ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 11/22 ojú ìwé 4-8
  • Àjàkálẹ̀ Àrùn ní Ọ̀rúndún Ogún

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àjàkálẹ̀ Àrùn ní Ọ̀rúndún Ogún
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Àrùn Àtijọ́ Ń Ṣèparun Lọ́nà Púpọ̀ Sí I
  • Àrùn àti Ipò Òṣì
  • Àwọn Àrùn Tí A Ṣẹ̀ṣẹ̀ Mọ̀
  • Àwọn Ohun Tí Ń Jẹ́ Kí Kòkòrò Àrùn Lè Ríni Gbé Ṣe
  • Àwọn Kòkòrò Àrùn Ń Gbẹ̀san
    Jí!—1996
  • Ayé Kan Níbi Tí Kò Ti Ní Sí Àrùn
    Jí!—2004
  • Ibi Táráyé Ṣẹ́gun Àrùn Dé àti Ibi Tó Kù Sí
    Jí!—2004
  • Ọjọ́ Pẹ́ Táráyé Ti Ń Gbógun Ti Àrùn
    Jí!—2004
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 11/22 ojú ìwé 4-8

Àjàkálẹ̀ Àrùn ní Ọ̀rúndún Ogún

ÀJÀKÁLẸ̀ àrùn Black Death tí ó ṣẹlẹ̀ ní ọ̀rúndún kẹrìnlá ní Yúróòpù kò mú ayé wá sópin, gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ ènìyàn ṣe sọ tẹ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n àkókò tiwa ńkọ́? Ǹjẹ́ àwọn àìsàn àti àrùn tí ń gbèèràn lọ́jọ́ wa fi hàn pé a ń gbé ní àkókò tí Bíbélì pè ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” bí?—Tímótì Kejì 3:1.

O lè ronú pé, ‘dájúdájú kò rí bẹ́ẹ̀.’ Àwọn ìtẹ̀síwájú ìmọ̀ ìṣègùn àti ti sáyẹ́ǹsì ti ṣe ohun púpọ̀ láti ràn wá lọ́wọ́ láti lóye, kí a sì gbógun ti àrùn nísinsìnyí ju ìgbàkígbà nínú ìtàn ẹ̀dá ènìyàn lọ. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì nípa ìṣègùn ti ṣe onírúurú oògùn agbógunti-kòkòrò-àrùn àti abẹ́rẹ́ àjẹsára—àwọn ohun ìjà lílágbára tí a fi ń gbéjà ko àwọn àrùn àti àwọn kòkòrò tí ń fà wọ́n. Mímú ọ̀nà tí a ń gbà ṣètọ́jú àwọn aláìsàn, ọ̀nà tí a ń gbà sọ omi di aláìléèérí, ọ̀nà ìṣèmọ́tótó, àti ọ̀nà tí a ń gbà gbọ́únjẹ sunwọ̀n sí i ti ṣèrànwọ́ nínú ogun tí a ń bá àwọn àrùn tí ń gbèèràn jà.

Ní ẹ̀wádún díẹ̀ sẹ́yìn, ọ̀pọ̀ ènìyàn rò pé ìjàkadì náà ti fẹ́rẹ̀ẹ́ parí. A ti mú àrùn ìgbóná kúrò pátápátá, a sì ti dájú sọ àwọn àrùn míràn tí a óò mú kúrò pátápátá. Àìmọye àmódi ni oògùn ti ṣẹ́gun lọ́nà gbígbéṣẹ́. Àwọn amọṣẹ́-ìlera-dunjú ń fi ẹ̀mí pé nǹkan-yóò-dára wo ọjọ́ iwájú. A óò borí àwọn àrùn tí ń gbèèràn; ọ̀kọ̀ọ̀kan ni a óò ṣẹ́gun wọn. Ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì nípa ìṣègùn ni yóò borí.

Síbẹ̀, kò borí. Lónìí, àrùn tí ń gbèèràn ni ó ṣì ń pa ènìyàn jù lọ, ó pa àwọn ènìyàn tí iye wọn lé ní 50 mílíọ̀nù ní 1996 nìkan. Ìdààmú tí ń pọ̀ sí i nípa ọjọ́ iwájú ti rọ́pò ẹ̀mí nǹkan-yóò-dára tí a ní tẹ́lẹ̀ rí. Ìwé ìléwọ́ náà, The World Health Report 1996, tí Àjọ Ìlera Àgbáyé (WHO) ṣe, kìlọ̀ pé: “Ọ̀pọ̀ lára ìtẹ̀síwájú tí a ti ní nínú mímú ìlera ẹ̀dá ènìyàn sunwọ̀n sí i ní àwọn ẹ̀wádún àìpẹ́ yìí ti wà nínú ewu báyìí. A wà ní bèbè ìṣòro àrùn tí ń gbèèràn káàkiri àgbáyé. Kò sí orílẹ̀-èdè tí ó mórí bọ́.”

Àwọn Àrùn Àtijọ́ Ń Ṣèparun Lọ́nà Púpọ̀ Sí I

Ohun kan tí ń fa ìdààmú ni pé àwọn àrùn tí a mọ̀ dunjú, tí a rò pé a ti ṣẹ́gun tẹ́lẹ̀ rí, ti ń pa dà wá ní àwọn ọ̀nà tí ó túbọ̀ ń ṣèparun, tí ó sì túbọ̀ ṣòro láti wò sàn. Àpẹẹrẹ kan ni ikọ́ ẹ̀gbẹ, àrùn tí a rò pé ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí mọ́ ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti gòkè àgbà. Àmọ́ ikọ́ ẹ̀gbẹ kò lọ; nísinsìnyí, ó ń pa nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́ta ènìyàn lọ́dọọdún. Bí a kò bá mú àwọn ìgbésẹ̀ àtikápá rẹ̀ sunwọ̀n sí i, nǹkan bí 90 mílíọ̀nù ènìyàn ni a retí pé yóò ní àrùn náà ní àwọn ọdún 1990. Ikọ́ ẹ̀gbẹ tí oògùn kò ràn ń gbèèràn ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè.

Àpẹẹrẹ àrùn míràn tí ó tún ń pa dà wá ni ibà. Ní 40 ọdún sẹ́yìn, àwọn dókítà ní ìrètí títètè mú ibà kúrò pátápátá. Lónìí, àrùn náà ń pa nǹkan bíi mílíọ̀nù méjì ènìyàn lọ́dọọdún. Ibà fìdí kalẹ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè tí iye wọn lé ní 90, ó sì ń wu ìpín 40 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn olùgbé ayé léwu. Àwọn oògùn apakòkòrò kò tún ran àwọn ẹ̀fọn tí ń gbé kòkòrò àrùn ibà kiri mọ́, àwọn kòkòrò àrùn náà fúnra wọn sì ti di èyí tí oògùn kò ràn mọ́ débi tí àwọn dókítà fi ń bẹ̀rù pé àwọn oríṣi ibà kan lè di èyí tí kò ṣeé wò sàn rárá láìpẹ́.

Àrùn àti Ipò Òṣì

Àwọn àrùn míràn ń pani láìdẹwọ́ láìka ti pé a ní àwọn ohun gbígbéṣẹ́ tí a fi ń gbéjà kò wọ́n sí. Fún àpẹẹrẹ, ronú nípa àrùn lọ́rùnlọ́rùn. Àwọn abẹ́rẹ́ àjẹsára tí ó lè dènà àrùn lọ́rùnlọ́rùn wà, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn oògùn tí a lè fi wò ó sàn wà. Ó bẹ́ sílẹ̀ ní apá ìsàlẹ̀ Sàhárà ilẹ̀ Áfíríkà ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1996. Bóyá o kò gbọ́ ohun púpọ̀ nípa rẹ̀; síbẹ̀, ó pa ju 15,000 ènìyàn lọ—ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn jẹ́ àwọn tálákà àti àwọn ọmọdé.

Àwọn àrùn ní apá ìsàlẹ̀ àwọn ẹ̀yà ọ̀nà èémí, títí kan òtútù àyà, ń pa mílíọ̀nù mẹ́rin ènìyàn lọ́dọọdún, ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn jẹ́ ọmọdé. Èéyi ń pa mílíọ̀nù kan ọmọdé lọ́dọọdún, ikọ́ àwúbì sì ń pa 355,000 míràn sí i. Ọ̀pọ̀ lára àwọn tí ń kú wọ̀nyí pẹ̀lú ni a lè tipasẹ̀ àwọn abẹ́rẹ́ àjẹsára tí kò wọ́n gba ẹ̀mí wọn là.

Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ ọmọdé ni àrùn ìgbẹ́ gbuuru tí ń gbẹ omi lára ń pa lójoojúmọ́. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo àwọn tí ń kú wọ̀nyí ni a lè gba ẹ̀mí wọn là nípa ṣíṣèmọ́tótó tàbí omi mímu mímọ́tónítóní tàbí nípa lílo àpòpọ̀ ohun mímu fún ìdápadà omi ara.

Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ikú wọ̀nyí ń ṣẹlẹ̀ ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, níbi tí ipò òṣì ti pọ̀ yanturu. Nǹkan bí 800 mílíọ̀nù ènìyàn—ìwọ̀n tí ó pọ̀ díẹ̀ lára iye àwọn olùgbé ayé—ni kò ní àǹfààní ìtọ́jú àìsàn. Ìwé ìléwọ́ The World Health Report 1995 sọ pé: “Ohun tí ń ṣekú pani jù lọ lágbàáyé, tí ó sì jẹ́ okùnfà títóbijùlọ fún àìlera àti ìjìyàn jákèjádò àgbáyé ni ó fẹ́rẹ̀ẹ́ kẹ́yìn nínú àkọsílẹ̀ Ìsọ̀rí Àwọn Àrùn Lágbàáyé. Òun ni wọ́n fún ní àmì náà, Z59.5—ipò òṣì paraku.”

Àwọn Àrùn Tí A Ṣẹ̀ṣẹ̀ Mọ̀

Síbẹ̀, àwọn àrùn míràn ṣẹ̀ṣẹ̀ dé ni, ẹnu àìpẹ́ yìí ni a mọ̀ wọ́n. Àjọ WHO sọ láìpẹ́ yìí pé: “Láàárín 20 ọdún tó kọjá, ó kéré tán àwọn àrùn tuntun tí iye wọn jẹ́ 30 ti yọjú láti wu ìlera ọgọ́rọ̀ọ̀rún mílíọ̀nù ènìyàn léwu. Ọ̀pọ̀ lára àwọn àrùn wọ̀nyí ni a kò ní ìtọ́jú, ìwòsàn tàbí abẹ́rẹ́ àjẹsára fún, àǹfààní àtiṣèdíwọ́ fún wọn tàbí kí a kápá wọn sì láàlà.”

Fún àpẹẹrẹ, ṣàgbéyẹ̀wò fáírọ́ọ̀sì HIV àti àrùn AIDS. A kò mọ̀ wọ́n ní nǹkan bí ọdún 15 péré sẹ́yìn, ní báyìí wọ́n ti ń pọ́n àwọn ènìyàn gbogbo kọ́ńtínẹ́ǹtì lójú. Ní lọ́wọ́lọ́wọ́, nǹkan bí 20 mílíọ̀nù àgbàlagbà ti kó fáírọ́ọ̀sì HIV, ó sì lé ní mílíọ̀nù 4.5 ènìyàn tí ó ti ní àrùn AIDS. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìléwọ́ náà, Human Development Report 1996, ti sọ, àrùn AIDS ló ń pa àwọn àgbàlagbà tí wọn kò tó ẹni ọdún 45 jù lọ ní Yúróòpù àti Àríwá Amẹ́ríkà. Jákèjádò ayé, nǹkan bí 6,000 ènìyàn ló ń ràn lójoojúmọ́—ẹnì kan láàárín ìṣẹ́jú àáyá 15. Ìfojúdíwọ̀n ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú fi hàn pé ńṣe ni iye ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn AIDS yóò máa yára pọ̀ sí i. Gẹ́gẹ́ bí ilé iṣẹ́ kan ní United States ti sọ, a retí pé tí ó bá máa di ọdún 2010, ìpíndọ́gba àkókò tí ẹnì kan lè retí láti wà láàyè mọ ní àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Áfíríkà àti Éṣíà tí àrùn AIDS ti ń jà jù yóò lọ sílẹ̀ sí ọdún 25.

Àrùn AIDS ha jẹ́ irú àrùn aláìlẹ́gbẹ́ kan, àbí àwọn àrùn míràn tí ó lè dá aburú tí ó jọra tàbí tí ó tilẹ̀ burú jù bẹ́ẹ̀ lọ lè bẹ́ sílẹ̀ ni? Àjọ WHO dáhùn pé: “Láìsí àní-àní, àwọn àrùn tí a kò tí ì mọ̀ nísinsìnyí, àmọ́ tí wọ́n lè wá di aṣèparun gan-an bí àrùn AIDS lọ́jọ́ iwájú, ṣì ń bọ̀.”

Àwọn Ohun Tí Ń Jẹ́ Kí Kòkòrò Àrùn Lè Ríni Gbé Ṣe

Èé ṣe tí àwọn ògbóǹkangí nínú iṣẹ́ ìlera fi ń dààmú nípa ìbẹ́sílẹ̀ àwọn àìsàn tí kò tí ì dé? Ìdí kan ni kíkún tí àwọn ìlú ńlá ń kún sí i. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, kìkì nǹkan bí ìpín 15 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn olùgbé ayé ní ń gbé àwọn ìlú ńlá. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, a ti méfò pé, tí ó bá máa di ọdún 2010, yóò lé ní ìdajì lára àwọn ènìyàn tí ń gbé ayé tí yóò máa gbé ní àwọn ìlú ńlá, ní pàtàkì ní àwọn ìlú ńlá tí wọ́n tóbi gan-an ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn kò tí ì gòkè àgbà.

Àwọn kòkòrò aṣokùnfà-àrùn máa ń gbèrú ní àwọn àgbègbè tí ó kún àkúnya. Bí ìlú ńlá kan bá ní ètò ilé gbígbé tí ó dára títí kan ti ìdàdọ̀tínù àti ìpèsè omi tí ó tẹ́rùn àti ti àbójútó ìlera tí ó dára, ewu ìbẹ́sílẹ̀ àìsàn yóò dín kù. Àmọ́ àwọn ìlú ńlá ní àwọn orílẹ̀-èdè tí kò lọ́rọ̀ ní ń yára kún. Àwọn ìlú ńlá kan ní ilé ìyàgbẹ́ kan péré fún ìpín 750 ènìyàn tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ọ̀pọ̀ àwọn ìlú ńlá kò tún ní ètò ilé gbígbé tí ó dára àti omi mímu tí kò léèérí àti àwọn ohun èlò ìṣègùn tí ó dára. Ó rọrùn gan-an láti tètè kó àrùn níbi tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún ènìyàn ti ń gbé pọ̀ níbi tí ó kún fọ́fọ́, ní àyíká onídọ̀tí.

Èyí ha túmọ̀ sí pé ìbẹ́sílẹ̀ àìsàn lọ́jọ́ iwájú yóò mọ sí àwọn ìlú ńlá títóbi tí ipò òṣì wà, tí ó sì kún àkúnya bí? Ìwé ìròyìn náà, Archives of Internal Medicine, dáhùn pé: “A gbọ́dọ̀ lóye ní tòótọ́ pé àwọn ibi àdádó tí ipò òṣì lílégbákan, ipò ọrọ̀ ajé tí kò láyọ̀lé, àti àwọn àbájáde wọn ti gbilẹ̀ ń fàyè tí ó pọ̀ jù lọ gba àkóràn àìsàn láti gbèrú dáradára, kí ó sì borí ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ ìyókù ìran aráyé.”

Kò rọrùn láti ká àrùn mọ́ àgbègbè kan. Ọ̀pọ̀ ènìyàn ń ṣí kiri. Lójoojúmọ́, nǹkan bíi mílíọ̀nù kan ènìyàn ń ti orílẹ̀-èdè kan lọ sí òmíràn. Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, mílíọ̀nù kan ènìyàn ń lọ káàkiri orílẹ̀-èdè tí ó tòṣì àti orílẹ̀-èdè ọlọ́rọ̀. Bí àwọn ènìyàn ti ń kó kiri, àwọn kòkòrò àrùn gbẹ̀mígbẹ̀mí ń bá wọ́n lọ. Ìwé ìròyìn The Journal of the American Medical Association ṣàlàyé pé: “A gbọ́dọ̀ ka ìbẹ́sílẹ̀ àrùn níbikíbi sí ewu fún ọ̀pọ̀ jù lọ orílẹ̀-èdè, ní pàtàkì àwọn ibi tí àwọn ènìyàn jákèjádò ayé máa ń lọ jù lọ.”

Nípa bẹ́ẹ̀, láìka ìtẹ̀síwájú tí a ti ní nínú ìmọ̀ ìṣègùn ní ọ̀rúndún ogún sí, àwọn àjàkálẹ̀ àrùn ṣì ń gba ẹ̀mí ọ̀pọ̀ ènìyàn, àwọn ènìyàn púpọ̀ sì ń bẹ̀rù pé èyí tí ó burú jù lọ ṣì ń bọ̀. Ṣùgbọ́n kí ni Bíbélì sọ nípa ọjọ́ iwájú?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 4]

Àrùn tí ń gbèèràn ni ó ṣì ń pa ènìyàn jù lọ, ó kéré tán, ó pa ènìyàn tí ó lé ní 50 mílíọ̀nù ní 1996 nìkan

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]

Oògùn Agbógunti Kòkòrò Àrùn Kò Ràn Wọ́n

Ó túbọ̀ ń ṣòro láti wo ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àrùn tí ń rànnìyàn sàn nítorí pé àwọn oògùn agbógunti kòkòrò àrùn kò ràn wọ́n. Ohun tí ń ṣẹlẹ̀ nìyí: Tí àwọn bakitéríà bá wọ ara ẹnì kan, wọ́n máa ń bí sí i lọ́pọ̀lọpọ̀, tí wọ́n sì ń tàtaré àwọn ànímọ́ àbùdá wọn sí àwọn ọmọ wọn. Pẹ̀lú ìmújáde ọmọ bakitéríà tuntun kọ̀ọ̀kan, ìyípadà lè ṣẹlẹ̀ nínú apilẹ̀ àbùdá—àṣìṣe díẹ̀ nínú ìmújáde ọmọ bakitéríà tí yóò fún bakitéríà tuntun náà ní ànímọ́ tuntun. Kò fi bẹ́ẹ̀ ṣeé ṣe pé ìyípadà yóò ṣẹlẹ̀ nínú apilẹ̀ àbùdá bakitéríà kan lọ́nà tí yóò mú kí oògùn agbógunti kòkòrò àrùn má ràn án. Ṣùgbọ́n àwọn bakitéríà máa ń bí ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù ọmọ, nígbà míràn, wọ́n máa ń bí ìran ọmọ mẹ́ta láàárín wákàtí kan. Ohun tí ó jọ pé kò lè ṣẹlẹ̀ yóò wá ṣẹlẹ̀—bakitéríà kan tí ó ṣòro láti fi oògùn agbógunti kòkòrò àrùn pa máa ń wáyé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan.

Nítorí náà, nígbà tí ẹni tí ó wà lára rẹ̀ náà bá lo oògùn agbógunti kòkòrò àrùn, àwọn bakitéríà tí oògùn ràn yóò kú dà nù, ó sì ṣeé ṣe kí ẹni náà gbádùn díẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn bakitéríà tí oògùn kò ràn ń wà nìṣó. Ṣùgbọ́n nísinsìnyí wọn kò gbọ́dọ̀ máa bá àwọn kòkòrò àrùn ẹlẹgbẹ́ wọn jìjàkadì fún àwọn èròjà aṣaralóore àti ibùgbé. Kò sí ohun tí ń dí wọn lọ́wọ́ láti bímọ rẹpẹtẹ. Níwọ̀n bí bakitéríà kan ti lè gbèrú di mílíọ̀nù 16 bakitéríà láàárín ọjọ́ kan ṣoṣo, kò ní pẹ́ tí ẹni náà yóò tún ṣàìsàn. Bí ó ti wù kí ó rí, oríṣi bakitéríà tí oògùn tí ó yẹ kí ó pa á kò ràn ti wà lára ẹni náà báyìí. Àwọn bakitéríà yí tún lè wọ ara àwọn ẹlòmíràn, kí apilẹ̀ àbùdá rẹ̀ sì tún tètè yí pa dà di èyí tí àwọn oògùn agbógunti kòkòrò àrùn míràn kò ràn.

Ọ̀rọ̀ olótùú kan nínú ìwé ìròyìn náà, Archives of Internal Medicine, sọ pé: “Kì í ṣe nípa pé bóyá a óò pòfo nínú ogun tí ènìyàn ń bá àwọn kòkòrò àrùn jà yí ni ìṣẹ̀lẹ̀ tuntun ayárakánkán ti ríràn tí àwọn ohun èlò àti ìlànà ìṣègùn lọ́ọ́lọ́ọ́ tí a fi ń ṣètọ́jú kò ran àwọn bakitéríà, fáírọ́ọ̀sì, kòkòrò fungi, àti kòkòrò àfòmọ́ ń múni ṣe kàyéfì nípa rẹ̀, àmọ́ nípa ìgbà tí yóò jẹ́.”—Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 7]

Díẹ̀ Lára Àwọn Àrùn Tuntun Tí Ń Gbèèràn Láti 1976

Ọdún Orúkọ Àrùn Ibi Tí Àwọn Àrùn Ti

Tí A Mọ̀ Ọ́n Kọ́kọ́ Ṣẹlẹ̀ Tàbí Tí

A Ti Mọ̀ Wọ́n

1976 Àrùn legionnaire United States

1976 Àrùn kòkòrò àfòmọ́ United States

cryptosporidiosis

1976 Àrùn àsun-ùndá ẹ̀jẹ̀ Ebola Zaire

1977 Fáírọ́ọ̀sì hantaan Korea

1980 Àrun mẹ́dọ̀wú ìpele D (Delta) Ítálì

1980 Fáírọ́ọ̀sì human T-cell Japan

lymphotropic

1981 Àrùn AIDS United States

1982 Bakitéríà E. coli O157:H7 United States

1986 Àrùn dìgbòlugi màlúù United Kingdom

1988 Bakitéríà salmonella United Kingdom

enteritidis PT4

1989 Àrùn mẹ́dọ̀wú ìpele C United States

1991 Àrùn àsun-ùndá ẹ̀jẹ̀ ti Venezuela Venezuela

1992 Bakitéríà kọ́lẹ́rà O139 Íńdíà

1994 Àrùn àsun-ùndá ẹ̀jẹ̀ ti Brazil Brazil

1994 Fáírọ́ọ̀sì morbillivirus Australia

lára ènìyàn àti ẹṣin

*Àwọn ẹranko nìkan ló ṣẹlẹ̀ sí.

[Credit Line]

Orísun: Àjọ WHO

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 8]

Àwọn Àrùn Àtijọ́ Tún Pa Dà Wá

Ikọ́ ẹ̀gbẹ: Ó lé ní 30 mílíọ̀nù ènìyàn tí a retí pé ikọ́ ẹ̀gbẹ yóò pa ní ẹ̀wádún yìí. Nítorí pé àwọn alárùn náà kò rí ìtọ́jú tó látẹ̀yìnwá, ikọ́ ẹ̀gbẹ tí oògùn kò ràn ti wá di ewu jákèjádò ayé. Àwọn oògùn tí ń pa bakitéríà náà nígbà kan rí kò tún ran àwọn oríṣi kan mọ́ nísinsìnyí.

Ibà: Lọ́dọọdún, àìsàn yí ń ṣe àwọn ènìyàn tí ó tó 500 mílíọ̀nù, ó sì ń pa mílíọ̀nù 2. Àìsí oògùn àti àṣìlò oògùn ti ń ṣèdíwọ́ fún kíkápá rẹ̀. Ní àbáyọrí rẹ̀, àwọn oògùn tí ń pa àwọn kòkòrò àfòmọ́ àrùn ibà nígbà kan kò tún ràn wọ́n mọ́. Ohun tí ó tún ń mú ìṣòro náà burú sí i ni ti àwọn ẹ̀fọn tí oògùn ẹ̀fọn kò ràn.

Kọ́lẹ́rà: Kọ́lẹ́rà ń pa 120,000 ènìyàn lọ́dọọdún, pàápàá jù lọ ní Áfíríkà, níbi tí ìbẹ́sílẹ̀ àìsàn náà ti gbilẹ̀ tí ó sì ń ṣe lemọ́lemọ́ sí i. Kọ́lẹ́rà tí wọn kò mọ̀ ní Gúúsù Amẹ́ríkà fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún bẹ́ sílẹ̀ ní Peru ní 1991, ó sì ti ń gbèèràn káàkiri kọ́ńtínẹ́ǹtì náà láti ìgbà náà wá.

Àrùn dengue: Fáírọ́ọ̀sì tí ẹ̀fọn ń gbé kiri yìí ń pọ́n àwọn ènìyàn tí a fojú díwọ̀n sí 20 mílíọ̀nù lójú lọ́dọọdún. Láàárín ọdún 1995, ìbẹ́sílẹ̀ àrùn dengue tí ó tí ì burú jù lọ ní Látìn Amẹ́ríkà àti àwọn ilẹ̀ Carib láàárín ọdún 15 kọ lu orílẹ̀-èdè 14, ó kéré tán. Ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn dengue ń pọ̀ sí i nítorí pé àwọn ìlú ńlá ń kún sí i, àwọn ẹ̀fọn tí ń gbé àrùn dengue kiri ń tàn kálẹ̀, ọ̀pọ̀ lára àwọn tí ó ti ràn sì ń ṣí kiri.

Akọ èfù: Ètò fífún gbogbo ènìyàn ní abẹ́rẹ́ àjẹsára tí ó bẹ̀rẹ̀ ní 50 ọdún sẹ́yìn mú kí àrùn yí ṣọ̀wọ́n gan-an ní àwọn orílẹ̀-èdè onílé-iṣẹ́ ẹ̀rọ ńláńlá. Síbẹ̀síbẹ̀, láti 1990, ìbẹ́sílẹ̀ àrùn akọ èfù ti wáyé ní orílẹ̀-èdè 15 ní ìhà Ìlà Oòrùn Yúróòpù àti ní Soviet Union tẹ́lẹ̀ rí. Ó tó ìdá kan nínú 4 tó kú lára àwọn tí wọ́n kó àrùn náà. Ní ìbẹ̀rẹ̀ apá àkọ́kọ́ ọdún 1995, nǹkan bí 25,000 ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn náà ni a ròyìn.

Àrùn ẹṣẹ́ lymph wíwú: Láàárín 1995, ó kéré tán, 1,400 ìṣẹ̀lẹ̀ ìyọnu àjàkálẹ̀ tí ó ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀dá ènìyàn ni a ròyìn fún Àjọ Ìlera Àgbáyé (WHO). Ní United States àti àwọn ibòmíràn, àrùn náà ti gbèèràn dé àwọn àgbègbè tí kò ti sí ìyọnu àjàkálẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún.

[Credit Line]

Orísun: Àjọ WHO

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Láìka ìtẹ̀síwájú tí a ti ní nínú ìmọ̀ ìṣègùn sí, ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì nípa ìṣègùn kò tí ì lè dá ìtànkálẹ̀ àwọn àrùn tí ń gbèèràn dúró

[Credit Line]

Fọ́tò àjọ WHO tí J. Abcede yà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Àrùn tètè máa ń gbèèràn bí àwọn ènìyàn bá ń gbé ibi tí ó kún fọ́fọ́, ní àyíká onídọ̀tí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Nǹkan bí 800 mílíọ̀nù ènìyàn tí ń gbé ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà ni kò ní àǹfààní rírí ìtọ́jú àìsàn gbà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́