Ohun kan tí Àwọn Ọ̀dọ́ Nílò Lónìí
Ọmọdébìnrin ọlọ́dún 14 kan ní New Jersey, U.S.A., sọ pé ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yìí, òún ní àròkọ kan láti kọ nípa “Ìdí Tí Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Fi Ń Ṣèrú Nínú Ìdánwò.” Ó mú ìwé rẹ̀ náà, Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, lọ sí ilé ẹ̀kọ́ láti ṣèwádìí nínú rẹ̀. Ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ mú ìwé náà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ka àwọn àkọlé ìpín kókó ẹ̀kọ inú ìwé náà, bíi “Ibalopọ Takọtabo ati Ìwàrere” ati “Dídá Ọjọ Àjọròde, Ifẹ, àti Ẹ̀yà Òdìkejì.”
Akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ náà béèrè pé: “Ṣé o lè fún mi ní ìwé yìí”?
Akẹ́kọ̀ọ́ náà sọ pé: “Mo ṣàlàyé pé ẹ̀dà tèmi nìyí, ṣùgbọ́n pé n óò mú ọ̀kan wá fún un. Nígbà tí mo mú un lọ fún un, akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ mìíràn rí ìwé náà, ó sì ní kí n bá òun pẹ̀lú wá ọ̀kan. Láìpẹ́ láìjìnnà, mo kó ìwé Awọn Ọ̀dọ́ Béèrè mẹ́wàá wá fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n fẹ́ ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan.”
Akẹ́kọ̀ọ́, ọmọ ọdún 14 náà nímọ̀lára pé ìwé náà ṣeyebíye láti ní. Ó wí pé: “A nílò ìwé yìí ní tòótọ́ nítorí pé kò rọrùn rárá láti jẹ́ èwe lákòókò yìí.”
Bí ìwọ yóò bá fẹ́ láti ní ẹ̀dà kan ìwé Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́ tàbí tí o bá fẹ́ kí ẹnì kan ké sí ọ ní ilé rẹ láti jíròrò ìníyelórí ẹ̀kọ́ Bíbélì pẹ̀lú rẹ, jọ̀wọ́ kọ̀wé sí Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State, Nigeria, fún ìsọfúnni, tàbí sí àdírẹ́sì tí ó sún mọ́ ọ jù lọ lára àwọn tí a tò sí ojú ìwé 5.