Ọjọ́ Pẹ́ Táráyé Ti Ń Gbógun Ti Àrùn
ÌPÍNLẸ̀ New York ni Joanne ń gbé, ó sì lárùn ìkọ́ fée. Ṣùgbọ́n irú ikọ́ fée tó ń ṣe é yìí yàtọ̀. Ó lárùn kan tó máa ń yí apilẹ̀ àbùdá èèyàn padà, tí ò sì gbóògùn, ìlàjì àwọn tí àrùn yìí bá kọlù ló sì máa ń pa. Àmọ́, Joanne kì í lọ tọ́jú ara rẹ̀ wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́, ó sì ti kó ikọ́ fée ran ọ̀pọ̀ èèyàn nígbà kan rí. Inú bí dókítà rẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tó fi sọ pé: ‘Ńṣe ló yẹ kí wọ́n wábi tì í mọ́.’
Ọjọ́ pẹ́ tí ikọ́ fée ti ń pààyàn. Bá a bá kà á ní méní méjì, ó ti tó àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn tí àrùn yìí ti mú tó sì ti pa A rí ẹ̀rí pé àrùn yìí ti jà rí lára àwọn òkú dídì tó wà nílẹ̀ Íjíbítì àti Peru ìgbàanì. Oríṣiríṣi ikọ́ fée tó tún padà sú yọ báyìí ń pa tó ọgọ́rùn-ún ọ̀kẹ́ èèyàn lọ́dọọdún.
Carlitos dùbúlẹ̀ sórí ibùsùn ní ahéré kan nílẹ̀ Áfíríkà, òógùn sì ń kán tó tó látorí rẹ̀. Àrùn ibà dá a gúnlẹ̀ débi tí ò tiẹ̀ lágbára láti ké pàápàá. Àwọn òbí rẹ̀ tí ṣìbáṣìbo ti bá ò rówó ra oògùn, kò sì sí ilé ìwòsàn alábọ́dé ní tòsí tí wọ́n lè gbé ọmọ wọn lọ fún ìtọ́jú. Ibà náà ò rọlẹ̀, ọmọ náà sì kú láàárín ọjọ́ méjì.
Bíi ti Carlitos, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àádọ́ta ọ̀kẹ́ ọmọdé tí ibà ń pa lọ́dọọdún. Láwọn abúlé tó wà ní Ìlà Oòrùn Áfíríkà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọdé làwọn ẹ̀fọn tó ń fa àrùn ibà ń jẹ nígbà àádọ́ta sí ọgọ́rin lóṣù. Àwọn ẹ̀fọn yìí ń tàn lọ síbi tí wọn ò sí tẹ́lẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì làwọn oògùn ibà ò fi bẹ́ẹ̀ ṣiṣẹ́ mọ́. Lọ́dọọdún àwọn tí ibà lílágbára ń ṣe máa ń tó ọ̀ọ́dúnrún mílíọ̀nù.
Lọ́dún 1980 ni Kenneth, ọkùnrin ẹni ọgbọ̀n ọdún kan, tó ń gbé ní ìlú San Francisco, ní ìpínlẹ̀ California kọ́kọ́ lọ rí dókítà rẹ̀. Ó sọ pé òun ń yàgbẹ́ gbuuru ó sì ń rẹ òun. Ọdún kan lẹ́yìn náà ló kú. Pẹ̀lú gbogbo báwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ oníṣègùn ṣe tọ́jú ẹ̀ tó, ńṣe ló ń rù tó ń gbẹ títí àrùn otútù àyà fi gbẹ̀mí ẹ̀.
Lọ́dún méjì lẹ́yìn ìyẹn, ohun kan náà bẹ̀rẹ̀ sí ṣe obìnrin kan lábúlé kan tó wà ní àríwá orílẹ̀-èdè Tanzania tó jìnnà tó ẹgbàájọ kìlómítà sí San Francisco. Lẹ́nu ọ̀sẹ̀ bí i mélòó kan péré, kò lè rìn mọ́, kò sì pẹ́ sígbà yẹn tó fi kú. Àwọn ará abúlé náà pe àràmàǹdà àrùn yìí ni àrùn Juliana nítorí wọ́n gbà pé ọkùnrin tó ń ta aṣọ tí wọ́n kọ orúkọ yẹn sí lára ló kó àrùn yìí ran obìnrin yìí àtàwọn obìnrin mìíràn ládùúgbò yẹn.
Àrùn kan náà ló pa Kenneth àti obìnrin ara Tanzania náà: àrùn ọ̀hún ni éèdì. Kété lẹ́yìn ọdún 1980, nígbà tó dà bíi pé ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ìṣègùn ti ṣẹ́pá ọ̀pọ̀ kòkòrò àrùn, làrùn tó ń ràn yìí wá bẹ̀rẹ̀ sí yọ aráyé lẹ́nu. Iye tí àrùn éèdì pa láàárín ogún ọdún tó iye tí àrùn kan tó la ilẹ̀ Yúróòpù àti Éṣíà kọjá ní ọ̀rúndún kẹrìnlá pa—àwọn ará ilẹ̀ Yúróòpù ò lè gbàgbé ìpakúpa tí àrùn náà pa wọ́n láé.
Àrùn Adápàádúdú
Ọdún 1347 la lè sọ pé àjàkálẹ̀ àrún tí wọ́n ń pè ní Àrùn Adápàádúdú, ìyẹn Black Death, bẹ̀rẹ̀ sí jà nígbà tí ọkọ̀ ojú omi kan láti erékùṣù Crimea gúnlẹ̀ sí ìlú Messina ní erékùṣù Sicily. Yàtọ̀ sí ẹrù tí ọkọ̀ ojú omi náà sábà máa ń kó wá, òun àti àrùn yìí ni wọ́n jọ wá lọ́tẹ̀ yìí.a Láìpẹ́ àjàkálẹ̀ àrùn yìí tàn káàkiri orílẹ̀-èdè Ítálì.
Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, Agnolo di Tura, ará ìlú Siena, lórílẹ̀-èdè Ítálì ṣàpèjúwe ohun tí àrùn náà fojú wọn rí nílùú rẹ̀, ó sọ pé: ‘Oṣù May làrùn ọ̀hún bẹ̀rẹ̀ sí pa àwọn ara Siena. Àjàkálẹ̀ àrùn burúkú gbáà ni. Pọ̀ọ́ pọ̀ọ́ ló ń pa àwọn tó bá kọ lù lojú ẹsẹ̀. Ṣe ló ń pa wọ́n lókìtì lókìtì, tọ̀sán tòru.’ Ó fi kún un pé: ‘Ọwọ́ ara mi báyìí ni mo fi gbé àwọn ọmọ mi márùn-ún sin, bẹ́ẹ̀ náà làwọn ẹlòmíì ṣe ń sin ọmọ tiwọn náà. Ẹni yòówù tí ì báà kú mọ́ wọn lọ́wọ́, kò sẹ́ni tó sunkún nítorí pé olúkúlùkù ń dúró de ikú tiẹ̀ ni. Òkú sùn lọ débí pé gbogbo wa rò pé òpin ayé ti dé nìyẹn.’
Àwọn òpìtàn kan sọ pé láàárín ọdún mẹ́rin, àjàkálẹ̀ àrùn náà ti tàn káàkiri ilẹ̀ Yúróòpù, nǹkan bí ìdámẹ́ta àwọn tó wà níbẹ̀ ló sì bá a rìn, àfàìmọ̀ kí wọ́n máà tó ogún mílíọ̀nù sí ọgbọ̀n mílíọ̀nù. Kódà, ó fẹ̀mí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣòfò ní ìyànníyàn ilẹ̀ Iceland. Wọ́n ní iye àwọn èèyàn tó wà ní orílẹ̀-èdè Ṣáínà, tó wà ní Ìpẹ̀kun Ìlà Oòrùn ayé dín kù láti mílíọ̀nù mẹ́tàlélọ́gọ́fà níbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kẹtàlá sí mílíọ̀nù márùndínláàádọ́rin ní ọ̀rúndún kẹrìnlá, kò sì lè ṣẹ̀yìn àjàkálẹ̀ àrùn yìí àti ìyàn tó bá a rìn.
Kò tíì sí àjàkálẹ̀ àrùn, ogun, tàbí ìyàn tó tíì fa ìjìyà tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ rí. Ìwé náà, Man and Microbes sọ pé: “Àjàkálẹ̀ àrùn tó tún burú tó báyìí ò tí ì ṣẹlẹ̀ rí látijọ́ aláyé ti dáyé. Àwọn tó ṣègbé pọ̀ tó ìdámẹ́rin sí ìdajì àwọn ará Yúróòpù, Àríwá Áfíríkà, àtàwọn ibì kan ní Éṣíà.”
Àwọn èèyàn tó wà ní gbogbo ilẹ̀ àti erékùṣù tó wà lágbègbè Amẹ́ríkà ò lùgbàdì àrùn Adápàádúdú nítorí pé wọ́n jìnnà sáwọn orílẹ̀-èdè tó kù láyé. Ṣùgbọ́n àwọn ọkọ̀ ojú omi kiri àrùn dé ọ̀dọ̀ wọn nígbà tó yá. Ní Ìwọ̀ Oòrùn Ìlàjì Ayé, àrùn kan bẹ́ sílẹ̀ ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún tó fẹ̀mí àwọn èèyàn ṣòfò ju àjàkálẹ̀ àrùn yìí lọ.
Àrùn Olóde Bo Àgbègbè Tó Wà Káàkiri Amẹ́ríkà
Nígbà tí Columbus dé sí erékùṣù West Indies lọ́dún 1492, ó ṣàpèjúwe àwọn ara ibẹ̀ bí àwọn èèyàn tó ‘dùn ún wò, tára wọ́n jí pépé, tí wọ́n ga níwọ̀nba tí wọ́n sì taagun.’ Bí ara wọ́n ṣe jí pépé yẹn ni kò jẹ́ káyé mọ̀ pé àwọn àrùn tó ń jà ní Ìlà Oòrùn Ìlàjì Ayé lè kọlu àwọn náà.
Lọ́dún 1518 àrùn olóde bẹ́ sílẹ̀ ní erékùṣù Hispaniola. Àwọn ará àgbègbè Amẹ́ríkà ò gbúròó àrùn olóde rí, nígbà tó wá jà níbẹ̀, ó pa rẹ́kẹrẹ̀kẹ sí wọn lára. Ará Sípéènì kan tí ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn ṣojú ẹ̀ ṣírò ẹ̀ pé kò lè ju ẹgbẹ̀rún kan èèyàn tó rù ú là ní erékùṣù náà. Kò pẹ́ tí àrùn náà fi dé Mẹ́síkò àti Peru, bó sì ṣe ń pa wọ́n lẹ́yọrọ lẹ́yọrọ níbẹ̀ náà nìyẹn.
Ní ọ̀rúndún tó tẹ̀lé e, nígbà táwọn arìnrìn àjò tí wọ́n tẹ̀dó sí ìlú Plymouth lọ́dún 1620 dé sí àgbègbè Massachusetts ní Àríwá Amẹ́ríkà, wọ́n rí i pé àrùn olóde ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pa gbogbo àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà tán. Aṣáájú àwọn arìnrìn-àjò náà, John Winthrop kọ̀wé pé: “Gbogbo àwọn ará ìlú yẹn ni olóde ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pa tán.”
Àwọn àjàkálẹ̀ àrùn mìíràn tún yọjú lẹ́yìn olóde. Ìwé kan sọ pé ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn tí Columbus dé, àwọn àrùn táwọn èèyàn kó wá láti ibòmíì pa ìdámẹ́sàn-án nínú mẹ́wàá àwọn tó ń gbé Ìwọ̀ Oòrùn Ìlàjì Ayé. Iye àwọn èèyàn tó ń gbé ní Mẹ́síkò ti dín kù láti ọgbọ̀n mílíọ̀nù sí mílíọ̀nù mẹ́ta, ti Peru sì dín kù láti mílíọ̀nù mẹ́jọ sí mílíọ̀nù kan. Kì í ṣe àwọn tó wà lágbègbè Amẹ́ríkà nìkan làrùn olóde bá jà ṣá o. Ìwé náà, Scourge—The Once and Future Threat of Smallpox sọ pé: “Láti inú ìtàn ẹ̀dá ènìyàn, àrùn olóde ti pa ọgọ́rọ̀ọ̀rún mílíọ̀nù èèyàn, iye tó pa ju àpapọ̀ iye àwọn tó kú látàrí àjàkálẹ̀ àrùn àti gbogbo ogun tí wọ́n jà ní ọ̀rúndún ogún lọ.”
Aráyé Ò Tíì Ṣẹ́gun Àrùn
Lóde òní, gbogbo ohun tí olóde fojú aráyé rí lè dà bí àjálù kan tó ti dọ̀rọ̀ ìtàn. Ní ọ̀rúndún ogún, aráyé ti ṣẹ́gun ọ̀pọ̀ àrùn tí kòkòrò ń fà, pàápàá jù lọ láwọn orílẹ̀-èdè tí ilé iṣẹ́ pọ̀ sí. Àwọn dókítà mọ nǹkan tó ń fa èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn àrùn, wọ́n sì ti rí ọ̀nà láti wò wọ́n. (Wo àpótí tó wà nísàlẹ̀ yìí.) Ńṣe lọ̀pọ̀ àjẹsára àti oògùn apakòkòrò inú ń ṣiṣẹ́ bí ajẹ́bíidán, wọ́n ń pa àwọn àrùn tí kì í tètè lọ pàápàá.
Àmọ́ ṣá, Dókítà Richard Krause, tó fìgbà kan rí jẹ́ alábòójútó Ibùdó fún Èèwọ̀ Ara àti Àwọn Àrùn Tó Ń Ràn ní Amẹ́ríkà sọ pé, “dandan lowó orí túláàsì laṣọ ìbora, bẹ́ẹ̀ náà lọ̀rọ̀ àjàkálẹ̀ àrùn rí.” Ikọ́ fée àti àrùn ibà ò tí ì kásẹ̀ nílẹ̀. Àrùn éèdì tó jẹ́ ṣẹ̀ṣẹ̀dé pẹ̀lú ń dún kùkùlajà mọ́ wa pé àrùn wà níbùba. Ìwé Man and Microbes sọ pé: “Àwọn àrùn tó ń ràn ló ń pààyàn jù lọ láyé; bí wọ́n á sì ṣe máa wà títí lọ nìyẹn.”
Àwọn dókítà kan ń bẹ̀rù pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ti kápá àrùn débi tó lápẹẹrẹ, gbogbo àṣeyọrí táwọn ń rí báyìí lè máà báwọn tálẹ́. Robert Shope tó jẹ́ onímọ̀ nípa àjàkálẹ̀ àrùn kìlọ̀ pé: “Ewu àwọn àjàkálẹ̀ àrùn ò tí ì kásẹ̀ nílẹ̀, ńṣe ló ń burú sí i.” Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e yìí yóò sọ ìdí ẹ̀.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Oríṣiríṣi ọ̀nà ni àjàkálẹ̀ àrùn yìí ń gbà yọjú, lára rẹ̀ ni èyí tó máa ń jẹ́ kí kókó so sára àti èyí tó máa ń ba ẹ̀dọ̀fóró jẹ́. Yọ̀rọ̀ ara èkúté ló ń tan èyí tó máa ń jẹ́ kí kókó so sára kálẹ̀ nígbà tó jẹ́ pé bí ẹni tó ní èyí tó máa ń ba ẹ̀dọ̀fóró jẹ́ lára bá ṣe ń wúkọ́ tàbí tó ń sín làrùn náà á ṣe máa tàn kálẹ̀.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 15]
Iye tí àrùn éèdì pa láàárín ogún ọdún tó iye tí àrùn kan tó la ilẹ̀ Yúróòpù àti Éṣíà kọjá ní ọ̀rúndún kẹrìnlá pa
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Ìyàtọ̀ Tó Wà Láàárín Ìmọ̀ àti Ìgbàgbọ́ Nínú Ohun Asán
Ní ọ̀rúndún kẹrìnlá, nígbà tí àrùn Adápàádúdú fẹ́ pa agboolé póòpù run ní ìlú Avignon, dókítà rẹ̀ sọ pé olórí ohun tó fa àjálù náà ni àwọn pílánẹ́ẹ̀tì mẹ́ta tí wọ́n dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ oòrùn—Sátọ̀n, Júpítà, àti Máàsì—tí ìrísí wọn dà bí ọ̀kan lára àwọn àmì ìwòràwọ̀.
Ní nǹkan bí irínwó ọdún lẹ́yìn náà, George Washington kó àrùn kan tó ń jẹ́ kí ọ̀nà ọ̀fun dùn ún. Àwọn ògbóǹtagí dókítà mẹ́ta tọ́jú àrùn yẹn nípa fífa jáálá ẹ̀jẹ̀ méjì lára rẹ̀. Láàárín wákàtí díẹ̀, ó kú. Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tàlá ọdún ni fífa ẹ̀jẹ̀ lára aláìsàn fi jẹ́ ọ̀nà pàtàkì tí wọ́n ń gbà tọ́jú aláìsàn, ìyẹn látìgbà ayé Hippocrates títí di ìdajì ọ̀rúndún kọkàndínlógún.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbàgbọ́ nínú ohun asán àti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ ṣèdíwọ́ fún ìtọ́jú ìṣègùn fúngbà díẹ̀, àwọn dókítà ti ṣiṣẹ́ kára láti rídìí ohun tó ń fa àwọn àrùn àti oògùn wọn. Ara àṣeyọrí díẹ̀ tí wọ́n ṣe la tò sísàlẹ̀ yìí.
◼ Olóde. Lọ́dún 1798, Edward Jenner ṣe oògùn àjẹsára kan tó lè dènà àrùn olóde. Ní ọ̀rúndún ogún, wọ́n ti ṣe ọ̀pọ̀ àjẹsára tó ń dènà àwọn àrùn míì bíi rọpárọsẹ̀, ibà pọ́njú, àti èéyí.
◼ Ikọ́ fée. Lọ́dún 1882, Robert Koch ṣàwárí kòkòrò bakitéríà tó ń fa ikọ́ fée, ó sì dán oògùn náà wò lára ẹni tó lárùn ọ̀hún. Ní nǹkan bí ọgọ́ta ọdún lẹ́yìn ìgbà náà wọ́n ṣàwárí oògùn apakòkòrò inú kan tí wọ́n ń pè ní streptomycin. Oògùn yìí pẹ̀lú wúlò gan-an fún ìtọ́jú ẹni tí àrùn tó ń jẹ́ kí kókó so síni lára bá ń yọ lẹ́nu.
◼ Ibà. Bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀rúndún kẹtàdínlógún, oògùn kan tó ń jẹ́ quinine tí wọ́n máa ń rí lára èèpo igi cinchona gbẹ̀mí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn tí àrùn ibà kọlù là. Lọ́dún 1897, Ronald Ross ṣàwárí rẹ̀ pé ẹ̀fọn kan tí wọ́n ń pè ní Anopheles ló ń kó àrùn ibà ran èèyàn, wọ́n sì ṣakitiyan láti dín ẹ̀fọn kù kí iye àwọn tí ibà ń pa láwọn ilẹ̀ olóoru lè dín kù.
[Àwọn àwòrán]
Àtẹ ìsọfúnni “zodiac” (lókè) àti fífa ẹ̀jẹ̀ lára aláìsàn
[Credit Line]
Méjèèjì: Biblioteca Histórica “Marqués de Valdecilla”
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Lónìí, bí ikọ́ fée ṣe tún padà wá yìí, ó ń pa tó ọgọ́rùn ọ̀kẹ́ èèyàn lọ́dún
[Àwọn Credit Line]
X ray: Ibùdó Tí Ìjọba Dá Sílẹ̀ fún Títọ́jú Ikọ́ Fée ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìṣègùn Ìlú New Jersey ọkùnrin: Fọ́tò: WHO/Thierry Falise
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Àwòrán àtọdúnmọ́dún kan tí wọ́n yà nílẹ̀ Jámánì láti bí ọdún 1500, níbi tí dókítà ti wọ ìbòjú láti fi dènà àrùn Adápàádúdú. Ìkó ara ìbòjú náà ní lọ́fíńdà nínú
[Credit Line]
Godo-Foto
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Kòkòrò bakitéríà tó ń fa àrùn tó máa ń jẹ́ kí kókó so síni lára
[Credit Line]
Gary Gaugler/Visuals Unlimited