Àwọn Igbó Àìro Di Pápá Ìṣekúpa Àwọn Labalábá Monarch
NÍGBÀ ìṣíkiri àgbàyanu kan nígbà ẹ̀ẹ̀rùn yẹn ní Kánádà àti ní ìhà àríwá United States, àwọn labalábá monarch na apá wọn aláwọ̀ ọsàn òun dúdú, wọ́n sì rọ́ kúrò ní Kánádà, gba United States kọjá, wọ́n sì kóra jọ sí ẹkùn ilẹ̀ kan ní ìwọ̀ oòrùn Ìlú Ńlá Mexico. Níbẹ̀, ní 1986, ìjọba Mexico gbé àwọn igbó àìro márùn-ún kalẹ̀ lórí àwọn òkè ńlá tí ó ga ní 3,400 mítà, tí àwọn igi fir bò. Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan tí a ṣe ní 1994 ṣe fi hàn, ó kéré tán, 60 mílíọ̀nù àwọn labalábá monarch ni wọ́n ń lo ìgbà òtútù wọn ní igbó àìro náà.
Àwọn labalábá monarch nífẹ̀ẹ́ sí àwọn igi fir, ní pàtàkì nítorí pé àwọn igi náà máa ń ní ibòji dídí tí ó máa ń dáàbò bo àwọn labalábá náà lọ́wọ́ òjò olótùútù àti òjò dídì. A ka gígé gẹdú léèwọ̀ nínú àwọn igbó àìro márùn-ún wọ̀nyí, ṣùgbọ́n ìyẹn kò dí gígé gẹdú láìbófin mu lọ́wọ́. Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa labalábá ń ṣàníyàn pé “bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ìjọba ti ka á léèwọ̀, gígé àwọn igi fir nínú àwọn igbó àìro Mexico ń jẹ́ kí àwọn ìjì líle àti òtútù túbọ̀ lè ṣèpalára fún àwọn labalábá monarch. . . . Pípàdánù àwọn igi àti ibòji wọn mú kí ó túbọ̀ ṣeé ṣe pé a óò fi ìdáàbòbò lọ́wọ́ òjò àti òjò dídì du àwọn labalábá náà.” Gígé gẹdú ń ba àwọn ibòji tí ń pèsè ààbò jẹ́. Bí Lincoln Brower, onímọ̀ nípa ẹranko ní Yunifásítì Florida, ní Gainesville, ti sọ nípa ìbòrí tí ń pèsè ààbò fún àwọn labalábá monarch pé: “Bí a bá ṣe ń gé àwọn ẹgàn lulẹ̀ tó ni ihò yóò máa pọ̀ sí i nínú ibòji tí ń pèsè ààbò tó.”
Ìwé agbéròyìnjáde The New York Times sọ pé: “Ojú ọjọ́ tí kò dára àti gígé àwọn igi máa ń ṣekú pa àwọn labalábá.” Ó wá ròyìn nípa ọ̀wààrà òjò dídì kan nínú igbó àìro náà ní òru December 30, 1995, pé: “Àwọn aṣọ́gbó ìjọba àti àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nipa ohun alààyè tí wọ́n rìn kiri apá kan àwọn igbó àìro náà sọ pé àwọn òkìtì òjò dídì pẹ̀lú ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn labalábá monarch tó ti gan lórí wọn, àti ọ̀pọ̀ labalábá tí òjò dídì bò mọ́lẹ̀ ló wà káàkiri.”
Fọ́tò tí ó wà lókè ojú ìwé yìí jẹ́rìí sí ìtàn abaninínújẹ́ náà.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 31]
Jorge Nunez/Sipa Press