àlàyé ní kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa bí a ṣe ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn dókítà àti àwọn alábòójútó ilé ìwòsàn láti mú ìdúró wa ní ìbámu pẹ̀lú Ìwé Mímọ́ ṣe kedere, àti láti fún wọn ní àwọn ohun àfidípò ẹ̀jẹ̀ tí ń kẹ́sẹ járí.”—Léfítíkù 17:10-12; Ìṣe 15:19-21, 28, 29.

‘Ṣé Pé Ìwọ Yóò Jẹ́ Kí Ọmọkùnrin Rẹ Kú?’

“Lẹ́yìn ìpàdé náà, ọkùnrin kán wáá bá mi, ó sì béèrè níkọ̀kọ̀ pé: ‘Ṣé pé ìwọ yóò jẹ́ kí ọmọkùnrin rẹ kú, bí ìjàm̀bá kan bá ṣe é, tí wọ́n sì gbé e wá síbi ìtọ́jú pàjáwìrì, tí ẹ̀jẹ́ sì ń dà lára rẹ̀ gan-an?’ Mo fi dá a lójú pé, mo lóye àníyàn rẹ̀, nítorí pé mo ti ní ọmọkùnrin kan rí, ó sì kú nínú ìjàm̀bá ọkọ̀ òfuurufú tí ó bú gbàù ní Lockerbie, Scotland, ní 1988. Ní ìdáhùn sí ìbéèrè rẹ̀, mo kọ́kọ́ sọ fún un pé, n kò níí fẹ́ kí ọmọkùnrin mí kú.

“A kò lòdì sí dókítà, tàbí sí ìtọ̀ọ́jú ìṣègùn, tàbí sí ilé ìwòsàn. A kì í ṣe onígbàgbọ́ wòósàn. A nílò ìtọ́jú tí àwọn onímọ̀ ìṣègùn ń pèsè. A ti gbẹ́kẹ̀ wa lé Ọlọ́run, ó sì dá wa lójú pé ìdarísọ́nà rẹ̀ lórí ọ̀ràn ẹ̀jẹ̀ yìí jẹ́ fún ire wa pípẹ́ títí. Bíbélì ṣàpèjúwe Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ‘[ẹni] tí ó kọ́ ọ fún èrè, ẹni tí ó tọ́ ọ ní ọ̀nà tí ìwọ ì bá máa lọ.’ (Aísáyà 48:l7) Ó ti fún Ọmọkùnrin rẹ̀ ní agbára láti jí àwọn òkú dìde. Jésù wí pé: ‘Èmi ni àjíǹde àti ìyè. Ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú mi, bí ó tilẹ̀ kú, yóò yè; àti olúkúlùkù ẹni tí ń bẹ láàyè tí ó sì ń lo ìgbàgbọ́ nínú mi kì yóò kú rárá láé. Ìwọ́ ha gba èyí gbọ́ bí?’—Jòhánù 11:25, 26.

“Gbogbo ohun tí a ń fẹ́ kí àwọn dókítà mọ̀ ni pé, ìdúró wá jẹ́ ọ̀ràn ẹ̀rí ọkàn, kò sì ṣeé fi báni dọ́rẹ̀ẹ́. A kò lè fi ọ̀ràn yìí báni dọ́rẹ̀ẹ́ lọ́nà kan náà tí a kò fi lè fi òfin Ọlọ́run nípa ṣíṣe panṣágà báni dọ́rẹ̀ẹ́. A kò lè bá Ọlọ́run dúnàádúrà, kí a sì wí pé, ‘Ìwọ Ọlọ́run, ǹjẹ́ mo lè ṣe panṣágà lábẹ́ ipò kankan bí?’ Mo wáá sọ fún ọkùnrin yìí pé: ‘O bi mí bóyá n óò jẹ́ kí ọmọkùnrin mi kú nípa kíkọ ìfàjẹ̀sínilára. Jọ̀wọ́, mo bẹ̀ ọ́, mo fẹ́ẹ́ béèrè bóyá ìwọ yóò jẹ́ kí ọmọkùnrin rẹ kú nínú iṣẹ́ ológun orílẹ̀-èdè èyíkéyìí?’ Lọ́gán, ó dáhùn pẹ̀lú ìtẹnumọ́ pé, ‘Bẹ́ẹ̀ ni! Nítorí pé iṣẹ́ àìgbọdọ̀máṣe rẹ̀ ni!’ Mo wí pé: ‘Ìwọ yóò yọ̀ǹda kí ọmọkùnrin rẹ kú nítorí pé ó jẹ́ fún ìdí kan tí ó gbà gbọ́ nínú rẹ̀. Yọ̀ǹda àǹfààní kan náà fún mi nípa ọmọkùnrin mi.’

“Ìṣẹ̀lẹ̀ ẹ̀yìn-ọ̀-rẹyìn kan tó wọni lọ́kàn ni pé alága ìṣètò ẹgbẹ́ náà, Ọ̀gbẹ́ni Dominguez, pe èmi àti ìyàwó mi síbi oúnjẹ alẹ́ kan pẹ̀lú òun àti ìyàwó rẹ̀. Ó rò pé ìyàwó òún ti ní àwọn ìsọfúnni òdì àti èrò òdì nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó tọ̀nà. Obìnrin náà ní ìsọfúnni òdì. A gbádùn ìrọ̀lẹ́ náà, ìyàwó rẹ̀ sì béèrè ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbéèrè nípa wa àti iṣẹ́ wa, ó sì fún wa láyè láti dáhùn ní ẹ̀kún rẹ́rẹ́. Ọkùnrin náà tẹ̀ wá láago lọ́jọ́ kejì, ó sì sọ pé òun àti ìyàwó òún gbádùn pípàdé pẹ̀lú èmi àti ìyàwó mi, àwọ́n sì lérò pé, ènìyàn rere ni wá.

“Mo ń bá a lọ ní ṣíṣe ìbẹ̀wò sọ́dọ̀ Ọ̀gbẹ́ni Dominguez déédéé, ó sì ń fi ọkàn ìfẹ́ jíjinlẹ̀ hàn nínú Bíbélì. Ó sọ fún mi pé: ‘N kò níí lọ́ra láti fún ọ níṣìírí pé kí o kàn sí àwọn alága ìṣètò Ẹgbẹ́ Rotary ní àdúgbò Greater San Francisco Bay, kí o sì fi bíbá ẹgbẹ́ wọn sọ irú ọ̀rọ̀ tí o bá ẹgbẹ́ wa sọ lọ̀ wọ́n. O lè dárúkọ mi fún wọn, nígbà tí wọ́n bá sì kàn sí mi, yóò dùn mọ́ mi láti dámọ̀ràn gidigidi pé kí wọ́n pè ọ́ gẹ́gẹ́ bí àlejò olùbánisọ̀rọ̀.’

“Ẹgbẹ́ Rotary wà kárí ayé. Ó ha lè ṣeé ṣe pé kí àwọn ẹgbẹ́ mìíràn ní United States àti jákèjádò àgbáyé tẹ́wọ́ gba ìgbékalẹ̀ ìjíròrò láti ọ̀dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bí?”

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde ní 1989.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Ọ̀gbẹ́ni Renan Dominguez, lápá òsì, àti Arákùnrin Ernest Garrett

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́