“Bí Ẹ Bá Jẹ Owó-Orí, Ẹ San Owó-Orí”
“NÍNÚ ayé yìí dandan ni ikú àti owó-orí.” Bí aṣáájú òṣèlú àti olùhùmọ̀ ara America kan ní ọ̀rúndún kejìdínlógún Benjamin Franklin ti sọ nìyẹn. Kìí ṣe kìkì àìṣeé yẹ̀ sílẹ̀ owó-orí nìkan ni àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí a sábà máa ń fàyọ fihàn, bíkòṣe ìfòyà tí wọ́n máa ń mú wá pẹ̀lú. Fún ọ̀pọ̀ ènìyàn, kíkú wú wọn lórí ju sísan owó-orí lọ.
Bí ó ti wù kí sísan owó-orí ṣàìgbádùn mọ́ni tó, èyí jẹ́ ojúṣe kan tí àwọn ojúlówó Kristian fi ọwọ́ ṣíṣe pàtàkì gidigidi mú. Aposteli Paulu kọ̀wé sí ìjọ Kristian tí ń bẹ ní Romu pé: “Ẹ fún olúkúlùkù ní ohun tí ẹ bá jẹ ẹ́: Bí ẹ bá jẹ owó-orí, ẹ san owó-orí; bí ó bá jẹ́ owó-àrígbàwọlé, nígbà náà owó àrígbàwọlé; bí ó bá jẹ́ ọ̀wọ̀, nígbà náà ọ̀wọ̀; bí ó bá jẹ́ ọlá, nígbà náà ọlá.” (Romu 13:7, New International Version) Jesu Kristi ń tọ́ka ní pàtó sí owó-orí nígbà tí ó sọ pé: “Ẹ san awọn ohun ti Kesari padà fún Kesari, ṣugbọn awọn ohun ti Ọlọrun fún Ọlọrun.”—Marku 12:14, 17, NW.
Jehofa ti yọ̀ọ̀da fún “awọn aláṣẹ onípò gíga” ti ìjọba àkóso láti wà ó sì béèrè pé kí àwọn ìránṣẹ́ òun fún wọn ní ìtẹríba tí ó ní ààlà. Nígbà náà, èéṣe tí Ọlọrun fi tẹpẹlẹ mọ́ ọn pé kí àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ máa san owó-orí? Paulu mẹ́nukan àwọn ìdí pàtàkì mẹ́ta: (1) “ìrunú” ti “awọn aláṣẹ onípò gíga” níti fífi ìyà jẹ àwọn arúfin; (2) ẹ̀rí-ọkàn Kristian, èyí tí kì yóò mọ́ bí ó bá ṣe ìrẹ́jẹ nínú owó-orí rẹ̀; (3) àìní náà láti sanwó fún àwọn “ìránṣẹ́ . . . sí gbogbo ènìyàn” wọ̀nyí fún àwọn iṣẹ́ ìpèsè tí wọ́n ń ṣe àti pípa ìwọ̀n ìwàlétòlétò mọ́. (Romu 13:1-7, NW) Ọ̀pọ̀ ènìyàn lè má fẹ́ láti san owó-orí. Síbẹ̀, kò sí iyèméjì pé wọ́n kì yóò tilẹ̀ fẹ́ láti gbé ní ilẹ̀ kan tí kò ní àwọn ọlọ́pàá tàbí ààbò lọ́wọ́ iná, níbi tí a kì í tún ojú-ọ̀nà ṣe, tí kò sí àwọn ilé-ẹ̀kọ́ fún gbogbo ènìyàn, tí kò sì sí ètò ìfìwéránṣẹ́. Nígbà kan rí mẹ́ḿbà ìgbìmọ̀ onídàájọ́ kan tí ó jẹ́ ará America Oliver Wendell Holmes sọ ọ́ lọ́nà yìí: “Owó-orí ni ohun tí a ń san fún ẹgbẹ́-àwùjọ ọlọ́làjú.”
Sísan owo-orí kìí ṣe nǹkan titun fún àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun. Àwọn olùgbé Israeli ìgbàanì san irú àwọn owó-orí kan láti ṣètìlẹ́yìn fún àwọn ọba wọn, àwọn kan lára àwọn alákòóso náà sì di ẹrù wíwúwo ru àwọn ènìyàn náà nípasẹ̀ owó-orí tí kò bọ́gbọ́nmu. Àwọn Ju pẹ̀lú san owó-òde àti owó-orí fún àwọn agbára àjèjì tí wọ́n jẹgàba lé wọn lórí, bí Egipti, Persia, àti Romu. Nítorí náà àwọn Kristian ní ọjọ́ Paulu mọ ohun tí ó ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ dáradára nígbà tí ó mẹ́nukan sísan owó-orí. Wọ́n mọ̀ pé yálà àwọn owó-orí náà mọ́gbọ́ndání tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, àti láìka ọ̀nà yòówù kí ìjọba gbà ná owó náà sí, wọ́n níláti san owó-orí èyíkéyìí tí wọ́n bá jẹ. Ohun kan náà ni ó jẹ́ òtítọ́ nípa àwọn Kristian lónìí. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ìlànà wo ni wọ́n lè fún wa ní ìtọ́sọ́nà nígbà tí a bá ń san owó-orí wa ní àwọn àkókò dídíjú wọ̀nyí?
Àwọn Ìlànà Atọ́nisọ́nà Márùn-Ún
Wà létòlétò. A ń ṣiṣẹ́sìn a sì ń ṣàfarawé Jehofa, tí “kì í ṣe Ọlọrun rúdurùdu, bíkòṣe ti àlàáfíà.” (1 Korinti 14:33, NW; Efesu 5:1) Wíwà létòlétò ṣekókó nígbà tí ó bá di ti sísan owó-orí. Àwọn àkọsílẹ̀ rẹ ha pé pérépéré, péye, tí wọ́n sì wà létòlétò bí? Gẹ́gẹ́ bí ó ti sábà máa ń rí, ìṣètò àwọn fáìlì ìkówèésí tí ó gbówólórí ni a kò béèrè fún. O lè ní fáìlì ìkówèésí fún oríṣi àkọsílẹ̀ kọ̀ọ̀kan (bíi rìsíìtì tí ń ṣe ìlàlẹ́sẹẹsẹ onírúurú àwọn owónàá). Ó lè ti tó láti pa àwọn wọ̀nyí jọ pọ̀ sínú fáìlì ìkówèésí tí ó túbọ̀ tóbi fún ọdún kọ̀ọ̀kan. Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ ó jẹ́ ohun tí ó pọndandan láti tọ́jú irú àwọn fáìlì bẹ́ẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ìjọba pinnu láti ṣàyẹ̀wò àwọn àkọsílẹ̀ tí ó ti kọjá. Nítorí náà máṣe ju ohunkóhun nù títí tí ìwọ yóò fi ní ìdánilójú pé o kò nílò rẹ̀ mọ́.
Jẹ́ aláìlábòsí. Paulu kọ̀wé pé: “Ẹ máa bá a lọ ní gbígbàdúrà fún wa, nitori awa nígbẹ̀ẹ́kẹ̀lé pé a ní ẹ̀rí-ọkàn aláìlábòsí, gẹ́gẹ́ bí a ti dàníyàn lati máa mú ara wa hùwà láìṣàbòsí ninu ohun gbogbo.” (Heberu 13:18, NW) Ìfẹ́-ọkàn àtinúwá láti jẹ́ aláìlábòsí níláti ṣamọ̀nà gbogbo ìpinnu kọ̀ọ̀kan tí a bá ṣe nígbà tí a bá ń san owó-orí wa. Lákọ̀ọ́kọ́, ṣàgbéyẹ̀wò àwọn owó-orí tí o níláti san lórí àwọn owó tí ń wọlé wa èyí tí ìjọba gbọ́dọ̀ mọ̀ nípa rẹ̀. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilẹ̀, àwọn àfikún owó tí ń wọlé wá—láti inú àwọn ẹ̀bùn owó, iṣẹ́ àfipawọ́, ọjà títà—ni a gbọ́dọ̀ san owó-orí fún níwọ̀n tí ó bá ti kọjá iye kan tí a ti sọ ní pàtó. Kristian kan tí ó ní “ẹ̀rí-ọkàn aláìlábòsí” yóò ṣèwádìí níbi tí ó ń gbé láti mọ èló ni iye owó tí ń wọlé wá tí a gbọ́dọ̀ san owó-orí fún yóò sì san owó-orí tí ó bá kàn án.
Èkejì, ọ̀ràn ti ìgékúrò pẹ̀lú kò gbẹ́yìn. Ní gbogbogbòò ìjọba máa ń yọ̀ǹda fún àwọn tí ń san owó-orí láti gé iye àwọn owó kan kúrò lára iye owó tí ń wọlé wá tí wọn yóò san owó-orí fún. Nínú ayé alábòsí yìí, ọ̀pọ̀ ènìyàn kò rí ohun tí ó burú nínú lílo “àtinúdá” tàbí jíjẹ́ “aronúwòye” nígbà tí wọ́n bá ń béèrè fún irúfẹ́ ìgékúrò bẹ́ẹ̀. Ọkùnrin kan ní United States ní a ròyìn rẹ̀ pé ó ra kóòtù onírun tí ó gbówólórí kan fún aya rẹ̀, lẹ́yìn náà ni ó gbé e kọ́ sí ibi iṣẹ́-òwò rẹ̀ fún ọjọ́ kan kí ó ba à lè gé owó rẹ̀ kù gẹ́gẹ́ bí irú “ohun ìṣelélóge” kan fún ibi iṣẹ́ rẹ̀! Ọkùnrin mìíràn béèrè fún owó ìṣègbéyàwó ọmọbìnrin rẹ̀ bí ẹ̀tọ́ tí ó yẹ kí ó gbà lẹ́nu iṣẹ́. Òmíràn sì tún gbìyànjú láti gé owó kù nítorí pé aya rẹ̀ bá a rìnrìn-àjò fún ọ̀pọ̀ oṣù ní Far East, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé níti tòótọ́ àwọn ète tí ó jẹmọ́ ti ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà àti ti eré ìtura ni ó bá lọ síbẹ̀. Ó dàbí ẹni pé irú àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀ kò lópin. Kí a sọ ọ́ ní kúkúrú, pípe ohun kan ní owó àgékúrò lára iṣẹ́-òwò nígbà tí kìí ṣe bẹ́ẹ̀ rárá jẹ́ irú irọ́ pípa kan—ohun kan tí Ọlọrun wa, Jehofa, kórìíra pátápátá.—Owe 6:16-19.
Jẹ́ oníṣọ̀ọ́ra. Jesu rọ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti “jẹ́ oníṣọ̀ọ́ra gẹ́gẹ́ bí ejò síbẹ̀ kí [wọ́n] jẹ́ ọlọ́rùnmímọ́ gẹ́gẹ́ bí àdàbà.” (Matteu 10:16, NW) Ìmọ̀ràn yẹn ni a lè fisílò dáradára nínú àwọn ọ̀nà tí a gbà ń san owó-orí wa. Ní pàtàkì jùlọ ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ń gòkè àgbà, àwọn ènìyàn púpọ̀ púpọ̀ síi ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí ń sanwó fún ilé-iṣẹ́ tí ń bójútó àkáǹtì tàbí àwọn àkọ́ṣẹ́mọṣẹ́ kan láti bá wọn pinnu iye tí ó yẹ kí owó-orí àwọn jẹ́. Lẹ́yìn náà wọn yóò wulẹ̀ bu ọwọ́ lu fọ́ọ̀mù náà wọ́n yóò sì fi sọ̀wédowó ránṣẹ́. Èyí yóò jẹ́ àkókò dídára kan láti kíyèsí ọ̀rọ̀ ìṣọ́ra tí a ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ sínú Owe 14:15: “Òpè ènìyàn gba ọ̀rọ̀ gbogbo gbọ́: ṣùgbọ́n amòye ènìyàn wo ọ̀nà ara rẹ̀ rere.”
Ọ̀pọ̀ àwọn tí ń san owó-orí ti dojúkọ ìṣòro pẹ̀lú ìjọba nítorí pé wọ́n ‘gba gbogbo ọ̀rọ̀’ àwọn oníṣirò owó tàbí aláìnírìírí olùbániṣètò owó-orí tí kìí tẹ̀lé ìlànà gbọ́. Ẹ wo bí ìbá ti dára tó láti jẹ́ ọlọgbọ́n! Lo ìṣọ́ra nípa fífi ara balẹ̀ ka ìwé àkọsílẹ̀ èyíkéyìí ṣáájú kí o tó bu ọwọ́ lù ú. Bí àwọn ohun kan tí a kọ, tí a fòdá, tàbí tí a gé kúrò bá ṣàjèjì sí ọ, mú kí a ṣàlàyé rẹ̀—léraléra bí ó bá pọndandan—títí tí yóò fi tẹ́ ọ lọ́rùn pé ọ̀ràn náà kò ní àbòsí ó sì bá òfin mú. Òtítọ́ ni pé, ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ àwọn òfin owó-orí ti di èyí tí ó díjú ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ṣùgbọ́n dé ìwọ̀n tí ó bá ṣeéṣe dé, ó jẹ́ ipa-ọ̀nà ọgbọ́n láti lóye ohunkóhun tí o bá bu ọwọ́ lù. Nínú àwọn ọ̀ràn kan, o lè rí i pé Kristian ẹlẹgbẹ́ rẹ kan tí ó mọ̀ nípa òfin owó-orí lè fún ọ ní ìlàlóye díẹ̀. Kristian alàgbà kan tí ń bójútó àwọn ọ̀ràn owó-orí gẹ́gẹ́ bí agbẹjọ́rò kan sọ ní ṣókí pé: “Bí oníṣirò owó rẹ̀ bá ń dábàá ohun kan tí ń dún bí èyí tí ó dára jù láti jẹ́ òtítọ́, nígbà náà ó ṣeéṣe kí ó má jẹ́ òtítọ́!”
Mọ ẹrù-iṣẹ́ níṣẹ́. Aposteli Paulu kọ̀wé pé: “Olúkúlùkù ni yoo ru ẹrù ti ara rẹ̀.” (Galatia 6:5, NW) Nígbà tí ó bá di ti sísan owó-orí, Kristian kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ tẹ́wọ́gba ẹrù-iṣẹ́ ti jíjẹ́ aláìlábòsí àti ṣíṣègbọràn sí òfin. Èyí kì í ṣe ọ̀ràn kan nínú èyí tí àwọn alàgbà ìjọ ti ń ṣàbójútó agbo lábẹ́ àbójútó wọn. (Fiwé 2 Korinti 1:24.) Wọn kì í lọ́wọ́ nínú àwọn ọ̀ràn owó-orí àyàfi bí àwọn ọ̀ràn ìwà-àìtọ́ wíwúwo kan, bóyá tí ó wémọ́ ìwà láìfí tí ń tinilójú nínú àwùjọ àdúgbò bá wá sí àfiyèsí wọn. Ní gbogbogbòò, èyí jẹ́ agbègbè kan nínú èyí tí Kristian kọ̀ọ̀kan ti ní ẹrù-iṣẹ́ fún lílo ẹ̀rí-ọkàn rẹ̀ tí a ti kọ́ dáradára láti fi àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ sílò. (Heberu 5:14) Èyí ní nínú mímọ̀ pé bíbu ọwọ́ lu ìwé àkọsílẹ̀ owó-orí kan—láìka ẹni yòówù tí ó kọ ọ́ sí—lè túmọ̀ sí gbólóhùn tí ó jẹmọ́ òfin pé o ti ka ìwé àkọsílẹ̀ náà o sì gbàgbọ́ pé ohun tí ń bẹ nínú rẹ̀ jẹ́ òtítọ́.a
Jẹ́ aláìlẹ́gàn. Àwọn Kristian alábòójútó gbọ́dọ̀ jẹ́ “aláìlẹ́gàn” kí wọ́n baà lè tóótun fún ipò wọn. Bákan náà, gbogbo ìjọ lódidi níláti jẹ́ aláìlẹ́gàn lójú Ọlọrun. (1 Timoteu 3:2; fiwé Efesu 5:27.) Nítorí náà wọ́n ń làkàkà láti di ìfùsì rere mú nínú ẹgbẹ́ àwùjọ, kódà nígbà tí ó bá kan ti sísan owó-orí. Jesu Kristi fúnraarẹ̀ fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ lọ́nà yìí. A bi Peteru ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ léèrè bí Jesu bá san owó-orí tẹ́ḿpìlì, ọ̀ràn kékeré kan tí ó wémọ́ dírákímà méjì. Nítòótọ́, owó-orí yìí kò kan Jesu, níwọ̀n bí tẹ́ḿpìlì náà ti jẹ́ ilé Bàbá rẹ̀ tí kò sì sí ọba tí í gbé owó-orí ka ọmọkùnrin òun tìkáraarẹ̀ lórí. Ohun tí Jesu náà sọ nìyẹn; síbẹ̀ ó san owó-orí náà. Níti tòótọ́, ó tilẹ̀ lo iṣẹ́ ìyanu láti pèsè owó tí wọ́n nílò! Èéṣe tí òun fi san owó-orí tí ó lómìnira yíyẹ láti máṣe san? Gẹ́gẹ́ bí Jesu fúnraarẹ̀ ti sọ, ó jẹ́ “kí a má baà mú wọn kọsẹ̀.”—Matteu 17:24-27, NW.b
Di Ìfùsì Rere tí Ń Bọlá fún Ọlọrun Mú
Bákan náà ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lónìí ń dù pé kí wọ́n máṣe mú àwọn ẹlòmíràn kọsẹ̀. Kò yanilẹ́nu, nígbà náà, pé lápapọ̀, wọ́n ń gbádùn ìfùsì rere kárí-ayé gẹ́gẹ́ bí ọlọ̀tọ̀ tí kò ní àbòsí, tí ń san owó-orí. Fún àpẹẹrẹ, ìwé agbéròyìnjáde lédè Spanish El Diario Vasco ṣàlàyé lórí yíyẹ owó-orí sílẹ̀ èyí tí ó gbilẹ̀ ní Spain, ṣùgbọ́n ó sọ pé: “Àyàfi kanṣoṣo tí ó wà [ni] ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Nígbà tí wọ́n bá ń rà tàbí ń tà, iye tí wọ́n bá pe [dúkìá] náà jẹ́ òtítọ́ pọ́ńbélé.” Bákan náà, ìwé agbéròyìnjáde ti United States San Francisco Examiner sọ ọ̀rọ̀ àkíyèsí ní àwọn ọdún díẹ̀ sẹ́yìn pé: “O lè ka [àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa] sí àwọn ọlọ̀tọ̀ àwòfiṣàpẹẹrẹ. Wọ́n fi ọwọ́ dan-in dan-in mú sísan owó-orí, ṣíṣètọ́jú àwọn aláìsàn, gbígbéjàko àìmọ̀-ọ́n-kọ mọ̀-ọ́n-kà.”
Kò sí Kristian tòótọ́ kan tí yóò fẹ́ láti ṣe ohunkóhun tí ó lè kó àbààwọ́n bá ìfùsì tí a jèrè nípasẹ̀ ìsapá aláápọn yìí. Bí yíyàn kan bá dojú kọ ọ́, ìwọ yóò ha jẹ́ dágbálé ohun tí yóò mú kí a mọ̀ ọ́ sí ẹni tí ń ṣe èrú nínú owó-orí nítorí àtitọ́jú owó díẹ̀ pamọ́ bí? Bẹ́ẹ̀kọ́. Ó dájú pé ìwọ yóò kúkú yàn láti pàdánù owó ju kí o kó èérí bá orúkọ rere rẹ̀ kí o sì mú kí àwọn ẹlòmíràn ní èrò òdì nípa àwọn ànímọ́ rere rẹ tàbí ìjọsìn Jehofa.
Nínú òtítọ́, dídi ìfùsì rere mú gẹ́gẹ́ bí olódodo, aláìlábòsí lè ná ọ ní owó ní àwọn ìgbà mìíràn. Gẹ́gẹ́ bí Plato onímọ̀ èrò-orí Griki ti ìgbàanì ti sọ ní ọ̀rúndún 24 sẹ́yìn: “Nígbà tí owó-orí lórí iye tí ń wọlé wá bá wà, ènìyàn tí ó jẹ́ olódodo yóò san àsanlé aláìṣòdodo yóò sì san àsandínkù lórí iye owó kan náà tí ń wọlé.” Ó ti lè fikún un pé ọkùnrin olódodo náà kò jẹ́ kábàámọ̀ láé nípa sísan iye náà nítorí jíjẹ́ olódodo. Kódà níní irú ìfùsì rere bẹ́ẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Èyí dájúdájú jẹ́ òtítọ́ nípa àwọn Kristian. Ìfùsì rere wọn ṣe iyebíye fún wọn nítorí pé ó ń bọlá fún Bàbá wọn ọ̀run ó sì ń ṣe ìrànlọ́wọ́ láti mú kí wọ́n fa àwọn ẹlòmíràn wá sí ojú ọ̀nà ìgbésí-ayé wọn àti sọ́dọ̀ Ọlọrun wọn, Jehofa.—Owe 11:30; 1 Peteru 3:1.
Ṣùgbọ́n, ju gbogbo rẹ̀ lọ, àwọn Kristian tòótọ́ fí ojú tí ó ṣeyebíye wo ipò-ìbátan wọn pẹ̀lú Jehofa. Ọlọrun ń rí gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe, wọ́n sì ní ìfẹ́-ọkàn láti mú inú rẹ̀ dùn. (Heberu 4:13) Nítorí náà, wọn kọ ìdẹwò náà láti gbìyànjú láti rẹ́ ìjọba jẹ. Wọ́n mọ̀ pé Ọlọrun ní inúdídùn nínú ìwà ìdúróṣinṣin, tí kò ní àbòsí. (Orin Dafidi 15:1-3) Níwọ̀n bí wọ́n sì ti fẹ́ láti mú ọkàn-àyà Jehofa láyọ̀, wọ́n ń san gbogbo owó-orí tí wọ́n jẹ.—Owe 27:11; Romu 13:7.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Èyí lè gbé ìpèníjà kan dìde fún àwọn Kristian tí wọ́n bá ní àkọsílẹ̀ owó-orí lórí àpapọ̀ iye tí ń wọlé pẹ̀lú alábàáṣègbéyàwó kan tí ó jẹ́ aláìgbàgbọ́. Kristian aya kan yóò ṣe ìsapá tọkàntọkàn láti mú ìlànà ipò-orí náà wà déédéé pẹ̀lú àìní náà láti ṣègbọràn sí òfin owó-orí ti Kesari. Àmọ́ ṣáá o, ó níláti mọ̀ nípa àbájáde tí ó lè jẹyọ níti ọ̀ràn òfin bí ó bá mọ̀ọ́mọ̀ bu ọwọ́ lu ìwé àkọsílẹ̀ kan tí ó ní èrú nínú.—Fiwé Romu 13:1; 1 Korinti 11:3.
b Lọ́nà tí ó dùnmọ́ni, Matteu ni ìwé Ìhìnrere kanṣoṣo náà tí ó ṣe àkọsílẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ yìí nínú ìgbésí-ayé Jesu lórí ilẹ̀-ayé. Gẹ́gẹ́ bí agbowó-orí kan tẹ́lẹ̀rí, kò sí iyèméjì pé Matteu fúnraarẹ̀ ni ìṣarasíhùwà Jesu nínú ọ̀ràn yìí wú lórí.