Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kó O Máa San Owó Orí?
“Ẹ san ohun tí ẹ bá jẹ ẹnikẹ́ni fún un. Ẹ san owó-orí fún ẹni tí ó tọ́ sí. Ẹ san owó-ibodè fún ẹni [tó] yẹ. Ẹ bu ọlá fún ẹni tí ọlá bá yẹ fún.”—Róòmù 13:7, Ìròyìn Ayọ̀.
NÍTORÍ bí owó orí ṣe túbọ̀ ń ga sí i, ó lè ṣòro láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó wà lókè yìí. Àmọ́ ṣá o, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ló sọ ọ̀rọ̀ náà, a sì ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ sínú Bíbélì. Kò sí iyèméjì pé o gba Bíbélì gbọ́. Àmọ́ o lè máa wò ó pé, ‘Ǹjẹ́ ó pọn dandan fún àwọn Kristẹni láti máa san gbogbo owó orí, títí kan àwọn tí àwọn kan lè máa wò pé ó pọ̀ jù tàbí pé kò tọ̀nà?’
Ronú ná lórí ohun tí Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Ó mọ̀ pé àwọn Júù bíi tirẹ̀ ní ìkórìíra gidigidi fún owó orí tí àwọn ará Róòmù máa ń bù lé wọn. Síbẹ̀, Jésù rọ̀ wọ́n pé: “Ẹ san àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì, ṣùgbọ́n àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.” (Máàkù 12:17) Ó yẹ ká tún kíyè sí i pé, ìjọba náà gan-an tó máa pa Jésù láìpẹ́ sígbà yẹn ló rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n máa san owó orí fún.
Ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà ni Pọ́ọ̀lù pèsè ìmọ̀ràn tá a fà yọ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí. Ó rọ̀ wọ́n láti máa san owó orí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ ológun àti ayé ìjẹkújẹ àwọn olú ọba Róòmù ni púpọ̀ lára owó orí náà máa ń bá lọ. Kí ló mú Pọ́ọ̀lù ní irú ojú ìwòye tí ọ̀pọ̀ èèyàn kò fara mọ́ yìí?
Àwọn Aláṣẹ Onípò Gíga
Gbé àwọn ọ̀rọ̀ tó yí gbólóhùn Pọ́ọ̀lù náà ká yẹ̀ wò. Ní Róòmù 13:1, ó kọ̀wé pé: “Kí olúkúlùkù ọkàn wà lábẹ́ àwọn aláṣẹ onípò gíga, nítorí kò sí ọlá àṣẹ kankan bí kò ṣe láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run; àwọn ọlá àṣẹ tí ó wà ni a gbé dúró sí àwọn ipò wọn aláàlà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” Nígbà táwọn alákòóso tó bẹ̀rù Ọlọ́run ń ṣàkóso orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, ó rọrùn láti wo fífi owó ṣètìlẹyìn fún orílẹ̀-èdè náà gẹ́gẹ́ bí ojúṣe ẹni àti gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìsìn béèrè. Àmọ́, ǹjẹ́ àwọn Kristẹni ní irú ojúṣe kan náà nígbà tó wá di pé àwọn alákòóso aláìgbàgbọ́ tó jẹ́ abọ̀rìṣà ló ń ṣàkóso? Bẹ́ẹ̀ ni! Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ fi hàn pé Ọlọ́run ti fún àwọn alákòóso ní “ọlá àṣẹ” láti máa ṣàkóso.
Iṣẹ́ ńlá làwọn ìjọba ń ṣe láti rí sí i pé àwọn nǹkan wà létòlétò. Èyí ń jẹ́ kó ṣeé ṣe fún àwọn Kristẹni láti máa bá onírúurú ìgbòkègbodò tẹ̀mí wọn nìṣó. (Mátíù 24:14; Hébérù 10:24, 25) Ìdí èyí ni Pọ́ọ̀lù fi sọ nípa àwọn ìjọba tó ń ṣàkóso pé: “Òjíṣẹ́ Ọlọ́run ni ó jẹ́ sí ọ fún ire rẹ.” (Róòmù 13:4) Pọ́ọ̀lù fúnra rẹ̀ lo àǹfààní ààbò tí ìjọba Róòmù pèsè. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó kó sọ́wọ́ àwọn jàǹdùkú èèyàn, àwọn sójà ilẹ̀ Róòmù ló gbà á sílẹ̀. Lẹ́yìn ìgbà náà, ó pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lọ́dọ̀ ètò ìdájọ́ ilẹ̀ Róòmù láti bá a gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ kó lè ṣeé ṣe fún un láti máa bá iṣẹ́ míṣọ́nnárì rẹ̀ nìṣó.—Ìṣe 22:22-29; 25:11, 12.
Pọ́ọ̀lù wá sọ àwọn ìdí mẹ́ta tó fi yẹ ká máa san owó orí. Àkọ́kọ́, ó sọ nípa “ìrunú” àwọn ìjọba èyí tó ń mú kí wọ́n máa fìyà jẹ àwọn tó bá rúfin. Èkejì, ó ṣàlàyé pé ẹ̀rí ọkàn ẹnì kan tó bá jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run kò ní lélẹ̀ rárá bí kò bá ṣòótọ́ nínú sísan owó orí rẹ̀. Àti èyí tó kẹ́yìn, ó fi hàn pé ńṣe ni owó orí wulẹ̀ jẹ́ ọ̀nà láti ṣètìlẹyìn fún àwọn iṣẹ́ tí ìjọba ń ṣe fún ìlú gẹ́gẹ́ bí “ìránṣẹ́ . . . sí gbogbo ènìyàn.”—Róòmù 13:1-6.
Ǹjẹ́ àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ Pọ́ọ̀lù tiẹ̀ mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí lò? Dájúdájú wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí pé òǹkọ̀wé aláfẹnujẹ́ Kristẹni ọ̀rúndún kejì náà, Justin Martyr (tó gbé ayé ní nǹkan bí ọdún 110 sí 165 Sànmánì Tiwa) sọ pé àwọn Kristẹni máa ń “wà ní ìmúratán láti” san owó orí wọn “ju gbogbo àwọn èèyàn mìíràn lọ.” Lónìí, nígbà tí àwọn ìjọba bá béèrè fún sísan àwọn nǹkan kan, yálà owó tàbí àkókò, àwọn Kristẹni ṣì ń bá a nìṣó láti máa fi tinútinú ṣe ohun tí ìjọba béèrè.—Mátíù 5:41.a
Àwọn Kristẹni lómìnira láti jàǹfààní àwọn ètò ẹ̀dínwó owó orí èyíkéyìí tó bófin mu. Láwọn ìgbà míì, ó tiẹ̀ lè ṣeé ṣe fún wọn láti jàǹfààní ètò tí ìjọba ṣe fún àwọn tó ń ṣètìlẹyìn fún ètò ẹ̀sìn láti má ṣe san owó orí. Àmọ́ ṣá o, ní ṣíṣègbọràn sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í sá fún sísan owó orí. Wọ́n máa ń san owó orí wọn, wọ́n sì máa ń fi àwọn aláṣẹ sílẹ̀ láti bójú tó owó náà bó bá ṣe tọ́ lójú wọn.
Owó orí tó máa ń pọ̀ kọjá ààlà wulẹ̀ jẹ́ ara ọ̀nà tí “ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.” (Oníwàásù 8:9) Ìlérí Bíbélì tó ń tu àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nínú ni pé láìpẹ́ ìdájọ́ òdodo yóò gbilẹ̀ fún àǹfààní gbogbo èèyàn lábẹ́ ìjọba Ọlọ́run, ìyẹn ìjọba kan tí kò ní di ẹrù owó orí tí kò tọ́ ru àwọn èèyàn.—Sáàmù 72:12, 13; Aísáyà 9:7.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìmọ̀ràn Jésù láti san “ohun ti Késárì . . . fún Késárì” kò túmọ̀ sí pé owó orí nìkan ṣoṣo la gbọ́dọ̀ san. (Mátíù 22:21) Ìwé náà, Critical and Exegetical Hand-Book to the Gospel of Matthew, látọwọ́ Heinrich Meyer, ṣàlàyé pé: “Kò yẹ ká lóye rẹ̀ pé gbólóhùn náà [ohun ti Késárì] . . . jẹ́ kìkì owó orí tó jẹ́ ojúṣe wa, bí kò ṣe gbogbo ohun tó bá jẹ́ ẹ̀tọ́ Késárì nítorí ìṣàkóso rẹ̀ tó bá òfin mu.”
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 11]
Àwọn Kristẹni ìjímìjí máa ń “wà ní ìmúratán láti” san owó orí wọn “ju gbogbo àwọn èèyàn mìíràn lọ.”—JUSTIN MARTYR
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Àwọn Kristẹni tòótọ́ máa ń ṣègbọràn sí òfin owó orí
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Jésù sọ pé: “Ẹ san àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì”
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 10]
© European Monetary Institute